Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Láti Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu?
ẸNI tó bá fẹ́ pẹ́ láyé, tó sì fẹ́ káyé òun dùn, kò gbọ́dọ̀ mu sìgá. Ó jọ pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, sìgá ló máa ń ṣekú pa ẹnì kan nínú méjì lára àwọn tó pẹ́ tí wọ́n ti ń mu ún. Gíwá Àjọ Ìlera Àgbáyé, sọ pé: “Sìgá jẹ́ . . . ohun kan tí wọ́n dọ́gbọ́n ṣe, tó ní èròjà olóró tó pọ̀ tó, ní ìwọ̀n tí yóò mú kó di bára kú fẹ́ni tó ń mu ún, kó tó wá pa onítọ̀hún.”
Nítorí náà, ọ̀kan lára ìdí tó fi yẹ kéèyàn yéé mu sìgá ni pé, ó ń fa àìsàn sára, ó sì ń fẹ̀mí wewu. A gbọ́ pé iye àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí tí sìgá ń fà lé ní mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Fún àpẹẹrẹ, òun ni eku ẹdá tó ń fa àrùn ọkàn, àrùn ẹ̀gbà, akọ àrùn gbọ̀fungbọ̀fun, ara wíwú rọ́tọ́rọ́tọ́, àti onírúurú àrùn jẹjẹrẹ, àgàgà àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró.
Àmọ́ o, ó lè ti pẹ́ gan-an téèyàn ti ń mu sìgá kí ọ̀kan lára àìsàn wọ̀nyí tó kì í mọ́lẹ̀. Kódà nígbà táìsàn ò tíì kì í mọ́lẹ̀ gan-an, sìgá mímu ò lè sọ ọ́ dẹni táráyé ń fẹ́. Àwọn tó ń polówó ọjà sábà máa ń sọ fáráyé pé àwọn tó gbáfẹ́, tára wọn le koko, làwọn tó ń mu sìgá. Kò sóòótọ́ eléépìnnì nínú irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Béèyàn bá ń mu sìgá, ńṣe lẹnu rẹ̀ á máa rùn, eyín rẹ̀ á wọjì, èékánná rẹ̀ á sì máa pọ́n ràkọ̀ràkọ̀. Ó tún máa ń fa kí àwọn ọkùnrin di akúra. Ó máa ń fa ikọ́ kẹ̀hẹ̀kẹ̀hẹ̀ táwọn amusìgá máa ń wú àti mímí gúlegúle. Ó tún jọ pé ojú àwọn tó ń mu sìgá tètè máa ń hun jọ, ó sì máa ń fa àwọn ìṣòro míì tó jẹ mọ́ awọ ara.
Jàǹbá Tí Sìgá Mímu Ń Ṣe Fáwọn Ẹlòmíì
Bíbélì sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Ìfẹ́ fún àwọn aládùúgbò rẹ—àwọn mẹ́ńbà ìdílé ẹ sì ni aládùúgbò tó sún mọ́ ẹ jù lọ—ìdí pàtàkì rèé tó fi yẹ láti jáwọ́.
Sìgá mímu ń pa àwọn tí kì í mu sìgá lára. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, èèyàn lè ṣáná sí sìgá níbikíbi, kò sì sẹ́ni tó máa wò ó kọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n ìṣesí àwọn èèyàn ti ń yí padà báyìí o, nítorí pé àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ló ti mọ̀ nípa ewu tó wà nínú fífa èéfín táwọn amusìgá ń tú sáfẹ́fẹ́ símú. Fún àpẹẹrẹ, ká ní ẹni tí kì í mu sìgá lọ fẹ́ ẹni tí ń mu sìgá, ṣíṣeéṣe kó ní àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró fi ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i, èyí tí kì bá rí bẹ́ẹ̀ ká ní ẹni tí kì í mu sìgá ló fẹ́. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ tí ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí tí ń mu sìgá ní àrùn otútù àyà tàbí àrùn gbọ̀fungbọ̀fun kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún méjì, èyí ò sì rí bẹ́ẹ̀ ní tàwọn ọmọ tó ń gbé nílé tí kò ti sí amusìgá.
