Bóo Ṣe Lè Jáwọ́ Ńbẹ̀
ŃṢE ni jíjáwọ́ nínú sìgá mímu dà bí ìgbà téèyàn ń kọ́ kẹ̀kẹ́ gígùn, bóyá lèèyàn fi lè mọ̀ ọ́n gùn nígbà àkọ́kọ́ tó bá gbìyànjú ẹ̀. Nítorí náà, bóo bá fẹ́ jáwọ́ lóòótọ́, o gbọ́dọ̀ ṣe tán láti gbìyànjú léraléra títí wàá fi ṣàṣeyọrí. Má sọ pé torí pé o tún padà lọ mu sìgá lẹ́ẹ̀kan, gbogbo ìsapá rẹ ti já sásán. Kà á sí pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bóo ṣe lè jáwọ́ ni, o kàn fìdí rẹmi díẹ̀ ni, wàá ṣì ṣàṣeyọrí. Àbá mélòó kan rèé tó ti ṣiṣẹ́ fáwọn ẹlòmíì. Wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún ìwọ náà.
Ní In Lọ́kàn Pé O Fẹ́ Jáwọ́ Ńbẹ̀
■ Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mú un dá ara rẹ lójú pé sísapá láti jáwọ́, tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìdí tóo fi fẹ́ jáwọ́, títí kan gbogbo àǹfààní tí wàá jẹ. Lẹ́yìn tóo bá ti jáwọ́ ńbẹ̀, ṣíṣàtúnyẹ̀wò àkọsílẹ̀ yìí yóò máa fún ìpinnu rẹ lókun. Ìfẹ́ láti ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí ni ète tó lágbára jù lọ tóo fi fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀. Bíbélì sọ pé ká fi gbogbo èrò inú, ọkàn-àyà, ọkàn, àti okun wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. A ò lè ṣe bẹ́ẹ̀ táa bá sọ sìgá di bára kú.—Máàkù 12:30.
■ Ṣàyẹ̀wò bóo ṣe máa ń mu sìgá tó, kí o lè mọ ìgbà tóo máa ń mu ún àti ìdí tóo fi máa ń mu ún. Á dáa kí o ní bébà kan tí wàá máa kọ ìgbà tí o ń mu sìgá kọ̀ọ̀kan sí, àti ibi tóo ti sábà máa ń mu ún. Èyí á jẹ́ kí o rí àwọn ipò tó lè fẹ́ sún ẹ mu sìgá lẹ́yìn tóo bá jáwọ́.
Dá Ọjọ́ Tóo Fẹ́ Jáwọ́ Ńbẹ̀
■ Dá ọjọ́ tóo fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀, kí o sì sàmì sí i lórí kàlẹ́ńdà. Ohun tó dáa jù ni pé kóo dá ọjọ́ tí nǹkan kan ò ní kó ìdààmú bá ẹ ju bó ti yẹ lọ. Tí ọjọ́ náà bá kò, jáwọ́ pátápátá—lẹ́ẹ̀kan fáú, láìwẹ̀yìn.
■ Kó tó dọjọ́ tóo fẹ́ jáwọ́, sọ gbogbo agolo tí o ń ṣẹ́ eérú sìgá sí, àti ìṣáná nù. Fọ gbogbo aṣọ rẹ tó ń run èéfín sìgá.
■ Béèrè fún ìtìlẹyìn àwọn tẹ́ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọ̀rẹ́, àti ìdílé rẹ, kí wọ́n lè fún ẹ níṣìírí bóo ti ń sapá láti jáwọ́. Má bẹ̀rù láti sọ pé kí àwọn èèyàn má mu sìgá ní sàkáání rẹ.
■ Ṣètò onírúurú ìgbòkègbodò fún ọjọ́ tóo fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀. O lè lọ síbi tí wọn kò ti gba sìgá mímu láyè, irúfẹ́ ibi tí wọ́n ń kó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí tàbí ibi eré orí ìtàgé. O sì lè lọ ṣe eré ìdárayá—bóyá kí o lọ lúwẹ̀ẹ́ tàbí kí o gun kẹ̀kẹ́ tàbí kí o kàn rìn gbafẹ́ lọ.
