Ibi Táráyé Ṣẹ́gun Àrùn Dé àti Ibi Tó Kù Sí
NÍ August 5, 1942, Dókítà Alexander Fleming rí i pé ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ń gbàtọ́jú lọ́dọ̀ rẹ̀ ń kú lọ. Àrùn yínrùnyínrùn ló ń da ọkùnrin ẹni ọdún méjìléláàádọ́ta yìí láàmú, pẹ̀lú gbogbo ipá tí Fleming sà, ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí dákú.
Lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣáájú ìgbà yẹn, Fleming ti ṣàdédé rí èròjà kan lára olú aláwọ̀ ewé mọ́ búlúù kan. Ó pè é ní penicillin. Ó kíyè sí i pé ó lágbára láti pa kòkòrò bakitéríà; ṣùgbọ́n kò mọ bó ṣe lè yọ ògidì penicillin lára rẹ̀, bí oògùn kòkòrò nìkan ló tíì lò ó rí. Àmọ́, nígbà tó di ọdún 1938, Howard Florey àtàwọn ikọ̀ rẹ̀ tí wọ́n jọ ń ṣe ìwádìí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Yunifásítì Oxford pinnu pé àwọn á sa gbogbo ipá àwọn láti ṣe oògùn náà sí i, kó sì pọ̀ tó iye táwọn èèyàn á lè lò wò. Fleming tẹ Florey láago, Florey sì gbà láti kó gbogbo penicillin tó ní fún un. Ohun tó kù tí Fleming lè ṣe rèé láti gbẹ̀mí ọ̀rẹ́ rẹ̀ là.
Àrùn yìí kọjá èyí tí abẹ́rẹ́ ìdí tàbí ti apá lè ràn, nítorí náà, tààràtà ni Fleming gún ọ̀rẹ́ rẹ̀ lábẹ́rẹ́ ní ọ̀pá ẹ̀yìn. Oògùn penicillin náà pa gbogbo kòkòrò yẹn; lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan péré sígbà yẹn ara ọ̀rẹ́ Fleming ti yá, araare ló sì bá kúrò nílé ìwòsàn. Ayé ti dayé oògùn apakòkòrò àrùn báyìí, àwọn èèyàn sì ti rí ọ̀nà àbáyọ láti lè máa ṣẹ́gun àrùn.
Ayé Dayé Oògùn Apakòkòrò Àrùn
Nígbà táwọn oògùn apakòkòrò àrùn kọ́kọ́ dé, oògùn ajẹ́bíidán ni wọ́n. Àwọn àrùn tí kòkòrò bíi bakitéríà àtàwọn mìíràn ń fà tí wọ́n ò gbóògùn tẹ́lẹ̀ rí ti wá ṣeé tọ́jú báyìí tí wọ́n á sì lọ. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn oògùn tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ ṣe, iye àwọn tí àrún yínrùnyínrùn, otútù àyà, àti ibà amáraléròrò ń pa ti dín kù gan-an ni. Àwọn àrùn téèyàn ń kó nílé ìwòsàn tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ ikú lẹ̀rọ̀ wọn ti wá di èyí tó ń kúrò lára láàárín ọjọ́ díẹ̀.
Látìgbà ayé Fleming àwọn olùwádìí ti ṣe oògùn apakòkòrò àrùn tó pọ̀ sí i, títí di ìsinsìnyí wọn ṣì ń wádìí àwọn mìíràn lọ ni. Láti ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn làwọn oògùn apakòkòrò àrùn ti wá di ohun tó ń ṣọkọ fún àrùn. Ká ní George Washington ṣì wà láyé dòní ni, kò sí àníàní pé àwọn dókítà á fi oògùn apakòkòrò àrùn tọ́jú ọ̀nà ọ̀fun tó ń dùn ún, ó sì ṣeé ṣe kára ẹ̀ yá láàárín bí ọ̀sẹ̀ kan. Ọ̀pọ̀ àrùn làwọn oògùn apakòkòrò àrùn ti rẹ́yìn wọn. Àmọ́, ó ṣe kedere pé ó níbi táwọn oògùn apakòkòrò àrùn wọ̀nyí kù díẹ̀ káàtó sí o.
