Àwọn Kòkòrò Àrùn Ń Gbẹ̀san
Ọ̀RÚNDÚN ogún yìí ti rí àwọn ìlọsíwájú àgbàyanu nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, ẹ̀dá ènìyàn ti wà láìlólùgbèjà kúrò nínú ìjìyà lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà ní àárín àwọn ọdún 1930, nígbà tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàwárí sulfanilamide, èròjà àkọ́kọ́ tí ó lè ṣẹ́gun bakitéríà láìṣèpalára púpọ̀ jù fún ẹni tí ó ní èèràn lára.a
Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe àwọn egbòogi tuntun tí ó lágbára láti bá àwọn àrùn eléèràn jà—chloroquine lati gbéjà ko ibà àti àwọn oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn láti ṣẹ́pá otútù àyà, ibà scarlet, àti àwúbì. Nígbà tí ó di ọdún 1965, ohun tí ó lé ní 25,000 èròjà oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn yíyàtọ̀ síra ni a ti ṣe. Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ parí èrò sí pé àwọn àrùn tí ń bá bakitéríà rìn kì í tún ṣe ohun bàbàrà mọ́ tàbí ohun tí ń ru ọkàn-ìfẹ́ fún ìṣèwádìí sókè. Ó ṣe tán, ìdí wo la fi ní láti máa ṣèwádìí nípa àwọn àrùn tí kò ní pẹ́ tí wọn óò fi pòórá?
Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà lágbàáyé, àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tuntun ń dín iye àwọn tí èéyi, ṣegede, àti èéyi rubella ń pa kù lọ́nà àrà. Atótó arére nílé-lóko nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára rọpárọsẹ̀, tí a fi lọ́lẹ̀ ní 1955, ṣàṣeyọrí sí rere gan-an débi pé ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Europe àti Àríwá America lọ sílẹ̀ gan-an láti 76,000 ní ọdún yẹn sí ohun tí kò tó 1,000 ní 1967. Àrùn olóde, tí ó jẹ́ lájorí àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí, ni a fòpin sí yíká ayé.
Ọ̀rúndún yìí tún ti rí ìhùmọ̀ àwọn awò asọhun-kékeré-di-ńlá onígbì electron, ìhùmọ̀ tí ó lágbára gan-an débi pé ó máa ń jẹ́ kí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ rí àwọn fáírọ́ọ̀sì tí ó fi ìlọ́po mílíọ̀nù kan kéré sí èékánná ènìyàn. Irú àwọn awò asọhun-kékeré-di-ńlá bẹ́ẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìlọsíwájú mìíràn nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, ti mú kí ó ṣeé ṣe láti mọ ohun tí àwọn àrùn eléèràn jẹ́, kí a sì lè bá wọn jà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Ó Jọ Pé Ìṣẹ́gun Dájú
Gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí àwọn àwárí wọ̀nyí, àwùjọ àwọn elétò ìlera ní ìfọ̀kànbalẹ̀ púpọ̀. Àwọn egbòogi òde òní bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun àwọn kòkòrò àrùn tí ń fa àwọn àrùn eléèràn. Ó dá àwọn ènìyàn lójú pé ìṣẹ́gun tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yóò ní lórí kòkòrò àrùn kò ní falẹ̀, kì yóò láṣìṣe, yóò sì jẹ́ pátápátá! Wọ́n lérò pé bí ìwòsàn fún àrùn pàtó kan kò bá tí ì sí lárọ̀ọ́wọ́tó, yóò wà láìpẹ́.
Láti 1948 ni akọ̀wé àgbà orílẹ̀-èdè United States, George C. Marshall, ti yangàn pé ìjagunmólú lórí gbogbo àwọn àrùn eléèràn rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) tẹnu mọ́ ọn pé, ó lè máà pẹ́ tí ibà ilẹ̀ Asia yóò fi wá di àrùn kan “tí kò ní lájorí ìjẹ́pàtàkì kan mọ́.” Ní àárín àwọn ọdún 1960, èrò ìgbàgbọ́ náà pé sànmánì ìyọnu àti àjàkálẹ̀ àrùn ti kọjá tàn kálẹ̀ gan-an tí ọ̀gá àgbà àwọn oníṣẹ́ abẹ́ ni United States, William H. Stewart, fi wí fún àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera pé ó ti tó àkókò láti jáwọ́ nínú gbígbé ọ̀ràn àwọn àrùn eléèràn sọ́kàn.
