Ayé Kan Níbi Tí Kò Ti Ní Sí Àrùn
“Ó yẹ kí gbogbo orílẹ̀-èdè pawọ́ pọ̀ bí òṣùṣù ọwọ̀ pẹ̀lú èròǹgbà láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè rí i pé ìlera wà fún gbogbo èèyàn nítorí pé ìrọ̀rùn igi ni ìrọ̀rùn ẹyẹ lọ̀rọ̀ ìlera láàárín àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè kan dé òmíràn.”—ÌPOLONGO ALMA-ATA, SEPTEMBER 12, 1978.
LỌ́DÚN mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sẹ́yìn, ó dà bíi pé á ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn tó wà láyé láti ní ìlera alábọ́dé. Àwọn aṣojú tó lọ síbi Ìpàdé Àpérò Lórí Ìlera Alábọ́dé tí wọ́n ṣe ní Alma-Ata tó wà ní orílẹ̀-èdè Kazakhstan báyìí, pinnu pé gbogbo èèyàn làwọn yóò fún ní àjẹsára láti dènà èyí tó wọ́pọ̀ lára àwọn àrùn tó ń ranni lọ́dún 2000. Wọ́n tún ronú pé tó bá fi máa di ọdún kan náà yẹn, àyíká tó mọ́ àti omi tó ṣeé mu á ti wà fún gbogbo aráyé. Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà nínú Àjọ Ìlera Àgbáyé ló tọ́wọ́ bọ̀wé ìpolongo náà.
Ohun tí wọ́n láwọn fẹ́ ṣe yìí má dára o, àmọ́ ẹnu dùn-ún ròfọ́ lọ̀rọ̀ náà dà. Ìlera alábọ́dé ò kárí gbogbo èèyàn, bẹ́ẹ̀ sì làwọn àrùn ṣì ń dún mọ̀huru mọ̀huru mọ́ aráyé. Àtọmọdé àtàgbà sì làwọn àrùn gbẹ̀mí gbẹ̀mí yìí ń dẹ́mìí wọn légbodò nígbà tí òdòdó wọn ṣì ń tàn.
Kódà àwọn àrùn tó dà bí ẹ̀ta òkò tí wọ́n ń dẹ́rù ba gbogbo èèyàn, ìyẹn àrùn éèdì, ikọ́ fée, àti ibà gan-an ò ní káwọn orílẹ̀-èdè “pawọ́ pọ̀ bí òṣùṣù ọwọ̀.” Wọ́n ní káwọn ìjọba orílẹ̀-èdè tó wà láyé dá iye owó tó jẹ́ bílíọ̀nù mẹ́tàlá dọ́là láti fi ṣètìlẹ́yìn fún ètò kan tí wọ́n fẹ́ fi gbógun ti àwọn àrùn yìí, ìyẹn Ètò Ìkówójọ Láti Gbógun Ti Éèdì, Ikọ́ Fée àti Ibà. Àmọ́, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2002, iye tí wọ́n rí kó jọ kàn rọra fi díẹ̀ ju bílíọ̀nù méjì dọ́là lọ ni, tó sì jẹ́ pé lọ́dún kan náà yìí, owó tí wọ́n ti ná lórí àwọn ọmọ ogun ti tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin bílíọ̀nù dọ́là! Ó mà ṣe o, aráyé ti kọ̀yìn síra wọn débi pé ìwọ̀nba ni ewu tí wọ́n lè torí rẹ̀ fìmọ̀ ṣọ̀kan kí gbogbo èèyàn bàa lè jàǹfààní.
Apá àwọn aláṣẹ lórí ètò ìlera gan-an kì í lè ká àwọn àrùn yìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò rere ni wọ́n ní lọ́kàn. Ìjọba lè má pèsè owó tó tó wọn lò. Oògùn ò ran àwọn kòkòrò àrùn mọ́ bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn fàáké kọ́rí pé bèbè àtikárùn làwọn ó ti máa gbé ìgbésí ayé àwọn. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn làlúrí bí òṣì, ogun, àti ìyàn tó ń bá àwọn kan fínra láwọn àgbègbè kan, ń ṣílẹ̀kùn fún àwọn kòkòrò àrùn láti pabùdó sí àgọ́ ara àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn.
