PA DÀ LỌ
Ẹ̀KỌ́ 8
Máa Ní Sùúrù
Ìlànà: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù.”—1 Kọ́r. 13:4.
Ohun Tí Jésù Ṣe
1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Jòhánù 7:3-5 àti 1 Kọ́ríńtì 15:3, 4, 7. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ṣe kọ́kọ́ rí lára àwọn arákùnrin ẹ̀?
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ò jẹ́ kó sú òun láti máa ran Jémíìsì àbúrò ẹ̀ lọ́wọ́?
Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
2. Ó yẹ ká máa ní sùúrù bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn, torí pé àwọn kan lè má tètè fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ wọn.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
3. Máa lo oríṣiríṣi ọ̀nà. Tẹ́nì kan ò bá tètè gbà pé kó o máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má ṣe fipá mú un. Láwọn ìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, o lè lo fídíò àtàwọn àpilẹ̀kọ kan láti jẹ́ kó mọ bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn àǹfààní tó máa rí.
4. Má fẹnì kan wé ẹlòmíì. Máa fi sọ́kàn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Tó bá dà bíi pé ẹnì kan nínú ìdílé ẹ tàbí ẹnì kan tó o wàásù fún ò fẹ́ kó o máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí tí kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, ńṣe ni kó o ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó fà á. Ṣé ohun kan wà tí wọ́n máa ń ṣe nínú ẹ̀sìn ẹ̀ tó fẹ́ràn gan-an? Ṣé àwọn ẹbí ẹ̀ tàbí àwọn ará àdúgbò ẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ ọn? Tó o bá ní sùúrù, ẹni náà lè wá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tó o sọ fún un, kó sì wá rí i pé òun máa jàǹfààní tóun bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
5. Máa gbàdúrà. Bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kọ́rọ̀ náà sú ẹ, kó sì fún ẹ lọ́gbọ́n tí wàá fi mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Tẹ́nì kan ò bá ṣe ohun tó fi hàn pé òun fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó o mọ ìgbà tí kò yẹ kó o lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ mọ́.—1 Kọ́r. 9:26.