Àwọn Àrùn Àtijọ́ Padà Wá
Bí ó ti wù kí ó rí, kò tí ì yá tí a óò jáwọ́ nínú gbígbé ọ̀ràn àwọn àrùn eléèràn sọ́kàn. Àwọn kòkòrò àrùn kò pòórá nínú pílánẹ́ẹ̀tì kìkì nítorí pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti hùmọ̀ àwọn egbòogi àti abẹ́rẹ́ àjẹsára. Dípò kí a ṣẹ́gun àwọn kòkòrò àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí tí a mọ̀ dunjú, wọ́n padà wá pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbẹ̀san tí ó lágbára! Ní àfikún, àwọn kòkòrò àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí mìíràn yọjú—àwọn kòkòrò àrùn tí àwọn dókítà kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn kòkòrò àrùn ti tẹ́lẹ̀ àti tuntun ń jà gùdù, wọ́n ń wu ìwàláàyè àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn léwu, wọ́n ń pọ́n ènìyàn lójú, wọ́n sì tilẹ̀ ń pa àwọn ènìyàn yíká ayé.
Àwọn àrùn panipani tí a lérò pé apá ti ká nígbà kan tún ti yọjú, agbára àtipani wọn tún ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó sì túbọ̀ ń ṣòro sí i láti fi egbòogi wò wọ́n. Àpẹẹrẹ kan ní ikọ́ àwúbì (TB). Ètò àjọ WHO sọ láìpẹ́ yìí pé: “Láti 1944, a ti ń lo àwọn egbòogi ikọ́ TB lọ salalu ní Japan, Àriwá America àti Europe láti dín àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ TB àti ikú kù lọ́nà tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìsapá láti kápá ikọ́ TB ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tí ì gòkè àgbà ni a ti pa tì, . . . tí èyí sì ń jẹ́ kí àrùn náà padà sí àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ léwu, tí ó sì ń gbógun ti egbòogi.” Ikọ́ TB òde òní, tí bakitéríà tí ó sá pamọ́ sínú ẹ̀dọ̀fóró, tí afẹ́fẹ́ ń gbé kiri, sábà máa ń ṣokùnfà, máa ń pa nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta ènìyàn lọ́dọọdún—iye tí ó lé ní 7,000 lójoojúmọ́. Nígbà tí ó bá fi máa di ọdún 2005, iye àwọn tí ń kú lè ti pọ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́rin lọ́dọọdún.
Àwọn panipani tẹ́lẹ̀ rí mìíràn ń pọ̀ sí i pẹ̀lú. Àrùn onígbáméjì ti tàn kálẹ̀ báyìí ní apá ibi púpọ̀ ní Africa, Asia, àti Latin America; ó ń pọ́n àwọn ènìyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i lójú, ó sì ń pa wọ́n. Oríṣi kan tí ó jẹ́ tuntun pátápátá ti yọjú ní Asia.
Ibà wórawóra, tí ẹ̀fọn Aëdes aegypti ń tàn ká, ń pọ̀ sí i pẹ̀lú; ó ń halẹ̀ mọ́ 2.5 bílíọ̀nù ènìyàn nísinsìnyí ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lé ní 100 yíká ayé. Láti àwọn ọdún 1950, irú àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí náà, tí ó jẹ́ tuntun, tí ó mú ìsun ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ ti yọjú, ó sì ti tàn ká gbogbo Ilẹ̀ Olóoru. A fojú díwọ̀n pé, ó ń pa 20,000 ènìyàn lọ́dọọdún. Bí ó ti rí ní ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àrùn onífáírọ́ọ̀sì, kò sí abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó lè dáàbò boni lọ́wọ́ àrùn náà, kò sì sí egbòogi tí a óò fi wò ó.
Ibà, tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fìgbà kan retí láti fòpin sí, ń pa nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì ènìyàn lọ́dọọdún nísinsìnyí. Ó túbọ̀ ń ṣòro sí i láti pa àwọn kòkòrò àrùn ibà àti ẹ̀fọn tí ń gbé wọn kiri.
