Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Yẹ Kó O Máa Ṣeré Ìmárale?
“Máa ṣeré ìmárale lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ kára ẹ lè le dáadáa. Máa fi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ṣeré ìmárale lójúmọ́. Má mu ọtí líle kó o má bàa ní àrùn jẹjẹrẹ. Máa mu ọtí líle kí àrùn ọkàn má bàa tètè mú ọ. Ǹjẹ́ o ò ti ní máa rò ó pé àwọn ìmọ̀ràn táwọn èèyàn ń sọ pé ó dáa yìí ti pọ̀ jù fún ọ? Ìwé ìròyìn kan lè fi ohun kan ṣe àkọlé báyìí, kó tún di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e kó máa sọ nǹkan míì. . . . Kí ló dé térò àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ò fi jọra ná? Kí ló dé tí wọ́n á sọ lọ́sẹ̀ kan pé kọfí léwu, táá sì tún di ọ̀sẹ̀ míì tí wọ́n á ní kò léwu mọ́?” —Barbara A. Brehm, ọ̀mọ̀wé nínú ẹ̀kọ́ nípa eré ìmárale àti eré ìdárayá ló sọ̀rọ̀ yìí.
ÀWỌN ọ̀mọ̀ràn lórí ìlera sábà máa ń tako ara wọn tó bá dọ̀ràn oúnjẹ jíjẹ àti bára á ṣe máa mókun. Ọ̀pọ̀ “ṣe tibí,” “má ṣe tọ̀hún” lórí kára lè le ti da gbogbo ẹ̀ rú mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lójú. Àmọ́, tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn máa fi ara rẹ̀ ṣiṣẹ́ lọ́nà tó mọ níwọ̀n, ó dà bíi pé ẹnu àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò, ohun tí gbogbo wọn ń sọ ni pé tó o bá fẹ́ kara rẹ le, o gbọ́dọ̀ máa ṣeré ìmárale déédéé!
Báwọn èèyàn kì í ṣeé lo ara wọn ti di ìṣòro ńlá lákòókò tá a wà yìí, pàápàá láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti ń fi ẹ̀rọ ṣe gbogbo nǹkan. Láyé àtijọ́, àwọn èèyàn máa ń fọwọ́ ara wọn ṣe iṣẹ́ tó gba agbára bíi dídáko, dídẹ̀gbẹ́, tàbí kíkọ́lé. Lóòótọ́, iṣẹ́ àṣekúdórógbó táwọn baba ńlá wa ń ṣe kí wọ́n tó lè bu òkèlè nígbà yẹn sábà máa ń fa ìnira bá wọn, kódà ó máa ń gé wọn lẹ́mìí kúrú. Àní, gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹyọ̀ náà Encyclopædia Britannica ṣe sọ, “nílẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù ayé àtijọ́, iye ọdún táwọn èèyàn sábà máa ń gbé láyé jẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n.” Àmọ́, nígbà tó fi máa kù díẹ̀ ká bọ́ sí ọdún 2000, iye ọdún tí wọ́n fojú bù pé àwọn èèyàn á máa gbé láyé láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin. Kí ló fa ìyàtọ̀ náà?
Ṣé Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Ń Ṣe Wa Lóore Ni àbí Ó Ń Dá Ìṣòro Sílẹ̀?
