Ọ̀nà 6 Tí O Lè Gbà Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
Ìṣòro Tó Ń Kojú Àwọn Èèyàn Láwọn Ilẹ̀ Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Gòkè Àgbà
Ọ̀PỌ̀ èèyàn lóde òní ní láti sapá gidigidi láti jẹ́ onímọ̀ọ́tótó, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tí omi tó dára ti ṣọ̀wọ́n, tí ètò ìmọ́tótó kò sì rí bó ṣe yẹ kó rí. Àmọ́ o, ọ̀ràn ìmọ́tótó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ògbógi fojú bù ú pé àwọn kòkòrò àrùn tó ń wọ ẹnu àwọn ọmọ kékeré nígbà tí wọ́n bá fi ọwọ́ ìdọ̀tí kan ẹnu tàbí tí wọ́n jẹ oúnjẹ ẹlẹ́gbin tàbí mu omi ẹlẹ́gbin ló ń fa èyí tó pọ̀ jù nínú gbogbo àìsàn tó ń ṣe wọ́n àti ikú tó ń pa wọ́n. Ó ṣeé ṣe láti dènà ọ̀pọ̀ àìsàn, pàápàá ìgbẹ́ gbuuru, nípa fífi àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí sílò, tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé Facts for Life, èyí tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé tẹ̀ jáde.
1 Máa da ìgbọ̀nsẹ̀ nù tàbí kó o máa bò ó mọ́lẹ̀
Ọ̀pọ̀ kòkòrò àrùn ló máa ń wà nínú ìgbọ̀nsẹ̀. Bí àwọn kòkòrò tó ń fi àrùn ṣeni bá dé inú omi mímu tàbí oúnjẹ, tàbí tí wọ́n kan ọwọ́ wa, ohun èlò tá a fi ń se oúnjẹ, orí ibi tá a ti ń gbọ́únjẹ tàbí tá a ti ń bù ú, wọ́n lè kàn wá lẹ́nu kí a sì gbé wọn mì, èyí á sì yọrí sí àìsàn. Ọ̀nà tó dára jù lọ láti dènà ìtànkálẹ̀ irú àwọn kòkòrò àrùn bẹ́ẹ̀ ni nípa dída gbogbo ìgbọ̀nsẹ̀ nù. Inú ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ṣáláńgá ló yẹ ká máa ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí. Máa rí i dájú pé kò sí ìgbẹ́ ẹranko kankan nítòsí ilé, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tàbí níbi tí àwọn ọmọdé ti ń ṣeré.
Níbi tí kò bá ti sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ṣáláńgá, máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Rántí pé gbogbo ìgbọ̀nsẹ̀ ló ní àwọn kòkòrò tó lè kó àrùn ranni, kódà ìgbọ̀nsẹ̀ àwọn ọmọ ọwọ́ pàápàá. Ó yẹ ká máa da ìgbọ̀nsẹ̀ àwọn ọmọ ọwọ́ pẹ̀lú sínú ṣáláńgá tàbí ká bò ó mọ́lẹ̀.
Máa fọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti ṣáláńgá déédéé. Máa fi nǹkan bo ṣáláńgá, kó o sì máa fi omi ṣan ìgbọ̀nsẹ̀ lọ nínú ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ìgbàlódé.
2 Máa fọ ọwọ́ rẹ
Ó yẹ kó o máa fọ ọwọ́ rẹ déédéé. Fífi ọṣẹ àti omi tàbí eérú àti omi fọwọ́ máa ń fọ àwọn kòkòrò àrùn kúrò lọ́wọ́ ẹni. Fífi omi ṣan ọwọ́ nìkan kò tó o, ó tún pọn dandan láti fi ọṣẹ tàbí eérú pa ọwọ́ kó o tó fi omi sí i.
Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o máa fọ ọwọ́ rẹ lẹ́yìn tó o bá ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ tán àti lẹ́yìn tó o bá ṣàndí fún ọmọ ọwọ́ tàbí ọmọ kékeré kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yàgbẹ́ tán. Bákan náà, máa fọ ọwọ́ rẹ lẹ́yìn tó o bá ti fọwọ́ kan ẹranko, ṣáájú kó o tó fọwọ́ kan oúnjẹ àti ṣáájú kó o tó fún àwọn ọmọdé lóúnjẹ.