Àwọn Àrùn Tuntun Tí Ń Ṣèparun
Bóyá èyí tí a mọ̀ jù lọ lára àwọn àrùn tuntun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń pọ́n ìran aráyé lójú ni àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí náà, AIDS. Fáírọ́ọ̀sì kan tí a kò mọ̀ ní nǹkan bí ọdún 12 sẹ́yìn ló ń fa àrùn tí kò gbóògùn yìí. Síbẹ̀, ní apá ìparí 1994, iye àwọn ènìyàn tí fáírọ́ọ̀sì náà ti ràn yíká ayé wà láàárín mílíọ̀nù 13 sí 15.
Àwọn àrùn eléèràn míràn tí a kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí ní nínú, àrùn hantavirus nínú ẹ̀dọ̀fóró. Ara òkété ni wọ́n ti máa ń kó o, ó fara hàn ní ìhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn United States, ó sì mú ikú lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó lé ní ìdajì lára èyí tí a mọ̀. Oríṣi méjì irú ibà tí ó mú ìsun ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́—tí àwọn méjèèjì jẹ́ tuntun, tí wọ́n sì ń mú ikú lọ́wọ́—ti yọjú ní Gúúsù America. Àwọn àrùn amúnifòyà míràn tún ti gbérí—àwọn fáírọ́ọ̀sì tí ń jẹ́ orúkọ tí a kò gbọ́ rí, tí ó ṣàjèjì—ibà Lassa, ibà Rift Valley, àkóràn Oropouche, ibà Rocio, àkóràn Q. Guanarito, kòkòrò àrùn VEE, kòkòrò àrùn monkeypox, àrùn Chikungunya, Mokola, Duvenhage, LeDantec, fáírọ́ọ̀sì Kyasanur Forest tí ń bá ọpọlọ jà, tí ó sì ń gbé fáírọ́ọ̀sì Semliki Forest kiri, ibà Crimean-Congo, fáírọ́ọ̀sì O’nyongnyong, fáírọ́ọ̀sì Sindbis, fáírọ́ọ̀sì Marburg, àrùn Ebola.
Èé Ṣe Tí Àwọn Àrùn Tuntun Fi Ń Yọjú?
Pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀ àti àwọn ohun èèlò tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn òde òní ní, èé ṣe tí ó fi ṣòro láti borí àwọn kòkòrò àrùn panipani? Ìdí kan ni ìlọkáàkiri àwọn ènìyàn òde òní lọ́nà púpọ̀ sí i. Àwọn ohun ìrìnnà òde òní lè tètè mú kí àjàkálẹ̀ àrùn àdúgbò kan lọ yíká ayé. Ìrìn àjò pẹ̀lú ọkọ̀ òfuurufú mú kí ó rọrùn fún àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí kan láti lọ jìnnà, bí ó ti sá pamọ́ sára ẹnì kan tí ó ní èèràn, láti ìhà ibì kan ní ayé sí ìhà èyíkéyìí mìíràn ní ayé láàárín wákàtí díẹ̀.
Ìdí kejì, tí ń fa ìtànkálẹ̀ àwọn kòkòrò àrùn, ni iye àwọn olùgbé ayé tí ń yára pọ̀ sí i—ní pàtàkì ní àwọn ìlú ńlá. Dájúdájú, pàǹtí máa ń pọ̀ pelemọ ní àwọn ìlú ńlá. Àwọn ike ìkóǹkansí àti táyà tí omi kún inú wọn máa ń wà nínú pàǹtí. Ní àwọn Ilẹ̀ Olóoru, ìyẹ́n máa ń yọrí sí ìsọdipúpọ̀ àwọn ẹ̀fọn tí wọ́n ń gbé àwọn àrùn panipani bí ibà, ibà pọ́njú, àti ibà wórawóra kiri. Ní àfikún sí i, gan-an gẹ́gẹ́ bí igbó kìjikìji ṣe lè ran iná lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùgbé púpọ̀ yamùrá ń pèsè ipò tí ó bára dé fún ìyáratànkálẹ̀ ikọ́ àwúbì, gágá, àti àwọn àrùn míràn tí afẹ́fẹ́ ń gbé kiri.