Oògùn apakòkòrò àrùn kì í ṣiṣẹ́ fún àwọn àrùn táwọn kòkòrò fáírọ́ọ̀sì ń fà bí àrùn éèdì tàbí àrùn gágá. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan wà tí oògùn tó ń pa kòkòrò àrùn ò bá lára mu. Àwọn oògùn apakòkòrò kan wà tó jẹ́ pé dìgbòlugi ni wọ́n, wọ́n lè pa àwọn kòkòrò kéékèèké tó ṣàǹfààní fára dà nù. Ṣùgbọ́n bóyá nìṣòro míì wà tó burú ju àlòjù àti àìlòtó oògùn apakòkòrò.
Béèyàn ò bá lò tó iye tí dókítà ní kó lò bóyá nítorí pé ó gbà pé ara òun ti yá tàbí pé á ti pẹ́ jù kó tó lò ó tán, àìlòtó oògùn apakòkòrò nìyẹn. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, oògùn apakòkòrò lè má pa gbogbo bakitéríà tó wà lára, àwọn tó rọ́kú nínú wọn tó bá yè é á sì máa gbá yìn-ìn. Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n bá ń tọ́jú ẹni tó ní ikọ́ fée rèé.
Àtàwọn dókítà o, àtàwọn àgbẹ̀ o, kò séyìí tó wẹ̀ tó yán kànrìnkàn tó bá dọ̀rọ̀ àlòjù àwọn oògùn tuntun yìí. Ìwé Man and Microbes sọ pé: “Wọ́n ti máa ń fúnni ní oògùn apakòkòrò àrùn jù lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, wọ́n tiẹ̀ máa ń lò ó nílòkulò jù bẹ́ẹ̀ lọ láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Wọ́n máa ń rọ wọn sínú oúnjẹ fáwọn ẹran ọ̀sìn, kì í ṣe torí àrùn o, ṣùgbọ́n kí wọ́n bàa lè tètè dàgbà; ìdí rèé tí ọ̀pọ̀ oògùn ò fi ran àwọn kòkòrò àrùn mọ́.” Ìwé náà wá kìlọ̀ pé ìyẹn lè ṣokùnfà “ká máà láwọn oògùn tuntun tó lè pa kòkòrò àrùn mọ́.”
Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí ti ominú tó ń kọ wọ́n nítorí àwọn oògùn kòkòrò àrùn tí ò fẹ́ máa pa àwọn kòkòrò mọ́ yìí, láàárín àádọ́ta ọdún tó kẹ́yìn ọ̀rúndún ogún ọ̀pọ̀ àrùn ni ìmọ̀ ìṣègùn ti gbá wọlẹ̀. Ó dà bíi pé àwọn olùṣèwádìí lórí ìmọ̀ ìṣègùn lè ṣẹ́gun gbogbo àrùn pátá. Ó sì ń dà bíi pé lọ́jọ́ iwájú àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára lè dènà gbogbo àrùn.
Ìmọ̀ Ìṣègùn Ṣẹ́gun Àwọn Àrùn Díẹ̀
Ìwé ìròyìn ọdọọdún náà, The World Health Report 1999, sọ pé: “Àṣeyọrí tá a tíì rí tó wúni lórí jù nínú ètò ìlera ni bí wọ́n ṣe ń fún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára.” Látàrí bí wọ́n ṣe ń fáwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára kárí ayé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn ni wọ́n ti gbẹ̀mí wọn là. Nígbà kan tí wọ́n fún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára ní gbogbo ayé, wọ́n ti gbá àrùn olóde wọlẹ̀; àrùn burúkú yìí pààyàn ju àpapọ̀ gbogbo ogun tí wọ́n jà ní ọ̀rúndún ogún lọ; irú ètò ìgbabẹ́rẹ́ àjẹsára kan náà ti fẹ́rẹ̀ gbá àrùn rọpárọsẹ̀ pẹ̀lú wọlẹ̀. (Wo àpótí náà, “Ibí Tí Apá Ká Àrùn Olóde àti Rọpárọsẹ̀ Dé.”) Wọ́n ti fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára báyìí láti dènà ọ̀pọ̀ àrùn tó ń pọmọ ní rèwerèwe.
