ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 6 ojú ìwé 3
  • Bá A Ṣe Lè Dènà Àrùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Dènà Àrùn
  • Jí!—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Kòkòrò Àrùn Ń Gbẹ̀san
    Jí!—1996
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
  • Ibi Táráyé Ṣẹ́gun Àrùn Dé àti Ibi Tó Kù Sí
    Jí!—2004
  • Ayé Kan Níbi Tí Kò Ti Ní Sí Àrùn
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2016
g16 No. 6 ojú ìwé 3

Kókó Iwájú Ìwé

Bá A Ṣe Lè Dènà Àrùn

Ojoojúmọ́ ni àgọ́ ara wa ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn kòkòrò àrùn tá ò lè rí. Lára wọn ni kòkòrò bakitéríà, fáírọ́ọ̀sì àti kòkòrò parasite tí wọ́n dà bíi májèlé tó lè ṣàkóbá fún ìlera wa.a A kì í mọ̀ tí àwọn nǹkan yìí bá ń ṣẹlẹ̀ nínú ara wa, torí pé kí àwọn májèlé yìí tó dá àìsàn sí wa lára ni àwọn ohun tó ń gbógun ti àrùn á ti mú wọn kúrò. Àmọ́ nígbà míì, àwọn májèlé yìí lè lágbára ju ara wa lọ kí wọ́n sì dá àìsàn sí wa lára. Àwọn oògùn tá a bá lò ló máa ń jẹ́ kí ara tún pa dà bọ̀ sípò.

Àwọn nǹkan tó ń fa àrùn, ìrìn àjò, àwọn kòkòrò tíntìntín, ìṣẹ́, àti síse oúnjẹ lọ́nà tí kò dáa

Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, àwọn èèyàn ò mọ nǹkan kan nípa ewu tí àwọn kòkòrò àrùn tíntìntín lè fà. Nígbà tó yá, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó gbáyé láwọn ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún wá jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kòkòrò yìí máa ń fa àrùn, wọ́n sì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa. Látìgbà náà wá, àwọn olùwádìí nínú ìmọ̀ ìṣègùn ti sapá gidigidi láti dín àwọn àrùn tó ń gbèèràn kù; bí ìgbóná àti àrùn rọpárọsẹ̀. Àìpẹ́ yìí ni àwọn àrùn bí ibà pọ́njú àti ibà dengue, tún bẹ̀rẹ̀ sí í jà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò:

  • Bí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ṣe ń rìnrìn àjò kárí ayé lọ́dọọdún, láìmọ̀, wọ́n lè fara gbé àwọn ohun tó lè fa àìsàn bá ẹlòmíì láti orílẹ̀-èdè kan sí orílẹ̀-èdè míì. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Clinical Infectious Diseases sọ pé: “Ìrìn àjò ayára bí àṣá táwọn èèyàn ń rìn kárí ayé wà lára ohun tó jẹ́ kí àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn gbèèràn.”

  • Àwọn kòkòrò bakitéríà kan kò gbóògùn apakòkòrò mọ́. Kódà, Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Ibi tí ayé dé báyìí, ó jọ pé apá oògùn apakòkòrò kò lè ká àwọn àìsàn mọ́, ó di kí ẹ̀fọ́rí lásán máa lu àwọn èèyàn pa.”

  • Ìjà abẹ́lé àti ipò òṣì kì í jẹ́ kí ìjọba lè kápá àrùn kó má bàa gbèèràn.

  • Ọ̀pọ̀ èèyàn kò mọ bí wọ́n ṣe lè dènà àrùn.

Láìka bí nǹkan ṣe rí yìí, ọgbọ́n wà tó o lè dá sí i kí ìwọ àti ìdílé rẹ lè dènà àrùn. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á jẹ́ kó o rí i pé ibi yòówù kó o máa gbé, àwọn nǹkan kéékèèké kan wà tó o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn.

a Kì í ṣe gbogbo kòkòrò àrùn tíntìntín ló máa ń dá àìsàn síni lára. Àmọ́ àwọn tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí lágbára láti ṣàkóbá fún ìlera wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́