Ìdí kẹta tí ó mú kí àwọn kòkòrò àrùn náà máa padà wá ní í ṣe pẹ̀lú ìyípadà nínú ìwà ẹ̀dá ènìyàn. Àwọn kòkòrò àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, wọ́n sì ti tàn kálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni púpọ̀ ní ìwọ̀n tí kò láfiwé, èyí tí ó wọ́pọ̀ ní apá ìparí ọ̀rúndún ogún yìí. Àrùn AIDS wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan ni.b
Ìdí kẹrin tí ó fi ṣòro gan-an láti borí àwọn kòkòrò àrùn panipani ni pé, àwọn ènìyàn ti gbógun ti àwọn igbó ńlá àti àwọn igbó olójò. Òǹkọ̀wé Richard Preston sọ nínú ìwé rẹ̀ The Hot Zone pé: “Ìrújáde àrùn AIDS, àrùn Ebola, àti àwọn asúnnásí àrùn míràn tí ó ní ìpìlẹ̀ láti inú àwọn igbó olójò fara hàn bí ìyọrísí àdánidá tí pípa àwọn ohun abẹ̀mí àti àyíká wọn run ní ilẹ̀ olóoru ṣokùnfà. Àwọn fáírọ́ọ̀sì tí wọ́n rú jáde náà ń jáde wá láti àwọn apá ibi tí a ti ba ibùgbé àwọn ohun alààyè jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀pọ̀ lára wọn wá láti ibi igbó olójò ilẹ̀ olóoru tí a ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ . . . Àwọn igbó olójò ilẹ̀ olóoru ni ibi tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀dá orí pílánẹ́ẹ̀tì yìí ń gbé, tí ó ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn irú ẹ̀yà irúgbìn àti ẹranko lágbàáyé. Àwọn igbó olójò tún jẹ́ ibi ìtọ́júpamọ́ títóbi jù lọ fún àwọn fáírọ́ọ̀sì àgbáyé, níwọ̀n bí gbogbo ohun alààyè ti ní fáírọ́ọ̀sì lára.”
Àwọn ẹ̀dá ènìyàn wá tipa bẹ́ẹ̀ ní ìfarakanra sísún mọ́ra jù lọ pẹ̀lú àwọn kòkòrò àti àwọn ẹranko ẹlẹ́jẹ̀ lílọ́wọ́ọ́wọ́ tí àwọn fáírọ́ọ̀sì ń fi ara wọn ṣelé, tí wọ́n máa ń mú irú jáde, tí wọ́n sì máa ń kú síbẹ̀ láìsí ìpalára. Àmọ́ nígbà tí fáírọ́ọ̀sì náà bá “fò” láti ara ẹranko sí ara ènìyàn, fáírọ́ọ̀sì náà lè di gbẹ̀mígbẹ̀mí.
Ààlà Tí Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Ìṣègùn Ní
Àwọn ìdí mìíràn tí àwọn àrùn eléèràn fi ń padà wá lọ́nà gíga tan mọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn fúnra rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn bakitéríà ti ń pe àwọn oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn tí ń pa wọ́n nígbà kan rí níjà nísinsìnyí. Ní òdì kejì sí bí ó ṣe yẹ kí ó jẹ́, àwọn oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn fúnra wọn ti mú kí ipò yìí wáyé. Fún àpẹẹrẹ, bí oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn kan bá ń pa kìkì ìpín 99 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn bakitéríà tí ó léwu lára ẹni tí ó ní èèràn, ìpín kan nínú ọgọ́rùn-ún yòókù tí ó gbéjà ko àwọn oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn náà lè dàgbà, kí ó sì pọ̀ sí i nísinsìnyí, bí oríṣi èpò lílágbára lórí pápá kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gé.