Ìlera àwọn èèyàn tó ń gbé ayé lóde òní dáa ju tàwọn tó gbé ayé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, ẹ̀mí wọn sì ń gùn báyìí ju tìgbà yẹn lọ. Ara ohun tó fà á ni ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú. Àwọn ẹ̀rọ táwọn èèyàn ń ṣe báyìí ti mú kí ọ̀nà tá à ń gbà ṣe àwọn nǹkan yàtọ̀, àwọn iṣẹ́ tó gba agbára tẹ́lẹ̀ ti wá di iṣẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ báyìí. Ìmọ̀ ìṣègùn ti tẹ̀ síwájú gan-an lórí ọ̀rọ̀ ìgbóguntàrùn, ìyẹn sì ti mú kí ara ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ máa jí pépé. Àmọ́ ṣá, ọ̀rọ̀ yìí tún pakasọ lápá ibòmíì o.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti mú kí ìlera àwọn èèyàn jí pépé sí i, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ti sọ èèyàn tó pọ̀ gan-an dẹni tó ń jókòó sójú kan. Ẹgbẹ́ Tó Ń Tọ́jú Àrùn Ọkàn Nílẹ̀ Amẹ́ríkà gbé ìròyìn kan jáde láìpẹ́ yìí, èyí tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní International Cardiovascular Disease Statistics, ìyẹn ni àbájáde ìwádìí tí wọ́n ṣe kárí ayé lórí àrùn ọkàn àti òpójẹ̀. Nínú ìròyìn náà, wọ́n ṣàlàyé pé “ìtẹ̀síwájú nínú ètò ọrọ̀ ajé, ìdàgbàsókè ìgbèríko, ìdásílẹ̀ iléeṣẹ́ àti ayé tó lu jára ló mú kí ìyípadà dé bá báwọn èèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé, èyí ló sì ń mú kí àrùn ọkàn pọ̀ sí i.” Ìròyìn náà sọ pé “àìṣiṣẹ́ tó gba agbára àti àìjẹ oúnjẹ tó ṣara lóore” wà lára olórí ohun tó ń mú kí ìṣòro náà pọ̀ sí i.
Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ní àádọ́ta ọdún péré sẹ́yìn, a lè rí ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ àṣekára táá máa fi ẹṣin àti ohun èlò ìtúlẹ̀ ṣiṣẹ́ lóko táá sì máa làágùn yọ̀bọ̀. Kẹ̀kẹ́ ló máa ń gùn lọ sábúlé àti báńkì, tó bá sì tún di ìrọ̀lẹ́, á ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan nínú ilé. Àmọ́, báwọn ọmọ ọmọ ẹ̀ ṣe ń gbé ìgbé ayé tiwọn yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Òṣìṣẹ́ òde òní lè jókòó sídìí kọ̀ǹpútà látàárọ̀ títí tó fi máa ṣíwọ́ iṣẹ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ibi gbogbo láá máa gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ lọ, bó bá sì dìrọ̀lẹ́, ìdí tẹlifíṣọ̀n ló máa jókòó sí.
Bí ìwádìí kan ṣe fi hàn, nígbà kan rí, àwọn agégẹdú ará ilẹ̀ Sweden máa ń yọ́ ooru tó pọ̀ tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún méje kálórì dà nù lójúmọ́ níbi tí wọ́n ti ń gégi tí wọ́n sì ń gbé e. Àmọ́ báyìí, àwọn ẹ̀rọ tó lágbára ni wọ́n máa ń lò fún èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ alágbára tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀nà tó wà láyé ni wọ́n fi jígà àti ṣọ́bìrì là nígbà kan rí, jígà àti ṣọ́bìrì náà ni wọ́n fi ń tún àwọn ọ̀nà yẹn ṣe. Ṣùgbọ́n ní báyìí, kódà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, katakata àtàwọn ẹ̀rọ ńlá míì ló ń húlẹ̀ tó sì ń kó o.
Láwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, kẹ̀kẹ́ tó ní ẹ́ńjìnnì ló kù báyìí táwọn èèyàn ń gùn dípò kẹ̀kẹ́ ológeere. Nílẹ̀ Amẹ́ríkà, níbi tí ìdá mẹ́rin òde táwọn èèyàn máa ń lọ ò ti jìn tó ibùsọ̀ kan, síbẹ̀ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin lára ìrìn àjò kú-kù-kú yìí ni wọ́n ń gbé ọkọ̀ lọ.
Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó dóde tún ti sọ àwọn èèyàn ayé òde òní dẹni tó ń jókòó sójú kan. Àbọ̀ ìwádìí kan fi hàn pé bó ṣe di pé àwọn eré ìdárayá orí fídíò “túbọ̀ ń dùn mọ́ àwọn ọmọdé sí i, tí wọ́n sì ń kà á sí ohun gidi, ńṣe làwọn ọmọdé . . . ń lo àkókò tó pọ̀ sí i níbi tọ́wọ́ wọn ti ń jó belebele lórí títẹ bọ́tìnnì tí wọ́n ti ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà.” Ohun kan náà làwọn èèyàn ń sọ nípa wíwo tẹlifíṣọ̀n àtàwọn irú eré ìnàjú míì tàwọn ọmọdé ń ṣe níbi tí wọ́n jókòó sí.
Ewu Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Ẹni Tó Ń Jókòó Sójú Kan
Níwọ̀n báwọn èèyàn ò ti fara ṣiṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ mọ́ báyìí, àìsàn ti wá pọ̀ sí i, bákan náà, ọpọlọ ọ̀pọ̀ èèyàn ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, ìrònú wọn sì ń ṣe ségesège. Bí àpẹẹrẹ, ilé iṣẹ́ ètò ìlera kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ròyìn láìpẹ́ yìí pé: “Àwọn ọmọ tí wọn kì í ṣiṣẹ́ lè dẹni tí kò fojú èèyàn gidi wo ara wọn mọ́, kí wọ́n máa ṣàníyàn púpọ̀ jù, kí ọkàn wọn má sì balẹ̀. Irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ló sábà máa ń yá lára jù láti mugbó kí wọn sì máa lo oògùn olóró. Àwọn òṣìṣẹ́ tí kì í ṣiṣẹ́ tó gba agbára sábà máa ń pa ibi iṣẹ́ jẹ ju àwọn tí iṣẹ́ wọn gba agbára lọ. Bó bá dọjọ́ alẹ́ wọn, àwọn tí kì í ṣiṣẹ́ tó gba agbára sábà máa ń pàdánù okun àti agbára tó yẹ kí wọ́n fi máa gbé ìgbé ayé wọn lójoojúmọ́. Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ wọn ni kì í lè dá wà lómìnira ara wọn mọ́, ọpọlọ wọn kì í sì í jí pépé mọ́.”
Cora Craig, ààrẹ Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Bára Ṣe Ń Gbé Kánkán Lórílẹ̀-Èdè Kánádà, ṣàlàyé pé “àwọn ọmọ ilẹ̀ Kánádà ò tiẹ̀ fi ara ṣiṣẹ́ mọ́ páàpáà, bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ . . . Tá a bá wò ó lọ wò ó bọ̀, bí wọ́n ṣe ń fi ara ṣiṣẹ́ ti dín kù gan-an.” Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Kánádà náà, Globe and Mail ròyìn pé: “Nǹkan bí ìlàjì àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Kánádà ló ki pọ́pọ́ jù, nígbà tí ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún wọn sì ti sanra jọ̀kọ̀tọ̀.” Ìwé ìròyìn yẹn fi kún un pé ní orílẹ̀-èdè yẹn, ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà tó wà níbẹ̀ ló ń jókòó sójú kan. Dókítà Matti Uusitupa, láti ilé ìwé gíga University of Kuopio, lórílẹ̀-èdè Finland kìlọ̀ pé “ńṣe làwọn tó ń kárùn àtọ̀gbẹ oríṣi kejì túbọ̀ ń pọ̀ jákèjádò ayé nítorí báwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń sanra jọ̀kọ̀tọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń jókòó sójú kan.”
