ORÍ 33
Àwọn Ewu Wo Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Sìgá Mímu?
Wo àwọn ohun tá a kọ yìí, kó o sì fi àmì ✔ sínú àpótí èyí tó bá ṣàpèjúwe ohun tó o fẹ́.
□ Mo fẹ́ mọ bó ṣe máa ń rí
□ Mo fẹ́ fi pa ìrònú rẹ́
□ Mo fẹ́ káwọn èèyàn gba tèmi
□ Mi ò fẹ́ bí mo ṣe sanra yìí
TÓ O bá fi àmì sí èyíkéyìí nínú àwọn àpótí tó wà lójú ìwé 237, a jẹ́ pé ohun kan wà tó jọra nínú ọ̀rọ̀ ìwọ àtàwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ tó ń mu sìgá tàbí tí wọ́n ń ronú pé àwọn fẹ́ mú un.a Bí àpẹẹrẹ, ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ rèé:
Mo fẹ́ mọ bó ṣe máa ń rí. “Mi ò mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá mu sìgá, torí náà mo gba sìgá lọ́wọ́ ọmọbìnrin kan nílé ìwé wa, mo yọ́ kẹ́lẹ́ jáde, mo sì lọ mú un.”—Tracy.
Mo fẹ́ fi pa ìrònú rẹ́, káwọn èèyàn sì gba tèmi. “Àwọn ọmọ ilé ìwé wa máa ń sọ pé, ‘Ó yẹ kí n wá wá sìgá mu.’ Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mú un tán, wọ́n á sọ pé, ‘Ọkàn mi ti wá balẹ̀ báyìí!’ Fún ìdí yìí, èmi náà máa ń fẹ́ mu sìgá nígbà tí nǹkan bá tojú sú mi.”—Nikki.
Mi ò fẹ́ sanra jù. “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan máa ń mu sìgá kí wọ́n má bàa sanra, ìyẹn sì rọrùn ju kéèyàn máa ṣọ́ oúnjẹ jẹ lọ!”—Samantha.
Àmọ́, kó o tó tanná sí sìgá tó o máa kọ́kọ́ mu, tàbí èyí tó kàn tó o fẹ́ mu, dúró ná, kó o ronú. Má ṣe dà bí ẹja tó ń jẹ ìjẹ tó wà lára ìwọ̀. Òótọ́ ni pé ẹja yẹn lè jàǹfààní díẹ̀, àmọ́ àfàìmọ̀ kí ẹ̀mí rẹ̀ má lọ sí i. Ṣe ni kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, kó o sì lo “ìrònú [rẹ] ṣíṣe kedere.” (2 Pétérù 3:1) Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí ná.
Kí Lohun Tó O Mọ̀ Gan-an Nípa Sìgá Mímu?
Fàmì sí òótọ́ tàbí irọ́ níwájú gbólóhùn kọ̀ọ̀kan.
a. Tí mo bá mu sìgá, ó máa dín ìdààmú ọkàn mi kù.
□ Òótọ́ □ Irọ́
b. Gbogbo èéfín sìgá yẹn ni màá tú jáde.
□ Òótọ́ □ Irọ́
d. Tí mo bá ń mu sìgá, kò lè ṣàkóbá fún ìlera mi báyìí, ó dìgbà tí mo bá dàgbà sí i.
□ Òótọ́ □ Irọ́
e. Sìgá mímu máa jẹ́ kí àwọn ọkùnrin (tàbí àwọn obìnrin) túbọ̀ gba tèmi.
□ Òótọ́ □ Irọ́
ẹ. Tí mo bá mu sìgá, kò pa ẹlòmíì lára, èmi nìkan ló ń pa lára.
□ Òótọ́ □ Irọ́
f. Bóyá mò ń mu sìgá tàbí mi ò mu sìgá, ìyẹn kò kan Ọlọ́run.
