ORIN 114
Ẹ Máa Ní Sùúrù
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọlọ́run wa
Nítara f’óókọ mímọ́ rẹ̀.
Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni pé
Kí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́.
Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà
Ti ń fara da ọ̀pọ̀ nǹkan.
Ó ń finúure hàn sí wa;
Ó ń fìfẹ́ ní sùúrù.
Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni pé
Kí ọ̀pọ̀ èèyàn rígbàlà.
Sùúrù tí Jèhófà ní
Látọjọ́ yìí kò já sásán.
2. Tá a bá jẹ́ onísùúrù,
Ó máa tọ́ wa sọ́nà tó dáa.
Ó máa fọkàn wa balẹ̀.
Kò ní jẹ́ ká bínú sódì.
Kò ní jẹ́ kí a máa ṣọ́
Àṣìṣe àwọn mìíràn.
Yóò jẹ́ ká nífaradà
Bí a tiẹ̀ níṣòro.
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run
Yóò jẹ́ ká lè máa ní sùúrù.
Tá a bá jẹ́ onísùúrù,
A máa fìwà jọ Ọlọ́run.
(Tún wo Ẹ́kís. 34:14; Àìsá. 40:28; 1 Kọ́r. 13:4, 7; 1 Tím. 2:4.)