Ẹja Clown Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀
ẸJA tó gbàfiyèsí bí ẹja clown ò wọ́pọ̀. Ó ní àwọ̀ mèremère, èyí sì mú kó fani mọ́ra gan-an. Ibi tó fi ṣe ilé tún yani lẹ́nu. Àárín ohun tó jọ òdòdó tí wọ́n ń pè ní anemone ló ń gbé. Òdòdó yìí ní ẹ̀gún lára, ẹ̀gún náà sì ní oró nínú. Àbájọ tí wọ́n tún fi ń pe ẹja clown yìí ní anemonefish, ìyẹn ẹja anemone.
Bíi ti àwọn eléré orí ìtàgé, ẹja yìí fẹ́ràn káwọn èèyàn máa yà á ní fọ́tò. Àwọn ẹja yìí máa ń “dúró” kí àwọn tó wá wẹ̀ nísàlẹ̀ omi ya fọ́tò wọn, tórí pé wọn kì í rìn jìnnà sí ilé wọn, wọn ò sì ń sá fún èèyàn.
Àmọ́ ohun tó mú kí ẹja clown ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú gbogbo ẹja ni ibi tó ń gbé. Àárín òdòdó tó ní ọwọ́ wọ́lọwọ̀lọ ló ń gbé, ẹ̀gún wà lára òdòdó náà, ó sì ní oró nínú. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ẹja yìí ń gbé láàárín ohun tó lè ṣekú pa á. Síbẹ̀, kò sí ohun tó lè ya àwọn méjèèjì. Kí ló mú kí àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ yìí ṣeé ṣe, kó sì yọrí sí rere?
‘WỌN KÌ Í FI ARA WỌN SÍLẸ̀’
Bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ lọ̀rọ̀ ẹja clown àti òdòdó anemone ṣe rí, wọ́n jọ máa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Kì í ṣe pé àjọṣe yìí rọ̀ ẹja clown lọ́rùn nìkan ni, ó tún ṣe pàtàkì gan-an fún ìwàláàyè rẹ̀. Kì nìdí? Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè inú okùn sọ pé ẹja clown kò lè dá gbé inú ibú omi láìsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òdòdó anemone. Ìdí ni pé ẹja yìí kò lè lúwẹ̀ẹ́ dáadáa, abẹ́ òdòdó anemone ló máa ń fi ṣe ilé àti ibi ààbò tí nǹkan kan bá fẹ́ pa á jẹ. Torí náà, bí ẹja yìí ṣe ń fi abẹ́ òdòdó anemone ṣe ilé, lè jẹ́ kó lò tó ọdún mẹ́wàá gbáko kó tó kú.
Yàtọ̀ sí pé ẹja yìí ń fi abẹ́ òdòdó anemone ṣe ilé, ibẹ̀ náà ló tún máa ń pamọ́ sí. Tí ẹja yìí bá fẹ́ yé ẹyin, ó máa ń lọ sí ìsàlẹ̀ òdòdó anemone, ibẹ̀ ni takọtabo wọn á ti máa bojú tó ẹyin wọn. Tí wọ́n bá pamọ, abẹ́ òdòdó yẹn ni wọ́n á máa gbé.
Àǹfààní wo ni àjọṣe yìí ń ṣe fún òdòdó anemone? Ẹja clown ló máa ń bá òdòdó anemone lé àwọn nǹkan tó lè ṣèpalára fún un, irú bi ẹja kan tí wọ́n ń pè ní butterfly fish, tó máa ń jẹ ọwọ́ òdòdó náà. Bí àpẹẹrẹ, oríṣi òdòdó anemone kan wà táwọn ẹja máa jẹ́ tí kò bá sí ẹja clown tó ń gbé láyìíká rẹ̀. Nígbà kan táwọn olùṣèwádìí kó ẹja clown kúrò lágbègbè òdòdó anemone, láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] péré, gbogbo òdòdó yìí ti pòórá. Ó jọ pé butterfly fish ló jẹ gbogbo ẹ̀ tán.
Ó tún jọ pé ẹja clown máa ń fún òdòdó yìí lágbára. Bí àpẹẹrẹ, èròjà kan wà tó máa ń jáde látara ẹja clown tó máa ń jẹ́ kí òdòdó yìí yára dàgbà. Bí ẹja clown sì ṣe ń lúwẹ̀ẹ́ yíká àwọn ọwọ́ òdòdó yìí, ó máa ń jẹ́ kí omi tó wà láyìíká òdòdó anemone ní afẹ́fẹ́ ọ́síjìn nínú.
Ó MÁA Ń LÚWẸ̀Ẹ́ NÍBI TÁWỌN ẸJA MÍÌ Ń BẸ̀RÙ LÁTI LỌ
Ara ẹja clown tún máa ń dáàbò bò ó. Ara wọn máa ń yọ̀, èyí kì í jẹ́ kí nǹkan ta á. Ọpẹ́lọpẹ́ bí ara rẹ̀ ṣe ń yọ̀ yìí ni kì í jẹ́ kí òdòdó anemone pa á lára, àfi bíi pé ìkan náà ni wọ́n. Onímọ̀ kan sọ pé ńṣe ló dà bí ìgbà tí ẹja clown “gbé àwọ̀ òdòdó anemone wọ̀.”
Ìwádìí kan fi hàn pé tí ẹja clown bá ń wá òdòdó tó máa fi ṣe ilé, ó máa kọ́kọ́ ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ibẹ̀ bá a lára mu. Wọ́n ṣàkíyèsí pé tí ẹja yìí bá kọ́kọ́ dé ibi tí òdòdó náà wà, á máa fara kan òdòdó náà díẹ̀díẹ̀ fún wákàtí mélòó kan. Ó jọ pé bó ṣe ń ṣe yìí máa ń jẹ́ kó lè mú èròjà tó ṣe déédéé pẹ̀lú oró tó wà lára òdòdó náà jáde. Láàárín àkókò náà, àwọn ẹ̀gún tó wà lára òdòdó náà máa gún un. Àmọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n á mọwọ́ ara wọn.
Àjọṣe àwọn ẹ̀dá méjì tó yàtọ̀ síra yìí kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa bó ṣe yẹ káwa èèyàn jọ máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Nínú ọ̀pọ̀ nǹkan táwa èèyàn ń ṣe, ó máa ń gba pé kí àwọn èèyàn tó wá látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jọ ṣe nǹkan pọ̀, èyí sì máa ń mú kí nǹkan lọ dáadáa láwùjọ. Bíi ti ẹja clown, ó lè gba àkókò kí àjọṣe àwa àtàwọn ẹlòmíì tó lè wọ̀ dáadáa, àmọ́ a máa rí èrè níbẹ̀.