Fáírọ́ọ̀sì Panipani Kọ Lu Zaire
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ ÁFÍRÍKÀ
KIKWIT, Zaire, jẹ́ ìlú onílé gátagàta létí igbó kìjikìji ilẹ̀ olóoru kan. Gaspard Menga Kitambala, ẹni ọdún 42 tí ń gbé ẹ̀yìn odi ìlú náà, nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú ìdílé rẹ̀. Menga máa ń ta èédú. Inú igbó jìngunjìngun ló sì ti máa ń lọ sun èédú rẹ̀, tí yóò dì í pọ̀, tí yóò sì fi orí rù ú wá sí Kikwit.
Ni January 6, 1995, ara rẹ̀ kò dá. Ó ṣubú lẹ́ẹ̀mejì nínú igbó nígbà tí ó ń bọ̀ wálé. Nígbà tí ó délé, ó sọ pé òún ní ibà àti ẹ̀fọ́rí.
Àìlera rẹ̀ le sí i láàárín ọjọ́ mélòó kan sí i. Ní January 12, ìdílé rẹ̀ gbé e lọ sí Ilé Ìwòsàn Gbogboǹṣe Kikwit. Àwọn Ẹlẹ́rìí nínú ìjọ tí Menga wà ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti bójú tó o ní ilé ìwòsàn. Ó bani nínú jẹ́ pé, àìlera rẹ̀ burú sí i. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í pọ ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ ń dà yàà jáde ní imú àti etí rẹ̀. Ní January 15, ó kú.
Kò pẹ́ rárá tí àwọn mìíràn nínú ìdílé Menga tí wọ́n ti fọwọ́ kan ara rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ àìsàn. Nígbà tí yóò fi di ìbẹ̀rẹ̀ oṣù March, ẹni 12 lára àwọn ìbátan tímọ́tímọ́ Menga ti kú, títí kan ìyàwó rẹ̀ àti méjì lára àwọn ọmọ wọn mẹ́fà.
Nígbà tí oṣù April yóò fi dé ìdajì, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn àti àwọn ẹlòmíràn ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, wọ́n sì ń kú bíi ti Menga àti ìdílé rẹ̀. Ní kíámọ́sá, àìsàn náà ti tàn dé ìlú méjì míràn ní ẹkùn náà. Ní kedere, wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ láti ibòmíràn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Muyembe, ògbólógbòó onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa fáírọ́ọ̀sì ní Zaire, lọ sí Kikwit ní May 1. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Jí! pé: “A parí èrò sí pé àjàkálẹ̀ àrùn méjì ló ń bá Kikwit jà: àrunṣu tí bakitéríà ń fà, èkejì sì ní ibà sùnjẹ̀sùnjẹ̀ tí fáírọ́ọ̀sì ń fà. Àmọ́ ṣáá o, a gbọ́dọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dájúdájú pé àwọn àrùn yìí ni. Nítorí náà, a gba ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ lára àwọn agbàtọ́jú, a sì fi ránṣẹ́ fún àyẹ̀wò ní Àwọn Ibùdó Ìṣàbójútó Àrùn (CDC) ní Atlanta, U.S.A.”
Ibùdó CDC fìdí ohun tí Muyembe àti àwọn dókítà mìíràn ní Zaire ti fura sí tẹ́lẹ̀ múlẹ̀. Àrùn Ebola ni.
Àrùn Panipani
Fáírọ́ọ̀sì Ebola lóró púpọ̀ jù. Ó lè yára pani. Kò ní abẹ́rẹ́ àjẹsára, bẹ́ẹ̀ ni a kò mọ ìtọ́jú kankan fún àwọn tó bá kọ lù.