Àwọn aláìsàn máa ń mú ìṣòro náà burú sí i nígbà tí wọn kò bá lo oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn tí dókítà wọn kọ fún wọn tán. Àwọn aláìsàn lè dáwọ́ lílo àwọn hóró egbòogi náà dúró gbàrà tí ara wọn bá ti ń yá díẹ̀díẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti lè ṣeé ṣe kí a ti pa àwọn kòkòrò àrùn tí kò lágbára jù lọ, àwọn tí wọ́n lágbára jù lọ máa ń là á já, tí wọ́n sì máa ń yára yọ́ kẹ́lẹ́ di púpọ̀. Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, àrùn náà máa ń yọjú padà, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, ó wá le jù, ó sì lè máà gbóògùn. Nígbà tí àwọn oríṣi kòkòrò àrùn tí ń gbógun ti egbòogi bẹ́ẹ̀ bá kọlu àwọn ẹlòmíràn, ó máa ń yọrí sí ìṣòro ìlera líle koko láàárín àwọn ará ìlú.
Àwọn ògbógi nínú ètò àjọ WHO sọ láìpẹ́ yìí pé: “Kíká tí agbára [àwọn oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn àti àwọn asúnnásí agbógunti kòkòrò tín-íntìn-ìntín mìíràn] kò ká àwọn kòkòrò àrùn mọ́ ń ràn kálẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kíká tí agbára onírúurú egbòogi kò sì ká kòkòrò àrùn mọ́ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà jẹ́ kí àwọn dókítà rọ́wọ́ yọ nínú títọ́jú àwọn àrùn tí ń pọ̀ sí i. Ní àwọn ilé ìwòsàn nìkan, èèràn bakitéríà tí a fojú díwọ̀n sí mílíọ̀nù kan ń yọjú lójoojúmọ́ yíká ayé, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn sì jẹ́ èyí tí agbára egbòogi kò ká.”
Ìfàjẹ̀sínilára, tí a ń lò lọ́nà gíga sí i láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, ti mú kí ó rọrùn láti tan àwọn àrùn eléèràn kálẹ̀ pẹ̀lú. Lójú àwọn ìsapá tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe láti má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ní àwọn kòkòrò àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí, lọ́nà tí ó ga, ìfàjẹ̀sínilára ti dá kún ìtànkálẹ̀ àrùn rẹ́kórẹ́kó, cytomegalovirus, àwọn bakitéríà tí agbaŕa oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn kò ká, ibà, ibà pọ́njú, àrùn Chagas, àrùn AIDS, àti ọ̀pọ̀ àwọn àrùn mìíràn tí ń múni fòyà.
Bí Àwọn Nǹkan Ti Rí Lónìí
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn ti nírìírí ìbúrẹ́kẹ́ ìmọ̀ láàárín ọ̀rúndún yìí, àwọn àdììtú púpọ̀ ṣì wà. C. J. Peters ṣèwádìí nípa àwọn kòkòrò àrùn eléwu ní Àwọn Ibùdó fún Ìkáwọ́ Òkùnrùn, ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó mú ipò iwájú jù lọ nínú ìlera ara America. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ní May 1995, ó sọ nípa àrùn Ebola pé: “A kò mọ ìdí tí ó fi lóró lọ́nà líle koko lórí ènìyàn bẹ́ẹ̀, a kò sì mọ ohun tí ó ń ṣe [tàbí] ibi tí ó wà, nígbà tí kò bá tí ì fa ìtànkálẹ̀ wọ̀nyí. A kò rí i. Kò sí ìdílé fáírọ́ọ̀sì míràn . . . tí a kò mọ̀kan nípa rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀.”
Kódà bí ìmọ̀ ìṣègùn, egbòogi, àti àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó gbéṣẹ́ bá wà láti bá àrùn jà, a nílò owó láti fi wọ́n fún àwọn tí wọ́n nílò rẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ní ń gbé nínú ipò òṣì. Àkọsílẹ̀ ìròyìn World Health Report 1995 ti ètò àjọ WHO sọ pé: “Ipò òṣì ni lájorí ìdí tí a kì í fi í fún àwọn ọmọdé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára, ìdí tí a kì í fi í fún àwọn ènìyàn ní omi dáradára, kí a sì mú wọn wà ní tónítóní, ìdí tí àwọn egbòogi aṣèwòsàn-àrùn àti àwọn ìtọ́jú mìíràn kò fi sí lárọ̀ọ́wọ́tó . . . Lọ́dọọdún ni 12.2 mílíọ̀nù àwọn ọmọdé tí wọn kò tí ì pé ọmọ ọdún 5 ń kú ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ láti ọwọ́ àwọn okùnfà tí a lè fi ìwọ̀nba owó díẹ̀ ré kúrò lórí ọmọ kọ̀ọ̀kan. Wọ́n ń kú ní ti gidi nítorí pé aráyé kò kọbi ara sí wọn, ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n ń kú nítorí pé wọ́n jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́.”
