Bóo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
Ó ṢÒRO gan-an lóde òní láti mọ ohun tó lè nípa jù lórí ìlera wa. Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ò sì jẹ́ kéèyàn rímú mí mọ́, pẹ̀lú gbogbo ìsọfúnni tí wọ́n ń gbé jáde ṣáá nípa ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ, ṣíṣeré ìdárayá, jíjẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀ràn mìíràn tó jẹ mọ́ ìlera. Ó tún wá lọ jẹ́ pé, púpọ̀ nínú ìsọfúnni ọ̀hún ló takora. Òǹkọ̀wé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nì, Denise Grady, sọ pé: “Ó jọ pé gbogbo ìgbà táa bá gbé àbájáde ìwádìí tuntun jáde nínú ìwé ìròyìn ìṣègùn ni ìyípadà bìrí máa ń dé bá ìmọ̀ràn táa ń fún àwọn aráàlú nípa ohun tó dáa ní jíjẹ, oògùn tó dáa ní lílò, àti ní pàtàkì, bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbé ìgbésí ayé wọn.”
Àwọn dókítà kan dámọ̀ràn pé rírọ̀ mọ́ àwọn àṣà ìlera tó ṣe kókó, bọ́gbọ́n mu ju kéèyàn tètè máa tẹ̀ lé gbogbo àṣà ìlera tó lòde. Fún àpẹẹrẹ, ìwé The American Medical Association Family Medical Guide sọ pé: “Ara rẹ lè le koko jálẹ̀ ayé ẹ, bóo bá ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ nínú ìgbésí ayé ẹ, tóo sì ń lọ fún àyẹ̀wò déédéé lọ́dọ̀ dókítà, kí ó lè ṣeé ṣe láti rí àìsàn èyíkéyìí tó fẹ́ yọjú, kí wọ́n sì tètè wá nǹkan ṣe sí i.” Ṣùgbọ́n kí ni irú “àwọn àtúnṣe tó yẹ nínú ọ̀nà ìgbésí ayé” tó lè ṣàǹfààní jù lọ? Ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́ta nínú wọn yẹ̀ wò.
Máa Jẹ Oúnjẹ Tí Ń Ṣara Lóore
Àwọn ògbógi nínú iṣẹ́ ìṣègùn dámọ̀ràn pé ká máa jẹ onírúurú oúnjẹ, kí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú èròjà afúnnilágbára máa wá látinú àwọn èròjà carbohydrate dídíjúpọ̀, pàápàá àwọn táa ń rí nínú hóró ọkà, ẹ̀wà, ewébẹ̀ àti èso.a Àmọ́ o, kì í ṣe kìkì ohun táa ń jẹ ló ń nípa lórí ìlera wa, ṣùgbọ́n bí ohun táa jẹ ti pọ̀ tó tún máa ń nípa lórí rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì láti jẹun níwọ̀nba. Àjẹjù àwọn èròjà afúnnilágbára lè jẹ́ ká sanra jù. Èyí, ẹ̀wẹ̀, lè dẹrù pa ọkàn-àyà, ó lè sọ ara di kùrẹ̀jẹ̀, ìwé ìròyìn kan sì sọ pé ó lè jẹ́ kéèyàn “ní àrùn ọkàn-àyà, àtọ̀gbẹ, làkúrègbé, àti ọ̀pọ̀ àmódi mìíràn.”
Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀rọ̀ ti pọ̀ gan-an lórí ọ̀ràn ọ̀rá inú oúnjẹ. Ọ̀pọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ọ̀ràn ìlera ń sọ pé téèyàn bá ń jẹ oúnjẹ tó ní ògidì ọ̀rá nínú, ó ṣeé ṣe kó ní àrùn ọkàn-àyà àti irú àwọn àrùn jẹjẹrẹ kan. Ṣùgbọ́n, èyí kò wá túmọ̀ sí pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ kankan tó bá ní ọ̀rá nínú. Mary Abbott Hess, tí í ṣe ààrẹ àná fún Àjọ Tí Ń Ṣalágbàwí Oúnjẹ Aṣaralóore Nílẹ̀ Amẹ́ríkà, sọ pé: “O láǹfààní láti máa jẹ ohun tóo bá fẹ́ lójoojúmọ́, tóo bá jẹ ẹ́ níwọ̀nba, tí kò fi ní pa ìlera rẹ lára.” Àṣírí rẹ̀ ni jíjẹ ìwọ̀n díẹ̀, kí o má sì jẹ àwọn oúnjẹ mí-ìn tó lọ́ràá.