□ Òótọ́ □ Irọ́
Ìdáhùn
a. Irọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé sìgá mímu máa ń gbani lọ́wọ́ àwọn ìnira téèyàn máa ń ní lásìkò téèyàn bá fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀, ìtura ọ̀hún kì í pẹ́ lọ títí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí pé ńṣe ni èròjà olóró tí wọ́n ń pè ní nicotine tó wà nínú sìgá máa ń dá kún ìdààmú ọkàn.
b. Irọ́. Ìwádìí fi hàn pé ìdá mẹ́jọ nínú mẹ́wàá èéfín sìgá tó o bá mu ló máa dúró sínú ara rẹ.
d. Irọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bó o ṣe ń mu sìgá kọ̀ọ̀kan ló túbọ̀ ń ṣàkóbá fún ara rẹ, síbẹ̀ o ò lè tètè rí àbájáde rẹ̀. Látorí sìgá àkọ́kọ́ tí àwọn kan mu ni wọ́n ti sọ sìgá mímu di bárakú. Ẹ̀dọ̀fóró rẹ kò ní lè ṣiṣẹ́ dáadáa bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó o bẹ̀rẹ̀ sí í wúkọ́ lemọ́lemọ́. Ara rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í hun jọ láìjẹ́ pé o ti darúgbó. Sìgá mímu lè dín agbára ìbálòpọ̀ rẹ kù, ó lè mú kí àyà rẹ kàn máa já, ó sì lè kó ìdààmú ọkàn bá ẹ.
e. Irọ́. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Lloyd Johnston ṣàwárí pé “ọ̀pọ̀ jù lọ ọkùnrin àti obìnrin ni kì í fi bẹ́ẹ̀ gba ti” àwọn ọ̀dọ́ tó ń mu sìgá.
ẹ. Irọ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún torí pé wọ́n ń fa èéfín sìgá táwọn míì ń mu sínú. Bó o bá ń mu sìgá, ó máa ṣàkóbá fáwọn ẹbí rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn ohun ọ̀sìn rẹ pàápàá.
f. Irọ́. Àwọn tó bá fẹ́ múnú Ọlọrun dùn gbọ́dọ̀ wẹ ara wọn mọ́ kúrò “nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ohun kan tó dájú ni pé sìgá mímu máa ń sọ ara èèyàn di ẹlẹ́gbin. Bó o bá sọ ara rẹ di ẹlẹ́gbin, tí o sì ń ṣèpalára fún ara rẹ àtàwọn ẹlòmíì nípa mímu sìgá, o kò lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Mátíù 22:39; Gálátíà 5:19-21.
Bó O Ṣe Lè Dènà Sìgá Mímu
Kí lo máa wá ṣe báyìí bí ẹnì kan bá fún ẹ ní sìgá? Ó sábà máa ń dáa gan-an béèyàn bá kàn sọ pé, “Rárá, èmi kì í mu sìgá.” Bí onítọ̀hún kò bá fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀ tàbí tó ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́, má ṣe gbàgbé pé ìpinnu tìrẹ lo ti sọ yẹn. O lè wá sọ pé:
● “Nígbà tí mo rí i pé sìgá mímu lè ṣàkóbá tó pọ̀ gan-an fún ara mi, mo pinnu pé mi ò ní mu sìgá.”
● “Mo ṣì ní àwọn nǹkan pàtàkì tí mo fẹ́ gbé ṣe lọ́jọ́ iwájú, bí mi ò bá sì lè mí dáadáa mọ́, mi ò ní lè ṣe àwọn nǹkan ọ̀hún.”
● “Ṣé o fẹ́ máa sọ fún mi pé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tí mo fẹ́ ni?”
Àmọ́ ọ̀rọ̀ tìrẹ lè dà bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ orí yìí, kó jẹ́ pé olórí ìṣòro tìrẹ ni pé sìgá sábà máa ń wù ẹ́ mu. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè borí ìṣòro yìí tó o bá bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi:
● ‘Àǹfààní wo gan-an ni sìgá mímu tiẹ̀ máa ṣe fún mi? Bí àpẹẹrẹ, tí mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá torí kí àwọn èèyàn lè gba tèmi, ṣé gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe lèmi náà á lè máa bá wọn lọ́wọ́ nínú rẹ̀? Ṣé àwọn tí inú wọn á máa dùn sí bí mo ṣe ń ṣàkóbá fún ìlera mi ló tiẹ̀ wá yẹ kí n máa fara wé?’
