ORIN 134
Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí
1. Tí tọkọtaya bá bímọ,
Tí àwọn méjèèjì wá di òbí,
Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà fún wọn
Pé kí wọ́n tọ́jú ọmọ náà.
Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni.
Òun ló dá wa, ó sì ní ìfẹ́ wa.
Ó fáwọn òbí ní ìtọ́ni
Kí wọ́n lè tọ́ ọmọ wọn dáadáa.
(ÈGBÈ)
Jèhófà ló ni ọmọ ‘wọ́ yín,
Ẹ̀bùn iyebíye ló jẹ́.
Ẹ̀bùn tó dáa jù tẹ́ ẹ lè fún un ni
Pé kẹ́ ẹ kọ́ ọ lófin Ọlọ́run.
2. Ẹ̀yin òbí gbọ́dọ̀ máa fi
Gbogbo àṣẹ Ọlọ́run sọ́kàn yín.
Kẹ́ ẹ máa fi kọ́ àwọn ọmọ yín.
Ohun tẹ́ ẹ gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn.
Ẹ fi kọ́ wọn tẹ́ ẹ bá ń rìn lọ́nà,
Tí ẹ bá jí àti kí ẹ tó sùn.
Wọn yóò máa rántí nígbà gbogbo,
Wọn yóò sì múnú Jèhófà dùn.
(ÈGBÈ)
Jèhófà ló ni ọmọ ‘wọ́ yín,
Ẹ̀bùn iyebíye ló jẹ́.
Ẹ̀bùn tó dáa jù tẹ́ ẹ lè fún un ni
Pé kẹ́ ẹ kọ́ ọ lófin Ọlọ́run.
(Tún wo Diu. 6:6, 7; Éfé. 6:4; 1 Tím. 4:16.)