Ká sòótọ́, kò rọrùn láti yí àwọn oúnjẹ rẹ padà. Àní àwọn kan lè ronú pé èèyàn ò ní gbádùn ìgbésí ayé mọ́ tó bá ń fi àwọn ohun tó kúndùn dù ara rẹ̀. Àmọ́, dípò rírinkinkin mọ́nà kan, gbìyànjú láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ohun táa ń sọ ni pé kí o dín in kù, kì í ṣe pé kí o má jẹ ẹ́ rárá. Ìwé Family Medical Guide táa fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ ṣáájú sọ pé: “Gbígbé ìgbésí ayé tó lè mú ìlera sunwọ̀n sí i kò wá sọ pé kóo ṣíwọ́ gbígbádùn ara rẹ.”
Àwọn onímọ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore dá a lábàá pé o lè yí àwọn oúnjẹ rẹ padà láìfi ni ara rẹ lára, nípa jíjáwọ́ díẹ̀díẹ̀ nínú jíjẹ àwọn oúnjẹ tí kò dáa fára. Fún àpẹẹrẹ, rí i dájú pé o ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore jálẹ̀ ọ̀sẹ̀, kì í kàn-án ṣe fọ́jọ́ kan. Bó bá ṣe pé ní báyìí, ojoojúmọ́ lò ń jẹ àwọn ẹran bíi námà, gbìyànjú àtisọ ọ́ di ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀. Ohun kan náà ni kóo ṣe sí àwọn oúnjẹ tó ní ògidì ọ̀rá, bíi bọ́tà, wàràkàṣì, áísìkirimù, àti àwọn ìpápánu tí ń ṣọ̀rá ṣìnkìn. Góńgó rẹ ni láti dín ọ̀rá tóo ń jẹ kù, kí ó má bàa lé ní ìpín ọgbọ̀n nínú ìpín ọgọ́rùn-ún gbogbo oúnjẹ afúnnilágbára tóo ń jẹ.
Dókítà Walter Willett ti Yunifásítì Harvard sọ pé kò dáa kéèyàn dín àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá kù tán, kó tún wá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn oúnjẹ onítááṣì àti oníṣúgà jẹ. Ṣe ló máa ń jẹ́ kéèyàn sanra sí i. Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn dín àti ọ̀rá àti àwọn oúnjẹ onítááṣì kù.
Eré Ìdárayá Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Ọ̀nà ìgbésí ayé tí ń mú ki ìlera sunwọ̀n sí i tún kan ètò eré ìdárayá déédéé. Dókítà Steven Blair, òǹkọ̀wé àgbà nínú ìròyìn tí ọ̀gá àgbà oníṣègùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà gbé jáde lórí ìlera ara, sọ pé: “Àwọn èèyàn tó sábà máa ń jókòó sójú kan ṣùgbọ́n tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tó mọ níwọ̀n, dín ewu kíkú ikú àrùn ọkàn-àyà kù dé ìdajì.” Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni kì í tilẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tó mọ níwọ̀n pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìpíndọ́gba ẹnì kan nínú mẹ́rin ni wọ́n ròyìn pé ó máa ń jókòó gẹlẹtẹ nígbà gbogbo. Ìwé ìròyìn The Toronto Star ròyìn pé, nílẹ̀ Kánádà, ìwádìí kan táa pè ní 1997 Physical Activity Benchmarks sọ pé “ìpín mẹ́tàlélọ́gọ́ta nínú ìpín ọgọ́rùn-ún àwọn ará Kánádà ló jẹ́ pé, èyí tí wọ́n fi ń fara ṣiṣẹ́ lóòjọ́, kò tó wákàtí kan.” Àwọn olùwádìí nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì sọ pé agbo àwọn ọmọdé kan tí wọ́n fi sábẹ́ àyẹ̀wò “kò tiẹ̀ fara ṣiṣẹ́ kankan, àní ó burú débi pé bóyá wọ́n jí ni o, tàbí wọ́n ń sùn ni o, ìyàtọ̀ ò sí nínú agbára ìlùkìkì ọkàn-àyà wọn.”—The Sunday Times.
Tẹ́lẹ̀ rí, èrò àwọn èèyàn ni pé kìkì eré ìmárale àṣelàágùn ló ń ṣàǹfààní fún ìlera. Ṣùgbọ́n kò dìgbà téèyàn bá ń ṣe eré ìmárale àṣe-fẹ́ẹ̀ẹ́-kú kára tó ṣe ṣémúṣémú. Àní, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ọ̀gá àgbà oníṣègùn ti wí, “lílo kìkì ìwọ̀n àádọ́jọ èròjà afúnnilágbára dànù lóòjọ́ [nípa ṣíṣe eré ìdárayá tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì] lè dín ewu àrùn ọkàn-àyà, ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn jẹjẹrẹ àti àtọ̀gbẹ kù.”
