September
Thursday, September 1
Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò tú ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn.—Jóẹ́lì 2:28.
Pétérù lo gbólóhùn kan tó yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì. (Ìṣe 2:16, 17) Kàkà kí Pétérù fi gbólóhùn náà “lẹ́yìn ìyẹn” bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ọjọ́ ìkẹyìn wo ni Pétérù ní lọ́kàn? Tá a bá fojú àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ wò ó, ó túmọ̀ sí ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn Júù. Lédè míì, ó sọ pé ìgbà yẹn ni Jèhófà máa tú ẹ̀mí rẹ̀ sára “onírúurú èèyàn.” Èyí jẹ́ kó yé wa pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá kí apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì tó ṣẹ. Lẹ́yìn táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní rí ẹ̀mí mímọ́ gbà lọ́nà ìyanu, wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù náà, wọ́n sì rí i pé ó délé dóko. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi máa kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará nílùú Kólósè, ìyẹn ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni, ó sọ pé ìhìn rere náà ti dé ọ̀dọ̀ “gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:23) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “gbogbo ẹ̀dá,” ohun tó ní lọ́kàn ni gbogbo ibi tóun àtàwọn míì bíi tiẹ̀ wàásù dé. Lónìí, ẹ̀mí mímọ́ ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò gan-an, àní dé “gbogbo ayé”!—Ìṣe 13:47. w20.04 6-7 ¶15-16
Friday, September 2
Èmi fúnra mi yóò wá àwọn àgùntàn mi, màá sì bójú tó wọn.—Ìsík. 34:11.
Gbogbo wa ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ títí kan àwọn àgùntàn tó ti ṣáko lọ. (Mát. 18:12-14) Jèhófà sọ pé òun máa wá àwọn àgùntàn òun tó sọ nù, òun á sì mú wọn pa dà sínú agbo. Ó tún sọ àwọn ìgbésẹ̀ tó máa gbé láti mú wọn pa dà sínú agbo, àwọn ìgbésẹ̀ yìí kan náà ni olùṣọ́ àgùntàn kan ní Ísírẹ́lì máa gbé tí àgùntàn rẹ̀ bá sọ nù. (Ìsík. 34:12-16) Lákọ̀ọ́kọ́, olùṣọ́ àgùntàn yìí máa wá àgùntàn náà lọ, ìyẹn sì máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá. Tó bá ti rí i, á gbé e pa dà sínú agbo. Tí àgùntàn náà bá ṣèṣe, á tọ́jú rẹ̀, tí ebi bá ń pa á, á gbé e mọ́ra, á sì fún un lóúnjẹ. Ìgbésẹ̀ yìí kan náà ló yẹ kí ẹ̀yin alàgbà tẹ́ ẹ jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn “agbo Ọlọ́run” máa gbé kẹ́ ẹ lè ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn tó ti ṣáko lọ. (1 Pét. 5:2, 3) Ẹ wá wọn lọ, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sínú ìjọ, kẹ́ ẹ sì fìfẹ́ bójú tó wọn nípa tẹ̀mí. w20.06 20 ¶10
Saturday, September 3
Àwọn pápá . . . ti funfun, wọ́n ti tó kórè.—Jòh. 4:35.
Ṣé torí pé Jésù gbà pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa tẹ̀ lé òun ló ṣe sọ pé pápá ti tó kórè? Rárá. Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ̀nba èèyàn ló máa ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Jòh. 12:37, 38) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn lọ́nà ìyanu. (Mát. 9:4) Síbẹ̀, ó pọkàn pọ̀ sórí bó ṣe máa ran àwọn tó ní ìgbàgbọ́ lọ́wọ́, ó sì fìtara wàásù fún gbogbo èèyàn. Tí Jésù tó mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn kò bá pa àwọn èèyàn tì, mélòómélòó àwa tá ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn! Torí náà, kò yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ tàbí ká pa wọ́n tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká gbà pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn. Ẹ má gbàgbé ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó sọ pé àwọn pápá ti funfun, ìyẹn ni pé wọ́n ti tó kórè. Èyí fi hàn pé àwọn èèyàn lè yí pa dà kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Jèhófà gbà pé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ó sì gbà pé “ohun iyebíye” ni wọ́n. (Hág. 2:7) Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo àwọn èèyàn làwa náà fi ń wò wọ́n, àá sapá láti mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. A ò ní wò wọ́n bí ẹni tí kò lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ àá gbà pé wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì di arákùnrin àti arábìnrin wa. w20.04 13 ¶18-19
Sunday, September 4
Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.—Jòh. 15:15.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé ká tó lè múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù. Ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe ká lè di ọ̀rẹ́ Jésù ni pé ká mọ̀ ọ́n. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ka àwọn Ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù. Bá a ṣe ń kíyè sí bí Jésù ṣe fìfẹ́ bá àwọn èèyàn lò nínú àwọn ìwé yìí tá a sì ń ṣàṣàrò lé wọn lórí, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù, àá sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un. Bí àpẹẹrẹ, kò ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí ẹrú bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni Ọ̀gá wọn. Dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn òun àti bí nǹkan ṣe rí lára òun. Jésù bá wọn kẹ́dùn, kódà ó sunkún pẹ̀lú wọn. (Jòh. 11:32-36) Àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá gbà pé ó di ọ̀rẹ́ àwọn tó tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Mát. 11:19) Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò, àá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì, ọkàn wa máa balẹ̀, àá láyọ̀, àá sì túbọ̀ mọyì Kristi. w20.04 22 ¶9-10
Monday, September 5
Ọba gúúsù máa múra sílẹ̀ fún ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tó lágbára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.—Dán. 11:25.
