Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Tọ́jú Ara Mi?
Fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àfojúsùn tó o máa fẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀.
◯ Mo fẹ́ dín sísanra kù
◯ Mo fẹ́ kí àwọ̀ mi dáa sí i
◯ Mo fẹ́ túbọ̀ lókun
◯ Mo fẹ́ túbọ̀ wà lójúfò
◯ Mo fẹ́ dín àníyàn kù
◯ Mi ò fẹ́ máa bínú jù
◯ Mo fẹ́ túbọ̀ dá ara mi lójú
ÀWỌN nǹkan kan wà tí o kò lè yàn fúnra rẹ. Bí àpẹẹrẹ, o ò lè yan àwọn òbí tó o fẹ́ kó bí ẹ, o ò lè yan àwọn tó máa jẹ́ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀, o ò lè yan ibi tó o máa gbé àtàwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Àmọ́, báyìí kọ́ lọ̀ràn ìlera rẹ rí. Bóyá ara rẹ le dáadáa tàbí kò le dáadáa, èyí lè sinmi lórí nǹkan tó o jogún látara àwọn òbí rẹ tàbí irú ìgbé ayé tó o yàn láti máa gbé.a
O lè ronú pé ‘ọmọdé ni mí jàre, kò sídìí fún mi láti máa da ara mi láàmú nípa ìlera mi!’ Ṣé òótọ́ ni pé kò yẹ kó o mọ bó o ṣe lè máa tọ́jú ara rẹ? Wo àwọn àfojúsùn tá a kọ sókè yìí. Mélòó nínú rẹ̀ lo sàmì sí? Jẹ́ kó yẹ́ ẹ pé, àfi kó o ní ìlera tó jíire kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ èyíkéyìí lára àwọn àfojúsùn wọ̀nyẹn.
Lóòótọ́ ìwọ náà lè máa ronú bíi ti Amber,b ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tó sọ pé: “Èmi ò lè máa jẹ kìkì àwọn oúnjẹ tá ò fi ìyẹ̀fun ṣe àti èyí tí kò ní ọ̀rá tàbí àwọn oúnjẹ tí kò ní ṣúgà nígbà gbogbo!” Bí ìwọ náà bá ní irú èrò bẹ́ẹ̀, fọkàn balẹ̀, kò dìgbà tó o bá ń fi gbogbo nǹkan du ara rẹ, tó o sì yẹra fún súìtì tàbí tó ń sáré kúṣẹ́kúṣẹ́ kọjá àlà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kó o tó lè ní ìlera tó jí pépé. Ó tiẹ̀ lè má ju pé kó o kàn ṣe àwọn àyípadà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan lọ kí ìrísí rẹ lè dára sí i, kó o lè gbádùn ara rẹ dáadáa, kí ara rẹ sì lè jí pépé. Jẹ́ ká wo bí àwọn ojúgbà rẹ kan ṣe ṣé e.
Máa Jẹ Oúnjẹ Tó Ṣara Lóore, Kí Ìrísí Rẹ Lè Dára Sí I!
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa hùwà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Òwe 23:20 sọ pé: “Máṣe wà ninu awọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun.” (Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ohun tí Bíbélì sọ yìí kì í rọrùn láti ṣe nígbà gbogbo.
● “Bó ṣe sábà máa ń rí fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́, gbogbo ìgbà ni ebi máa ń pa mí. Àwọn òbí mi tiẹ̀ máa ń sọ pé ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni ikùn mi!”—Andrew, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15].
● “Torí pé mi ò tíì rí ìṣòro tí àwọn oúnjẹ kan tí mò ń jẹ ń fà sí mi lára báyìí, kò jọ pé ó burú.” —Danielle, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].
Ṣé ó yẹ kó o máa kó ara rẹ níjàánu tó bá dọ̀rọ̀ oúnjẹ? Wo ohun táwọn ojúgbà rẹ kan sọ pé ó ran àwọn lọ́wọ́.
Má jẹun jù. “Tẹ́lẹ̀ iye èròjà afáralókun tó wà nínú oúnjẹ tí mo bá jẹ ni mò ń kà, àmọ́ ní báyìí, ńṣe ni mo máa ń ṣíwọ́ oúnjẹ tí mo bá a rí i pé mo ti yó.”
Yẹra fún àwọn oúnjẹ tí kì í ṣe ara lóore. “Láàárín oṣù kan tí mi ò fi mu ọtí ẹlẹ́rìndòdò, nǹkan bíi kìlógíráàmù márùn-ún ni mo fi jò sí i!”
Yé jẹ ìjẹkújẹ. Erin tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún sọ pé: “Mo gbìyànjú láti rí i pé mi kì í pa dà lọ bu oúnjẹ nígbà kejì.”
Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Rí i pé ò ń jẹun lákòókò. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ebi tó ń pa ẹ́ á jẹ́ kó o máa jẹ àjẹkì.
Túbọ̀ Máa Ṣe Eré Ìmárale, Kí Ara Rẹ Lè Dá Ṣáṣá!
Bíbélì sọ pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní.” (1 Tímótì 4:8) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ kì í fẹ́ ṣe eré ìmárale.
● “Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ láti rí i pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò ṣàṣeyọrí nínú ẹ̀kọ́ eré ìmárale nígbà tí mo wà níléèwé gíga. Lójú tèmi ṣe ló dà bí ẹni fi àkàràjẹ̀kọ!”—Richard, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21].
● “Àwọn kan rò pé, ‘Kò yẹ kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sá kiri nínú oòrùn torí pé ó fẹ́ ṣeré ìmárale, nígbà tó jẹ́ pé ó lè gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà níbi tó o ti lè díbọ́n bí ẹlòmíì.’”—Ruth, ẹni ọdún méjìlélógún [22].
Ṣé eré ìmárale kì í wù ẹ́ rárá? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àǹfààní mẹ́ta tó o máa rí tó o bá ń ṣe eré ìmárale déédéé nìyí.
Àǹfààní àkọ́kọ́. Eré ìmárale máa jẹ́ kí àwọn èròjà tó ń dènà àrùn nínú ara rẹ túbọ̀ lágbára. Rachel tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Bàbá mi máa ń sọ pé, ‘Bí o kò bá ráyè eré ìmárale, àfi kó o yáa múra láti fàyè sílẹ̀ de àìsàn.’”
Àǹfààní kejì. Eré ìmárale máa ń tú omi kan jáde nínú ọpọlọ tó máa ń jẹ́ kí ara balẹ̀. Emily tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sọ pé, “Bí ọ̀pọ̀ nǹkan bá ń dààmú mi, bí mo bá ti sáré báyìí, ńṣe ni ara mi máa ń balẹ̀. Ó máa ń jẹ́ kí ara tù mí, ọkàn mi á sì tún balẹ̀.”
Àǹfààní kẹta. Eré ìmárale lè jẹ́ kí ara rẹ yá gágá. Ruth, ọmọ ọdún méjìlélógún [22] sọ pé, “Mo fẹ́ràn kí n máa ṣe eré ìdárayá ní ìta gbangba, irú bíi rírìn lọ síbi tó jìn díẹ̀, lílúwẹ̀ẹ́, gígun àpáta, ṣíṣeré lórí yìnyín àti gígun kẹ̀kẹ́.”
Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Ó kéré tán, máa fi ogún [20] ìṣẹ́jú ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn kan tó o fẹ́ràn lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀.
Máa Sùn Dáadáa, Kí Ara Rẹ Lè Jí Pépé!
Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Tó bá jẹ́ pé o kì í sùn dáadáa, o ò ní lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ kó o ṣe é!
● “Bí mi ò bá sùn dáadáa, wàhálà dé nìyẹn. Mi ò ní lè pọkàn pọ̀ rárá!”—Rachel, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].
● “Bó bá ti ń di nǹkan bí aago méjì ọ̀sán, ó máa ń rẹ̀ mí gan-an débi pé mo lè sùn lọ níbi tí mo bá ti ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀!”—Kristine, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].
Ṣé ó yẹ kó o túbọ̀ máa sùn dáadáa? Ohun táwọn ojúgbà rẹ kan ti ṣe nìyí.
Máa tètè sùn. Catherine, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé, “Mò ń sapá gan-an láti rí i pé mo máa ń tètè sùn.”
Má ṣe máa rojọ́ lóru. Richard, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] sọ pé, “Nígbà míì, òru ni àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń pè mí tàbí kí wọ́n fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, àmọ́ ní báyìí, mo máa ń tètè sọ fún wọn pé mo fẹ́ sùn, màá sì lọ sùn.”
Yan àkókò pàtó tí wàá máa sùn àti ìgbà tí wàá máa jí. Jennifer, ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Ní báyìí, mò ń gbìyànjú láti ní àkókò pàtó tí mò ń sùn àti àkókò pàtó tí mò ń jí lójoojúmọ́.”
Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Rí i pé ò ń sun oorun wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá mọ́jú.
Èwo nínú àwọn ohun mẹ́ta tí àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ lé lórí ló yẹ kó o fún láfiyèsí?
◯ oúnjẹ ◯ eré ìmárale ◯ oorun
Kọ ohun tó o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ kó o lè ṣàṣeyọrí sí ìsàlẹ̀ yìí.
