August
Thursday, August 1
Wọ́n sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀ torí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà àti àwọn tó ń ṣe àṣàrò lórí orúkọ rẹ̀.—Mál. 3:16.
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi ń fetí sí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lórí orúkọ rẹ̀, tó sì wá ń kọ orúkọ wọn sínú “ìwé ìrántí” rẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Ohun tó wu Jèhófà ni pé káwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gbádùn ayé wọn títí láé nínú ayé tuntun. Àwọn ọ̀rọ̀ tá a bá ń sọ ló máa fi hàn bóyá Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. (Jém. 1:26) Àwọn kan tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń fìbínú sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ gúnni lára, wọ́n sì máa ń fọ́nnu. (2 Tím. 3:1-5) A ò ní fẹ́ fìwà jọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kó máa wù wá láti máa sọ ohun tó máa múnú Jèhófà dùn. Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó tuni lára nípàdé àti lóde ẹ̀rí àmọ́ tá a wá ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sáwọn tó wà nínú ìdílé wa?—1 Pét. 3:7. w22.04 5 ¶4-5
Friday, August 2
Wọ́n máa kórìíra aṣẹ́wó náà, wọ́n máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò, wọ́n máa jẹ ẹran ara rẹ̀, wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá.—Ìfi. 17:16.
Ọlọ́run ti fi sí ọkàn ìwo mẹ́wàá àti ẹranko náà láti pa Bábílónì Ńlá run. Jèhófà máa mú kí àwọn orílẹ̀-èdè lo ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, ìyẹn Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé láti pa gbogbo ẹ̀sìn èké ayé run pátápátá. (Ìfi. 18:21-24) Kí ló yẹ ká ṣe? “Ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run” ló yẹ ká máa ṣe. (Jém. 1:27) A ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀kọ́ èké láyè, a ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí àwọn àjọ̀dún tó wá látinú ìbọ̀rìṣà. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí gbogbo ìwà ìbàjẹ́ tó kúnnú ayé lónìí tàbí àwọn iṣẹ́ òkùnkùn tí Bábílónì Ńlá ń ṣe. Nǹkan míì tá a máa ṣe ni pé ká máa pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n “jáde kúrò nínú [Bábílónì Ńlá],” kí wọ́n má bàa gbà nínú ẹ̀bi rẹ̀ níwájú Ọlọ́run.—Ìfi. 18:4. w22.05 11 ¶17-18
Saturday, August 3
Màá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.—Àìsá. 63:7.
Ẹ̀yin òbí, ẹ máa lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan dáadáa tó ti ṣe. (Diu. 6:6, 7) Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé ọkọ ẹ tàbí aya ẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ò sì lè kọ́ àwọn ọmọ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ déédéé nílé. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Christine sọ pé: “Àkókò tí mo lè fi bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀ Bíbélì ò tó nǹkan rárá, torí náà gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ ni mo máa ń lò.” Bákan náà, máa sọ nǹkan tó dáa nípa Jèhófà àtàwọn ará. Má sọ̀rọ̀ àwọn alàgbà láìdáa. Ohun tó o bá sọ nípa àwọn alàgbà ló máa pinnu bóyá àwọn ọmọ ẹ á lọ bá wọn nígbà ìṣòro àbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ilé yín. Máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ọkọ ẹ àtàwọn ọmọ ẹ mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Má sọ̀rọ̀ ọkọ ẹ láìdáa, máa bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí á jẹ́ kó rọrùn fáwọn ọmọ ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.—Jém. 3:18. w22.04 18 ¶10-11
Sunday, August 4
Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ.—Ìfi. 3:1.
Ohun tí Jésù sọ fún ìjọ tó wà ní Éfésù fi hàn pé àwọn tó wà nínú ìjọ náà ní ìfaradà, wọ́n sì ń sin Jèhófà nìṣó bí wọ́n tiẹ̀ ń dojú kọ onírúurú ìṣòro. Síbẹ̀, wọ́n ti fi ìfẹ́ tí wọ́n ní níbẹ̀rẹ̀ sílẹ̀. Ó yẹ kí wọ́n mú kí iná ìfẹ́ wọn pa dà máa jó, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lónìí, ìfaradà nìkan ò tó, ó yẹ ká mọ ìdí tá a fi ń fara da ohun kan. Kì í ṣe ohun tá à ń ṣe nìkan ni Ọlọ́run ń wò, ó tún ń wo ìdí tá a fi ń ṣe é. Ìdí tá a fi ń jọ́sìn ẹ̀ ló ṣe pàtàkì lójú ẹ̀ torí ó fẹ́ ká máa jọ́sìn òun tọkàntọkàn, ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ òun. (Òwe 16:2; Máàkù 12:29, 30) A gbọ́dọ̀ máa kíyè sára. Ìṣòro ọ̀tọ̀ làwọn ará tó wà ní ìjọ Sádísì ní. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ ìsìn wọn tẹ́lẹ̀, ní báyìí wọ́n ti ń dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe fún Ọlọ́run. Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n “jí.” (Ìfi. 3:1-3) Ó dájú pé Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ wa.—Héb. 6:10. w22.05 3 ¶6-7
Monday, August 5
Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.—Òwe 14:23.