Wọ́n tiẹ̀ ti ká àwọn àrùn mìíràn lọ́wọ́ kò láìlo abẹ́rẹ́ àjẹsára. Àwọn àrùn tí wọ́n máa ń kó látinú omi mímu, bí àrùn onígbá méjì kì í sábà jà níbi tí wọ́n bá ti ń ṣe ìmọ́tótó tí omi tó dára fún mímu sì wà. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, bó ṣe rọrùn láti rí dókítà àti báwọn ilé ìwòsàn ṣe pọ̀ nílùú ti jẹ́ kó rọrùn láti tètè mọ àrùn tó ń ṣeni ká sì bójú tó o kó tó di ran-nto. Oúnjẹ tó dára táráyé ń rí jẹ àti bófin tó múlẹ̀ ṣe wà lórí àbójútó àti ìtọ́jú oúnjẹ pẹ̀lú ti ṣàlékún ìlera tó dára fún gbogbo èèyàn.
Táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ bá ti lè mọ ohun tó ń fa àjàkálẹ̀ àrùn báyìí, á ṣeé ṣe fáwọn aláṣẹ ìjọba lórí ètò ìlera láti tètè máa dá ríràn rẹ̀ dúró. Ìwọ gbé àpẹẹrẹ kan péré yẹ̀ wò. Àrùn tó máa ń jẹ́ kí kókó so sára tó bẹ́ sílẹ̀ nílùú San Francisco lọ́dún 1907 ò pààyàn púpọ̀ nítorí pé àwọn aráàlú tètè gbógun ti àwọn eku tí yọ̀rọ̀ ara wọn ń fa àrùn ọ̀hún. Bẹ́ẹ̀ sì rèé lórílẹ̀ èdè Íńdíà, àrùn kan náà yìí ti fi ọdún méjìlá jà, bẹ̀rẹ̀ látọdún 1896, ó sì pa tó mílíọ̀nù mẹ́wàá èèyàn nítorí pé wọn ò tíì mọ ohun tó ń fà á nígbà yẹn.
Àwọn Ibi Tó Kù Sí Lórí Gbígbógun Ti Àrùn
Ó hàn gbangba pé àwọn àrùn kan ti dàwátì. Ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù làwọn àṣeyọrí kan tí wọ́n ti ṣe nínú ètò ìlera mọ sí. Àwọn àrùn tó ṣeé wò ṣì ń pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn nítorí pé wọn ò lówó lọ́wọ́. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀sẹ̀ ń gòkè àgbà, kò tíì ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ní ìmọ́tótó, ìtọ́jú ìṣègùn tó dára àti omi tó ṣeé mu. Ohun tó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ burú tó bẹ́ẹ̀ ni báwọn èèyàn ṣe ń ya kúrò láwọn ìlú kéékèèké tí wọ́n ń ṣí lọ sáwọn ìlú ńlá ńlá láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Àwọn nǹkan tó fà á rèé tó fi jẹ́ pé ibi táwọn tálákà pọ̀ sí “ni ibùjókòó àrùn,” gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe pè é.