Nígbà tó fi máa dọdún 1870, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ń ṣàkóso àwọn ilẹ̀ tó pọ̀ jù láyé, òun ló sì ní ẹgbẹ́ ológun tó lágbára jù lọ. Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ìwo kékeré kan tó ṣẹ́gun ìwo mẹ́ta míì. Ìwo kékeré yẹn ṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà táwọn ìwo yòókù ṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Faransé, orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Netherlands. (Dán. 7:7, 8) Òun ni ọba gúúsù títí dìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Láàárín àsìkò yìí kan náà, Amẹ́ríkà ni orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù lọ láyé, ó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jọ pawọ́ pọ̀ ja ogun náà, ìyẹn sì mú kí wọ́n lágbára gan-an. Àsìkò yẹn ni wọ́n di ohun tá a mọ̀ lónìí sí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọba yìí ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tó lágbára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni ọba gúúsù. w20.05 4 ¶7-8
Tuesday, September 6
Ibi tí àwọn odò ti ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n ń pa dà sí.—Oníw. 1:7.
Omi wà lórí ilẹ̀ ayé yìí torí pé ayé ò jìnnà jù sí oòrùn bẹ́ẹ̀ sì ni kò sún mọ́ ọn jù. Bí ayé bá sún mọ́ oòrùn jù, ooru rẹ̀ á fa gbogbo omi ayé gbẹ; bó bá sì jìnnà jù, omi inú ayé yóò di yìnyín gbagidi. Bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí tó sì fi í síbi tó yẹ ló mú kí ìyípo omi ṣeé ṣe kó lè máa gbé ẹ̀mí wa ró. Oòrùn máa ń fà lára omi tó wà nínú òkun, adágún, odò tàbí òkìtì yìnyín lọ sí ojú ọ̀run níbi tó ti máa gbára jọ. Lọ́dọọdún, iye omi tí oòrùn máa ń fà lọ sókè pọ̀ gan-an, kódà wọ́n fojú bù ú pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó máìlì ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà (120,000) lóròó àti níbùú. Lẹ́yìn tí omi náà bá ti wà lójú òfúrufú fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá, á rọ̀ bí òjò tàbí yìnyín. Àgbàrá òjò náà á ṣàn pa dà sínú òkun, adágún àti odò, ìyípo náà á sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Bí Jèhófà ṣe ṣe é kí omi máa yípo lọ́nà yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti alágbára.—Jóòbù 36:27, 28. w20.05 22 ¶6
Wednesday, September 7
Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín.—Ìṣe 1:8.
Jésù rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:9, 13) Jèhófà máa ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yìí fún wa ní agbára, àní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí. Ẹ̀mí mímọ́ tún máa ń jẹ́ ká lè ṣe ojúṣe wa nínú ètò Ọlọ́run, ó sì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ já fáfá nínú àwọn ohun tá a mọ̀ ọ́n ṣe. Ká sòótọ́, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló ń jẹ́ ká lè gbé onírúurú nǹkan ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀, kì í ṣe agbára wa. A lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí mímọ́ tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká mọ̀ tá a bá ti ń ní èrò tí kò tọ́ nínú ọkàn wa. (Sm. 139:23, 24) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ̀ bóyá èrò tí kò tọ́ ti ń gbilẹ̀ lọ́kàn wa. Àá wá bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ká lè fa èrò tí kò tọ́ náà tu. Èyí á fi hàn pé a ò fẹ́ kí ohunkóhun dí Jèhófà lọ́wọ́ àtimáa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́.—Éfé. 4:30. w20.05 28-29 ¶10-12
Thursday, September 8
Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ.—Jòh. 17:26.
Àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé tá a bá jẹ́ káwọn míì mọ òótọ́ nípa Jèhófà. Yàtọ̀ sí pé Jésù sọ orúkọ Baba rẹ̀ fáwọn èèyàn, ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ìwà àwọn Farisí àtohun tí wọ́n fi ń kọ́ni mú káwọn èèyàn máa wo Jèhófà bí ẹni tó le koko jù, tí kì í gba tẹni rò, tí kò ṣeé sún mọ́, tí kò sì láàánú. Àmọ́ Jésù fi hàn pé Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ó kọ́ni pé Jèhófà máa ń gba tàwọn èèyàn rò, ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó máa ń mú sùúrù, ó sì ń dárí jini. Ó tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ nínú ìwà rẹ̀ torí pé ó gbé ànímọ́ Baba rẹ̀ yọ lọ́nà tó pé pérépéré. (Jòh. 14:9) Bíi ti Jésù, àwa náà lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni, ó sì jẹ́ onínúure. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé irọ́ làwọn ọ̀tá Jèhófà ń pa mọ́ ọn. A lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni. Ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. A lè dá orúkọ Jèhófà láre tá a bá jẹ́ káwọn èèyàn lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. w20.06 6 ¶17-18
Friday, September 9
Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.—Gál. 5:26.