Lórílẹ̀-èdè Hong Kong, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé ìdá márùn-ún àwọn tó ń kú láti bí ẹni ọdún márùndínlógójì sókè ló jẹ́ àìfaraṣiṣẹ́ ló pa wọ́n. Ọ̀jọ̀gbọ́n Tai-Hing Lam láti ilé ìwé gíga University of Hong Kong ló darí ìwádìí náà, ọdún 2004 ni àbọ̀ ìwádìí náà sì fara hàn nínú ìwé Annals of Epidemiology. Nínú ìwádìí náà, wọ́n rí i pé “ewu tó wà nínú kéèyàn má máa fara ṣiṣẹ́ pọ̀ ju èyí tó wà nínú sìgá mímu” fáwọn ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà tó wà lórílẹ̀-èdè Hong Kong. Àwọn olùṣèwádìí náà wá sọ tẹ́lẹ̀ pé “ikú tí àìfaraṣiṣẹ́ ń fà ò ní pẹ́ kárí apá ibi tó kù” nílẹ̀ Ṣáínà.
Ṣé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí tó nǹkan téèyàn ń rò ni? Ṣé lóòótọ́ ni àìfaraṣiṣẹ́ lè pa wá lára ju sìgá mímu lọ? Kò sí iyàn jíjà níbẹ̀ pé tá a bá fàwọn tó ń lo ara wọn wé àwọn tí kì í lo ara wọn, ìfúnpá àwọn tí kì í lo ara wọn sábà máa ń ga, àwọn làrùn rọpárọsẹ̀ àti àrùn ọkàn tètè máa ń mú, àwọn náà làrùn jẹjẹrẹ lè mú, àwọn ni eegun wọn kì í lágbára, àwọn ló sì máa ń sanra jọ̀kọ̀tọ̀.a
Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé: “Lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, kódà láwọn ibi tí àìjẹunrekánú ti ń bá wọn fínra, àwọn èèyàn tó ń ki jù tàbí tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ń pọ̀ sí i ni, pípọ̀ tí wọ́n ń pọ̀ yìí ò sì ṣeé gbójú fò dá. Kí lolórí ohun tó ń fà á o? Kò ṣẹ̀yìn jíjẹ oúnjẹ tí èròjà kálórì pọ̀ nínú ẹ̀ àti jíjókòó sójú kan tó ń mú káwọn èèyàn máa sanra jọ̀kọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” Dókítà Stephan Rössner, ọ̀jọ̀gbọ́n tó mọ̀ nípa ìlera èèyàn ní ilé ìwé Karolinska Institute nílùú Stockholm, lórílẹ̀-èdè Sweden fara mọ́ èrò náà, ó tún wá fi kún un pé: “Kò sí orílẹ̀-èdè náà láyé táwọn tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ò ti máa pọ̀ sí i.”
Ó Ti Di Ìṣòro Tó Kárí Ayé
Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé ó yẹ ká máa ṣeré ìmárale tó mọ níwọ̀n kára wa lè máa jí pépé. Àmọ́, pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe mọ ewu tó wà nínú kí wọ́n má máa ṣeré ìmárale tó yìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn tó ń gbé láyé ni kì í lo ara wọn rárá. Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìtọ́jú Ọkàn Lágbàáyé gbà pé láàárín ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àti ìdá márùndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó wà láyé “ni kì í fara ṣiṣẹ́ dé ìwọ̀n tó lè ṣe ara wọ́n lóore, pàápàá àwọn ọmọbìnrin àtàwọn ìyá.” Àjọ yìí sọ pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ọmọdé tí wọn kì í fara ṣiṣẹ́ débi táá fi ṣara wọn lóore.” Nǹkan bí ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá àwọn àgbàlagbà ló máa ń jókòó sójú kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà nígbà tó sì jẹ́ pé nǹkan bí ìdajì àwọn ọmọdé láàárín ẹni ọdún méjìlá sí mọ́kànlélógún ni kì í ṣe àwọn nǹkan tó lè mú wọn làágùn.