Ọwọ́ fífọ̀ kò ní jẹ́ kí àwọn aràn tó ń kó àrùn ranni wọnú ara. Àwọn aràn wọ̀nyí kéré débi pé èèyàn ò lè fi ojú ìyójú rí wọn àyàfi kéèyàn lo awò tó ń sọ nǹkan di ńlá. Inú ìgbọ̀nsẹ̀ àti ìtọ̀ ni wọ́n ń gbé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún máa ń wà nínú omi tó dá rogún àti nínú erùpẹ̀, nínú ẹran tútù tàbí ẹran téèyàn ò sè jinná. Ọ̀nà pàtàkì kan téèyàn lè fi dènà àwọn aràn kó má bàa wọnú ara ni nípa fífọ ọwọ́ ẹni. Síwájú sí i, bó o bá ń wọ bàtà nígbà tó o bá wà nítòsí ṣáláńgá, èyí kò ní jẹ́ kí àwọn aràn tó ṣeé ṣe kó wà níbẹ̀ gba inú àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ wọ ara rẹ.
Àwọn ọmọdé sábà máa ń fi ọwọ́ kan ẹnu, nípa bẹ́ẹ̀ máa fọ ọwọ́ wọn déédéé, pàápàá lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ tán àti ṣáájú kí wọ́n tó jẹun. Kọ́ wọn láti máa fọ ọwọ́ wọn, kí wọ́n má sì máa ṣeré nítòsí ṣáláńgá, ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ibikíbi táwọn èèyàn bá ti ń ṣe ìgbọ̀nsẹ̀.
3 Máa fọ ojú rẹ lójoojúmọ́
Kí kòkòrò àrùn má bàa wọnú ẹyinjú rẹ, máa fi ọṣẹ àti omi fọ ojú rẹ lójoojúmọ́. Ó tún yẹ ká máa fọ ojú àwọn ọmọdé pẹ̀lú. Àwọn eṣinṣin tó ń gbé kòkòrò àrùn kiri máa ń bà sí ojú tó bá dọ̀tí. Àwọn kòkòrò àrùn wọ̀nyí lè fa àrùn ojú, kódà wọ́n lè fa ìfọ́jú pàápàá.
Máa yẹ ojú àwọn ọmọ rẹ wò déédéé. Ojú tó bá wà ní ipò tó dára máa ń dán gbinrin, kì í gbẹ fúrúfúrú. Bí ojú ọmọ rẹ bá gbẹ fúrúfúrú, tó pọ́n, tó wú, tàbí tó ń ṣepin, ó yẹ kó o gbé e lọ fún àyẹ̀wò lọ́dọ̀ òṣìṣẹ́ ìlera kan tàbí dókítà.
4 Omi tó mọ́ nìkan ni kó o máa lò
Àwọn ìdílé tó bá ń lo omi tó mọ́, tí wọn kò sì jẹ́ kí kòkòrò àrùn ráyè wọnú omi wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàìsàn. Bó o bá fẹ́ máa lo omi tó mọ́, máa pọn omi láti ẹnu ẹ̀rọ tó dáa, kì í ṣe látinú páìpù ẹ̀rọ tó ti bẹ́. O tún lè rí omi tó mọ́ nínú kànga tàbí ìsun omi tí kò lẹ́gbin. Omi téèyàn bá pọn nínú adágún, odò, àgbá omi tàbí kànga tí kò ní ìdérí kì í fi bẹ́ẹ̀ mọ́, àmọ́ ó ṣeé mu béèyàn bá sè é.
Ó yẹ ká máa fi nǹkan bo kànga. Ó yẹ ká máa fọ àwọn korobá, okùn ìfami àtàwọn ohun tí à ń pọnmi sí déédéé, ká sì máa gbé wọn sí ibi tó mọ́ tónítóní, kì í ṣe sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀. A kò gbọ́dọ̀ fàyè gba àwọn ẹranko nítòsí ibi tí omi mímu wà àti níbi tí àwọn aráalé ń lò sí. Má ṣe máa lo àwọn oògùn apakòkòrò àrùn tàbí kẹ́míkà nítòsí ibi tí omi lílò wà.
Nínú ilé, ó yẹ ká jẹ́ kí omi mímu wà nínú ohun ìpọnmisí tó mọ́ tónítóní, tí a sì fi nǹkan bò. Ohun tó dára jù ni pé ká máa lo ohun ìpọnmisí tí wọ́n ṣe ẹnu ẹ̀rọ sí. Bí wọn ò bá ṣe ẹnu ẹ̀rọ sí i, ìkéèmù tàbí kọ́ọ̀pù tó mọ́ ló yẹ ká máa fi bu omi látinú ohun ìpọnmisí náà. A kò gbọ́dọ̀ gba ẹnikẹ́ni láyè láti ki ọwọ́ ìdọ̀tí bọnú omi náà.
