Máa Ṣe Àwọn Nǹkan Tó Máa Jẹ́ Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I
ṢÉ O rántí Ram tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí? Bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé, Ram kò mọ bí oúnjẹ téèyàn ń jẹ àtàwọn nǹkan míì téèyàn ń ṣe lójoojúmọ́ ti ṣe pàtàkì tó sí ìlera ẹni. Ó sọ pé: “Àpilẹ̀kọ náà, ‘Oúnjẹ Aṣaralóore Ń Bẹ Níkàáwọ́ Rẹ’ nínú Jí! (May 8, 2002) ló jẹ́ kí n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti kíyè sára nípa oúnjẹ tí mò ń jẹ.”
Ram ṣàlàyé pé: “A gbìyànjú láti fi àwọn nǹkan tá a kọ́ nínú àpilẹ̀kọ náà sílò nínú ìdílé wa. Lẹ́yìn ọjọ́ bíi mélòó kan, a rí i pé ara wa ti túbọ̀ lágbára láti gbéjà ko àrùn. Kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí ohun tá à ń jẹ, òtútù sábà máa ń mú wa, àmọ́ ní báyìí ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan là ń gbúròó òtútù. A tún kọ́ bá a ṣe lè máa rí omi tó mọ́ tí kò ní ná wa lówó púpọ̀, ọpẹ́lọpẹ́ àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Jí! tó sọ pé ‘Ọ̀nà 6 Tí O Lè Gbà Dáàbò Bo Ìlera Rẹ.’”—October 8, 2003.
“Àpilẹ̀kọ míì nínú ìwé ìròyìn Jí! tún ràn mí lọ́wọ́ láti mú kí ìlera ìdílé mi dára sí i. Àkòrí rẹ̀ ni ‘Ọṣẹ—“Abẹ́rẹ́ Àjẹsára” Tó O Lè Gún Fúnra Rẹ,’ nínú ẹ̀dà December 8, 2003. A gbìyànjú àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ní gbàrà tá a kà á. Ní báyìí, a kì í ní ìṣòro ojú bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.
“Níbi tá à ń gbé, àwọn èèyàn ò tiẹ̀ ka bí àwọn eṣinṣin àti ẹ̀fọn ṣe pọ̀ yamùrá níbẹ̀ sí bàbàrà. Àmọ́ ìdílé wa kẹ́kọ̀ọ́ látinú fídíò náà The Bible—Its Power in Your Life,a pé ó yẹ ká máa ṣọ́ra fún irú àwọn kòkòrò bẹ́ẹ̀. Èyí náà wà lára àwọn ohun tó ń jẹ́ ká ní ìlera tó dára.”
Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ! Àyípadà yòówù tó o bá fẹ́ láti ṣe, wàá kẹ́sẹ járí tó o bá bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, tí o kò sì gbé àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ rẹ kò lè tẹ̀ ka iwájú rẹ. Bí àpẹẹrẹ, dín jíjẹ àwọn oúnjẹ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣara lóore kù, dípò tí o kò fi ní jẹ ẹ́ mọ́ rárá. Gbìyànjú láti máa sùn lásìkò, kó o sì máa ṣe eré ìmárale ju bó o ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀ lọ. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àkókò díẹ̀ ló fi ń ṣeré ìmárale, ó sàn ju kó o má ṣe é lọ. Ó sábà máa ń gba àkókò, bóyá ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù kó tó di pé àṣà tuntun kan bẹ̀rẹ̀ sí í mọ́ra. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, bí o kò bá rí àǹfààní ojú ẹsẹ̀ nínú ìsapá rẹ, má ṣe bẹ̀rù. Tí o kò bá jẹ́ kó sú ẹ, láìka àwọn ìjákulẹ̀ tó o bá pàdé sí, ó ṣeé ṣe kí ìlera rẹ dára sí i.
Nínú ayé aláìpé yìí, kò ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti ní ìlera pípé. Tó o bá ṣàìsàn, ó lè máà jẹ́ àìka nǹkan sí rẹ ló fà á, àmọ́ kó jẹ́ àìpé tá a jogún ló fà á. Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀ràn ìlera tàbí ohunkóhun míì fa ìdààmú àti àníyàn fún ẹ. Jésù sọ pé: “Ta ni nínú yín nípa ṣíṣàníyàn tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?” (Lúùkù 12:25) Kàkà bẹ́ẹ̀, sapá láti jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn nǹkan tó máa ń ké ẹ̀mí èèyàn kúrú, tàbí tí kò ní jẹ́ kéèyàn gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o gbádùn ìlera tó dára títí di ọjọ́ náà nínú ayé tuntun Ọlọ́run tí kò ní sí “olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.