Ọlọ́run Ò Dágunlá sí Ìlera Wa
Ojútùú wà. Ẹ̀rí tó ṣe kedere wà pé gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ lórí ìlera ọmọnìyàn ni Jèhófà Ọlọ́run ń kíyè sí. Ẹ̀rí tó dájú wà pé Ọlọ́run ò dágunlá sí ìlera aráyé. A sì lè rí èyí tá a bá kíyè sí bó ṣe dá agbára ìdènà àrùn mọ́ wa. Ọ̀pọ̀ òfin tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì fi hàn pé ó ń fẹ́ láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn àrùn tó lè kéèràn ràn wọ́n.a
Jésù Kristi tó fi bí Bàbá rẹ̀ ọ̀run ṣe rí hàn wà pàápàá lo ìyọ́nú fáwọn aláìsàn. Ìhìn Rere Máàkù ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù pàdé ọkùnrin kan tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀. Adẹ́tẹ̀ yẹn sọ pé: ‘Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.’ Nígbà tí Jésù rí bí ọkùnrin yẹn ṣe ń jẹ̀rora àti ìyà tó ń forí rọ́, àánú ẹ̀ ṣe é. Jésù dá a lóhùn pé: ‘Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́.’—Máàkù 1: 40, 41, Bíbélì Mímọ́.
Kì í ṣe àwọn èèyàn díẹ̀ ni Jésù fi iṣẹ́ ìyanu wò sàn. Òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Mátíù kọ̀wé pé Jésù “lọ yí ká jákèjádò Gálílì, ó ń kọ́ni . . . ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà, ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú [àrùn] àti gbogbo onírúurú àìlera ara láàárín àwọn ènìyàn.” (Mátíù 4:23) Àwọn èèyàn tó ṣàìsàn ní Jùdíà àti Gálílì nìkan kọ́ làwọn ìwòsàn tó ṣe yẹn ràn lọ́wọ́. Wọ́n jẹ́ ká rí bí gbogbo àrùn ṣe máa dàwátì nígbẹ̀yìngbẹ́yín nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù ń wàásù nípa rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso lórí gbogbo ènìyàn láìsí àtakò.
Ìlera fún Gbogbo Àgbáyé Kì Í Ṣe Àlá Tí Ò Lè Ṣẹ
Bíbélì fi dá wa lójú pé ìlera fún gbogbo àgbáyé kì í ṣe àlá tí ò lè ṣẹ. Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran ìgbà tí ‘àgọ́ Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú aráyé.’ Nígbà tí Ọlọ́run bá wá pàgọ́ tì wá báyìí, “ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Èyí ò wa dà bí àsọdùn lásán bí? Ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ polongo pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.”—Ìṣípayá 21:3-5.
Kò sí bí òpin ṣe lè dé bá àrùn láìṣe pé òṣì, ìyàn àti ogun ò sí mọ́ nítorí pé àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ń kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú àwọn kòkòrò àrùn ni. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi yan iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí fún Ìjọba rẹ̀, ìyẹn ìjọba ọ̀run tó wà níkàáwọ́ Kristi. Gẹ́gẹ́ bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ṣe ń gbàdúrà tọkàn tara, ìjọba yìí yóò dé, yóò sì rí i dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 6:9, 10.
Ìgbà wo ni ká wá máa retí Ìjọba Ọlọ́run sí o? Nígbà tí Jésù ń dáhùn ìbéèrè yẹn ó sàsọtẹ́lẹ̀ pé ayé á rí oríṣiríṣi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tá á jẹ́ àmì pé Ìjọba Ọlọ́run kò ní pẹ́ ṣe nǹkan kan. Ọ̀kan nínú àwọn àmì wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ ni pé ‘àjàkálẹ̀ àrùn yóò máa jà láti ibi kan dé ibòmíràn.’ (Lúùkù 21:10, 11; Mátíù 24:3, 7) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “àjàkálẹ̀ àrùn” tọ́ka sí “àrùn èyíkéyìí tó lè ran èèyàn.” Ní ọ̀rúndún ogún a rí bí ọ̀pọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn tó ń ṣẹ̀rù ba àwọn èèyàn ṣe jà láìka bí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn ti rìn jìnnà tó sí.—Wo àpótí náà, “Iye Àwọn Tí Àjàkálẹ̀ Àrùn Pa Látọdún 1914.”
Àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Ìṣípayá tó bá àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó wà nínú ìwé Ìhìn Rere mu, fi hàn bí oríṣiríṣi àwọn ẹlẹ́ṣin ṣe ń tẹ̀ lé Jésù Kristi nígbà tó gbagbára lọ́run. Ẹlẹ́ṣin kẹrin ń gun “ẹṣin ràndánràndán kan,” ó sì ń fọ́n “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani” nítorí pé iṣẹ́ tiẹ̀ nìyẹn. (Ìṣípayá 6:2, 4, 5, 8) Tá a bá wo iye àwọn èèyàn táwọn àjàkálẹ̀ àrùn tó gbòde ń pa látọdún 1914, a ó rí i dájú pé ẹlẹ́ṣin tá a ṣàpẹẹrẹ yìí ti ń gẹṣin rẹ̀. Ìjìyà tí “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani” ti mú báwọn èèyàn kárí ayé tún fi ọ̀kan kún ẹ̀rí tó wà pé Ìjọba Ọlọ́run ò ní pẹ́ dé.b—Máàkù 13:29.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìlera ti dín bí àjàkálẹ̀ àrùn ṣe ń tàn kálẹ̀ kù, ó ṣeé ṣe kí àjàkálẹ̀ àrùn mìíràn bẹ́ sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó ṣe kedere pé ohun tá yanjú ìṣòro yìí tán yán-án-yán kọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn. Ẹlẹ́dàá wa sì ṣèlérí pé òun á yanjú ẹ̀. Wòlíì Aísáyà mú un dá wa lójú pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Síwájú sí i, “[Ọlọ́run] yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Aísáyà 25:8; 33:22, 24) Nígbà tí ojúmọ́ ọjọ́ náà bá mọ́, àrùn á ti dọ̀rọ̀ ìtàn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Òfin Mósè ní àwọn ìtọ́ni tó kan bí wọ́n á ṣe máa palẹ̀ ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́, ìmọ́tótó, àti sísé alárùn mọ́. Dókítà H. O. Philips sọ pé “àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ àti ìbímọ, ṣíṣàyẹ̀wò àìsàn, ìtọ́jú aláìsàn, àti dídènà àìsàn ṣiṣẹ́ ju àwọn èrò orí Hippocrates lọ.”
b Àlàyé lórí àwọn àmì mìíràn tó fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ò ní pẹ́ dé wà ní orí kọkànlá ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Iye Àwọn Ti Àjàkálẹ̀ Àrùn Pá Látọdún 1914
Àfojúbù làwọn ìṣirò tó wà níbí o. Àmọ́ wọ́n fi hàn bí àjàkálẹ̀ àrùn ṣe han aráyé léèmọ̀ tó látọdún 1914.
◼ Olóde (ó pa tó bí ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù èèyàn) Kò sí ìgbà kan rí tí wọ́n tíì ṣe oògùn kan to lè tọ́jú ẹni tó bá lárùn olóde. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ètò àjẹsára kárí ayé kan tí wọ́n ṣe ló pa á run lọ́dún 1980.
◼ Ikọ́ fée (ó pa tó bí ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù sí àádọ́jọ mílíọ̀nù èèyàn) Ikọ́ fée ń pa iye àwọn ènìyàn tá tó ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dún, ẹnì kan nínú mẹ́ta tó wà láyé báyìí ló sì ní kòkòrò àrùn tó ń fa ikọ́ fée lára.
◼ Ibà (ó pa tó bí ọgọ́rin mílíọ̀nù sí ọgọ́fà mílíọ̀nù èèyàn) Fún àádọ́ta ọdún àkọ́kọ́ ní ọ̀rúndún ogún, àwọn èèyàn tí ibà pa fẹ́rẹ̀ tó ọgọ́rùn-un ọ̀kẹ́ tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ibi tó sì ti ń pààyàn jù lọ ni àárín gbùngbùn ilẹ̀ Áfíríkà, níbi tó ti ń pa iye tó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ lọ́dún.
◼ Àrùn gágá (ó pa tó bí ogún mílíọ̀nù sí ọgbọ̀n mílíọ̀nù èèyàn) Àwọn òpìtàn kan sọ pé iye àwọn tó pa jù bẹ́ẹ̀ lọ fíìfíì. Àrùn panipani yìí pa àwọn èèyàn lápalù káàkiri ayé ní ọdún 1918 àti 1919 bí ogun àgbáyé kìíní ṣe parí. Ìwé Man and Microbes sọ pé: “Kódà àrùn tó ń jẹ́ kí kókó so síni lára gan-an kì í yára pààyàn tó bẹ́ẹ̀.”
◼ Ibà jẹ̀funjẹ̀fun (ó pa tó bí ogún mílíọ̀nù èèyàn) Àrùn ibà jẹ̀funjẹ̀fun sábà máa ń bá ogun rìn ni, ogun àgbáyé kìíní sì hú ibà jẹ̀funjẹ̀fun kan síta èyí tó pààyàn bíi rẹ́rẹ ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù.
◼ Àrùn éèdì (ó pa iye tó ju ogún mílíọ̀nù èèyàn) Àjálù ti éèdì yìí ń pa tó mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn lọ́dún ní báyìí. Ìṣirò tí Ètò Àbójútó Àrùn Éèdì ti Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé “nítorí pé kò sí ọ̀nà tá a fi lè kòòré àrùn éèdì àti bá a ṣe lè tọ́jú rẹ̀, èèyàn mílíọ̀nù méjìdínláàádọ́rin ló máa pa . . . láàárín ọdún 2000 sí 2020.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run irú àwọn àrùn báyìí ò ní bà wá lẹ́rù mọ́
Éèdì
Ibà
Ikọ́ fée
[Àwọn Credit Line]
Éèdì: CDC; ibà: CDC/Dókítà Melvin; Ikọ́ fée: © 2003 Dennis Kunkel Microscopy, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jésù wo onírúurú àrùn àti àìlera