Ká sòótọ́, ìkànnì àjọlò wúlò láyè tiẹ̀, bí àpẹẹrẹ ó máa ń jẹ́ kó rọrùn láti kàn sí tẹbí-tọ̀rẹ́. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé torí káwọn èèyàn lè máa kan sáárá sí wọn làwọn kan ṣe ń gbé fọ́tò, fídíò àtàwọn nǹkan míì sórí ìkànnì? Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń sọ pé “Ẹ wò mí kẹ́ ẹ tún mi wò.” Àwọn kan máa ń sọ ọ̀rọ̀ àrífín àtàwọn ọ̀rọ̀ rírùn nípa fọ́tò wọn àtèyí táwọn míì gbé síbẹ̀. Torí pé àwa Kristẹni lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a sì máa ń gba tàwọn míì rò, a kì í sọ ọ̀rọ̀ tí kò bójú mu nípa àwọn míì. (1 Pét. 3:8) Tó o bá ń lo ìkànnì àjọlò, ó yẹ kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àwọn ọ̀rọ̀, fọ́tò tàbí àwọn fídíò tí mò ń gbé síbẹ̀ fi hàn pé mò ń gbéra ga tàbí fọ́nnu? Ṣé àwọn míì kò ní máa jowú tí wọ́n bá rí àwọn nǹkan tí mo gbé síbẹ̀?’ Àwa Kristẹni ò fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé wa gẹ̀gẹ̀. A máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní sọ́kàn. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa ṣe bíi tàwọn èèyàn ayé tí wọ́n ń gbéra ga tí wọ́n sì ń fẹ́ káwọn míì máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀.—1 Jòh. 2:16. w20.07 6 ¶14-15
Saturday, September 10
Asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni, mo sì jẹ́ aláfojúdi. Síbẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, torí àìmọ̀kan ni mo fi hùwà.—1 Tím. 1:13.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, ìyẹn kó tó di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, aláfojúdi ni, ó sì máa ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ìṣe 7:58) Jésù fúnra ẹ̀ ló dá Pọ́ọ̀lù lẹ́kun àtimáa ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni. Jésù bá a sọ̀rọ̀ látọ̀run, ó sì mú kó fọ́ lójú. Kí ojú ẹ̀ tó lè là, Jésù sọ fún un pé ó gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ti ń ṣenúnibíni sí tẹ́lẹ̀. Ó gbà kí Ananáyà, ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ran òun lọ́wọ́, ojú ẹ̀ sì là. (Ìṣe 9:3-9, 17, 18) Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni, àwọn èèyàn sì mọ̀ ọ́n dáadáa. Síbẹ̀, kò jẹ́ gbàgbé ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ ọ nígbà tó ń lọ sí Damásíkù. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ́ mú kó jẹ́ káwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ran òun lọ́wọ́. Ó gbà pé “orísun ìtùnú” ni wọ́n jẹ́ fún òun.—Kól. 4:10, 11. w20.07 18-19 ¶16-17
Sunday, September 11
Baba yín ti fọwọ́ sí i láti fún yín ní Ìjọba náà.—Lúùkù 12:32.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni alágbára gbogbo, kò sì sóhun tí kò lè ṣe, síbẹ̀ ó fáwọn míì lágbára láti ṣe àwọn nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ó yan Jésù láti jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó sì tún fún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) èèyàn lágbára láti bá Jésù ṣàkóso. Jèhófà tún dá Jésù lẹ́kọ̀ọ́ láti di Ọba àti Àlùfáà Àgbà. (Héb. 5:8, 9) Bákan náà, ó dá àwọn tó máa bá Jésù jọba lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ kò gbéṣẹ́ fún wọn tán kó tún wá máa tojú bọ iṣẹ́ tó gbé fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fọkàn tán wọn pé ohun tí òun fẹ́ ni wọ́n á ṣe. (Ìfi. 5:10) Tí Jèhófà Baba wa ọ̀run tí kò nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni bá lè gbéṣẹ́ fún àwọn míì tó sì fọkàn tán wọn, mélòómélòó àwa èèyàn! Bí àpẹẹrẹ, ṣé olórí ìdílé ni ẹ́ àbí alàgbà ìjọ? Fara wé Jèhófà, máa gbéṣẹ́ fáwọn míì, má sì máa tojú bọ iṣẹ́ náà tàbí kó o máa ṣọ́ wọn lọ́wọ́ ṣọ́ wọn lẹ́sẹ̀. Tó o bá ń fara wé Jèhófà, iṣẹ́ náà á di ṣíṣe, wàá tipa bẹ́ẹ̀ dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ọkàn àwọn ẹni náà á sì balẹ̀ pé àwọn lè ṣe iṣẹ́ náà.—Àìsá. 41:10. w20.08 9 ¶5-6
Monday, September 12
Ọmọ èèyàn wá, kó lè wá ohun tó sọ nù, kó sì gbà á là.—Lúùkù 19:10.