Sólómọ́nì sọ pé téèyàn bá ń gbádùn iṣẹ́ tó ń ṣe, “ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníw. 5:18, 19) Sólómọ́nì mọ̀ pé bó ṣe rí nìyẹn torí pé òṣìṣẹ́ kára lòun náà. Ó kọ́ ọ̀pọ̀ ilé, ó gbin àwọn ọgbà àjàrà, ó sì ṣe àwọn ọgbà ọ̀gbìn àtàwọn adágún omi. Yàtọ̀ síyẹn, ó kọ́ àwọn ìlú. (1 Ọba 9:19; Oníw. 2:4-6) Ó dájú pé iṣẹ́ àṣekára ló ṣe, àmọ́ iṣẹ́ yẹn fún un láyọ̀. Síbẹ̀, Sólómọ́nì mọ̀ pé àwọn iṣẹ́ yẹn nìkan ò lè fún òun láyọ̀. Torí náà, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó bójú tó iṣẹ́ tẹ́ńpìlì ológo kan tí wọ́n kọ́ fún ìjọsìn Jèhófà, ọdún méje gbáko ni wọ́n sì fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà! (1 Ọba 6:38; 9:1) Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ fún ìjọsìn Ọlọ́run àti iṣẹ́ tara ẹ̀, ó rí i pé iṣẹ́ Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì ju gbogbo iṣẹ́ yòókù lọ. Ó sọ pé: “Òpin ọ̀rọ̀ náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—Oníw. 12:13. w22.05 22 ¶8
Tuesday, August 6
Ọlọ́run . . . tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.—Éfé. 4:32.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló wà nínú Bíbélì tí Jèhófà dárí jì fàlàlà. Ta lẹni tó wá sí ẹ lọ́kàn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Ọba Mánásè. Èèyàn burúkú ni Ọba Mánásè, ó sì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì sí Jèhófà. Ó jọ́sìn òrìṣà, ó sì ní kí àwọn èèyàn ẹ̀ náà máa bọ̀rìṣà. Ó pa àwọn ọmọ ẹ̀, ó sì fi wọ́n rúbọ sí àwọn ọlọ́run èké. Kódà, ó kọjá àyè ẹ̀ débi pé ó gbé àwọn òrìṣà wá sínú tẹ́ńpìlì mímọ́ Jèhófà. Bíbélì sọ nípa Mánásè pé: “Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.” (2 Kíró. 33:2-7) Ṣùgbọ́n nígbà tí Mánásè ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà dárí jì í. (2 Kíró. 33:12, 13) Ẹlòmíì tó ṣeé ṣe kó wá sí ẹ lọ́kàn ni Ọba Dáfídì. Ó dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lójú Jèhófà, lára wọn ni àgbèrè àti ìpànìyàn. Àmọ́ nígbà tí Dáfídì gbà pé òun ṣàṣìṣe, tó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà dárí ji òun náà. (2 Sám. 12:9, 10, 13, 14) Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé ó máa ń wu Jèhófà láti dárí jì wá fàlàlà. w22.06 3 ¶7
Wednesday, August 7
Ẹ ní sùúrù; ẹ mọ́kàn le.—Jém. 5:8.
A gbọ́dọ̀ sapá gan-an kí ìrètí tá a ní lè dá wa lójú. Torí náà, ó lè máa ṣe wá bíi pé àkókò tí Jèhófà sọ pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ ti ń pẹ́ jù. Àmọ́ torí pé Jèhófà ti wà tipẹ́, kò sì lè kú láéláé, nǹkan tó dà bíi pé ó ń pẹ́ lójú wa ò pẹ́ rárá lójú tiẹ̀. (2 Pét. 3:8, 9) Gbogbo nǹkan tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe ló máa ṣe, àmọ́ ó lè má jẹ́ lásìkò tá a retí pé ó máa ṣe é. Torí náà, kí ló máa jẹ́ kí ìrètí tá a ní dá wa lójú bá a ṣe ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ? (Jém. 5:7) Dúró sọ́dọ̀ Jèhófà torí òun ló máa jẹ́ ká rí ohun tá à ń retí gbà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ká tó lè nírètí, a gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà wà àti pé “òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.” (Héb. 11:1, 6) Tó bá dá wa lójú hán-ún hán-ún pé Jèhófà wà, ọkàn wa á túbọ̀ balẹ̀ pé ó máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Tá a bá fẹ́ jẹ́ kí ìrètí tá a ní dá wa lójú, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì máa ka Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí Jèhófà, a ṣì lè jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀. A lè bá a sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà, ó sì dá wa lójú pé ó máa gbọ́ wa.—Jer. 29:11, 12. w22.10 26-27 ¶11-13
Thursday, August 8
Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sì ń fi ọjọ́ tí wọ́n bí i gégùn-ún.—Jóòbù 3:1.
Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ná. Jóòbù jókòó sínú eérú, ara sì ń ro ó gan-an. (Jóòbù 2:8) Àwọn tó pe ara wọn ní ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń sọ fún un ṣáá pé èèyàn burúkú ni àti pé kò ṣe ohun tó dáa rí. Àwọn ìṣòro tó dé bá Jóòbù ò rọrùn fún un rárá, ṣe ló dà bíi pé wọ́n di ẹrù tó wúwo kan lé e lórí, ikú àwọn ọmọ ẹ̀ náà sì ń kó ìdààmú tó lé kenkà bá a. Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, Jóòbù ò sọ nǹkan kan. (Jóòbù 2:13) Táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù bá rò pé bó ṣe dákẹ́ yẹn, ó ti gba ohun táwọn sọ, ó sì ti kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá ẹ̀, irọ́ ni wọ́n pa. Nígbà tó dójú ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Jóòbù gbójú sókè wo àwọn tó pe ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́ ẹ̀ nígbà tó sọ fún wọn pé: “Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!” (Jóòbù 27:5) Kí ló mú kí Jóòbù ṣọkàn akin, kó má sì bẹ̀rù láìka gbogbo ìṣòro yìí sí? Nígbà tọ́rọ̀ náà tojú sú u, kò ronú pé Ọlọ́run ò ní ran òun lọ́wọ́. Ó gbà pé tóun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí òun dìde.—Jóòbù 14:13-15. w22.06 22 ¶9
Friday, August 9
Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.”—Mát. 6:9, 10.
Ẹni tó ṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé ti fún wa láǹfààní kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó fún wa láǹfààní láti máa gbàdúrà sí òun. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó ná, kò sígbà tá ò lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀, kò sì sí èdè tá ò lè fi bá a sọ̀rọ̀. A lè gbàdúrà sí i tá a bá wà lórí bẹ́ẹ̀dì nílé ìwòsàn tàbí tá a bá wà lẹ́wọ̀n, ó sì dá wa lójú pé Bàbá wa ọ̀run máa gbọ́ wa. Torí náà, ọwọ́ pàtàkì ló yẹ ká fi mú àǹfààní ńlá yìí. Ọba Dáfídì mọyì àǹfààní tó ní láti gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ó sọ fún Jèhófà pé: “Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí tí a ṣètò sílẹ̀ níwájú rẹ.” (Sm. 141:1, 2) Nígbà ayé Dáfídì, wọ́n máa ń fara balẹ̀ ṣe tùràrí táwọn àlùfáà máa ń lò. (Ẹ́kís. 30:34, 35) Bí Dáfídì ṣe mẹ́nu ba tùràrí yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé bíi tàwọn tó ń fara balẹ̀ ṣe tùràrí, òun náà máa ń fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó fẹ́ sọ nígbà tó bá fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà. Ohun táwa náà sì fẹ́ ṣe nìyẹn torí a fẹ́ kí inú Jèhófà dùn sí àdúrà wa. w22.07 20 ¶1-2; 21 ¶4
Saturday, August 10
“Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san,” ni Jèhófà wí.—Róòmù 12:19.
Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gbẹ̀san. Jèhófà ò gbà wá láyè láti gbẹ̀san tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá. (Róòmù 12:20, 21) Torí pé aláìpé ni wá, kì í ṣe gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan la máa mọ̀, ìyẹn kì í sì í jẹ́ ká dájọ́ bó ṣe yẹ. (Héb. 4:13) Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lára wa máa ń jẹ́ ká ṣi ẹjọ́ dá. Jèhófà mí sí Jémíìsì láti sọ pé: “Ìbínú èèyàn kì í mú òdodo Ọlọ́run wá.” (Jém. 1:20) Torí náà, ó dájú pé ohun tó tọ́ ni Jèhófà máa ṣe, ó sì máa rí i pé òun dá ẹjọ́ náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Tá a bá ń dárí ji àwọn èèyàn, ìyẹn á fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ṣèdájọ́ òdodo. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, àmọ́ tá a fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́, ìyẹn á fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa mú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn tí ọ̀rọ̀ náà fà kúrò lọ́kàn wa. Nínú ayé tuntun, ọgbẹ́ ọkàn tí àìpé àwọn èèyàn ti fà “ò ní wá sí ìrántí, wọn ò sì ní wá sí ọkàn” wa mọ́ títí láé.—Àìsá. 65:17. w22.06 10-11 ¶11-12
Sunday, August 11
Gbogbo orílẹ̀-èdè máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.—Mát. 24:9.