Ní ọdún 1995, àwọn àrùn eléèràn àti àwọn àfòmọ́ ni panipani tí ó pọ̀ jù lọ lágbàáyé, tí ń gbọn ìwàláàyè mílíọ̀nù 16.4 ènìyàn dà nù lọ́dọọdún. Ó bani nínú jẹ́ pé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn ń gbé nínú àwọn ipò tí ó ṣẹnuure fún yíyọjú àti ìtànkálẹ̀ àwọn kòkòrò àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí. Ronú nípa ipò apanilẹ́kún náà lónìí. Ó lé ní bílíọ̀nù kan ènìyàn tí ń gbé nínú ipò òṣì pátápátá. Ìdajì lára gbogbo àwọn olùgbé ayé ni kò ní ọ̀nà àtirí ìtọ́jú ìṣègùn àti àwọn egbòogi pàtàkì gbà déédéé. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ tí a pa tì ní ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri lójú pópó ní àwọn ìlú ńlá fàkìàfàkìà, ọ̀pọ̀ lára wọn ń gún ara wọn lábẹ́rẹ́ oògùn líle, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ń lálàṣí ní àwọn àgọ́ tí ó dọ̀tí láàárín àrùn onígbáméjì, ìgbẹ́ ọ̀rìn, àti àwọn àrùn míràn.
Nínú ogun tí ènìyàn ń bá kòkòrò àrùn jà, ipò nǹkan ti gbe àwọn kòkòrò àrùn lọ́nà púpọ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Sulfanilamide jẹ́ ohun àpòpọ̀ oníyọ̀ tí a fi ṣe àwọn egbòogi agbógunti bakitéríà ní ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Àwọn egbòogi agbógunti bakitéríà lè ṣèdíwọ́ fún ìdàgbàsókè bakitéríà, tí yóò sì jẹ́ kí àwọn ìṣiṣẹ́ agbára ìdènà ara pa bakitéríà náà.
b Àpẹẹrẹ àwọn àrùn mìíràn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré: Jákèjádò ayé, nǹkan bíi mílíọ̀nù 236 ènìyàn ni èèràn trichomoniasis ti ràn, nǹkan bíi mílíọ̀nù 162 ènìyàn sì ni èèràn chlamydia ti ràn. Lọ́dọọdún, nǹkan bíi mílíọ̀nù 32 ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun ti wọ́n-ọ̀nwọ́n-ọ̀n tí ń yọ níbi ẹ̀yà ìbímọ, mílíọ̀nù 78 ìṣẹ̀lẹ̀ àtọ̀sí, mílíọ̀nù 21 ìṣẹ̀lẹ̀ herpes níbi ẹ̀yà ìbímọ, mílíọ̀nù 19 ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ́kórẹ́kó, àti mílíọ̀nù 9 ìṣẹ̀lẹ̀ chancroid.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Ní àwọn ilé ìwòsàn nìkan, èèràn bakitéríà tí a fojú díwọ̀n sí mílíọ̀nù kan ń yọjú lójoojúmọ́ yíká ayé, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn sì jẹ́ èyí tí agbára egbòogi kò ká.” Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Nígbà Tí Àwọn Kòkòrò Àrùn Jà Padà
Kòkòrò àrùn kan tí a mọ̀ sí bakitéríà “wọn iye tí ó kére tó gíráàmù 0.00000000001. Ẹja àbùùbùtán aláwọ̀ búlúù tẹ̀wọ̀n tó nǹkan bí 100,000,000 gíráàmù. Síbẹ̀, bakitéríà kan lè pa àbùùbùtán kan.”—Bernard Dixon, 1994.
