Ẹ̀KỌ́ 2
Sọ̀rọ̀ Bí Ẹni Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀
2 Kọ́ríńtì 2:17
KÓKÓ PÀTÀKÌ: Sọ̀rọ̀ bó o ṣe máa ń sọ̀rọ̀ gangan, sọ̀rọ̀ látọkàn wá, jẹ́ kó hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àtàwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Gbàdúrà, kó o sì múra sílẹ̀ dáadáa. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí ohun tó o fẹ́ sọ láì pàfíyèsí sí ara rẹ. Jẹ́ kí àwọn kókó tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí ṣe kedere lọ́kàn rẹ. Má ṣe máa ka ọ̀rọ̀ jáde bó ṣe wà nínú ìwé gẹ́lẹ́; ńṣe ni kó o sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ara rẹ.
Sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Ronú nípa ìdí tó fi yẹ kí àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ. Jẹ́ kí ọkàn rẹ wà lọ́dọ̀ wọn. Kíyè sí bó o ṣe dúró, bó o ṣe ń fara ṣàpèjúwe àti bí ojú rẹ ṣe rí. Àwọn nǹkan yìí máa fi hàn bóyá ohun tó ò ń sọ ti ọkàn rẹ wá àti bóyá o ka àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ sí ọ̀rẹ́.
Máa wojú àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀. Máa wo ojú àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀, ìyẹn níbi tí wọn ò bá ti kà á sí ìwà àrífín. Tó o bá ń sọ àsọyé, kì í ṣe àwùjọ lápapọ̀ nìkan ni kí o wò, tún wo àwọn tó wà nínú àwùjọ lọ́kọ̀ọ̀kan.