● ‘Èló ni sìgá mímu máa ná mi, àkóbá wo ló máa ṣe fún ìlera mi, ṣé àwọn ẹlòmíì á ṣì máa bọ̀wọ̀ fún mi?’
● ‘Ṣé ó wá yẹ kí n ba àjọṣe àárín èmi àti Ọlọ́run jẹ́ nítorí sìgá mímu?’
Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ó ti di bárakú fún ẹ ńkọ́? Kí lo lè ṣe láti jáwọ́ nínú rẹ̀?
Bó O Ṣe Lè Jáwọ́
1. Jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ ṣe dá ẹ lójú. Kọ àwọn ìdí tó o fi fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu sílẹ̀, kó o sì máa ṣàyẹ̀wò rẹ̀ déédéé. Fífẹ́ tó o fẹ́ láti jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run lè túbọ̀ mú kó o jáwọ́.—Róòmù 12:1; Éfésù 4:17-19.
2. Wá ìrànlọ́wọ́. Tó o bá ti ń mu sìgá ní kọ̀rọ̀, àkókò nìyí fún ẹ láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀. Sọ fún àwọn tí o kò fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ò ń mu sìgá tẹ́lẹ̀ pé o fẹ́ jáwọ́, kó o sì ní kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá fẹ́ sin Ọlọ́run, gbàdúrà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́.—1 Jòhánù 5:14.
3. Dá ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́. Dá ọ̀sẹ̀ méjì, tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀, fún ara rẹ, kó o sì sàmì sí ọjọ́ tó o pinnu láti jáwọ́ lórí kàlẹ́ńdà rẹ. Sọ ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu fún àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
4. Wá àwọn sìgá tó kù sí ẹ lọ́wọ́, kó o sì kó o dà nù. Kó tó di ọjọ́ tó o máa jáwọ́ nínú sìgá mímu, wá inú yàrá rẹ, inú ọkọ̀ rẹ àti inú àpò àwọn aṣọ rẹ bóyá wàá rí sìgá. Kó àwọn sìgá, àwọn ohun tó o fi ń tanná ran sìgá àti àwo tó o máa ń ṣẹ́ eérú sìgá sí dà nù.
5. Fara da ìnira tó lè wáyé nígbà tó o bá fẹ́ jáwọ́. Máa jẹ èso tó pọ̀ dáadáa, máa mu omi tó pọ̀ gan-an, kó o sì máa sùn dáadáa. Máa fi sọ́kàn pé ìnira tó o máa rí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ àǹfààní rẹ̀ máa wà títí lọ gbére!
6. Yẹra fún àwọn nǹkan tó lè mú kí sìgá wù ẹ́ mu. Máa yàgò fún àwọn ibi tí sìgá á ti fẹ́ máa wù ẹ́ mu àtàwọn ipò tó lè mú kó fẹ́ wù ẹ́ mu. Ó tún lè gba pé kó o má ṣe máa bá àwọn tó ń mu sìgá rìn mọ́.—Òwe 13:20.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Tàn Ẹ́
Lọ́dọọdún, àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe sìgá máa ń ná ọ̀pọ̀lọpọ̀ bílíọ̀nù owó dọ́là sórí ìpolówó sìgá. Àwọn wo gan-an ni wọ́n fẹ́ dìídì sọ di oníbàárà wọn? Ìwé àkọsílẹ̀ kan nílé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe sìgá sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ òní ló máa di oníbàárà lọ́la.”