Ọwọ́ wo ni Jèhófà fẹ́ ká fi mú àwọn àgùntàn òun tó ṣáko lọ? A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Jésù ṣe. Ó mọ̀ pé gbogbo àgùntàn Jèhófà ló ṣeyebíye lójú rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù” lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Mát. 15:24) Torí pé olùṣọ́ àgùntàn àtàtà ni Jésù, ó tún ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí èyíkéyìí lára àgùntàn Jèhófà má bàa sọ nù. (Jòh. 6:39) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn alàgbà ìjọ Éfésù níyànjú pé kí wọ́n fara wé ọwọ́ tí Jésù fi mú agbo, ó ní: “Ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ sọ pé: ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.’ ” (Ìṣe 20:17, 35) Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ńlá làwọn alàgbà ní bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe sọ. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Salvador láti orílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Tí n bá ronú lórí bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí àgùntàn rẹ̀ bá sọ nù àti bó ṣe máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó máa ń wu èmi náà láti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Mo mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí n ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sínú agbo.” w20.06 23 ¶15-16
Tuesday, September 13
Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.—Ìfi. 21:4.
Jèhófà máa mú sùúrù fún wa dìgbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí ká tó di pípé. Títí dìgbà yẹn, Jèhófà á máa gbójú fo àwọn àṣìṣe wa. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwa náà máa wo ibi táwọn míì dáa sí, ká sì máa mú sùúrù fún wọn. Inú Jésù àtàwọn áńgẹ́lì dùn nígbà tí Jèhófà dá ayé. Ẹ wá wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó nígbà tó bá di pé àwọn èèyàn pípé tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ nìkan ló wà láyé. Ẹ tún wo bí inú àwọn tó lọ jọba pẹ̀lú Jésù lọ́run ṣe máa dùn tó bí wọ́n ṣe ń rí i tí aráyé ń jàǹfààní látinú iṣẹ́ wọn. (Ìfi. 4:4, 9-11; 5:9, 10) Wo bó ṣe máa rí lára ẹ nígbà táwọn èèyàn bá ń yọ̀ dípò kí wọ́n máa sunkún, tí àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú sì ti pòórá títí láé. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, pinnu pé wàá máa fìfẹ́ hàn, wàá máa fọgbọ́n hùwà, wàá sì máa mú sùúrù fáwọn míì bíi ti Jèhófà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀ láìka ìṣòro èyíkéyìí tó ò ń kojú sí. (Jém. 1:2-4) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ṣèlérí pé “àjíǹde . . . yóò wà”!—Ìṣe 24:15. w20.08 19 ¶18-19
Wednesday, September 14
A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.—Mát. 24:14.
Ẹ̀bùn iyebíye ni Bíbélì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìfẹ́ tí Baba wa ọ̀run ní sí àwa ọmọ rẹ̀ ló mú kó mí sí àwọn èèyàn láti kọ ọ́. Jèhófà ń lo Bíbélì láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù tá a máa ń béèrè. Lára wọn ni: Ibo gan-an la ti wá? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé? Kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwa ọmọ rẹ̀ mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, torí náà ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló ti ń mú kí àwọn èèyàn túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè. Lónìí, odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ ti wà ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) lọ. Òun ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ, tí wọ́n sì pín kiri jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé. A lè fi hàn pé a mọyì Bíbélì tá a bá ń kà á lójoojúmọ́, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ohun tá a kọ́ sílò. Bákan náà, a lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa yìí tá a bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo èèyàn.—Sm. 1:1-3; Mát. 28:19, 20. w20.05 24-25 ¶15-16
Thursday, September 15
Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti di ohun tó ń fa èébú àti yẹ̀yẹ́ . . . láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.—Jer. 20:8.
Àwọn èèyàn tí Jèhófà rán wòlíì Jeremáyà sí kò tẹ́tí sí i rárá àti rárá. Ìgbà kan wà tó rẹ̀wẹ̀sì tó sì ronú pé òun ò ní sọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́. Àmọ́, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé “ọ̀rọ̀ Jèhófà” dà bí iná tó ń jó nínú Jeremáyà, kò sì lè pa á mọ́ra! (Jer. 20:9) Bó ṣe máa rí lára tiwa náà nìyẹn tá a bá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà lọ́kàn wa. Èyí jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayọ̀ wa á máa pọ̀ sí i, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa á sì túbọ̀ méso jáde. (Jer. 15:16) Torí náà, ohun yòówù kó mú kó o rẹ̀wẹ̀sì, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Á jẹ́ kó o lè fara da àìpé àti kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ, á dúró tì ẹ́ tó o bá ń ṣàìsàn. Á jẹ́ kó o lè máa fi ojú tó tọ́ wo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run, á sì jẹ́ kó o láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, máa sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ fún Jèhófà Baba rẹ ọ̀run. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, wàá borí ìrẹ̀wẹ̀sì. w20.12 27 ¶20-21
Friday, September 16
Pàrọwà fún . . . àwọn àgbà obìnrin bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin bí ọmọ ìyá, pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.—1 Tím. 5:1, 2.