5 Má ṣe jẹ́ kí àwọn kòkòrò àrùn wọnú oúnjẹ rẹ
Bó o bá se oúnjẹ jinná dáadáa, á ṣeé ṣe fún ọ láti pa àwọn kòkòrò àrùn. Ó yẹ ká máa se oúnjẹ jinná dáadáa, pàápàá ẹran màlúù tàbí ẹran adìyẹ. Àwọn kòkòrò àrùn kì í pẹ́ di púpọ̀ nínú oúnjẹ lílọ́wọ́ọ́rọ́. Nítorí náà, ó yẹ ká máa tètè jẹ oúnjẹ lẹ́yìn tá a bá ti sè é tán. Bó bá pọn dandan pé kó o tọ́jú oúnjẹ fún ohun tó ju wákàtí méjì lọ, rí i pé o gbé e sí ibi tó gbóná tàbí ibi tó tutù. Bákan náà, bó bá pọn dandan pé kó o tọ́jú oúnjẹ sísè di ìgbà mìíràn kó o tó jẹ ẹ́, rí i pé o bò ó. Èyí kò ní jẹ́ kí eṣinṣin àtàwọn kòkòrò mìíràn ráyè wọnú rẹ̀. Ṣáájú kó o tó jẹ oúnjẹ náà, tún un gbé kaná.
Wàrà ìyá ni wàrà tó dára jù lọ fún àwọn ọmọ ọwọ́ àtàwọn ọmọ kékeré. Wàrà ẹranko tí wọ́n rọra sè tàbí tí wọ́n ti sè dáadáa dára ju wàrà tí wọn kò sè lọ. Má ṣe máa fi fídà fún ọmọ rẹ lóúnjẹ, àyàfi bó o bá ń kọ́kọ́ fi omi gbígbóná fọ̀ ọ́ kó o tó lò ó. Àwọn kòkòrò àrùn tó ń fa ìgbẹ́ gbuuru sábà máa ń fara pa mọ́ sẹ́nu fídà. Fífún ọmọ lọ́mú tàbí lílo kọ́ọ̀pù tó mọ́ tónítóní dára ju lílo fídà lọ.
Máa fi omi tó mọ́ fọ èso àti ewébẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì gidigidi bó bá jẹ́ pé a ò sè é ká tó fún àwọn ọmọ ọwọ́ àtàwọn ọmọ kékeré jẹ.
6 Máa da gbogbo pàǹtírí inú ilé nù
Àwọn eṣinṣin, aáyán, lárìnká àti èkúté máa ń gbé kòkòrò àrùn kiri. Inú pàǹtírí làwọn ìṣẹ̀dá wọ̀nyí máa ń wà. Bí kò bá sí ètò ìkódọ̀tí níbi tó ò ń gbé, máa da gbogbo pàǹtírí inú ilé sínú kòtò kan níbi tó o lè máa rì í mọ́ tàbí kó o máa sun ún lójoojúmọ́. Máa rí i pé ilé rẹ wà ní mímọ́ tónítóní, má sì ṣe jẹ́ kí pàǹtírí àti omi ẹlẹ́gbin máa wà níbẹ̀.
Bó o bá ń ṣàmúlò àwọn àbá wọ̀nyí déédéé, wàá rí i láìpẹ́ pé wọ́n á mọ́ ọ lára. Wọn kò ṣòro láti mú lò, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò náni lówó rẹpẹtẹ, àmọ́ wọ́n á dáàbò bo ìlera ìwọ àti ìdílé rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Níbi tí kò bá ti sí ṣáláńgá tàbí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ìgbàlódé, máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Máa fọ ọwọ́ rẹ déédéé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]
Àwọn ìdílé tó bá ń lo omi tó mọ́, tí wọn kò sì jẹ́ kí kòkòrò àrùn ráyè wọnú rẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàìsàn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Máa fi ọṣẹ àti omi fọ ojú rẹ lójoojúmọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bó bá pọn dandan pé kó o tọ́jú oúnjẹ sísè di ìgbà mìíràn kó o tó jẹ ẹ́, rí i pé o bò ó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Máa sun àwọn pàǹtírí tàbí kó o máa rì wọ́n mọ́lẹ̀ lójoojúmọ́