Wọ́n ṣèwádìí kan lórílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nílẹ̀ Yúróòpù. Ìwádìí náà fi hàn pé orílẹ̀-èdè Sweden làwọn tí kì í fara ṣiṣẹ́ ti kéré jù, wọ́n jẹ́ ìdá mẹ́tàlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún; orílẹ̀-èdè Potogí ni wọ́n pọ̀ sí jù, wọ́n jẹ́ ìdá mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún. Ní ìlú São Paulo, lórílẹ̀-èdè Brazil, nǹkan bí ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ló ń jókòó sójú kan. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé “ohun tá a rí nínú ìṣirò tó ń wá láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé lórí ọ̀ràn ìlera bára mu.” Nítorí náà, kò gbọ́dọ̀ yà wá lẹ́nu pé ikú tó ń pa mílíọ̀nù méjì èèyàn lọ́dọọdún kò ṣẹ̀yìn jíjókòó gẹlẹtẹ láìfara ṣiṣẹ́.
Àwọn ògbógi lórí ọ̀ràn ìlera sọ pé ibi tí ọ̀ràn ń lọ yìí ò dáa o. Látàrí èyí, àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba jákèjádò ayé ti bẹ̀rẹ̀ onírúurú ìpolongo láti la àwọn aráàlú lọ́yẹ̀ nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣeré ìmárale níwọ̀n. Àwọn orílẹ̀-èdè bí Ọsirélíà, Japan àti Amẹ́ríkà nírètí pé tó bá fi máa di ọdún 2010, eré ìmárale táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà á máa ṣe á ti fi ìdá mẹ́wàá pọ̀ sí i. Ilẹ̀ Scotland ń fojú sùn ún pé tó bá fi máa di ọdún 2020, ìdajì àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà tó jẹ́ àgbà yóò máa ṣeré ìmárale déédéé. Ìròyìn kan láti ilé iṣẹ́ Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣàlàyé pé “àwọn orílẹ̀-èdè míì tí wọ́n ti sọ ètò tí wọ́n fẹ́ máa ṣe lórí èrè ìmárale ni Mẹ́síkò, Brazil, Jàmáíkà, New Zealand, Finland, Rọ́ṣíà, Mòrókò, Vietnam, South Africa àti Slovenia.”
Láìka gbogbo akitiyan àwọn ìjọba àtàwọn ilé iṣẹ́ ìlera sí, ó dọwọ́ olúkúlùkù láti tọ́jú ìlera ara rẹ̀ o. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé ‘Ṣé mò ń lo ara mi tó? Ṣé eré ìmárale tí mò ń ṣe pọ̀ tó? Tí kò bá tó, kí ni mo lè ṣe tí màá fi lè kúrò lẹ́ni tó ń jókòó sójú kan?’ Àpilẹ̀kọ tó máa tẹ̀ lé èyí á fi hàn ọ́ bó o ṣe lè túbọ̀ máa lo ara rẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Téèyàn ò bá máa fara ṣiṣẹ́, àwọn àìsàn kan tó lè gbẹ̀mí èèyàn lè tètè kọ lu olúwarẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Àrùn Ọkàn Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé téèyàn ò bá máa fara ẹ̀ ṣiṣẹ́, àrùn ọkàn lè tètè ṣe é, ó sì lè tètè lárùn ẹ̀jẹ̀ ríru. Àrùn ọkàn àti òpójẹ̀ àti àrùn rọpárọsẹ̀ tún lè tètè pa á.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Ìnáwó Tí Àìfaraṣiṣẹ́ Ń Fà
Ọ̀pọ̀ ìjọba orílẹ̀-èdè àtàwọn ilé iṣẹ́ ìlera ló ń ṣàníyàn gidigidi nítorí ìnáwó lórí ìṣòro tí àìfaraṣiṣẹ́ àwọn èèyàn ń dá sílẹ̀ láwùjọ.
● Ọsirélíà - Lórílẹ̀-èdè yìí, owó tí wọ́n ń ná lórí àwọn ìṣòro tó tan mọ́ àìfaraṣiṣẹ́ pọ̀ tó mílíọ̀nù ọ̀rìnlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín mẹ́ta [377,000,000] dọ́là.