Ńṣe làwọn aboyún tó ń mu sìgá ń fẹ̀mí oyún inú wọn wewu. Ńṣe làwọn èròjà olóró bíi nicotine, èéfín carbon monoxide, àtàwọn májèlé míì tó wà nínú èéfín sìgá máa ń wọnú ẹ̀jẹ̀ ìyá, tó sì máa ń lọ sọ́dọ̀ ọmọ tó wà nínú ilé ọlẹ̀ ní tààràtà. Ara ohun tó lè tìdí ẹ̀ yọ ni kí oyún ṣẹ́ mọ́ ìyá lára, tàbí kí ọmọ yẹn kú sínú, tàbí kí ọmọ náà kú láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá bí i. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ewu ikú òjijì àwọn ọmọdé tún pọ̀ ní ìlọ́po mẹ́ta nínú àwọn ọmọ jòjòló tí ìyá wọn ń mu sìgá nínú oyún.
Ó Ń Jẹ Owó Gan-an
Ìdí mìíràn tó fi yẹ kéèyàn jáwọ́ nínú sìgá mímu ni pé ó ń jẹ owó gan-an. Ìwádìí kan tí Báńkì Àgbáyé ṣe díwọ̀n pé iye tí wọ́n ń ná lọ́dọọdún sórí títọ́jú àwọn àìsàn tí sìgá mímu ń fà jẹ́ nǹkan bí igba bílíọ̀nù dọ́là. Kí ẹ sì máa wò ó, ohun tí wọn ò ṣírò mọ́ ọn ni ìyà àti ìrora tó ń dé bá àwọn tó kó àwọn àìsàn tí sìgá ń fà.
Iye tí olúkúlùkù àwọn tó ń mu sìgá ń ná sórí sìgá kò ṣòroó ṣírò rárá. Tóo bá ń mu sìgá, ṣírò iye owó tí ò ń ná sórí sìgá lójoojúmọ́ ní ìlọ́po iye ọjọ́ tó wà nínú ọdún kan. Ìyẹn ni wàá fi mọ iye owó tóò ń ná sórí rẹ̀ lọ́dún kan. Tún ṣírò iye yẹn ní ìlọ́po mẹ́wàá, ìyẹn á sì jẹ́ kí o mọ iye tóo máa ná sórí sìgá bí o bá ṣì ń mu ún ní ọdún mẹ́wàá òní. Àròpọ̀ rẹ̀ lè yà ẹ́ lẹ́nu. Ronú nípa nǹkan míì tí ò bá fi owó tùùlù-tuulu yẹn ṣe.
Ǹjẹ́ Èèyàn Bọ́ Lọ́wọ́ Ewu Tó Bá Ń Mu Oríṣi Míì?
Àwọn iléeṣẹ́ sìgá máa ń polówó àwọn sìgá tí wọ́n sọ pé oró èéfín wọn àti èròjà olóró inú wọn kò pọ̀ rárá—wọ́n ń pé irú sìgá bẹ́ẹ̀ ní sìgá tí kò le tàbí sìgá tó tuni lára—wọ́n ní èyí á dín jàǹbá tí sìgá mímu ń ṣe fún ìlera kù. Àmọ́ o, àwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá tí wọ́n ti dín oró èéfín àti èròjà olóró rẹ̀ kù ṣì ń fẹ́ ìwọ̀n kan náà yìí tí wọ́n ń fà sínú tẹ́lẹ̀. Fún ìdí yìí, àwọn amusìgá tó wá bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá tí wọ́n ti dín oró èéfín àti èròjà olóró rẹ̀ kù sábà máa ń fa ìwọ̀n èròjà kan náà sínú nípa mímu sìgá púpọ̀ sí i, fífa èéfín púpọ̀ sí i sínú léraléra ju ti tẹ́lẹ̀, tàbí nípa gbígbìyànjú láti mu sìgá kọ̀ọ̀kan tán pátápátá. Kódà ní ti àwọn tí ò fi kún iye tí wọ́n ń mu, díẹ̀ làǹfààní tó ń ṣe fún ìlera wọn táa bá fi wéra pẹ̀lú àǹfààní tó wà nínú jíjáwọ́ ńbẹ̀ pátápátá.
