Ojú Ìwòye Bíbélì
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná?
“Bí owó oṣù mi ṣe ń dín kù sí i, bẹ́ẹ̀ ni bùkátà mi ń fẹjú sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mi kì í lè sùn lóru, mo máa ń ronú nípa bí mo ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé mi.”—James.
“Ó máa ń ṣe mí bíi pé mo ti sún kan ògiri àti pé kò sí ọ̀nà àbáyọ.”—Sheri.
IRÚ àwọn ọ̀rọ̀ báyìí kò ṣàjèjì láwọn àkókò tí ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀. Nígbà tí ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ lágbàáyé, ìyẹn International Labour Office, ń sọ̀rọ̀ nípa ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ lágbàáyé, ó ní: “Gbogbo èèyàn kárí ayé ni ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ yìí kàn, kì í ṣe àwọn ará ìlú New York nìkan.”
Bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹni lójijì tàbí tí kò sówó téèyàn lè fi gbọ́ bùkátà ìdílé, èyí lè fa ìdààmú ọkàn tí kò mọ níwọ̀n, ó sì lè mú kéèyàn máa ronú pé kò sí ọ̀nà àbáyọ. Ìgbà kan wà tí Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì náà rò pé òun ò lọ́nà àbáyọ. Ó gbàdúrà pé: “Wàhálà ọkàn-àyà mi ti di púpọ̀; mú mi jáde kúrò nínú másùnmáwo tí ó bá mi.” (Sáàmù 25:17) Kí ni Bíbélì sọ nípa àkókò wa, ṣé àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó wà nínú rẹ̀ lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ kó sì jẹ́ ká túbọ̀ ní àlàáfíà?
Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọlọgbọ́n fún Àwọn Àkókò Lílekoko
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìroragógó wàhálà” àti “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ni àmì tá a máa fi mọ̀ pé ayé yìí ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” rẹ̀. (2 Tímótì 3:1; Mátíù 24:8) Ẹ̀rí fi hàn báyìí pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ ìrètí ṣì wà síbẹ̀, torí pé Ọlọ́run ti tipasẹ̀ Ìwé Mímọ́ fún wa ní ọgbọ́n tá a nílò láti ṣàṣeyọrí, kódà nígbà tí ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ irú ojú tó yẹ ká máa fi wo owó. Oníwàásù 7:12 kà pé: “Nítorí ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” Òótọ́ ni pé owó lè dáàbò boni dé ìwọ̀n àyè kan, àmọ́ ọgbọ́n Ọlọ́run, tó wà nínú Bíbélì nìkan ló lè pèsè ojúlówó ààbò fún wa nígbà gbogbo. Gbé àwọn àpẹẹrẹ yìí yẹ̀ wò.
Ohun Tá A Lè Ṣe Nígbà Tí Ọrọ̀ Ajé Bá Le Koko
Jẹ́ aláápọn. “Ọ̀lẹ ń fọkàn fẹ́, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò ní nǹkan kan. Bí ó ti wù kí ó rí, àní ọkàn àwọn ẹni aláápọn ni a óò mú sanra.” (Òwe 13:4) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ẹsẹ Bíbélì yìí? Jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́ sí olóòótọ́, ẹni tó máa ń ṣiṣẹ́ kára. Àwọn agbanisíṣẹ́ máa ń mọyì àwọn òṣìṣẹ́ tí kì í fiṣẹ́ ṣeré, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ fẹ́ gbà síṣẹ́, wọn kì í sì í tètè dá irú wọn dúró.—Éfésù 4:28.
Máa ronú dáadáa kó o tó ra ohunkóhun. Jésù sọ pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àpèjúwe nípa ìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn ro ohun tó máa ná wọn láti di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni Jésù ń sọ, síbẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún wúlò nínú àwọn nǹkan míì tá a bá ń ṣe. Torí náà, gbéṣirò lé owó tó o fẹ́ ná, ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó o dìídì nílò àti iye tó máa ná ọ.
Má ṣe fowó ṣòfò sórí àwọn àṣà tí kò ní láárí. Inú Ọlọ́run kò dùn sí àwọn àṣà bíi tẹ́tẹ́ títa, sìgá mímu, ìlòkulò oògùn àti ọtí àmujù.—Òwe 23:20, 21; Aísáyà 65:11; 2 Kọ́ríńtì 7:1.
Ṣọ́ra fún “ìfẹ́ owó.” (Hébérù 13:5) Ó dájú pé àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ owó kì í láyọ̀, wọ́n sì máa ń rí ìjákulẹ̀, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ “fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:9, 10) Ìyẹn nìkan kọ́, ṣe ni wọ́n á di ẹrú fún ìfẹ́ ọkàn tí kò ṣeé tẹ́ lọ́rùn, torí pé kò sí bí owó tí wọ́n ní ṣe lè pọ̀ tó, kò lè tẹ́ wọn lọ́rùn.—Oníwàásù 5:10.
Kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn. “A kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:7, 8) Ó máa rọrùn fún àwọn tí nǹkan díẹ̀ bá ń tẹ́ lọ́rùn láti yẹra fún ṣíṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ nígbà tí ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀. Torí náà, kọ́ bó o ṣe lè jẹ́ kí ohun tó o ní máa tẹ́ ọ lọ́rùn.—Wo àpótí tó wà lápá ọ̀tún.
Kò sí ẹni tó mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la nínú wa. Oníwàásù 9:11 sọ pé: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo [wa].” Torí náà àwọn tó jẹ́ ọlọgbọ́n kì í “gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run” ẹni tó ṣèlérí fún àwọn tó dúró ṣinṣin tì í pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—1 Tímótì 6:17; Hébérù 13:5.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí ni Bíbélì sọ nípa àkókò tá a wà yìí?—2 Tímótì 3:1-5.
● Ibo la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé lóde òní?—Sáàmù 19:7.
● Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí ìdílé mi ní ìrètí tó fini lọ́kàn balẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la?—Oníwàásù 7:12.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
BÓ O ṢE LÈ ṢỌ́WÓ NÁ
Tó o bá fẹ́ ra ọjà: Kọ àwọn ohun tó o fẹ́ rà sílẹ̀. Má ṣe máa ra gbogbo ohun tó bá ṣáà ti wù ẹ́. Máa wá ibi tó o ti lè rajà lówó pọ́ọ́kú. Àwọn ilé ìtajà tí wọ́n ti máa fún ẹ ní ẹ̀dínwó ni kó o ti máa rajà. Máa ra àwọn ohun tó o bá nílò nígbà tí wọ́n bá fẹ́ tà á ní ẹ̀dínwó àti lásìkò tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò nílò rẹ̀. Nígbà tó bá ṣeé ṣe, máa ra ọjà lọ́pọ̀.
Ìnáwó nínú ilé: Tètè máa san owó àwọn ohun tẹ́ ẹ máa ń lò nínú ilé, irú bí iná ìjọba àti omi, kí èlé má bàa gun orí rẹ̀. Máa se oúnjẹ àti àwọn ohun mímu fúnra rẹ nílé, má ṣe jẹ àjẹkì, má sì mutí lámujù. Máa pa iná àti àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ tí o kò bá lò. Tó bá ṣeé ṣe máa lo àwọn ohun tí kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹ iná mànàmáná. Ronú nípa gbígbé ní ilé tí kò tóbi púpọ̀.
Ìnáwó ọkọ̀: Tó o bá nílò mọ́tò, èyí tí kò ní máa yọnu, tí kò sì ní máa jẹ epo ju bó ṣe yẹ lọ ni kó o rà. Kò pọn dandan kó jẹ́ ọkọ̀ tuntun. Máa pa ìrìn àwọn ibi tó o fẹ́ lọ pọ̀ sí ẹ̀ẹ̀kan, ìwọ àtàwọn ẹlòmíì sì lè jọ máa gbé mọ́tò kan dípò tí kálukú á fi máa gbé ọkọ̀ tiẹ̀ sọ́nà. Nígbà míì, o lè wọ ọkọ̀ èrò tàbí kó o fi ẹsẹ̀ rìn, o sì lè gun kẹ̀kẹ́. Àsìkò tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í lọ síbi ìgbafẹ́ ni kó o máa lọ, má sì lọ gbafẹ́ níbi tó bá jìnnà jù sílé.
Fóònù àti eré ìnàjú: Ṣó pọn dandan kó o ní fóònú alágbèéká àti tilé? Bí àwọn ọmọ rẹ bá ní fóònù alágbèéká, ǹjẹ́ wọ́n lè dín bí wọ́n ṣe ń lò ó kù tàbí kí wọ́n tiẹ̀ má lò ó rárá? Bó o bá ń san àsansílẹ̀ owó fún ilé iṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n kan, ǹjẹ́ o lè ní kí wọ́n dín iye ìkànnì tó o lè wò kù, kí owó tó ò ń san lè dín kù?a Máa yá ìwé nílé ìkówèésí, kó o sì máa ya fíìmù dípò kó o máa rà á.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá ń fẹ́ àbá púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Máa Fọgbọ́n Náwó,” nínú Jí! April–June 2009 àti “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo ni mo ṣe lè máa ṣọ́wó ná?” nínú Jí! July–September 2006.