Kíkojú Àwọn Ìṣòro Tó Wà Nínú Jíjáwọ́ Ńbẹ̀
Bó bá jẹ́ pé afìkan-ràn-kan ni ẹ́, àwọn ìṣòro kan á yọjú nítorí pé o jáwọ́, ìyẹn á sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ láàárín wákàtí díẹ̀ tóo bá mu sìgá àmugbẹ̀yìn. Ó lè jẹ́ àwọn ìṣòro bíi kíkanra, àìní sùúrù, ṣíṣe gbúngbùngbún, ìbẹ̀rù, ìsoríkọ́, àìróorunsùn, ara àìbalẹ̀, oúnjẹ àjẹjù, yíyánhànhàn fún sìgá. Ó ṣeé ṣe kí dókítà rẹ lè kọ oògùn fún ẹ, tí á lè ṣiṣẹ́ fún ìṣòro wọ̀nyí. Ní àfikún, àwọn nǹkan kan wà tóo lè ṣe, tí yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ja àjàṣẹ́gun.
■ Láàárín àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ àkọ́kọ́ tó nira, máa jẹ àwọn oúnjẹ tí kò ní èròjà afúnnilágbára púpọ̀, sì máa mu omi púpọ̀. Àwọn kan ti rí i pé ó dáa láti máa fi àwọn nǹkan jíjẹ tútù bíi kárọ́ọ̀tì panu. Bóo bá ń ṣe eré ìdárayá, èyí á jẹ́ kóo dín sísanra kù, á sì jẹ́ kára ó tù ẹ́.
■ Yẹra fún àwọn ibi àti ipò tó lè sún ẹ mu sìgá.
■ Má fàyè gba ìrònú òdì tó lè sún ẹ mu sìgá. Àwọn èrò kan tó máa ń wá síni lọ́kàn rèé nígbà téèyàn bá jáwọ́: ‘Òní nìkan ni màá mu sìgá nítorí pé ara mi ò gbà á mọ́.’ ‘Sìgá mímu nìkan ni nǹkan tí mo ń ṣe tí kò dáa!’ ‘Sìgá ò kúkú burú tó bí wọ́n ṣe ń sọ; a sáà ti rí àwọn afìkan-ràn-kan tó lò ju àádọ́rùn-ún ọdún láyé.’ ‘Ṣe bí nǹkan kan ló sáà máa pa mí.’ ‘Ayé yìí ò lè dùn láìjẹ́ pé èèyàn mu sìgá.’
■ Bóo bá rí i pé o tún ti fẹ́ padà mu sìgá, dúró díẹ̀ ná. Bó tiẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré lo fi dúró, ìyánhànhàn yẹn lè lọọlẹ̀. Nígbà míì, ìrònú pé o ò ní mu sìgá mọ́ láé lè dà ẹ́ lọ́kàn rú. Bóo bá ń ronú bẹ́ẹ̀, pọkàn pọ̀ sórí jíjáwọ́ lónìí nìkan.
■ Bó bá ṣe pé o fẹ́ sin Ọlọ́run ni, gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ lè pèsè “ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́” fún àwọn tó ń làkàkà láti mú ìgbésí ayé wọn bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Hébérù 4:16) Ṣùgbọ́n má retí iṣẹ́ ìyanu o. O gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lé ohun tóo ń gbàdúrà fún.
Má Padà Sídìí Sìgá Mọ́ O
■ Oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ ló máa ń le jù, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìyẹn pàápàá, nígbà tó bá ti ṣeé ṣe, ó yẹ kóo ṣì máa yẹra fún àwọn amusìgá àtàwọn ipò tó lè jẹ́ kí sìgá máa wù ẹ́ mu.
■ Má tan ara rẹ jẹ nípa rírò pé o lè máa mu sìgá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kódà bó bá ti lé lọ́dún kan tóo ti jáwọ́ nínú sìgá mímu.
■ Dènà ìyánhànhàn láti mu “ẹyọ sìgá kan péré.” Ẹyọ kan péré lè jẹ́ kóo tún mu òmíì, láìpẹ́, gbogbo làálàá rẹ láti jáwọ́ sì lè já sásán. Àmọ́ o, tóo bá sọra nù, tóo sì mu ẹyọ sìgá kan, kò sídìí láti tún mu òmíì. Tóo bá ṣèèṣì padà mu ún, tún jáwọ́ ńbẹ̀.
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ amusìgá ló ti jáwọ́ ńbẹ̀ pátápátá. Pẹ̀lú ìmúratán àti ìforítì, ìwọ náà lè jáwọ́ ńbẹ̀!