Ìkòkò àti tábà ńkọ́? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí iléeṣẹ́ sìgá ti ń sọ pé àwọn èèyàn pàtàkì ló ń mu ìkòkò àti tábà, ṣùgbọ́n èéfín gbẹ̀mígbẹ̀mí tó ń ti inú sìgá jáde ló ń ti inú àwọn náà jáde. Bí àwọn tó ń mu tábà tàbí ìkòkò kì í tilẹ̀ẹ́ fa èéfín wọn sínú, síbẹ̀ wọ́n lè tètè kó àrùn jẹjẹrẹ ètè, ti ẹnu, àti ti ahọ́n.
Ǹjẹ́ ewu kankan wà nínú tábà tí kò léèéfín? Oríṣi méjì rẹ̀ ló wà: aáṣáà àti tábà tí wọ́n ń jẹ lẹ́nu. Tábà lílọ̀ ni wọ́n ń pè ní aáṣáà, wọ́n sì sábà máa ń tà á nínú agolo tàbí akóló ẹ̀. Àwọn tó ń lò ó sábà máa ń lé e sórí ahọ́n tàbí kí wọ́n bù ú sí ẹ̀rẹ̀kẹ́. Ní ti tábà tí wọ́n ń jẹ lẹ́nu, gbọọrọ-gbọọrọ ni wọ́n máa ń tà á, ó sábà máa ń wà nínú akóló. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi hàn, ṣe ni wọ́n máa ń jẹ ẹ́ lẹ́nu, wọn kì í lá a. Aáṣáà àti tábà tí wọ́n ń jẹ lẹ́nu máa ń jẹ́ kí ẹnu rùn, ó máa ń jẹ́ kí eyín dúdú, ó máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ ẹnu àti ti ọ̀nà ọ̀fun, ó máa ń jẹ́ kí èròjà olóró inú sìgá di bárakú, ó máa ń dá ègbò funfun síni lẹ́nu, ègbò yìí sì lè di àrùn jẹjẹrẹ, ó máa ń jẹ́ kí ẹran ìdí eyín ṣí, ó sì máa ń ba egungun tó wà ní àyíká eyín jẹ́. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ọ́, aáṣáà tàbí tábà tí wọ́n ń jẹ lẹ́nu kì í ṣe ohun tó dáa láti fi rọ́pò mímu sìgá.
Àwọn Àǹfààní Tí Ń Bẹ Nínú Jíjáwọ́ Ńbẹ̀
Ká sọ pé o ti ń mu sìgá bọ̀ ọjọ́ ti pẹ́. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tóò bá mu ún mọ́? Láàárín ogún ìṣẹ́jú tóo jáwọ́ nínú mímu sìgá, ẹ̀jẹ̀ rẹ á lọọlẹ̀ sí ìwọ̀n yíyẹ. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, èròjà olóró nicotine inú sìgá kò ní sí nínú ara rẹ mọ́. Lẹ́yìn oṣù kan, ikọ́ híhú, ọ̀fìnkìn ìgbà gbogbo, àárẹ̀ ara, àti mímí gúlegúle, gbogbo rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí lọọlẹ̀. Lẹ́yìn ọdún márùn-ún, ewu pé àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró lè pa ẹ́ á ti dín kù dé ìdajì. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ewu pé o lè ní àrùn kí ẹ̀jẹ̀ má ṣàn lọ sí ọkàn-àyà déédéé á lọọlẹ̀ pátápátá, àfi bí ẹni pé o ò mu sìgá rí.
Oúnjẹ á máa lọ lẹ́nu dáadáa. Òórùn burúkú ò ní máa jáde látẹnu rẹ mọ́, láti ara rẹ, àti láti ara aṣọ rẹ. Kò ní sí wàhálà tàbí ìnáwó ríra sìgá mọ́. Inú rẹ yóò dùn pé o ṣàṣeyọrí. Bóo bá lọ́mọ, ó ṣeé ṣe kí àpẹẹrẹ rẹ mú kí wọ́n yẹra fún sìgá mímu. Ó ṣeé ṣe kí o pẹ́ sí i láyé. Ní àfikún, ìgbésẹ̀ rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, níwọ̀n bí Bíbélì ti sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Má ṣe lérò pé ó ti pẹ́ jù láti jáwọ́ ńbẹ̀; sá tètè jáwọ́ báyìí, ìjáfara léwu.