Ohun táwọn èèyàn fẹ́ jẹ nìkan ni wọ́n mọ̀, èyí ló ń fà á táwọn orílẹ̀-èdè kan fi ń lárùn lára ju àwọn mìíràn lọ. Ìwé Man and Microbes sọ pé: “Àwọn ibi tí àrùn tó burú jù lọ ti ń jà jìnnà réré sáwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà. Àwọn ilẹ̀ olóoru nìkan ni díẹ̀ lára àwọn àrùn yìí wà.” Àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ tó sì ti gòkè àgbà àtàwọn ilé iṣẹ́ oògùn ò fara mọ́ yíya owó sọ́tọ̀ láti tọ́jú àrùn wọ̀nyí níwọ̀n bí wọn ò ti ní rí nǹkan jẹ lórí ẹ̀.
Ìwà èdìdààrẹ́ táwọn èèyàn fúnra wọn ń hù tún ń ṣe nínú bí àrùn ṣe ń tàn kálẹ̀. Àpẹẹrẹ tá a lè fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà tó lè tètè yé wa ni ti kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì tó ń gba inú gbogbo nǹkan bí omi látara ẹnì kan dé ara ẹlòmíràn. Láàárín ọdún mélòó kan, àjàkálẹ̀ àrùn yìí ti tàn káàkiri ayé. (Wo àpótí náà “Éèdì—Àgbákò Àkókò Wa.”) Joe McCormick tó jẹ́ onímọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn sọ pé: “Àwọn ọmọ èèyàn ló fọwọ́ ara wọn fà á fúnra wọn. Eléyìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé à ń ṣòfin lórí bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà, òótọ́ pọ́ńbélé ni.”
Báwo làwọn èèyàn ṣe ń tan kòkòrò àrùn éèdì kálẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀? Ìwé náà, The Coming Plague sọ pé àwọn nǹkan tó lè fà á rèé: Bí nǹkan ṣe ń yí padà láwùjọ, pàápàá jù lọ báwọn kan ṣe ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi èèyàn, èyí ló jẹ́ kí àrùn tí wọ́n ń kó látinú ìbálòpọ̀ máa tàn kálẹ̀ tó sì jẹ́ kí kòkòrò tó ń fa àrùn náà rídìí jókòó, èyí sì ń jẹ́ káwọn tó lárùn náà lè máà pín in fẹ́ni tí kò tíì ní in. Òmíràn ni lílò táwọn oníṣègùn láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà máa ń lo abẹ́rẹ́ tí ẹni tó lárùn náà ti lò láti tọ́jú ẹlòmíràn tàbí fífà táwọn èèyàn ń fi irú abẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀ fa oògùn olóró sára. Àwọn tó ń ta ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ń fà síni lára pẹ̀lú ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àrùn éèdì láti máa ti ọ̀dọ̀ ẹnì kan dé ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn nípa títa ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà látara ẹni tó ti lárùn náà nítorí owó gọbọi tí wọ́n ń pa lórí ẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, àlòjù tàbí àìlòtó oògùn apakòkòrò àrùn ń jẹ́ kí onírúurú kòkòrò àrùn tí ò gbóògùn túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Ìṣòro ńlá lèyí, ó sì ń burú sí i ni. Tẹ́lẹ̀, bakitéríà tó ń jẹ́ staphylococcus, tó máa ń wọ ojú egbò máa ń kú bí wọn bá ti fi èròjà tí wọ́n máa ń rí látara oògùn tó ń jẹ́ penicillin sí i. Ṣùgbọ́n, ní báyìí o, àwọn oògùn apakòkòrò àrùn wọ̀nyẹn kì í síṣẹ́ mọ́ lọ́pọ̀ ìgbà. Nítorí náà àfi káwọn dókítà máa lo oògùn apakòkòrò àrùn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe, tó wọ́nwó, tó sì jẹ́ pé èkukáká la fi lè rí i nílé ìwòsàn láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Kódà, àwọn oògùn apakòkòrò àrùn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde gan-an lè máà kápá àwọn kòkòrò àrùn mìíràn, ìyẹn sì lè jẹ́ káwọn àrùn tí wọ́n ń kó nílé ìwòsàn máa pọ̀ sí i, kí wọ́n sì máa pààyàn púpọ̀ sí i. Dókítà Richard Krause, tó fìgbà kan rí jẹ́ alábòójútó Ibùdó fún Èèwọ̀ Ara Àtàwọn Àrùn Tó Ń Ràn ní Amẹ́ríkà, júwe ọ̀rọ̀ náà ṣàkó gẹ́gẹ́ bí “ìṣòro àjàkálẹ̀ àrùn ti àwọn kòkòrò tí ò gbóògùn.”