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ilé iṣẹ́ sìgá gba owó rẹ. Kí ló dé tí wàá fi jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́ jẹ? Àwọn tó ń polówó sìgá àtàwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ tí wọ́n fẹ́ kó o mu sìgá kò wá ire rẹ. Dípò tí wàá fi gbọ́ tiwọn, ìmọ̀ràn Bíbélì ni kó o fetí sí, kó o sì kọ́ bí wàá ṣe “ṣe ara rẹ láǹfààní.”—Aísáyà 48:17.
Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa ń fẹ́ kó o mu ọtí? Mọ ìdí tó fi yẹ kó o mọ ibi tágbára ẹ gbé e dé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń mu sìgá la sọ nínú orí yìí, àwọn ìṣòro àtàwọn ewu tó wà níbẹ̀ kan àwọn tó ń mu tábà tàbí tí wọ́n ń fín aáṣáà pẹ̀lú.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
‘Jìnnà pátápátá sí ohunkóhun tí kì í jẹ́ kí ara wa wà ní mímọ́.’—2 Kọ́ríńtì 7:1, Bíbélì Contemporary English Version.
ÌMỌ̀RÀN
Má ṣe tan ara rẹ jẹ, kó o máa rò pé, ‘màá kàn fà á fìn-ìn lẹ́ẹ̀kan péré, ó tán.’ Ṣe làwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ tún máa ń dẹni tó ń mu sìgá lójú páálí.—Jeremáyà 17:9.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Tábà tí wọ́n ń fín símú, èyí tí wọ́n ń jẹ lẹ́nu tàbí èyí tí wọ́n ń fi sórí ahọ́n, máa ń ní èròjà olóró tí wọ́n ń pè ní nicotine púpọ̀ ju ti sìgá lọ, ó sì tún ní èròjà olóró mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] míì tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ, irú bíi jẹjẹrẹ ọ̀nà ọ̀fun àti ti ẹnu.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Tí ọmọ ilé ìwé mi bá ń rọ̀ mí pé kí n mu sìgá, màá ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o mọ àwọn àkóbá tí sìgá mímu máa ń fà, kí nìdí tó tún fi lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o mu sìgá?
● Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àṣàkaṣà ni kéèyàn máa mu sìgá?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 240]
“Nígbà tí wọ́n bá fi sìgá lọ̀ mí, ṣe ni mo kàn máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́, màá sì sọ pé, ‘Ẹ ṣé gan-an, mi ò fẹ́ kó àrùn jẹjẹrẹ.’”—Alana
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 241]
Ṣé Igbó Mímu Burú Tó Bẹ́ẹ̀ Ni?
Ẹnì kan tó ń jẹ́ Ellen tó ń gbé ní ilẹ̀ Ireland sọ pé: “Àwọn kan máa ń sọ pé téèyàn bá ń mugbó, ó máa jẹ́ kó bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro, pé kì í sì í ṣàkóbá kankan fún èèyàn.” Ṣé ìwọ náà ti gbọ́ káwọn èèyàn máa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nípa igbó mímu? Wo àwọn àròsọ lásán táwọn èèyàn máa ń sọ àti ohun tó jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀.
Àròsọ. Kò sí ìpalára kankan tí igbó máa ń ṣe fúnni.
Òótọ́ Ọ̀rọ̀. Àwọn ìpalára tó máa ń ṣe fúnni àti àkóbá tó lè ṣe nìwọ̀nyí: Ó máa ń da ọpọlọ rú, kì í jẹ́ kéèyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, ó sì máa ń ṣèpalára fáwọn èròjà tó ń gbógun ti àrùn nínú ara, bákan náà, ó máa ń ṣèpalára fún agbára ìbálòpọ̀ ẹni. Ó lè fa kí nǹkan máa tojú sú èèyàn, kéèyàn máa ṣe gán-gàn-gán, kéèyàn sì máa fura òdì sáwọn èèyàn. Àwọn ọmọ tí obìnrin tó ń mu igbó bá bí lè ya ọmọkọ́mọ, wọn ò ní lè máa pọkàn pọ̀, ó sì lè máa ṣòro fún wọn gan-an láti ṣèpinnu.