Ìdí Tó Fi Nira Gan-an Láti Jáwọ́ Ńbẹ̀
Ó ṣòro láti jáwọ́ nínú sìgá mímu—kódà ó ṣòro fáwọn tí ọkàn wọn fẹ́ bẹ́ẹ̀ gidigidi. Ohun pàtàkì tó máa ń fà á ni pé nicotine, èròjà olóró inú sìgá, jẹ́ oògùn líle tó máa ń ṣòroó fi sílẹ̀. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Lára àwọn oògùn líle tó ń pani lọ́bọlọ̀, nicotine tó jẹ́ èròjà olóró inú sìgá máa ń ṣòroó fi sílẹ̀ ju heroin [àti] kokéènì lọ.” Èròjà olóró inú sìgá yàtọ̀ sí heroin àti kokéènì ní ti pé kì í jẹ́ kí èèyàn máa ṣe bí amugbó, ìyẹn làwọn èèyàn ò fi ka agbára rẹ̀ sí. Ṣùgbọ́n bó ṣe máa ń jẹ́ kágbárí jí pépé fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ máa ń jẹ́ kó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, wọ́n máa ń fẹ́ irú ìmóríyá bẹ́ẹ̀ léraléra. Èròjà olóró inú sìgá ń yí ìṣesí rẹ padà ní tòótọ́; ó máa ń lé àníyàn lọ. Àmọ́, ara ìdí tí sìgá fi ń dín pákáǹleke kù ni ìyánhànhàn tí èròjà olóró inú ẹ̀ máa ń fà lápá kan.
Ó tún nira láti jáwọ́ nínú sìgá mímu nítorí pé àṣà tí ń mọ́ni lára ni. Yàtọ̀ sí pé oògùn líle inú sìgá máa ń ṣòroó fi sílẹ̀, ó ti mọ́ àwọn tí ń mu sìgá lára láti máa ṣáná sí sìgá, kí wọ́n sì máa rú èéfín túú. Àwọn kan lè máa sọ pé, ‘Kì í jẹ́ kí ọwọ́ gbófo.’ ‘Ó máa ń jẹ́ kí ọwọ́ dí.’
Kókó kẹta tó fi máa ń nira láti jáwọ́ ńbẹ̀ ni pé wọ́n ti sọ sìgá di ohun téèyàn ń rí ní gbogbo ìgbà. Àwọn iléeṣẹ́ sìgá ń ná iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́fà dọ́là lọ́dọọdún láti fi polówó ọjà wọn, tí wọ́n á máa sọ pé àwọn tó gbáfẹ́, tó lááyan, tó ń ta kébékébé, tó sì jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé ló ń mu sìgá. Wọ́n sábà máa ń gbé àwòrán irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ jáde, tí wọ́n ń gẹṣin, tí wọ́n ń lúwẹ̀ẹ́, tí wọ́n ń ṣeré ìmárale, tàbí tí wọ́n ń ṣe nǹkan míì tó gbámúṣé. Sinimá àtàwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n máa ń gbé àwọn èèyàn jáde tí ń mu sìgá—wọn kì í sì í ṣe èèyànkéèyàn nínú sinimá náà. Kò jọ pé ibì kankan wà tí òfin ti de sìgá títà, ìyẹn ló fi wà lórí àtẹ níbi gbogbo. Ṣàṣà nìgbà tí a kì í rí ẹnì kan tí ń mu sìgá nítòsí wa. Ojú rẹ ò lè ṣàìrí ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí.
Ó mà ṣe o, pé kò sí oògùn tóo lè lò láti fi mú ìfẹ́ àtimu sìgá kúrò lọ́kàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti lè lo oògùn ẹ̀fọ́rí. Téèyàn bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, kó má mu sìgá mọ́, pẹ̀lú gbogbo wàhálà tó wà nídìí ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ ti inú ọkàn onítọ̀hún wá. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ọ̀ràn àwọn tó fẹ́ di ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, ó ń béèrè ìpinnu tó lágbára fún àkókò pípẹ́. Ọwọ́ ẹni tó ń mu sìgá ló wà tí yóò bá ṣàṣeyọrí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
Láti Àárọ̀ Ọjọ́ Ló Ti Di Bárakú fún Wọn
Ìwádìí kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ẹnì kan nínú mẹ́rin lára gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tó dán sìgá mímu wò ni kò lè jáwọ́ mọ́. Iye yìí ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí iye àwọn tó ṣòro fún láti jáwọ́ nínú kokéènì àti heroin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́langba tí ń mu sìgá kábàámọ̀ pé àwọn bẹ̀rẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ ló lè jáwọ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
Kí Ló Wà Nínú Èéfín Sìgá?