Ìpàdé nìkan làwọn arábìnrin kan ti máa ń láǹfààní láti wà pẹ̀lú àwọn ará. Torí náà, ó yẹ ká máa lo àǹfààní yẹn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì wọn àti pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà máa wáyè láti wà pẹ̀lú àwọn arábìnrin. (Lúùkù 10:38-42) A lè pè wọ́n pé ká jọ jẹun tàbí ká jọ ṣeré jáde. Nírú àwọn àsìkò yẹn, ká rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró là ń sọ. (Róòmù 1:11, 12) Ó ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà máa fara wé Jésù. Ó mọ̀ pé kò rọrùn fáwọn kan láti wà láìṣègbéyàwó, síbẹ̀ ó jẹ́ kó ṣe kedere pé kò dìgbà téèyàn bá ṣègbéyàwó tàbí tó lọ́mọ kó tó lè ní ojúlówó ayọ̀. (Lúùkù 11:27, 28) Dípò bẹ́ẹ̀, téèyàn bá ń fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nìkan ló máa ní ojúlówó ayọ̀. (Mát. 19:12) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn alàgbà mú àwọn arábìnrin bí ọmọ ìyá tàbí bí ìyá wọn. Á dáa káwọn alàgbà máa wáyè bá àwọn arábìnrin sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé. w20.09 21-22 ¶7-9
Saturday, September 17
Àgbẹ̀ máa ń dúró kí ilẹ̀ mú èso tó ṣeyebíye jáde . . . Kí ẹ̀yin náà ní sùúrù.—Jém. 5:7, 8.
Ẹ̀yìn òjò àkọ́rọ̀ ni àgbẹ̀ kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì máa ń gbin irúgbìn, ó sì máa ń kórè lẹ́yìn òjò àrọ̀kẹ́yìn. (Máàkù 4:28) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa mú sùúrù bíi ti àwọn àgbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Àwa èèyàn aláìpé máa ń fẹ́ kí iṣẹ́ wa tètè sèso. Síbẹ̀, tá a bá jẹ́ àgbẹ̀, tá a sì fẹ́ kí irúgbìn wa sèso, a gbọ́dọ̀ tulẹ̀, ká gbin irúgbìn, ká máa ro ó, ká sì máa bomi rin ín. Bí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí náà nìyẹn. Ó máa ń gba àkókò ká tó lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ láti fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu kúrò lọ́kàn wọn, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn. Tá a bá ń mú sùúrù, a ò ní rẹ̀wẹ̀sì táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ tẹ́tí sí wa. Kódà táwọn èèyàn bá tẹ́tí sí wa, a ṣì nílò sùúrù torí pé a ò lè fipá mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti tẹ̀ síwájú. Ó ṣe tán, ìgbà kan wà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà ò tètè lóye ohun tó kọ́ wọn. (Jòh. 14:9) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé tá a bá tiẹ̀ gbìn tá a sì bomi rin, Jèhófà nìkan ló lè mú kó dàgbà.—1 Kọ́r. 3:6. w20.09 11 ¶10-11
Sunday, September 18
Màá fi gbogbo ọkàn mi yin Jèhófà nínú àwùjọ àwọn adúróṣinṣin àti nínú ìjọ.—Sm. 111:1.
Gbogbo wa la fẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé ká gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa wá sípàdé. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó tètè bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ló máa ń tẹ̀ síwájú jù. Àwọn akéde kan máa ń sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn pé ìdajì nǹkan tó yẹ kí wọ́n mọ̀ ni wọ́n máa kọ́ tí wọn ò bá wá sípàdé torí pé ìpàdé ni wọ́n á ti kọ́ èyí tó kù. Ka Hébérù 10:24, 25 fún un, kó o sì jẹ́ kó mọ àǹfààní tó máa rí tó bá ń wá sípàdé. Sọ ohun tó o gbádùn nípàdé fún un, kó o sì jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ pé lóòótọ́ lo gbádùn ẹ̀. Ìyẹn máa jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé dípò kó o kàn máa sọ fún un pé kó wá. Ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa rí tó sì máa kọ́ nípàdé àkọ́kọ́ tó wá máa yàtọ̀ pátápátá sóhun tó rí nínú àwọn ilé ìjọsìn míì tó ti lọ. (1 Kọ́r. 14:24, 25) Yàtọ̀ síyẹn, ó máa rí àwọn míì tó lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn tí wọ́n á sì ràn án lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú kó lè ṣèrìbọmi. w20.10 10-11 ¶14-15
Monday, September 19
Olùkọ́ wo ló dà bí [Ọlọ́run]?—Jóòbù 36:22.
Ẹ̀mí Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi ohun tó ò ń kà àtohun tó ò ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Máa gbàdúrà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀ kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” (Sm. 86:11) Torí náà, máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe torí kó o lè ní ìmọ̀ nìkan lo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó o fẹ́ ni pé kí òtítọ́ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, kó o sì máa fi í sílò láyé rẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kó o tún máa fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin níṣìírí. (Héb. 10:24, 25) Kí nìdí? Ìdí ni pé ọmọ ìyá ni gbogbo wa nínú ìdílé Jèhófà. Bákan náà, máa gbàdúrà pé kí ẹ̀mí mímọ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa dáhùn látọkàn wá nípàdé kó o sì máa ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún ẹ dáadáa. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, o sì nífẹ̀ẹ́ àwọn “àgùntàn” wọn. (Jòh. 21:15-17) Torí náà, máa tẹ́tí sí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá, kó o sì máa jẹ onírúurú oúnjẹ tẹ̀mí tó ń pèsè. w20.10 24-25 ¶15-17
Tuesday, September 20
Gbogbo wọn fi í sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ.—Máàkù 14:50.
