Rọ̀ Mọ́ Ìpinnu Rẹ
“Rírọ̀ mọ́ ìpinnu téèyàn ṣe láti jáwọ́ nínú sìgá mímu ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ti jáwọ́ nínú sìgá mímu.”— Ìwé kan tó ń jẹ́,“Stop Smoking Now!”
LẸ́NU kan, bó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu, ohun kan ni pé, o gbọ́dọ̀ ṣe tán láti rọ̀ mọ́ ìpinnu tó o ṣe. Báwo lo ṣe lè rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ? Ọ̀nà kan ni pé kó o ronú nípa bí ìgbésí ayé rẹ á ṣe sunwọ̀n sí i bó o bá jáwọ́ nínú sìgá mímu.
Wàá ní àjẹṣẹ́kù. Bí ẹnì kan bá ń mu páálí sìgá kan lójúmọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa ná tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún náírà sórí sìgá lọ́dún. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Gyanu láti orílẹ̀-èdè Nepal sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé owó kékeré kọ́ ni mo fi ṣòfò lórí sìgá mímu.”
Ó yẹ kí ayé rẹ túbọ̀ ládùn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Regina lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Ìgbà tí mo jáwọ́ nínú sìgá mímu ni mo bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun, ńṣe ni ayé mi wá ń dáa sí i.” Béèyàn bá jáwọ́ nínú sìgá mímu, òun fúnra rẹ̀ máa mọ̀ ọ́n lára pé agbára ìtọ́wò àti ìgbóòórùn òun ti sunwọ̀n sí i, á wá dẹni tó túbọ̀ ní okun nínú, ìrísí rẹ̀ á sì túbọ̀ fani mọ́ra.
Ìlera rẹ lè sunwọ̀n sí i. “Ì báà jẹ́ ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé tàbí àgbà, ló jáwọ́ nínú sìgá mímu, kì í pẹ́ rárá tí wọ́n fi máa ń rí i tí ìlera wọn á sunwọ̀n sí i.”—Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Wàá túbọ̀ dá ara rẹ lójú. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Henning lórílẹ̀-èdè Denmark sọ pé: “Mo jáwọ́ nínú sìgá mímu torí pé mi ò fẹ́ kí sìgá di ọ̀gá mi. Èmi ni mo fẹ́ máa darí ara mi.”
Tẹbí-tọ̀rẹ́ ló máa jàǹfààní. “Bó o bá ń mu sìgá, . . . Ò ń ṣèpalára fún ìlera àwọn tó wà ní àyíká rẹ. . . . Ìwádìí fi hàn pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró àti àìsàn ọkàn ń pa lọ́dọọdún látàrí bí èéfín sìgá táwọn ẹlòmíì mu ṣe ń kó sí wọn lágbárí.”—Ẹgbẹ́ Tó Ń Gbógun Ti Àrùn Jẹjẹrẹ Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Wàá mú inú Ẹlẹ́dàá rẹ dùn. “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní . . . mímọ́, [lọ́nà] tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.”—Róòmù 12:1.
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sylvia lórílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Ní gbàrà tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run kò fẹ́ ká máa lo àwọn nǹkan tó ń ṣàkóbá fún ara wa, ńṣe ni mo pinnu láti jáwọ́ nínú sìgá mímu.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè gba pé kéèyàn ṣe ju rírọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ̀ lọ. A tún lè nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì, títí kan tẹbí-tọ̀rẹ́. Kí ni wọ́n lè ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́?