Májèlé kan tó ń jẹ́ tar wà nínú èéfín sìgá, májèlé yìí sì ní tó kẹ́míkà tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin lọ. Lára àwọn kẹ́míkà wọ̀nyí, mẹ́tàlélógójì la mọ̀ tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ. Lára àwọn kẹ́míkà náà ni cyanide, benzene, methanol, àti acetylene (kábáàdì). Èéfín nitrogen oxide àti irú èéfín tó máa ń jáde lẹ́nu salẹ́ńsà mọ́tò tún ń bẹ nínú èéfín sìgá, èéfín olóró sì ni méjèèjì yìí. Èròjà tó lágbára jù lọ nínú rẹ̀ ni nicotine, tí í ṣe oògùn líle tí kì í ṣeé fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ríran Àwọn Èèyàn Wa Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Ńbẹ̀
Bí o kì í bá mu sìgá, ṣùgbọ́n tóo mọ àwọn ewu tó wà nínú sìgá mímu, á máa dùn ẹ́ gan-an táwọn ọ̀rẹ́ àti èèyàn rẹ kò bá yéé mu sìgá. Kí lo lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè jáwọ́? Ìyọlẹ́nu ṣáá, ẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dábọ̀, ìfagbáramúni, àti ìfiniṣẹ̀sín ò ràn án. Bẹ́ẹ̀ náà ni nínà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀ ò ràn án. Dípò kí amusìgá náà tìtorí èyí jáwọ́, ó lè tún nawọ́ gán sìgá, kó fi pàrònú rẹ́. Fún ìdí yìí, gbìyànjú láti lóye bó ti ṣòro tó láti jáwọ́, àti pé ó nira gan-an fáwọn kan ju àwọn míì lọ.
O ò lè fagbára mú ẹnì kan jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ó gbọ́dọ̀ ti ọkàn onítọ̀hún wá, kí ó sì ti pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ fi sìgá mímu sílẹ̀. Ohun tí wàá kàn ṣe ni pé kóo wá àwọn ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ tí o lè fi fún un níṣìírí, kí o sì gbárùkù tì í kó lè jáwọ́.
Báwo lo ṣe lè ṣe é? Nígbà tó bá wọ̀, o lè jẹ́ kí onítọ̀hún mọ̀ pé o fẹ́ràn rẹ̀, kí o sì sọ fún un pé sìgá tó ń mu yìí mà ń kó ìrònú bá ẹ. Ṣàlàyé pé wàá gbárùkù tì í tó bá pinnu láti jáwọ́ ńbẹ̀. Àmọ́ o, tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà lo ń sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, tó bá yá kò ní tà mọ́.
Kí lo lè ṣe tí èèyàn rẹ kan bá pinnu láti jáwọ́? Má gbàgbé pé jíjáwọ́ lè fa ìkanra àti ìsoríkọ́. Orí lè máa fọ́ ọ, kí ó má sì róorun sùn. Rán èèyàn rẹ ọ̀hún létí pé àmì wọ̀nyí ò ní pẹ́ lọ àti pé ìyẹn ló fi hàn pé ara ti ń padà bọ̀ sípò díẹ̀díẹ̀. Máa ṣọ̀yàyà sí i, pẹ̀lú ẹ̀mí pé ọ̀la-ń-bọ̀-wá-dáa. Jẹ́ kó mọ̀ pé inú rẹ dùn gan-an pé ó fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀. Jálẹ̀ gbogbo àkókò tó fi dáwọ́ lé jíjáwọ́ nínú mímu ún, ràn án lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ipò ìdààmú tó lè jẹ́ kó tún padà sídìí sìgá mímu.
Tó bá tún bẹ̀rẹ̀ sí mu ún ńkọ́? Ṣe sùúrù. Fi ojú àánú hàn. Kà á sí pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni, nígbà tó bá sì fi máa gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ṣeé ṣe kí ó kógo já.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn iléeṣẹ́ sìgá ń ná iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́fà dọ́là lọ́dọọdún láti fi polówó ọjà wọn