“Ṣé Nǹkan Ti Ṣẹ́ Pẹ́rẹ́ Lónìí?”
Nísinsìnyí, níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún, ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn ò tíì yé bẹ̀rù àrùn. Àrùn éèdì tó ń ràn mù-ùn láìdáwọ́dúró, àwọn kòkòrò tí oògùn ò ràn tí wọ́n ń sú yọ, àwọn àrùn tó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń pààyàn bí ikọ́ fée àti ibà—gbogbo èyí fi hàn pé aráyé ò tíì rẹ́yìn àrùn.
Joshua Lederberg tó gba àmì ẹ̀yẹ Nobel béèrè pé: “Tá a bá fi òde òní wé ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, èwo ló sàn jù?” Ó dáhùn pé: “Lọ́nà tó pọ̀ jù lọ ni àkókò tiwa fi burú jù. Nítorí pé a ti gbójú fo àwọn kòkòrò àrùn dá, àwọn ló wá ń fín wa lápe báyìí.” Ṣé tí wọ́n bá káràmáásìkí lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn, tí gbogbo orílẹ̀-èdè àgbáyé sì ṣán ṣòkòtò wọn, a lè borí àwọn ibi tí ọ̀ràn ìlera kù díẹ̀ káàtó sí? Ṣé a lè rẹ́yìn àwọn àrùn tó gbajúmọ̀ bá ṣe rẹ́yìn àrùn olóde? Àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn yóò tú iṣu àwọn ìbéèrè wọ̀nyí désàlẹ̀ ìkòkò.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ibí Tí Apá Ká Àrùn Olóde àti Rọpárọsẹ̀ Dé
Níparí oṣù October 1977, Àjọ Ìlera Àgbáyé rí èyí tó gbẹ̀yìn lára ohun tó ń jẹ́ kárùn olóde ṣàdédé bẹ́ sílẹ̀. Àìsàn yìí kọlu Ali Maow Maalin, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Sòmálíà, tó ń dáná fún wọn ní ilé ìwòsàn kan, àmọ́ kò dá a gúnlẹ̀, ara rẹ̀ sì yá láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan. Gbogbo àwọn tó sún mọ́ ọn ni wọ́n fún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára.
Fún ọdún méjì gbáko làwọn dókítà fi ń retí ẹni tá tún lárùn náà. Wọ́n ṣèlérí pé àwọn á fún ẹnikẹ́ni tó bá lè fẹ̀rí ẹ̀ hàn pé òun rí “ibi tí àrùn olóde ti ń pa wọ́n” ní ẹgbẹ̀rún kan owó dọ́là. Kò mà sẹ́ni tó lè yọjú kó sì gba ẹ̀bùn yìí o, nígbà tó sì di May 8, 1980, Àjọ Ìlera Àgbáyé kéde ní gbangba pé “gbogbo aráyé pátá ti bọ́ lọ́wọ́ olóde o.” Lọ́dún mẹ́wàá péré ṣáájú ìgbà náà, nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì èèyàn ni olóde ń pa lọ́dọọdún. Ìyẹn jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ láyé tí wọ́n rẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pani nípakúpa.a
Ó dà bí i pé aráyé ò ní pẹ́ rẹ́yìn àrùn rọpárọsẹ̀ tó máa ń sọ àwọn ọmọdé daláàbọ̀ ara. Lọ́dún 1955, Jonas Salk ṣe oògùn tó kápá àrùn rọpárọsẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gba abẹ́rẹ́ àjẹsára nílẹ̀ Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn àjẹsára tí wọ́n ń tọ́ sí èèyàn lẹ́nu. Lọ́dún 1988, Àjọ Ìlera Àgbáyé bẹ̀rẹ̀ ètò bí wọ́n ṣe máa gbá àrùn rọpárọsẹ̀ dànù.