A mọ Ebola fún ìgbà àkọ́kọ́ ní 1976. Orúkọ odò kan ní Zaire ni wọ́n fi sọ ọ́, àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ ní ìhà gúúsù Sudan àti ní ìhà àríwá Zaire láìpẹ́ lẹ́yìn náà. Ó bẹ́ sílẹ̀ ní ráńpẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i ní 1979 ní Sudan. Lẹ́yìn ìyẹn, yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn mélòó kan tí àwọn àmì àrùn tí ó jọ ti Ebola ń pa, àrùn náà pòórá fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Ìṣọwọ́pani fáírọ́ọ̀sì Ebola le tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ń ṣèwádìí rẹ̀ ní Atlanta fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ibi ìwádìí aláàbò gíga jù lọ tí a kọ́ pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ àfẹ́yíká afẹ́fẹ́ tí kò lè gba kòkòrò àrùn tí afẹ́fẹ́ ń gbé ká kankan láyè láti jáde. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà máa ń gbé “aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ko àgbéròfurufú” tí ń dáàbò boni wọ̀, kí wọ́n tó wọ ibi ìwádìí náà. Bí wọ́n ti ń jáde níbẹ̀ ni wọ́n ń fi oògùn apakòkòrò àrùn wẹ̀. Agbo àwọn oníṣègùn tí ó wá sí Kikwit di ìhámọ́ra àwọn nǹkan adáàbòboni—àwọn ìbọ̀wọ́ àti ìbòrí tí ó ṣeé dà nù, àwọn awò ojú àti àwọn àkànṣe aṣọ tí ń bo gbogbo ara, tí kò lè fàyè gba fáírọ́ọ̀sì náà láti kanni lára.
Ó yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé Kikwit tí kò ní ìmọ̀ àti ohun èèlò tí wọ́n lè fi dáàbò bo ara wọn. Àwọn mìíràn ń mọ̀ọ́nmọ̀ fi ìwàláàyè wọn wewu, tàbí pàdánù rẹ̀ ní bíbójú tó àwọn olólùfẹ́ wọn tí ń ṣàìsàn. Àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí máa ń gbé àwọn aláìsàn àti àwọn òkú pọ̀n sẹ́yìn tàbí kọ́ èjìká láìsí ohun adáàbòboni kankan. Àbájáde rẹ̀ jẹ́ ìpàdánù ìwàláàyè lọ́nà bíbùáyà; fáírọ́ọ̀sì náà run ọ̀pọ̀ ìdílé lódindi.
Kíkápá Ìṣẹ̀lẹ̀ Náà
Gbogbo àgbáyé dáhùn padà sí ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ Kikwit fún ìrànwọ́ nípa pípèsè ẹ̀bùn owó àti ohun èèlò ìṣègùn. Àwùjọ àwọn olùwádìí wá láti Europe, Gúúsù Áfíríkà, àti United States. Ète méjì ni wọ́n bá wá: àkọ́kọ́, láti bá wọn kápá ìṣẹ̀lẹ̀ náà; àti èkejì, láti ṣàwárí ibi tí fáírọ́ọ̀sì náà ń gbé láàárín àkókò àjàkálẹ̀ kan sí òmíràn.
Láti dá àjàkálẹ̀ àrùn náà dúró, àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ń kiri ojúlé láti ṣàwárí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àwọn àmì àrùn náà. Wọ́n kó àwọn tí ń ṣàìsàn lọ sí ilé ìwòsàn, níbi tí a ti lè yà wọ́n kúrò lára àwọn ẹlòmíràn kí a sì tọ́jú wọn láìséwu. A fi àwọn abala láílọ́ọ̀nù wé àwọn tí ó kú, a sì sìnkú wọn ní kíámọ́sá.
A fi ìgbétásì gbígbòòrò kan lọ́lẹ̀ láti pèsè ìsọfúnni pípéye nípa àrùn náà fún àwọn òṣìṣẹ́ olùtọ́jú ìlera àti gbogbo mùtúmùwà lápapọ̀. Apá kan ìsọfúnni náà kìlọ̀ lòdì sí àṣà ìsìnkú ìbílẹ̀, nínú èyí tí àwọn ẹbí ti ń fọwọ́ kan òkú náà tí wọ́n sì ń wẹ̀ ẹ́ lọ́nà aláàtò.