․․․․․
Wàá jàǹfààní gan-an tó o bá ṣe àwọn nǹkan kan tí kò ṣòro rárá kó o lè tọ́jú ara rẹ. Rántí pé bí ìlera rẹ bá dáa, àwọ̀ rẹ á fani mọ́ra, ara rẹ á yá gágá, ara rẹ á sì jí pépé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà tí kò sí ohun tó o lè ṣe nípa rẹ̀, rántí pé dé ìwọ̀n àyè kan, o lè pinnu bó o ṣe fẹ́ kí ìlera rẹ rí. Erin tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé, “Ohun kan ni pé, ìwọ lo máa pinnu bó o ṣe fẹ́ kí ìlera rẹ rí.”
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ló ní àìlera tàbí àrùn tó jẹ́ pé kò sóhun tí wọ́n lè ṣe nípa rẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ kí àwọn tó ní irú ìṣòro yìí mọ bí wọ́n ṣe lè mú ìlera wọn sunwọ̀n sí i débi tí agbára wọn mọ.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
● Ipa wo ni bó o ṣe ń tọ́jú ìlera rẹ lè ní lórí ojú tó o máa fi wo ara rẹ?
● Bó bá di ọ̀rọ̀ ìlera rẹ, báwo lo ṣe lè lo ìfòyebánilò?—Fílípì 4:5.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ
“Ara àwa èèyàn dà bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ó kù sọ́wọ́ ẹni tó ni ín láti máa bójú tó o bó ṣe yẹ. Ìdí nìyẹn tí mo fi máa ń ṣe eré ìmárale.”
“Béèyàn bá lẹ́ni tí wọ́n á jọ máa ṣe eré ìmárale, èyí máa fún un níṣìírí gan-an, torí kò ní fẹ́ já ẹni náà kulẹ̀.”
“Mo máa ń gbádùn ara mi bí mo bá ṣe eré ìmárale. Bí mo bá sì ti kíyè sí pé ó ṣe mí láǹfààní, ńṣe ló túbọ̀ máa ń dá mi lójú pé ó yẹ kí n máa ṣe é! ”
[Àwọn àwòrán]
Ethan
Briana
Emily
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
“MO YÍ ÌGBÉ AYÉ MI PA DÀ”
“Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà, mo rí rùmúrùmú díẹ̀. Díẹ̀díẹ̀ ni mo wá rí i pé àwọn ohun tí mo kà sí ìgbádùn ti jẹ́ kí n di ẹni tí ẹnu rẹ̀ kì í gbófo. Mi kì í sì í ṣe iṣẹ́ agbára kankan rárá, mi ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i. Kí n tó mohun tó ń ṣẹlẹ̀, mo ti wá sanra jọ̀kọ̀tọ̀ kí n tó pé ọmọ ogún ọdún, kò sì wù mí kí ń sanra bẹ́ẹ̀ rárá. Bí mo ṣe rí ò tẹ́ mi lọ́rùn, inú mi kì í sì í dùn. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń jẹ oríṣi àwọn oúnjẹ kan kí n lè fọn díẹ̀, àmọ́ ṣe ni mo máa ń tóbi pa dà. Torí náà, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], mo pinnu pé mo ní láti ṣe nǹkan lórí ọ̀rọ̀ yìí! Mo fẹ́ dín sísanra kù lọ́nà tó yẹ, kí n má sì tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ mọ́. Mo ra ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó yẹ kéèyàn máa jẹ àti béèyàn ṣe lè máa ṣe eré ìmárale dáadáa, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fàwọn ohun tí mo kà sílò. Mo wá pinnu pé bí àwọn ohun tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe yìí bá tiẹ̀ sú mi fúngbà díẹ̀ tàbí tí mo dáwọ́ rẹ̀ dúró díẹ̀, mi ò ní jáwọ́ ńbẹ̀. Inú mi dùn gan-an pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í fọn lóòótọ́! Láàárín ọdún kan mo ti dín kùn ní ìwọ̀n kìlógíráàmù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Ọdún méjì ti kọjá báyìí tí mi ò pa dà sanra mọ́. Mi ò tiẹ̀ rò pé ó lè ṣeé ṣe rárá! Mo rò pé kì í ṣe torí pé mo dín oúnjẹ tí mò ń jẹ kù nìkan ló mú kí n ṣàṣeyọrí, àmọ́ mo tún yí ìgbé ayé mi pa dà. Nígbà tí mo ti mọ̀ pé gbogbo apá ìgbésí ayé mi ni ohun tí mo dáwọ́ lé yẹn máa kàn, èyí mú kí n múra tán láti ṣe gbogbo àyípadà tó bá yẹ.”—Catherine, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ni ìlera rẹ ṣe rí, bí o kò bá bójú tó o bó ṣe yẹ, ńṣe ló máa dẹnu kọlẹ̀