Àròsọ. Èéfín igbó kò léwu tó èéfín sìgá.
Òótọ́ Ọ̀rọ̀. Tá a bá fi èéfín sìgá wé èéfín igbó, èéfín igbó máa ń jẹ́ kí ọ̀nà ọ̀fun èèyàn dúdú ní ìlọ́po mẹ́rin ju èéfín sìgá lọ, afẹ́fẹ́ olóró tí wọ́n ń pè ní carbon monoxide tó sì máa ń lọ sínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn tó ìlọ́po márùn-ún ju ti èéfín sìgá. Igbó wíwé márùn-ún péré lè tú ìwọ̀n èròjà olóró tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ tó pọ̀ tó èyí tó wà nínú odindi páálí sìgá kan sínú ara èèyàn.
Àròsọ. Èèyàn ò lè sọ igbó mímu di bárakú.
Òótọ́ Ọ̀rọ̀. Àwọn ọ̀dọ́ tí wọn ò tíì pé ọmọ ogún ọdún tí ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá lè tètè sọ igbó mímu di bárakú. Àwọn ọ̀dọ́ míì lè sọ ọ́ di bárakú tó bá ti pẹ́ tí wọ́n ti ń mu ún. Bákan náà, ìwádìí fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ tí wọn ò tíì pé ọmọ ogún ọdún tí wọ́n ń mu igbó máa ń tètè dẹni tó ń lo àwọn oògùn olóró míì tó máa ń di bárakú fún èèyàn, irú bíi kokéènì.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 244, 245]
Ìpalára Tí Tábà Máa Ń Ṣe Fún Ara Rẹ
Fojú inú wo àwọn èèyàn tára wọn le, tójú wọn ń dán tí wọ́n máa ń lò láti fi polówó sìgá; wá fìyẹn wé ìpalára tí sìgá mímú ń ṣe fún ara rẹ.
Ẹnu àti ọ̀nà ọ̀fun Ó lè fa àrùn jẹjẹrẹ níbí
[Àwòrán]
Ahọ́n tó ní àrùn jẹjẹrẹ
Ọkàn Ó ń jẹ́ kí àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ ẹni le gbagidi, kí wọ́n sì máa lẹ̀ pọ̀, kì í jẹ́ kí ọkàn rí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tó, ó sì lè tètè jẹ́ kéèyàn ní àrùn ọkàn ní ìlọ́po mẹ́rin tá a bá fi wé tẹni tí kì í mu sìgá
[Àwòrán]
Òpó ẹ̀jẹ̀ tó ti fẹ́ dí
Ẹ̀dọ̀fóró Ó máa ń ṣàkóbá fún inú ẹ̀dọ̀fóró, ó ń jẹ́ kí ọ̀nà ọ̀fun wú, ó sì lè tètè jẹ́ kí àrùn jẹjẹrẹ mú èèyàn ní ẹ̀dọ̀fóró ní ìlọ́po mẹ́tàlélógún tá a bá fi wé tẹ́ni tí kì í mu sìgá
[Àwòrán]
Ẹ̀dọ̀fóró amusìgá
Ọpọlọ Ó máa ń jẹ́ kéèyàn tètè ní àìsàn rọpárọsẹ̀ ní ìlọ́po mẹ́rin tá a bá fi wé tẹni tí kì í mu sìgá
Awọ Ara Ó lè jẹ́ kára èèyàn hun jọ bíi ti arúgbó
Eyín Ó lè jẹ́ kí eyín èèyàn máa pọ́n
Ikùn Ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ níbí
Àmọ́ Ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ níbí
Àpò-ìtọ̀ Ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ níbí
Kíndìnrín Ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ níbí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 239]
Bíi ti ẹja tó ń jẹ ìjẹ náà ni ẹni tó ń mu sìgá ṣe ń rí nǹkan kan gbà níbẹ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n máa fi dí i kì í ṣe kékeré