Báa Ṣe Lè Ní Èrò Orí Tó Yè Kooro
ÌLERA wa sinmi púpọ̀ lé ohun táa ń jẹ. Bó bá ṣe pé ìjẹkújẹ lèèyàn ń jẹ nígbà gbogbo, kò sí ni kó má fàbọ̀ sí i lára. Ìlànà yìí kan náà kan ìlera wa ní ti èrò orí.
Fún àpẹẹrẹ, o lè fi àwọn ohun táa ń mú wọnú èrò inú wa wé oúnjẹ ọpọlọ. Oúnjẹ ọpọlọ kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, ìsọfúnni táa ń gbà wọlé látinú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, eré orí tẹlifíṣọ̀n, fídíò, àwọn eré orí fídíò, ìsokọ́ra alátagbà Internet, àti àwọn ọ̀rọ̀ orin lè nípa lórí ìrònú wa àti ìwà wa, gan-an gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ gidi ti lè nípa lórí ara wa. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Ọ̀gá kan tẹ́lẹ̀ rí nínú iṣẹ́ ìpolówó ọjà, Jerry Mander, kọ̀wé lórí ipa tí tẹlifíṣọ̀n ń ní lórí ìgbésí ayé wa, ó ní: “Lára gbogbo nǹkan tó lè nípa lórí wa, tẹlifíṣọ̀n nìkan ni ẹ̀rọ tí ń gbé àwòrán lọ sínú ọpọlọ wa tààrà.” Ṣùgbọ́n nígbà táwòrán wọ̀nyẹn bá ti dénú ọpọlọ tán, wọ́n ń ṣe ju dídá wa lárayá lọ. Ìwé ìròyìn The Family Therapy Networker sọ pé: “Èdè, àwòrán, ìró, ojú ìwòye, ìṣesí, ipò àwọn nǹkan, àti àwọn ohun pàtàkì lójú àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn, àtàwọn èròǹgbà tí wọ́n ń gbé jáde, ló máa ń di pàtàkì ìrònú wa, ìmọ̀lára wa, àti ojú ìwòye wa.”
Òdodo ọ̀rọ̀, yálà a mọ̀ tàbí a kò mọ̀, ohun táa ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n àti àwọn eré ìnàjú mìíràn lè máa dọ́gbọ́n yí ìrònú àti ìmọ̀lára wa padà. Ibi tí ewu sì wà gan-an nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí Mander ti wí, “kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ làwa èèyàn máa ń sọ ara wa di àwòrán ohunkóhun tó bá wà nínú èrò inú wa.”
Májèlé Ló Jẹ́ fún Ọpọlọ
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fara balẹ̀ ṣọ́ ohun tí wọ́n ń jẹ ṣùgbọ́n wàdùwàdù ni wọ́n ń gba ohunkóhun tí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn bá gbé jáde sínú ọpọlọ wọn. Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o ti gbọ́ rí tẹ́nì kan sọ pé: “Èèyàn ò lè rí nǹkan dáadáa wò lórí tẹlifíṣọ̀n mọ́!” Ó jọ pé tẹlifíṣọ̀n ti ra àwọn kan níyè, débi pé ṣe ni wọ́n á máa torí ìkànnì kan bọ́ sórí òmíràn, bóyá wọ́n á lè rí ohun tó dáa wò. Èrò àtipa tẹlifíṣọ̀n kò tilẹ̀ wá sí wọn lọ́kàn rí!
Yàtọ̀ sí pé ó ń jẹ àkókò gan-an, ọ̀pọ̀ eré tí wọ́n ń ṣe ló dá lé àwọn ohun tó yẹ kí Kristẹni yàgò fún. Gary Koltookian, tí í ṣe òǹkọ̀wé nípa eré orí ìtàgé sọ pé: “Ní àfikún sí ìsọkúsọ tí wọ́n máa ń sọ, àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ tí ń kọni lóminú àti àwọn tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ takọtabo ń fara hàn lemọ́lemọ́ lóde òní nínú tẹlifíṣọ̀n ju bó ti rí láyé ijọ́un.” Àní, ìwádìí àìpẹ́ yìí kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé láàárín aago méje sí mọ́kànlá alẹ́, táwọn èèyàn máa ń ráyè jókòó ti tẹlifíṣọ̀n dáadáa, ìgbà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni wọ́n ń tọ́ka sí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo láàárín wákàtí kan.