Wíwá Ibi Tí Ó Ti Ṣẹ̀ Wá Kiri
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń fẹ́ láti mọ ibi tí fáírọ́ọ̀sì náà ti wá. Gbogbo ohun tí a mọ̀ ni pé: Àwọn fáírọ́ọ̀sì kì í ṣe ẹ̀dá tí ó lè dá gbé, tí ó lè dá jẹ, tí ó lè dá mu, kí wọ́n sì máa di púpọ̀ sí i fúnra wọn. Láti wà láàyè kí wọ́n sì bí sí i, wọn gbọ́dọ̀ fò mọ́ ara àwọn alààyè sẹ́ẹ̀lì, kí wọ́n sì máa kó wọn nífà.
Nígbà tí fáírọ́ọ̀sì kan bá kọ lu ẹranko kan, ó sábà máa ń jẹ́ ọ̀ràn àjùmọ̀gbépọ̀ onífohùnsọ̀kan—ẹranko náà kò ní pa fáírọ́ọ̀sì, fáírọ́ọ̀sì náà kò sì ní pa ẹranko. Àmọ́ bí ẹ̀dá ènìyàn kan bá fara kanra pẹ̀lú ẹranko tí ó ní fáírọ́ọ̀sì náà, tí fáírọ́ọ̀sì náà sì rọ́nà bọ́ sí ẹ̀dá ènìyàn náà lára, ó lè la ikú lọ.
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé fáírọ́ọ̀sì Ebola náà máa ń yára pa ènìyàn àti ọ̀bọ, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ méfò pé, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ pé fáírọ́ọ̀sì náà ń fi ara ẹ̀dá alààyè míràn ṣelé. Bí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera bá ṣàwárí irú ẹ̀dá alààyè tí ó máa ń ní fáírọ́ọ̀sì náà lára, nígbà náà ni wọn yóò tó lè gbé ìgbésẹ̀ gbígbéṣẹ́ fún yíyẹra fún un àti dídènà ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú. Ìbéèrè tí a kò tí ì rí ìdáhùn sí nípa Ebola ni pé, Ibo ni fáírọ́ọ̀sì náà ń gbé láàárín àkókò àjàkálẹ̀ kan tí ó fi kọlu àwọn ènìyàn sí òmíràn?
Láti dáhùn ìbéèrè náà, àwọn olùwádìí gbọ́dọ̀ tọpa fáírọ́ọ̀sì náà lọ sí ìpìlẹ̀ rẹ̀. Ìsapá láti mọ ẹranko tí kì í pa lára bí ó bá ní in kò kẹ́sẹ járí. Ṣùgbọ́n, àjàkálẹ̀ tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní Kikwit tún ti pèsè àǹfààní ìwádìí mìíràn.
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lérò pé Gaspard Menga ni ẹni àkọ́kọ́ tí àjàkálẹ̀ àrùn náà kọlù ní Kikwit. Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe kó o? Bí ó bá jẹ́ lára ẹranko kan ni, irú ọ̀wọ́ ẹranko wo ni? Ó bọ́gbọ́n mu pé a lè rí ìdáhùn náà nínú igbó tí Menga ti ń ṣiṣẹ́. Agbo àwọn tí ń ṣa nǹkan jọ fún ìwádìí dẹ páńpẹ́ 350 sí àwọn ibi tí Menga ti ń sun èédú rẹ̀. Wọ́n mú àwọn eku ajẹkorun, gúlúsọ, ọ̀pọ̀lọ́, aláǹgbá, ejò, ẹ̀fọn, àmúkùrù, eégbọn, ìdun, iná, jìgá, yọ̀rọ̀—àpapọ̀ 2,200 ẹranko kéékèèké àti 15,000 kòkòrò. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, tí wọ́n di ìhámọ́ra àwọn ohun èèlò adáàbòboni, fi afẹ́fẹ́ apàmọ̀lára pa àwọn ẹranko náà. Wọ́n wá fi àwọn àmúṣàyẹ̀wò wọn ránṣẹ́ sí United States, níbi tí a ti lè yẹ̀ wọ́n wò bóyá wọ́n ní fáírọ́ọ̀sì náà.