Kí ni Jésù ṣe fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lásìkò tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì? Kété lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ fún àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi [pé mo ti jíǹde].” (Mát. 28:10a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì náà fi Jésù sílẹ̀, Jésù ò pa wọ́n tì. Kódà, ó pè wọ́n ní “awọn arákùnrin mi.” Bíi ti Jèhófà, aláàánú ni Jésù, ó sì máa ń dárí jini. (2 Ọba 13:23) Bíi ti Jésù, ọ̀rọ̀ àwon tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ máa ń jẹ wá lọ́kàn. Ó ṣe tán, arákùnrin àti arábìnrin wa ni wọ́n, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. A ṣì ń rántí iṣẹ́ takuntakun táwọn ará wa ọ̀wọ́n yìí ti ṣe sẹ́yìn fún Jèhófà. Kódà, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn kan fi ṣe bẹ́ẹ̀. (Héb. 6:10) Àárò wọn ń sọ wá gan-an! (Lúùkù 15:4-7) Gba àwọn tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ níyànjú pé kí wọ́n máa wá sípàdé. Tí wọ́n bá sì wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀. w20.11 6 ¶14-17
Wednesday, September 21
Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.—1 Kọ́r. 4:6.
Jémíìsì àti Jòhánù pẹ̀lú ìyá wọn sọ pé kí Jésù ṣe ohun tó ju agbára ẹ̀ lọ. Jésù ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Bàbá òun nìkan ló lè pinnu ẹni tó máa jókòó sápá ọ̀tún tàbí apá òsì òun nínú Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 20:20-23) Ó hàn pé Jésù mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, kò sì kọjá àyè ẹ̀. Kò ṣe kọjá ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. (Jòh. 12:49) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? A lè fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa bíi ti Jésù tá a bá ń fi ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sọ́kàn. Torí náà, táwọn èèyàn bá ní ká fún àwọn ní ìmọ̀ràn, kò yẹ kó jẹ́ pé ohun tó kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn tàbí èrò tiwa la máa sọ fún wọn. Dípò bẹ́ẹ̀, ìlànà Bíbélì tàbí àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run ló yẹ ká ní kí wọ́n tẹ̀ lé. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa àti pé “àwọn àṣẹ òdodo” Jèhófà ló dáa jù.—Ìfi. 15:3, 4. w20.08 11-12 ¶14-15
Thursday, September 22
Má ṣe òdodo àṣelékè, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe gbọ́n ní àgbọ́njù. Àbí o fẹ́ pa ara rẹ ni?—Oníw. 7:16.
Tó bá pọn dandan pé kó o fún ọ̀rẹ́ ẹ kan nímọ̀ràn, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Kó o tó lọ bá a, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mi ò máa ṣe “òdodo àṣelékè”?’ Ìlànà ara ẹ̀ lẹni tó jẹ́ olódodo àṣelékè fi máa ń dá àwọn míì lẹ́jọ́ dípò ìlànà Jèhófà, kì í sì í lójú àánú. Lẹ́yìn tó o bá ti da ọ̀rọ̀ náà rò, tó o sì rí i pé ó pọn dandan pé kó o bá ọ̀rẹ́ ẹ sọ̀rọ̀, jẹ́ kó mọ ohun tó o kíyè sí ní pàtó, bi í láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, kó sì rí ibi tóun ti ṣàṣìṣe. Rí i dájú pé orí Ìwé Mímọ́ lo gbé ìmọ̀ràn rẹ kà, má sì gbàgbé pé Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ máa jíhìn fún, kì í ṣe ìwọ. (Róòmù 14:10) Yàtọ̀ síyẹn, jẹ́ kí ọgbọ́n Ọlọ́run darí ẹ nígbà tó o bá ń gbani nímọ̀ràn, kó o sì máa fàánú hàn bíi ti Jésù. (Òwe 3:5; Mát. 12:20) Kí nìdí? Ìdí ni pé ọwọ́ tá a bá fi mú àwọn èèyàn ni Jèhófà náà máa fi mú wa.—Jém. 2:13. w20.11 21 ¶13
Friday, September 23
Ẹ yéé fi ìrísí òde ṣe ìdájọ́, àmọ́ ẹ máa dá ẹjọ́ òdodo.—Jòh. 7:24.
Ṣé inú ẹ máa dùn táwọn èèyàn bá dá ẹ lẹ́jọ́ torí àwọ̀ ẹ, bí ojú ẹ ṣe rí tàbí torí pé o sanra tàbí o pẹ́lẹ́ńgẹ́? Ó dájú pé inú ẹ ò ní dùn. A mà dúpẹ́ o pé kì í ṣe ohun tó hàn sójú táyé ni Jèhófà fi ń dá wa lẹ́jọ́! Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Sámúẹ́lì rí àwọn ọmọ Jésè, kì í ṣe ohun tí Jèhófà rí ló rí. Jèhófà ti sọ fún Sámúẹ́lì pé ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Jésè ló máa di ọba Ísírẹ́lì. Àmọ́ èwo ló máa jẹ́ nínú wọn? Nígbà tí Sámúẹ́lì rí àkọ́bí Jésè tó ń jẹ́ Élíábù, ó sọ pé “ó dájú pé ẹni àmì òróró Jèhófà ló dúró yìí.” Élíábù sì dà bí ọba lóòótọ́. “Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Má wo ìrísí rẹ̀ àti bí ó ṣe ga tó, torí pé mo ti kọ̀ ọ́.’ ” Kí lèyí kọ́ wa? Jèhófà fi kún un pé: “Ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.” (1 Sám. 16:1, 6, 7) Ó yẹ káwa náà máa fara wé Jèhófà nínú bá a ṣe ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lò. w20.04 14 ¶1; 15 ¶3
Saturday, September 24
Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè.—Jòh. 4:35.
