ORIN 103
Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jáà fún wa ní àwọn ọkùnrin;
Ẹ̀bùn nínú èèyàn.
Wọ́n ń fàpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀;
Wọ́n máa ń tọ́ wa sọ́nà.
(ÈGBÈ)
Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́
Ni Ọlọ́run yàn fún wa
Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀;
Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn.
2. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wa
Kì í fọ̀rọ̀ wa ṣeré.
Tí ìṣòro bá sì dé bá wa,
Wọ́n máa ń bójú tó wa.
(ÈGBÈ)
Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́
Ni Ọlọ́run yàn fún wa
Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀;
Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn.
3. Wọ́n máa ń gbà wá nímọ̀ràn tó dáa
Ká lè ṣohun tó tọ́.
Wọ́n máa ń pèsè ‘rànwọ́ tá a nílò
Ká lè máa jọ́sìn Jáà.
(ÈGBÈ)
Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́
Ni Ọlọ́run yàn fún wa
Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀;
Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn.
(Tún wo Àìsá. 32:1, 2; Jer. 3:15; Jòh. 21:15-17; Ìṣe 20:28.)