Lára àwọn bakitéríà tí a bẹ̀rù jù lọ tí a máa ń rí ní àwọn ilé ìwòsàn ni àwọn oríṣi Staphylococcus aureas tí agbára egbòogi kì í sábà ká jù lọ. Àwọn oríṣi yìí máa ń pọ́n àwọn aláìsàn àti aláìlera lójú, tí ó sì ń fa èèràn gbẹ̀mígbẹ̀mí inú ẹ̀jẹ̀, òtútù àyà, àti ìkìmọ́lẹ̀ tí èròjà onímájèlé ń fà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣirò kan ti wí, bakitéríà staph ń pa nǹkan bí 60,000 ènìyàn ní United States lọ́dọọdún—iye tí ó pọ̀ ju àwọn tí ń kú nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ lọ. Láàárín ọdún bíi mélòó kan, àwọn oríṣi bakitéríà wọ̀nyí ti di èyí tí agbára oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn kò ká mọ́ gan-an débi pé ní 1988, oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn kan ṣoṣo péré ni ó lè bá wọn jà, ìyẹn egbòogi tí ń jẹ́ vancomycin. Bí ó ti wù kí ó rí, kò pẹ́ kò jìnnà tí àwọn ìròyìn nípa oríṣi àwọn kan tí agbára vancomycin náà kò ká tún bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú jákèjádò ayé.
Síbẹ̀, kódà nígbà tí àwọn oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn bá ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ kí wọ́n ṣe, àwọn ìṣòro mìíràn máa ń dìde. Ní àárín ọdún 1993, Joan Ray lọ sí ilé ìwòsàn kan ní United States fún iṣẹ́ abẹ ráńpẹ́ kan. Ó retí pé òun yóò padà sílé láàárín ọjọ́ bíi mélòó kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ó lò ní ilé ìwòsàn jẹ́ ọjọ́ 322, ní pàtàkì, nítorí èèràn tí ó kó lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ. Àwọn dókítà bá èèràn náà jà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn, títí kan vancomycin, ṣùgbọ́n agbára rẹ̀ kò ká àwọn kòkòrò àrùn náà. Joan sọ pé: “N kò lè gbé ọwọ́ mi méjèèjì. N kò lè gbé ẹsẹ̀ mi méjèèjì. . . . N kò tilẹ̀ lè gbé ìwé láti kà.”
Àwọn dókítà jà fitafita láti wádìí ohun tí ó fà á tí Joan fi ń ṣàìsàn síbẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n ti lo oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn fún un fún ọ̀pọ̀ oṣù. Iṣẹ́ tí wọ́n ṣe níbi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fi hàn pé, ní àfikún sí àkóràn bakitéríà staph, Joan ní irú bakitéríà míràn nínú ara rẹ̀—enterococcus tí agbára vancomycin kò ká. Bí orúkọ rẹ̀ ti fi hàn, vancomycin kò ṣèpalára kankan fún bakitéríà yìí; ó tún jọ pé agbára gbogbo oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn mìíràn kò ká a.
Àwọn dókítà náà kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan tí ó yà wọ́n lẹ́nu. Kì í ṣe pé agbára egbòogi tí ó yẹ kí ó pa bakitéríà náà kò ká a nìkan ni, ṣùgbọ́n ní òdì kejì ohun tí wọ́n retí, ohun tí ó wulẹ̀ ń ṣe ní ti gidi ni pé ó ń lo vancomycin láti máa ṣara rindin! Dókítà tí ń tọ́jú Joan, amọṣẹ́dunjú nínú ìtọ́jú àrùn eléèràn, sọ pé: “[Bakitéríà náà] nílò vancomycin yẹn kí ó lè máa pọ̀ sí i, bí wọn kò bá sì ní i, wọn kò ní dàgbà. Nítorí náà, lọ́nà kan ṣá, wọn ń lo vancomycin náà gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ ni.”
Nígbà tí àwọn dókítà náà kò fún Joan ní vancomycin mọ́, bakitéríà náà kú, ara Joan sì ń yá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn kòkòrò àrùn máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ bí àwọn aláìsàn kò bá lo oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn bó ti yẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìfàjẹ̀sínilára máa ń tan àwọn kòkòrò àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí kálẹ̀