Níwọ̀n bí ibi tí fáírọ́ọ̀sì lè sá sí kò ti lópin, kò sí ìdánilójú pé a óò mọ ibi tí ó ti ṣẹ̀ wá. Dókítà C. J. Peters, tí ó jẹ́ olórí ẹ̀ka ìwádìí okùnfà àrùn ní ibùdó CDC náà sọ pé: “Mo rò pé ṣíṣeéṣe láti mọ ẹranko tí fáírọ́ọ̀sì Ebola kì í pa lára bí ó bá ní in àti àìṣeéṣe rẹ̀ jẹ́ ọgbọọgba ní báyìí ná.”
Àjàkálẹ̀ Náà Pòórá
Ní August 25, wọ́n kéde pé àjàkálẹ̀ náà ti tán nílẹ̀, níwọ̀n bí kò ti sí ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀ titun mìíràn láàárín ọjọ́ 42, tí ó jẹ́ ìlọ́po méjì àkókò tí ó gùn jù lọ tí ó lè fi wọnú ara ènìyàn sí àkókò tí yóò fara hàn síta. Èé ṣe tí àrùn náà kò fi gbilẹ̀ rẹpẹtẹ? Ìdí abájọ kan ni ìsapá ìṣègùn àtòkèèrèwá tí a ṣe láti kápá rẹ̀. Kókó mìíràn tí ó ké àjàkálẹ̀ náà kúrú ni bí àrùn náà fúnra rẹ̀ ṣe le koko tó. Nítorí pé ó máa ń dé, tí ó sì máa ń yára pànìyàn, tí ó sì jẹ́ pé ìfarakanra pẹ́kípẹ́kí nìkan ní ń tàn án kálẹ̀, kò tàn dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Àkọsílẹ̀ ìjọba fi hàn pé àrun náà ran 315 ènìyàn, 244 lára wọ́n sì kú—ìwọ̀n ìṣekúpani rẹ̀ jẹ́ ìpín 77 nínú ọgọ́rùn-ún. Ebola ti kógbá sílé ní báyìí. Nínú ayé tuntun ti Jehofa, kì yóò yọjú láéláé. (Wo Isaiah 33:24.) Ní báyìí ná, àwọn ènìyàn ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ebola yóò ha tún bẹ́ sílẹ̀ láti pa àwọn ènìyàn bí?’ Bóyá. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò mọ ibi tí ó ti lè ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí ìgbà tí ó lè ṣe é.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
Bí Àjàkálẹ̀ Àrùn Náà Ṣe Bá Àwọn Àrùn Míràn Tan
Panipani ni Ebola, àmọ́ àwọn àrùn tí kò gbàfiyèsí tó bẹ́ẹ̀ ń wu àwọn ará Áfíríkà léwu jù ú lọ. Láàárín àkókò tí Ebola ń jà yẹn, àwọn àrùn míràn ń yọ́ pa àwọn tí ó ní wọn lára. A ròyìn pé ní ìwọ̀n kìlómítà mélòó kan sí ìhà ìlà oòrùn Kikwit, 250 ènìyàn ni àrùn rọpárọsẹ̀ kọ lù láìpẹ́ yìí. Ní ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn, àwọn oríṣi àrùn onígbáméjì tí ń pani kọ lu Mali. Ní ìhà gúúsù, ní Angola, 30,000 ènìyàn ni àrùn sunrunsunrun kọ lù. Ní agbègbè gbígbòòrò Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ló kú nínú àjàkálẹ̀ àrùn ìwúlé ọpọlọ. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times wí pé: “Fún àwọn ará Áfíríkà, ìbéèrè tí ń dani láàmú náà dìde nípa ìdí tí àwọn ìkọlù aṣekúpani ojoojúmọ́ [ti Áfíríkà] nípasẹ̀ àwọn àrùn tí a lè dènà ọ̀pọ̀ jù lọ wọn kì í fi í gba ayé lọ́kàn.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń wá ibi tí fáírọ́ọ̀sì panipani náà ti ṣẹ̀ wá