Èyí wá jẹ́ kéèyàn máa ṣe kàyéfì nípa ipa tí nǹkan wọ̀nyí ń ní lórí ìrònú àwọn èèyàn. Ní Japan, eré orí tẹlifíṣọ̀n kan tí gbogbo aráàlú ń wò, wọ ọ̀pọ̀ èèyàn lára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ní ilẹ̀ náà fi sọ pé ó fa “ìbúrẹ́kẹ́ ìwà panṣágà.” Síwájú sí i, àwọn tó ṣe ìwé náà Watching America sọ pé: “Ojú yíyan ohun tó bá kálukú lára mu . . . làwọn èèyàn fi ń wo ọ̀pọ̀ ìwà ìbálòpọ̀ takọtabo tó wọ́pọ̀ lóde òní.”
Ṣùgbọ́n o, kékeré làwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n tí ń kókìkí ìbálòpọ̀ takọtabo jẹ́ lára ìṣòro tí ń bẹ nílẹ̀. Gbígbé ìwà ipá jáde láìlábùlà wọ́pọ̀ pẹ̀lú. Ohun tí ń dani láàmú ní pàtàkì ni ipa burúkú táwọn eré oníwà ipá tí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá ń gbé jáde lè ní lórí àwọn ọ̀dọ́, tó ṣeé tètè yí lérò padà. Ọ̀gbẹ́ni David Grossman, tó jẹ́ ajagunfẹ̀yìntì àti ògbógi nínú ìmọ̀ ohun tí ń fa ìpànìyàn, sọ pé: “Nígbà táwọn ọmọdé bá rí ẹnì kan tí wọ́n ta níbọn lórí tẹlifíṣọ̀n, tàbí tí wọ́n fipá bá lò pọ̀, tí wọ́n hàn léèmọ̀, tí wọ́n sọ dẹni yẹ̀yẹ́, tàbí tí wọ́n pa, ṣe ni wọ́n máa ń rò pé ó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi.” Nígbà tí ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro yìí kan náà, ó sọ pé: “Láti ọmọ ọdún mẹ́ta àti mẹ́rin sókè, ọ̀pọ̀ ọmọdé ni kò mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an àti ohun táa kàn fi ṣeré nínú tẹlifíṣọ̀n, wọn kò sì lè mọ̀yàtọ̀ ọ̀hún kódà báwọn àgbàlagbà tilẹ̀ ṣàlàyé fún wọn.” Lédè mìíràn, bí òbí tilẹ̀ sọ fọ́mọ rẹ̀ pé, ‘Àwọn èèyàn tóo ń rí wọ̀nyẹn kò kú o; wọ́n kàn ń díbọ́n pé àwọn ti kú ni,’ síbẹ̀ lọ́kàn ọmọ náà, kò síyàtọ̀. Lójú ọmọdé, ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n ń ṣẹlẹ̀ ní ti gidi ni, kì í ṣọ̀ràn eré.
Nígbà tí ìwé ìròyìn Time ń ṣàkópọ̀ “ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n,” ó sọ pé: “Ìwọ̀nba àwọn olùwádìí díẹ̀ ló kù tó ṣì ń jiyàn pé ìtàjẹ̀sílẹ̀ orí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá kì í nípa lórí àwọn ọmọ tí ń wò ó.” Irú ipa wo ló ń ní? Michael Medved, tí ń ṣàyẹ̀wò àwọn sinimá, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún táwọn èèyàn ní gbogbo gbòò ti fi wo àwọn eré oníwà ipá ti yí ojú ìwòye àti ìwà ọmọlúwàbí wọn padà.” Ó fi kún un pé: “Kì í ṣe ohun tó dáa rárá, kó má tilẹ̀ sóhun tí ń jọ àwọn èèyàn lójú mọ́.” Abájọ tí òǹkọ̀wé kan fi sọ pé mímú ọmọ ọdún mẹ́rin lọ wo àwọn sinimá oníwà ipá “jẹ́ májèlé fún ọpọlọ [rẹ̀].”