● Kánádà - Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Tó Ń Rí sí Ìtọ́jú Ọkàn Lágbàáyé ṣe sọ, láàárín ọdún kan péré, orílẹ̀-èdè Kánádà ná iye tó ju bílíọ̀nù méjì dọ́là lọ lórí ìṣòro ìlera “tó jẹ mọ́ àìfaraṣiṣẹ́.”
● Amẹ́ríkà - Láàárín ọdún 2000, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ná òbítíbitì owó tó pọ̀ tó bílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gọ́rin dọ́là lórí ìṣòro ìlera tí àìfaraṣiṣẹ́ dá sílẹ̀.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn Ọmọdé Nílò Kí Wọ́n Máa Lo Okun Wọn
Ìwádìí tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn ọmọdé tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i kì í fi okun wọn ṣe eré ìmárale déédéé. Àárín àwọn ọmọbìnrin sì nìṣòro yìí pọ̀ sí jù. Ó dà bíi pé báwọn ọmọ ṣe ń dàgbà ni eré ìmárale tí wọ́n ń ṣe á ṣe máa dín kù. Àmọ́, àǹfààní wọ̀nyí làwọn ọmọdé lè jẹ bí wọ́n bá ń ṣeré ìmárale déédéé:
● Eegun wọn á máa lágbára, wọ́n á ki dáadáa, oríkèé ara wọn á sì lágbára
● Wọn ò ní ki pọ́pọ́ jù, wọn ò sì ní sanra jọ̀kọ̀tọ̀
● Kò ní jẹ́ kí wọ́n tètè níṣòro ìfúnpá gíga, tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ ní in láé
● Kò ní jẹ́ kí wọ́n ní àrùn àtọgbẹ oríṣi kejì
● Á jẹ́ kí wọ́n máa fojú èèyàn gidi wo ara wọn, àníyàn àti pákáǹleke ò sì ní bá wọn
● Bí wọ́n bá ń bá ṣíṣeré ìmárale nìṣó tí wọ́n fi dàgbà, wọn ò ní dẹni tó ń jókòó sójú kan
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ó Ń Mú Kára Àwọn Àgbàlagbà Le
Wọ́n ti máa ń sọ pé bó o bá ṣe dàgbà tó bẹ́ẹ̀ ni ṣíṣe eré ìmárale tó mọ níwọ̀n á ṣe ṣe ẹ́ láǹfààní tó. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àgbàlagbà ni kì í fẹ́ ṣeré ìmárale torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n pé wọ́n lè ṣèṣe tàbí pé ó lè fa àìsàn sí wọn lára. A mọ̀ pé ó yẹ káwọn àgbàlagbà lọ rí dókítà wọn kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ eré ìmárale tó gba agbára. Síbẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀ràn gbà pé ṣíṣe eré ìmárale lè mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ dùn mọ́ wọn sí i. Díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tí wọ́n lè jẹ tí wọ́n bá ń ṣe eré ìmárale déédéé rèé:
● Ọpọlọ wọn á jí pépé
● Wọ́n á máa ṣe nǹkan bó ṣe tọ́, wọ́n á sì mọwọ́ yí padà
● Ọkàn wọn á máa balẹ̀
● Bí wọ́n bá ṣàìsàn tàbí ṣèṣe, ará wọn á tètè máa yá
● Wọn ò ní máa bẹ̀rù àrùn tó ń bá kíndìnrín àti ìfun jà, ẹ̀dọ̀ wọn á sì máa ṣiṣẹ́ dáadáa
● Oúnjẹ á máa ṣiṣẹ́ dáadáa lára wọn
● Ara wọn á lè máa gbogun tàrùn
● Eegun wọn á gbó keke
● Okun inú wọn á máa pọ̀ sí i