Nígbà tóo bá yàn láti máa ṣe eré ìdárayá kan, ó ṣe pàtàkì láti yan èyí tí wàá gbádùn. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò ní bá ẹ lára mu. Kókó pàtàkì náà ni pé, kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe irú eré ìdárayá tí o ń ṣe ló jà, bí kò ṣe bí o ṣe ń ṣe é léraléra tó. Àjọ Ìlera ti Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà dá a lábàá pé gẹ́gẹ́ bí ìlànà gbogbo gbòò, “kí tọmọdé tàgbà ṣètò ó kéré tán ọgbọ̀n ìṣẹ́jú fún ìgbòkègbodò àfaraṣe tó mọ níwọ̀n, kí wọ́n máa ṣe é ní ọjọ́ tó pọ̀ jù lọ lọ́sẹ̀, ṣùgbọ́n ì bá sàn jù tó bá lè jẹ́ lójoojúmọ́.”
Irú ìgbòkègbodò wo ni wọ́n kà sí èyí tó mọ níwọ̀n? Lílúwẹ̀ẹ́, rírìn kánmọ́kánmọ́, gígun kẹ̀kẹ́, fífọ mọ́tò àti nínù ún, gígun òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, àti títọ́jú àyíká ilé. Kò dìgbà tóo lọ wọ ẹgbẹ́ àwọn tí ń lọ sí gbọ̀ngàn ibi ìfarapitú tàbí ibi eré ìmárale kí o tó lè dáàbò bo ìlera rẹ. Àmọ́ o, ká sín ẹ ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ kan: Àwọn ògbógi nínú ọ̀ràn ìṣègùn dá a lábàá pé tóo bá ní àrùn tó jẹ mọ́ ọkàn-àyà, àbí tóo bá jẹ́ ọkùnrin tó ti lé lógójì ọdún tàbí obìnrin tó ti lé láàádọ́ta ọdún, ó yẹ kóo rí i dájú pé o sọ fún dókítà rẹ kóo tó bẹ̀rẹ̀ eré ìdárayá èyíkéyìí.
Sìgá Mímu, Oògùn Líle, àti Ọtí Líle Ńkọ́?
Sìgá Mímu: Èròjà tó lè ṣàkóbá fún ìlera tó wà nínú èéfín sìgá lé ní ẹgbàajì, a sì mọ̀ pé igba lára ìwọ̀nyí jẹ́ májèlé pọ́ńbélé. Ṣùgbọ́n, láìka iye májèlé tó wà sí, kò sí iyèméjì pé sìgá mímu ń ba ìlera jẹ́. Bóyá la fi rí lára àwọn èròjà táa ń ṣe jáde téèyàn ń mú lọ sẹ́nu tó ń ṣekú pani tó tábà. Fún àpẹẹrẹ, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn tí àwọn àrùn tó jẹ mọ́ tábà ń pa jẹ́ ìlọ́po mẹ́wàá àwọn tí jàǹbá ọkọ̀ ń pa. Àjọ Ìlera Àgbáyé díwọ̀n pé, kárí ayé, sìgá mímu ń gbà tó mílíọ̀nù mẹ́ta ẹ̀mí lọ́dọọdún!
Ní àfikún sí ṣíṣeéṣe káwọn amusìgá kó àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn-àyà, ìgbà gbogbo ni ọ̀fìnkìn kì í jẹ́ kí wọ́n gbádùn, wọn ò sì bọ́ lọ́wọ́ ọgbẹ́ inú, àrùn gbọ̀fungbọ̀fun, àti ẹ̀jẹ̀ ríru tó burú ju tàwọn tí kì í mu sìgá. Kò tán síbẹ̀ o, sìgá mímu kì í jẹ́ kéèyàn gbóòórùn dáadáa, kì í sì í jẹ́ kéèyàn mọ adùn. Dájúdájú, ṣíṣíwọ́ sìgá mímu jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù lọ téèyàn fi lè pa ìlera rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n oògùn líle àti ọtí líle ńkọ́?
