O Lè Ṣàṣeyọrí!
ÀKÓKÒ ti tó fún ẹ báyìí láti “jẹ́ onígboyà kí o sì gbé ìgbésẹ̀.” (1 Kíróníkà 28:10) Paríparí rẹ̀, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táa jẹ́ kí àṣeyọrí rẹ túbọ̀ dájú?
Dá ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́. Iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà Tó Ń Bójú Tó Ìlera àti Ìpèsè fún Aráàlú dábàá pé bó o bá ti pinnu láti fi sìgá mímu sílẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ tó o máa fòpin sí i pátápátá ju ọ̀ṣẹ̀ méjì lọ sígbà yẹn. Èyí á jẹ́ kó o lè rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ. Sàmì sí ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́ lórí kàlẹ́ńdà, sọ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ, má sì ṣe yí ọjọ́ náà pa dà, láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí.
Ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o lè jáwọ́. Àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí wà lára ohun tó o lè kọ, o sì tún lè kọ àwọn nǹkan míì tó lè mú kó o rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ:
● Ìdí tó o fi fẹ́ jáwọ́
● Nọ́ńbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àwọn tó o lè pè tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o tún mu sìgá
● Àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ẹsẹ Bíbélì tó o lè máa ronú lé tí kò ní jẹ́ kó o yẹ ìpinnu rẹ, irú bíi Gálátíà 5:22, 23
Máa mú àkọsílẹ̀ rẹ dání nígbà gbogbo, kó o sì máa kà á lákàtúnkà lójoojúmọ́. Kódà lẹ́yìn tó o bá ti jáwọ́, rí i pé ò ń ka àkọsílẹ̀ náà nígbàkigbà tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o tún mu sìgá.
Jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tó lè mú kó o tún bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá. Kó tó di ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tó o bá fẹ́ mu sìgá. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé gbàrà tó o bá ti jí láràárọ̀ lo máa ń mu sìgá, rí i pé o ò mu sìgá láàárín nǹkan bíi wákàtí kan lẹ́yìn tó o bá jí. Bó bá jẹ́ pé o máa ń mu sìgá nígbà tó o bá ń jẹun tàbí ní gbàrà tó o bá jẹun tán, rí i pé o ò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Má ṣe máa lọ síbi tí wọ́n bá ti ń mu sìgá. Nígbà tó o bá dá wà, máa ṣe ìdánrawò nípa sísọ̀rọ̀ sókè pé: “Ẹ ṣeun. Mi ò mu sìgá mọ́.” Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti jáwọ́ ní ọjọ́ tó o ti yàn. Ṣíṣe àwọn nǹkan yìí á tún máa rán ẹ létí pé, láìpẹ́ o máa di ẹni tí kì í mu sìgá mọ́.
Múra sílẹ̀. Bí ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́ ṣe ń sún mọ́, wá àwọn nǹkan ìpanu sí ìtòsí, àwọn nǹkan bíi: kárọ́ọ̀tì, ṣingọ́ọ̀mù, ẹ̀pà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Máa rán tẹbí-tọ̀rẹ́ létí ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kó tó di ọjọ́ náà, kó àwọn agolo tí ò ń ṣẹ́ eérú sìgá sí àti ìṣáná kúrò nílẹ̀ àti ohunkóhun tó lè mú kí sìgá tún wù ẹ́ mu, irú bí àwọn sìgá tó lè wà káàkiri nínú ilé, nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, nínú àpò rẹ tàbí ní ibi iṣẹ́ rẹ. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ó rọrùn láti mú sìgá tó o ti fi sínú àpótí kan jáde ju kó o béèrè lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ kan tàbí kó o ra páálí kan. Bákan náà, máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì túbọ̀ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà lẹ́yìn tó o bá ti jáwọ́.—Lúùkù 11:13.
Àìmọye èèyàn ló ti “fòpin sí” àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti sìgá tó jẹ́ ọ̀rẹ́ èké àti apanilára tí wọ́n ní nígbà kan. Ìwọ náà lè fòpin sí àjọṣe àárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ burúkú yìí. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìlera rẹ á sunwọ̀n sí i, wàá sì ní òmìnira fàlàlà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Máa mú àkọsílẹ̀ rẹ dání nígbà gbogbo, kó o sì máa kà á lákàtúnkà lójoojúmọ́