Àmọ́ o, kò wá túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tí tẹlifíṣọ̀n ń gbé jáde ló burú o. A lè sọ ohun kan náà nípa àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, fídíò, eré orí kọ̀ǹpútà, àti àwọn eré ìnàjú mìíràn. Ṣùgbọ́n, ó ṣe kedere pé púpọ̀ àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń pè ní eré ìnàjú kò bójú mu fáwọn tó bá fẹ́ ní èrò orí yíyè kooro.
Fọgbọ́n Yan Eré Ìnàjú
Àwọn àwòrán tí ojú ń gbé wọnú ọkàn wa ń ní ipa tó lágbára lórí èrò àti ìṣesí wa. Fún àpẹẹrẹ, báa bá ń jókòó ti eré oníṣekúṣe nígbà gbogbo, ìpinnu wa láti ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì láti “sá fún àgbèrè” lè má fẹsẹ̀ rinlẹ̀ mọ́. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, báa bá ń gbádùn àwọn eré ìnàjú tó jẹ́ ti “àwọn aṣenilọ́ṣẹ́,” a lè rí i pé ó nira fún wa láti jẹ́ “ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Sáàmù 141:4; Róòmù 12:18) Láti yẹra fún èyí, a gbọ́dọ̀ gbójú wa sá fún “ohun tí kò dára fún ohunkóhun.”—Sáàmù 101:3; Òwe 4:25, 27.
A gbà pé, torí àìpé táa jogún, gbogbo wá ní láti làkàkà láti ṣe ohun tó tọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sòótọ́ ọ̀rọ̀ nígbà tó jẹ́wọ́ pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” (Róòmù 7:22, 23) Èyí ha túmọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn àìlera rẹ̀? Àgbẹdọ̀! Ó sọ pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, . . . kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.”—1 Kọ́ríńtì 9:27.
Bákan náà, a ò ní fẹ́ lo àìpé wa bí àwíjàre fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Nínú Bíbélì, Júúdà kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, . . . mo rí i pé ó pọndandan láti kọ̀wé sí yín láti gbà yín níyànjú láti máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́ tí a fi lé àwọn ẹni mímọ́ lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.” (Júúdà 3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni, dandan ni pé ká “máa ja ìjà líle,” ká sì yàgò fáwọn eré ìnàjú tó lè sún wa ṣe ohun búburú.a
Wá Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run
Níní ojú ìwòye yíyè kooro kì í sábàá rọrùn nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Àmọ́, Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ó ṣeé ṣe láti wà ní mímọ́ ní ti èrò orí àti ní ti ìwà rere. Lọ́nà wo? Nínú Sáàmù 119:11, a kà pé: “Inú ọkàn-àyà mi ni mo fi àsọjáde rẹ ṣúra sí, kí n má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.”
Láti fi àwọn àsọjáde Ọlọ́run ṣúra túmọ̀ sí láti máa fojú ribiribi wò wọ́n, tàbí láti kà wọ́n sí ohun iyebíye. Ó dájú pé yóò ṣòro láti máa gbé Bíbélì gẹ̀gẹ̀ bí a kò bá mọ ohun tó sọ. Nípa gbígba ìmọ̀ pípéye sínú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣe ni a ń gba èrò Ọlọ́run sínú. (Aísáyà 55:8, 9; Jòhánù 17:3) Èyí, ẹ̀wẹ̀, ń sọ wá dọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí, ó sì ń gbé ìrònú wa ga.