Dókítà Gro Harlem Brundtland, tó jẹ́ olùdarí Àjọ Ìlera Àgbáyé nígbà náà sọ pé: “Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ akitiyan yìí lọ́dún 1988, àrùn rọpárọsẹ̀ máa ń sọ àwọn ọmọ ọwọ́ tó ju ẹgbẹ̀rún kan lọ di arọ lójúmọ́. Ní 2001, iye àwọn ọmọ tó lárùn náà ò tó ẹgbẹ̀rún kan lódindi ọdún kan.” Kò tó orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí àrùn náà ṣì wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tabua ní wọ́n nílò láti lè ran àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè rẹ́yìn àrùn náà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àrùn kan tó rọrùn láti ṣẹ́gun ni olóde nítorí pé kò dà bí àwọn àrùn míì táwọn ohun abẹ̀mí bí eku àtàwọn kòkòrò máà ń tàn kálẹ̀, ara èèyàn nìkan ni kòkòrò tó ń fa olóde lè gbé.
[Àwòrán]
Ọmọkùnrin ará Etiópíà kan tí wọ́n fún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà àrùn rọpárọsẹ̀
[Credit Line]
© WHO/P. Virot
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àrùn Éèdì—Ìdààmú Àkókò Wa
Nígbà tí àrùn éèdì yọjú gbogbo àgbáyé ló ṣẹ̀rù bà. Ní báyìí, ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n, àwọn èèyàn tó ju ọgọ́ta mílíọ̀nù ló ti kó o. Àwọn aláṣẹ ètò ìlera sì kìlọ̀ pé éèdì “ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.” Iye àwọn tó ń kárùn yìí “túbọ̀ ń ròkè kọjá ibi tá a lérò pé ó lè dé,” ohun tó sì ń fojú wọn rí láwọn ibi tó ti ń báwọn fínra jù burú kọjá sísọ.
Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó lárùn éèdì tàbí tí kòkòrò yẹn wà lára wọn ló jẹ́ àwọn tí wọ́n ṣì lágbára láti ṣiṣẹ́.” Àwọn olùwádìí gbà pé nítorí náà tó bá fi máa di ọdún 2005, ìdámẹ́wàá sí ìdámárùn-ún àwọn èèyàn tó lè ṣiṣẹ́ ajé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó wà lápá gúúsù Áfíríkà ni yóò ti kú. Ìròyìn náà tún sọ pé: “Iye ọdún táwọn oníṣirò díwọ̀n pé àwọn ará àárín gbùngbùn ilẹ̀ Áfíríkà á lò láyé ti dín kù sí mẹ́tàdínláàádọ́ta. Ká ní kò sí ti àrùn éèdì ni, ì bá tó méjìlélọ́gọ́ta.”
Pàbó ni gbogbo ìsapá àwọn èèyàn láti rí oògùn tí wọ́n á fi dènà rẹ̀ ń já sí, ìdámẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn mílíọ̀nù mẹ́fà tó lárùn yìí ló sì ń gbàtọ́jú. Lójúmọ́ tó mọ́ lónìí o, éèdì ò lóògùn, àwọn dókítà sì ń bẹ̀rù pé gbogbo àwọn tí kòkòrò yìí ti wọnú ara wọn ló pàpà máa lárùn ọ̀hún.
[Àwòrán]
Sẹ́ẹ̀lì “lymphocyte T” kan tí kòkòrò àrùn éèdì ti wọ̀
[Credit Line]
Godo-Foto
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Òṣìṣẹ́ ilé àyẹ̀wò kan tó ń ṣàyẹ̀wò kòkòrò fáírọ́ọ̀sì kan tó ṣòro pa
[Credit Line]
CDC/Anthony Sanchez