Ohun 4—Ṣọ́ra fún Ohun Tó Lè Ṣàkóbá fún Ìlera Rẹ
“Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Ṣíṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan lè mú ká dènà àìsàn, ìbànújẹ́, àti fífi àkókò àti owó ṣòfò.
◯ Jẹ́ kí ara rẹ wà ní mímọ́ tónítóní. Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Fífọ ọwọ́ ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà dènà títan àrùn tó ń ranni kálẹ̀, kéèyàn sì ní ìlera tó dára.” Ó tó ìdá mẹ́jọ nínú mẹ́wàá lára àwọn àrùn tó ń ranni tó jẹ́ pé láti ara ọwọ́ tó dọ̀tí lèèyàn ti ń kó o. Torí náà máa fọ ọwọ́ rẹ ní gbogbo ìgbà. Ní pàtàkì jù lọ ṣáájú kó o tó jẹun, kó o tó gbọ́ oúnjẹ, tàbí tó o bá fẹ́ fọwọ́ kan ojú egbò tàbí tó o fẹ́ wẹ̀ ẹ́, kó o máa fọ ọwọ́ rẹ tó o bá fi kan ẹranko kan, tó o bá lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí tó o pààrọ̀ ìtẹ́dìí ọmọdé.
Fífi omi àti ọṣẹ fọwọ́ dára gan-an ju lílo àwọn kẹ́míkà tí wọ́n ṣe fún fífọ ọwọ́. Ara àwọn ọmọ máa ń túbọ̀ le bí àwọn òbí bá kọ́ wọn pé kí wọ́n máa fọ ọwọ́ wọn, kí wọ́n má sì máa tọwọ́ bọ ẹnu àti ojú. Téèyàn bá ń wẹ̀ lójoojúmọ́, tó ń wọ aṣọ tó mọ́, tí kì í jẹ́ kí aṣọ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀ dọ̀tí, ó máa ń pa kún ìlera tó dáa.
◯ Ṣọ́ra fún àwọn àrùn tó ń ranni. Máa ṣọ́ra fún àwọn tó bá ní ọ̀fìnkìn tàbí ilẹ̀ẹ́gbóná, má sì lo àwọn nǹkan ìjẹun bíi ṣíbí, fọ́ọ̀kì tàbí abọ́ tí wọ́n bá ti lò láìjẹ́ pé o fọ̀ ọ́ dáadáa. Èèyàn lè kó àrùn náà látinú itọ́ ẹnu wọn àti ikun imú wọn. Ipasẹ̀ ìbálòpọ̀, fífi abẹ́rẹ́ fa oògùn sínú iṣan ara àti gbígba ẹ̀jẹ̀ sára lèèyàn ti máa ń kó àwọn àrùn tó wà nínú ẹ̀jẹ̀, irú bí àrùn mẹ́dọ̀wú (hepatitis B àti C) àti àrùn éèdì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé abẹ́rẹ́ àjẹsára lè dènà àwọn àrùn kan tó máa ń ranni, síbẹ̀ ẹni tó bá gbọ́n ní láti máa ṣọ́ra nígbà tó bá wà lọ́dọ̀ àwọn tó ní àrùn tó máa ń ranni. Ṣọ́ra fún àwọn kòkòrò tó máa ń jẹ èèyàn. Má ṣe jókòó tàbí kó o sùn sí ìta láìfi nǹkan bo ara rẹ nígbà tí ẹ̀fọn àtàwọn kòkòrò tó máa ń gbé àrùn kiri bá ń jà. Máa lo àpò ẹ̀fọn, ní pàtàkì fún àwọn ọmọdé, kó o sì máa lo àwọn oògùn tó má ń lé kòkòrò sá.a
◯ Jẹ́ kí ilé rẹ wà ní mímọ́ tónítóní. Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti mú kí ilé rẹ wà létòlétò, kó sì mọ́ tónítóní tinú-tòde. Má ṣe jẹ́ kí omi máa rogún síbì kankan, kó o sì rí i dájú pé kò sí ibì kankan tí àwọn ẹ̀fọn lè fara pa mọ́ sí. Àwọn kòkòrò àti eku sábà máa ń wà níbi tó bá dọ̀tí, níbi táwọn nǹkan ẹlẹ́gbin bá wà, nínú àwọn oúnjẹ tí a kò fi nǹkan bò àti níbi tí à ń dalẹ̀ sí, èyí sì máa ń pe àwọn kòkòrò tó lè fa àrùn síni lára. Bí kò bá sí ilé ìyàgbẹ́, o lè gbẹ́ ihò kó o sì máa yàgbẹ́ sí. Walẹ̀ bo ihò náà nítorí àwọn eṣinṣin tó máa ń kó àrùn ojú àtàwọn àrùn míì ranni.
◯ Ṣọ́ra fún àwọn nǹkan tó lè ṣe ẹ́ léṣe. Máa pa òfin ààbò mọ́ nígbà tó o bá ń rìn, tó o bá ń wa kẹ̀kẹ́ tàbí alùpùpù tàbí tó o bá ń wa ọkọ̀. Rí i dájú pé ọkọ̀ rẹ wà ní ipò tó dára kó o tó gbé e sọ́nà. Lo àwọn nǹkan ìdáàbòbò àti aṣọ tó yẹ, irú bí awò tó ń dáàbò bo ojú, àṣíborí, bàtà, bẹ́líìtì ààbò tó wà nínú ọkọ̀ ìrìnnà àti ohun tá a máa ń kì bọ etí nítorí ariwo. Má ṣe máa pẹ́ jù nínú oòrùn, torí pé èyí máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ, ó sì máa ń jẹ́ kí ara èèyàn tètè hun jọ. Tó o bá ń mu sìgá, jáwọ́. Tó o bá jáwọ́ báyìí, o lè tipa bẹ́ẹ̀ dènà níní àrùn ọkàn, àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ fóró àti rọpárọsẹ̀.b
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn kòkòrò tó máa ń gbé àrùn kiri, ìyẹn “When Insects Spread Disease” nínú Jí! May 22, 2003, lédè Gẹ́ẹ̀sì.
b Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí ẹ̀yìn ìwé náà “Bó O Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu” nínú Jí! July–September 2010.