Ìgbà kan wà tí Jésù rìnrìn àjò gba inú oko tí wọ́n gbin ọkà bálì sí. (Jòh. 4:3-6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ oko ọkà bálì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń hù, tó sì máa tó oṣù mẹ́rin kí wọ́n tó lè kórè rẹ̀. Jésù wá sọ ohun kan tó ṣàjèjì sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè.” (Jòh. 4:35, 36) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí a ṣe máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ni Jésù ń sọ. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ará Samáríà, Jésù wàásù fún obìnrin ará Samáríà kan. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé obìnrin yẹn fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jésù, ó sì mọyì rẹ̀! Kódà, Jésù ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa pápá tó ‘funfun, tó sì ti tó kórè’ lọ́wọ́ nígbà táwọn tó gbọ́ nípa rẹ̀ lẹ́nu obìnrin yẹn ti ń bọ̀ lọ́dọ̀ ẹ̀. (Jòh. 4:9, 39-42) Nígbà tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó ní: “Bó ṣe wu àwọn èèyàn náà láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù . . . fi hàn pé wọ́n ṣe tán láti di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bíi ti ọkà tó ti tó kórè.” w20.04 8 ¶1-2
Sunday, September 25
Ẹ jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.—Héb. 10:24.
Àwọn ìpàdé wa máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọ bá a ṣe lè wàásù, ká sì kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń kọ́ wa bá a ṣe lè lo àwọn ohun tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́nà tó gbéṣẹ́. Torí náà, máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa. Tó o bá wà nípàdé, máa fetí sílẹ̀, kó o sì rí i pé ò ń fi ohun tó o kọ́ sílò. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, wàá di “ọmọ ogun rere fún Kristi Jésù.” (2 Tím. 2:3) Jèhófà ń lo ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì láti dáàbò bò wá. Ṣé ẹ rántí ohun tí áńgẹ́lì kan ṣoṣo gbé ṣe? (Àìsá. 37:36) Ẹ wá ronú ohun tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì máa gbé ṣe. Kò sí èèyàn náà tàbí ẹ̀mí èṣù tó lè dúró níwájú àwọn ọmọ ogun Jèhófà. Ẹ rántí ohun tí wọ́n máa ń sọ pé ẹni tó bá ti ní Olúwa, ohun gbogbo ló ní. Torí náà, tá a bá ní Jèhófà, kò sí ọ̀tá náà tó lè dojú kọ wá bó ti wù kí wọ́n pọ̀ tó. (Oníd. 6:16) Fi àwọn kókó yìí sọ́kàn tí ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, ọmọ ilé ìwé ẹ tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá ń ta kò ẹ́. Máa rántí pé Jèhófà àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ wà lẹ́yìn ẹ, wọn ò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ torí pé ìfẹ́ Jèhófà lò ń ṣe. w21.03 29 ¶13-14
Monday, September 26
Tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde, “ẹ jẹ́ ká máa jẹ, ká sì máa mu, torí ọ̀la la máa kú.”—1 Kọ́r. 15:32.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò tí kò tọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní bó ṣe wà nínú Àìsáyà 22:13 ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí. Dípò káwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ Ọlọ́run, bí wọ́n á ṣe jayé orí wọn ló gbà wọ́n lọ́kàn. Ká kúkú sọ pé, ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ń sọ ni pé “màá jayé òní, mi ò mọ ẹ̀yìn ọ̀la,” irú èrò tó sì wọ́pọ̀ lóde òní nìyẹn. Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde, àwọn kan wà tá ò gbọ́dọ̀ bá kẹ́gbẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn tí kò gbà gbọ́ pé àwọn òkú máa jíǹde. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ náà ni pé kò sí àǹfààní kankan tá a máa rí tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ò mọ̀ ju bí wọ́n ṣe máa jayé orí wọn lọ. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lè mú kí Kristẹni kan ní èrò tí kò tọ́, wọ́n sì lè ba ìwà rere ẹ̀ jẹ́. Kódà, wọ́n lè mú kí Kristẹni náà máa ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí orí yín pé lọ́nà òdodo, ẹ má sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà.”—1 Kọ́r. 15:33, 34. w20.12 9 ¶3, 5-6
Tuesday, September 27
Orí gbogbo ọkùnrin ni Kristi; bákan náà, orí obìnrin ni ọkùnrin; bákan náà, orí Kristi ni Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 11:3.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ṣètò ìdílé rẹ̀ lọ́run àti láyé. Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, òun ló ní gbogbo àṣẹ láyé àti lọ́run. Jèhófà wá ṣètò ipò orí, ó sì fún àwọn kan ní àṣẹ, àmọ́ àwọn tó fún láṣẹ yìí máa jíhìn fún un. (Róòmù 14:10; Éfé. 3:14, 15) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fún Jésù ní àṣẹ lórí ìjọ, àmọ́ Jésù máa jíhìn fún Jèhófà nípa ọwọ́ tó fi mú wa. (1 Kọ́r. 15:27) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún fún ọkọ ní àṣẹ lórí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀. Àmọ́, báwo ló ṣe lè lo ipò orí ẹ̀ lọ́nà tó dáa? Ó gbọ́dọ̀ lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ kó mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣètò pé kóun jẹ́ olórí ìdílé àti ní pàtàkì bóun ṣe lè fara wé Jèhófà àti Jésù. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ti fún àwọn olórí ìdílé ní àṣẹ nínú ìdílé wọn, ó sì fẹ́ kí wọ́n lò ó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—Lúùkù 12:48b. w21.02 2 ¶1-3
Wednesday, September 28
Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.—Àìsá. 48:17.