Ǹjẹ́ òṣùwọ̀n kankan wà táa lè fi díwọ̀n ohun tó yè kooro nípa tẹ̀mí àti èrò orí? Bẹ́ẹ̀ ni o! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.
Ṣùgbọ́n bí a óò bá jàǹfààní gidi, a béèrè ju kìkì níní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run. Lábẹ́ ìmísí, wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe kìkì pé ó yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún yẹ ká máa gbégbèésẹ̀ lórí ìmọ̀ náà.
Ọ̀nà mìíràn táa fi lè jàǹfààní ní ti ìwà rere àti nípa tẹ̀mí ni láti máa ké pe Jèhófà, tí í ṣe “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2; 66:19) Báa bá fi òtítọ́ inú àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tọ Ẹlẹ́dàá wa lọ, òun yóò fetí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. Báa bá sì “wá a, òun yóò jẹ́ kí [a] rí òun.”—2 Kíróníkà 15:2.
Nítorí náà, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti mú kí èrò orí wa yè kooro nínú ayé oníwà ipá àti oníṣekúṣe yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe! Nípa ṣíṣàì jẹ́ kí eré ìnàjú ayé yìí mú èrò inú wa yigbì, nípa fífún agbára ìrònú wa lókun nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nípa wíwá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, a lè ní èrò orí yíyè kooro!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àfikún ìsọfúnni lórí yíyan eré ìnàjú tó mọ́yán lórí, wo Jí!, May 22, 1997, ojú ìwé 8 sí 10.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“Ọ̀pọ̀ ọmọdé ni kò mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an àti ohun táa kàn fi ṣeré nínú tẹlifíṣọ̀n”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
“Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún táwọn èèyàn ní gbogbo gbòò ti fi wo àwọn eré oníwà ipá ti yí ojú ìwòye àti ìwà ọmọlúwàbí wọn padà”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
Dídín Ewu Àrùn Ọkàn-Àyà Tó Lè Ṣe Ọ́ Kù
Ìwé ìròyìn Nutrition Action Healthletter dámọ̀ràn àwọn ìgbésẹ̀ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dín ewu àrùn ọkàn-àyà kù.
• Ṣíwọ́ sìgá mímu. Jíjáwọ́ lónìí lè dín ewu àrùn ọkàn-àyà kù láàárín ọdún kan, kódà bóo bá tilẹ̀ sanra sí i.
• Dín ìwọ̀n ìsanra kù. Bóo bá sanra jù, jíjo ìwọ̀nba ẹ̀sún bíi márùn-ún sí mẹ́wàá dànù lè ṣàǹfààní.
• Ṣeré ìdárayá. Ṣíṣe eré ìdárayá déédéé (ó kéré tán lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀) yóò ṣèrànwọ́ láti dín èròjà cholesterol tí kò dára (LDL) kù, kò ní jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ máa ru, kò sì ní jẹ́ kí o sanra jù.
• Má ṣe jẹ ògidì ọ̀rá jù. Bí LDL rẹ bá pọ̀ jù, bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn ẹran tí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́ràá, kí o sì gbìyànjú àtimáa mu mílíìkì (aláìlọ́ràá púpọ̀) tí ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ìpín kan nínú ọgọ́rùn-ún, tàbí mílíìkì (aláìlọ́ràá rárá) tí a ti ré ìfófòó rẹ̀, dípò mímu mílíìkì tí ọ̀rá rẹ̀ pọ̀ tó ìpín méjì nínú ọgọ́rùn-ún.
• Dín ọtí mímu kù. Àmì fi hàn pé àwọn tí ń mu wáìnì pupa níwọ̀nba lè dín ewu àrùn ọkàn-àyà kù.
• Túbọ̀ máa jẹ èso, ewébẹ̀, àti àwọn oúnjẹ mí-ìn tó ní ṣákítí rírọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n dà bí májèlé fún ọpọlọ ọmọdé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn ọmọdé máa ń dán ìwà ipá tí wọ́n ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ nípa pípèsè ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìwé tó dáa