KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ ÀRÙN
Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àrùn
LÁYÉ àtijọ́, wọ́n máa ń mọ ògiri gìrìwò yí ìlú ká láti dáàbò bò ó. Bí àwọn ọ̀tá bá rí àlàfo kékeré gbà wọlé, gbogbo ìlú náà kó sí wàhálà nìyẹn. Bákan náà, ara wa dà bí ìlú tí ògiri yíká. Àmọ́ bí a ṣe ń bójú tó ara wa ló máa pinnu bí ìlera wa ṣe máa rí. Jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà márùn-ún tó ṣeé ṣe kí àrùn gbà wọlé sí wa lára àti bí a ṣe lè dènà wọn.
1 OMI
EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò àrùn lè “wọlé” sínú àgọ́ ara wa látinú omi tó dọ̀tí.
BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Ohun tó gbéṣẹ́ jù tó o lè ṣe ni pé kí ó má ṣe jẹ́ kí ìdọ̀tí wọnú omi rẹ. Àmọ́ tó o bá kíyè sí pé ìdọ̀tí ti wọnú rẹ̀, o lè fi oògùn apakòkòrò sínú ẹ̀.a Jẹ́ kí omi máa wà nínú ohun tó ní ìdérí, kọ́ọ̀bù tó ní ọwọ́ ni kó o sì máa fi bù ú tàbí kó o ṣe ẹnu ẹ̀rọ sí i. Má ṣe máa kọwọ́ bọ inú omi. Tó bá ṣeé ṣe, rí i dájú pé àdúgbò tó mọ́ tónítóní lò ń gbé, kó sì jẹ́ ibi tí wọn kò fi ìgbẹ́ tàbí ìtọ̀ bà jẹ́.
2 OÚNJẸ
EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò àrùn lè wà nínú oúnjẹ
BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Àwọn oúnjẹ míì lè ní ìdọ̀tí tàbí májèlé nínú síbẹ̀ kó fani mọ́ra. Torí náà, fi kọ́ra láti máa fọ àwọn èso àti ẹ̀fọ́ rẹ dáadáa kó o tó jẹ ẹ́. Rí i dájú pé àwọn nǹkan ìdáná àti nǹkan ìjẹun rẹ títí kan ibi tó o ti ń dáná tàbí jẹun, wà ní mímọ́ tónítóní. Àwọn oúnjẹ kan wà tó o ní láti sè dáadáa torí àwọn kòkòrò tó lè fa àrùn. Ṣọ́ra fún jíjẹ́ oúnjẹ tó o bá fura sí pé ó ti ń bàjẹ́ tàbí tí àwọ̀ rẹ̀ ti yí pa dà tàbí tó ti ń rùn. Gbé oúnjẹ tí o kò bá jẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sínú fìríìjì. Má sì ṣe dáná oúnjẹ fún ẹnikẹ́ni nígbà tí ara rẹ kò bá yá.b
3 KÒKÒRÒ
EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò kan máa ń gbé ohun tó lè fa àrùn kiri, wọ́n sì lágbára láti kó àrùn tó wà lára wọn ran èèyàn.
BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Máa yẹra fún àwọn kòkòrò tó máa ń kó àrùn ranni. Ohun tó o lè ṣe ni pé kó o wọ aṣọ tó bo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ tàbí kó o má ṣe jókòó síta lákòókò táwọn kòkòrò náà bá ń fò kiri. Ó tún lè sùn sábẹ́ nẹ́ẹ̀tì apẹ̀fọn tàbí kó o lo oògùn ẹ̀fọn. Tètè máa da omi ìdọ̀tí nù kí àwọn ẹ̀fọn tó sọ ibẹ̀ dilé.c
4 ẸRANKO
EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò àrùn tó ń gbénú ẹranko láìpa wọn lára lè hàn àwa èèyàn léèmọ̀. Bí ẹranko bá fi èékánná ya wá tàbí tó bá gé wá jẹ tàbí tá a fẹsẹ̀ kó ìgbẹ́ rẹ̀, a lè tipa bẹ́ẹ̀ kó àrùn.
BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Àwọn kan kì í jẹ́ kí àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wọnú ilé, kí wọ́n má bàa kó àìsàn látara wọn. Rí i pé o fọ ọwọ́ rẹ lẹ́yìn tó o bá fọwọ́ kan ẹran ọ̀sìn wọn, kó o sì yẹra fún fífara kan àwọn ẹranko igbó. Bí ẹranko bá fi èékánná ya ẹ́ tàbí gé ẹ jẹ, fomi fọ ibẹ̀ dáadáa kó o sì lọ sọ́dọ̀ dókítà.d
5 ÈÈYÀN
EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò àrùn kan lè bá ikọ́ tàbí ikunmú ẹni kan jáde sára ẹlòmíì. A tún lè kó wọn tá a bá ń gbáni mọ́ra tàbí bọ ara ẹni lọ́wọ́. Nígbà míì àwọn kòkòrò bẹ́ẹ̀ lè lẹ̀ mọ́ ọwọ́ ìlẹ̀kùn, àtẹ̀gùn, ara tẹlifóònù, rìmóòtù, kọ̀ǹpútà tàbí keyboard.
BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Má ṣe máa pín bíléèdì lò títí kan tówẹ̀lì àti búrọ́ọ̀ṣì ìfọnu. Má ṣe jẹ́ kí omi ara títí kan ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíì tàbí ti ẹranko kan ara rẹ. Rántí pé ara ọ̀nà kan tó o lè gbà yẹra fún àrùn ni pé kó o máa fọ ọwọ́ rẹ lóòrèkóòrè. Òun gan-an ni ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ láti yẹra fún àìsàn.
Tó bá ṣeé ṣe, dúró sílé tó o bá ń ṣàìsàn. Àjọ Centers for Disease Control and Prevention, tó ń rí sí ìdènà àrùn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé tó o bá fẹ́ sín, lo bébà tàbí aṣọ pélébé kan, má ṣe sín sínú ọwọ́ rẹ.
Òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Òótọ́ ọ̀rọ̀ gbáà ni ọ̀rọ̀ yẹn, pàápàá lónìí tí ayé kún fún àwọn àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí! Torí náà, máa sá fún ewu kó o sì máa bójú tó ìlera rẹ déédéé. Máa kíyè sí ohun tó ń lọ láyìíká rẹ, kó o lè dènà àrùn!
a Àjọ Ìlera Àgbáyé dábàá àwọn ọ̀nà tá a lè gbà tọ́jú omi wa. Wọ́n ní a lè máa se omi tàbí ká máa fi oògùn apakòkòrò sínú rẹ̀ tàbí ká máa gbé e sínú oòrùn, tàbí ká fi asẹ́ sẹ́ ẹ.
b Bó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i lórí bó o ṣe lè máa tọ́jú oúnjẹ, wo Jí! July-September 2012 ojú ìwé 3 sí 9.
c Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó o lè ṣe láti dènà àìsàn ibà, wo Jí! September-October 2015 ojú ìwé 12 àti 13.
d Tí ejò bá ṣán ẹ tàbí tí àkekèé ta ẹ́, ojú ẹsẹ̀ ni kó o lọ sílé ìwòsàn.