Oògùn Líle: Ìjoògùnyó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí kárí ayé. Iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà Tí Ń Bójú Tó Ìlera àti Ìpèsè fún Aráàlú sọ pé: “Lọ́dọọdún, ìjoògùnyó máa ń pa ẹgbàáje [14,000] àwọn ará Amẹ́ríkà.” Ṣùgbọ́n kì í ṣe kìkì àwọn tí ń lo oògùn líle nílòkulò nìkan ni òwò oògùn líle ń kó wàhálà bá. Láti lè rówó ra oògùn tó ti di bárakú fún wọn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ajoògùnyó wọ̀nyí ló máa ń hu ìwà ipá àti ìwà ọ̀daràn. Ìwé The Sociology of Juvenile Delinquency sọ pé: “Ìjà nítorí ètò ìpínkiri [kokéènì] ti sọ àdúgbò àwọn mẹ̀kúnnù di ‘àgbègbè ikú’ nígboro, níbi tí iye ìpànìyàn ti pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ọlọ́pàá kì í lọ sírú àdúgbò bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí wọ́n kà á sí àgbègbè tí kò ṣeé ṣàkóso.”
Ṣùgbọ́n Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan kọ́ ló níṣòro ìjoògùnyó. Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti díwọ̀n rẹ̀, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ [160,000] sí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá ààbọ̀ [210,000] èèyàn lágbàáyé ló ń kú nítorí gígún ara wọn lábẹ́rẹ́ oògùn líle. Kò tán síbẹ̀ o, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tún ń lo àwọn egbòogi olóró mìíràn, bíi khat (ewé kan tí ń mú kéèyàn máa hùwà bí amugbó), hóró inú èso betel, àti kokéènì.
Ọtí Líle: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oògùn líle bíi kokéènì àti heroin ló ń gba àfiyèsí gbogbo èèyàn, ìpalára tí ìmukúmu ọtí ń fà ló pọ̀ jù. Ìwé ìròyìn The Medical Post ròyìn pé ìmukúmu ọtí “ń nípa lórí ẹnì kan nínú mẹ́wàá gbogbo àwọn ará Kánádà, ó sì ń ná ètò ìlera ilẹ̀ náà ní bílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là lọ́dọọdún.” A ṣírò rẹ̀ pé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ọtí líle wà lára ohun tí ń fa ìdajì gbogbo jàǹbá ohun ìrìnnà àti iná, òun náà ló ń fa ìpín márùnlélógójì nínú ìpín ọgọ́rùn-ún kíkú sómi, àti ìpín mẹ́rìndínlógójì jàǹbá àwọn ẹlẹ́sẹ̀. Ìmukúmu ọtí pẹ̀lú ló ń fa ọ̀pọ̀ ìwà ọ̀daràn. Pípànìyàn, kíkọluni, fífipá báni lò pọ̀, híhùwà àìdáa sọ́mọdé, tàbí ìpara ẹni, gbogbo rẹ̀ ló sábà máa ń lọ́wọ́ ọtí nínú.
Bí ẹnì kan tóo nífẹ̀ẹ́ bá gbára lé ọtí líle, tábà, tàbí àwọn oògùn líle, tètè wá nǹkan ṣe sí i.b Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Bẹ́ẹ̀ ni, gbígbáralé ìtìlẹyìn onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ ìdílé àti ọ̀rẹ́ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an láti kojú ipò tó nira.
Àmọ́ o, bóo bá fẹ́ jẹ́ onílera ní tòótọ́, ó ń béèrè ju kìkì ìlera ara ìyára lọ. Àwọn kókó tó jẹ mọ́ èrò orí àti tẹ̀mí ń kó ipa pàtàkì nínú ọ̀nà ìgbésí ayé tó dáa fún ìlera. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò jíròrò èyí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò lórí oúnjẹ aṣaralóore, wo Jí!, June 22, 1997, ojú ìwé 7 sí 13.
b Wo ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà “Help for Alcoholics and Their Families” [Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Onímukúmu Ọtí àti Ìdílé Wọn] nínú Jí! [lédè Gẹ̀ẹ́sì], ìtẹ̀jáde May 22, 1992
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Gbígbé ìgbésí ayé tó lè mú ìlera sunwọ̀n sí i kò wá sọ pé kóo ṣíwọ́ gbígbádùn ara rẹ”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣírò pé sìgá mímu ń gbẹ̀mí mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn lọ́dọọdún
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“O láǹfààní láti máa jẹ ohun tóo bá fẹ́ lójoojúmọ́, tóo bá jẹ ẹ́ níwọ̀nba, tí kò fi ní pa ìlera rẹ lára”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ṣíṣeré ìdárayá déédéé lè jẹ́ ara ọ̀nà àtimú ìlera sunwọ̀n sí i
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Má ṣe mu sìgá àti àwọn oògùn tí kò bófin mu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Èso àti ewébẹ̀ yóò ṣara rẹ lóore
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kódà àwọn iṣẹ́ ilé ojoojúmọ́ lè jẹ́ eré ìdárayá tí ń ṣara lóore