Ó tún yẹ ká fara wé Jèhófà tó máa ń yàn láti gbàgbé àwọn nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, agbára ìrántí Jèhófà ò láàlà, síbẹ̀ tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà, Jèhófà máa dárí jì í, á sì gbàgbé àṣìṣe tẹ́ni náà ṣe. (Sm. 25:7; 130:3, 4) Ohun kan náà ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe, ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, kódà bí ohun tí wọ́n ṣe bá tiẹ̀ dùn wá. (Mát. 6:14; Lúùkù 17:3, 4) A lè fi hàn pé a mọyì ọpọlọ tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá fún wa tá a bá ń lò ó láti bọlá fún un. Àwọn kan ò mọyì ẹ̀bùn yìí torí pé àǹfààní ara wọn nìkan ni wọ́n ń lò ó fún, wọ́n máa ń ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ láìfi ìlànà Ọlọ́run pè. Àmọ́, ṣó tiẹ̀ yẹ kí Jèhófà fún wa ní ìlànà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó bọ́gbọ́n mu torí pé òun ló dá wa, ìlànà rẹ̀ ló sì bọ́gbọ́n mu jù lọ. (Róòmù 12:1, 2) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀. (Àìsá. 48:18) Àá mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká fayé wa ṣe, ìyẹn ni pé ká máa bọlá fún Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa, ká sì máa múnú ẹ̀ dùn.—Òwe 27:11. w20.05 23-24 ¶13-14
Thursday, September 29
Ẹ ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín.—Róòmù 12:10.
Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin túbọ̀ jinlẹ̀ lónìí? Tá a bá sapá láti túbọ̀ mọ àwọn ará wa, àá túbọ̀ lóye wọn, ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn. A lè di ọ̀rẹ́ wọn yálà wọ́n kéré sí wa tàbí wọ́n dàgbà jù wá lọ tàbí pé àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa. Ẹ rántí pé nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ, síbẹ̀ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wọ́n. Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ yín tó kéré sí ẹ lọ́jọ́ orí tàbí tó dàgbà jù ẹ́ lọ tó o lè mú lọ́rẹ̀ẹ́? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń fi hàn pé o “nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará.” (1 Pét. 2:17) Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, ó ṣe kedere pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ló yẹ ká ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí. Àmọ́, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo wọn la lè mú lọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́? Rárá, ìyẹn lè má ṣeé ṣe. Kò sóhun tó burú tá a bá sún mọ́ àwọn kan ju àwọn míì lọ torí ohun tá a jọ nífẹ̀ẹ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù pe gbogbo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní “ọ̀rẹ́” rẹ̀, àmọ́ ó sún mọ́ Jòhánù ju àwọn yòókù lọ. (Jòh. 13:23; 15:15; 20:2) Àmọ́ o, Jésù ò ka Jòhánù sí pàtàkì ju àwọn yòókù lọ.—Máàkù 10:35-40. w21.01 23 ¶12-13
Friday, September 30
Ó jọ pé ẹ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run ju bí àwọn yòókù ṣe bẹ̀rù wọn lọ.—Ìṣe 17:22.
Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe wàásù fáwọn Kèfèrí tó wà ní Áténì yàtọ̀ sí bó ṣe wàásù fáwọn Júù tó wà nínú sínágọ́gù. Ó fara balẹ̀ kíyè sí àyíká rẹ̀ àtàwọn àṣà tó wà nínú ẹ̀sìn àwọn èèyàn náà. (Ìṣe 17:23) Lẹ́yìn náà, ó wá ibi tọ́rọ̀ rẹ̀ àti tiwọn ti jọra. Torí náà Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá àwọn ará Áténì mu. Ó sọ fún wọn pé ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run Àìmọ̀” tí wọ́n fẹ́ jọ́sìn ni ohun tóun ń bá wọn sọ ti wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kèfèrí yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ lóye Ìwé Mímọ́, Pọ́ọ̀lù ò ronú pé wọn ò lè di Kristẹni láéláé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wò wọ́n bí ọkà tó ti tó kórè, ìyẹn sì mú kó yí bó ṣe wàásù fún wọn pa dà. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, máa kíyè sí àyíká ẹ. Kíyè sí àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o mọ ohun táwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín gbà gbọ́. Àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ wo ni wọ́n fi sára ilé tàbí ohun ìrìnnà wọn? Ṣé orúkọ ẹni náà, aṣọ tó wọ̀, bó ṣe múra tàbí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi irú ẹ̀sìn tó ń ṣe hàn? w20.04 9-10 ¶7-8