Báwọn èèyàn ṣe kórìíra wa yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ Jésù ń ṣẹ, Jèhófà sì fọwọ́ sí ohun tá à ń ṣe. (Mát. 5:11, 12) Èṣù ló ń lo àwọn èèyàn láti máa ta kò wá. Àmọ́ Jésù lágbára ju Èṣù lọ! Bí Jésù ṣe ń tì wá lẹ́yìn ń jẹ́ ká lè máa wàásù fún àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ jẹ́ ká gbé ẹ̀rí kan yẹ̀ wò. Ìṣòro míì tá à ń dojú kọ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni bá a ṣe máa wàásù fáwọn èèyàn ní èdè wọn. Nínú ìfihàn tí àpọ́sítélì Jòhánù gbà látọ̀dọ̀ Jésù, ó jẹ́ ká mọ̀ pé lákòókò wa yìí, àwọn èèyàn máa gbọ́ ìwàásù ní èdè wọn. (Ìfi. 14:6, 7) Kí ló máa jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe? Èdè táwọn èèyàn gbọ́ la fi ń wàásù fún wọn, ìyẹn sì ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ láti máa gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Lónìí, kárí ayé làwọn èèyàn ti lè ka àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì tó wà lórí ìkànnì jw.org torí pé àwọn ìwé náà wà ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ! Ètò Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé ká túmọ̀ ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! sí èdè tó ju ọgọ́rùn-ún méje (700) lọ. Ìwé yìí la sì fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn! w22.07 9 ¶6-7
Monday, August 12
Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.—Òwe 11:14.
Àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe Jésù. Àpọ́sítélì Mátíù sọ pé: “Nígbà tó rí àwọn èrò, àánú wọn ṣe é, torí wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Àmọ́ báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára Jèhófà? Jésù sọ pé: “Kò wu Baba mi tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.” (Mát. 18:14) Ẹ ò rí i pé èyí fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jésù, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á máa lágbára sí i. Tó o bá ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣọ̀rẹ́, wàá mọ bó o ṣe lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, òtítọ́ á sì jinlẹ̀ nínú ìwọ náà. Máa kíyè sí ayọ̀ tí wọ́n ní. Wọn ò kábàámọ̀ ìpinnu tí wọ́n ṣe láti sin Jèhófà. O lè ní kí wọ́n sọ díẹ̀ fún ẹ lára ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. O lè lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ wọn tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.” w22.08 3 ¶6-7
Tuesday, August 13
Ojú Jèhófà wà lára àwọn olódodo.—1 Pét. 3:12.
Gbogbo wa pátápátá la máa dojú kọ àdánwò. Àmọ́ Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ nígbà ìṣòro. Bí bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ ṣe máa ń bójú tó o, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń bójú tó wa. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń wà pẹ̀lú wa, ó sì máa ń gbọ́ wa tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Àìsá. 43:2) Ó dájú pé kò sí ìṣòro tó lè dé bá wa tó máa jẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀ torí gbogbo nǹkan tó máa jẹ́ ká lè fara dà á ló ti pèsè fún wa. Ara àwọn nǹkan tó pèsè fún wa ni pé ó ní ká máa gbàdúrà sí òun, ó fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìwé, fídíò àtàwọn orin tó ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, ó sì tún fi àwọn ará jíǹkí wa kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. A mà dúpẹ́ o pé Bàbá wa ọ̀run ń bójú tó wa! “Ọkàn wa [sì] ń yọ̀ nínú rẹ̀.” (Sm. 33:21) A lè fi hàn pé a mọyì bí Jèhófà ṣe ń bójú tó wa tá a bá ń lo àwọn nǹkan tó pèsè fún wa. Ó tún yẹ ká ṣe ipa tiwa, ìyẹn ni pé ká má fi Jèhófà sílẹ̀. Lédè míì, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣègbọràn sí Jèhófà, tá a sì ń ṣe ohun tó fẹ́, ó dájú pé títí láé lá máa bójú tó wa! w22.08 13 ¶15-16
Wednesday, August 14
Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ.—Sm. 119:160.
Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni kì í fọkàn tán àwọn èèyàn. Ìdí sì ni pé wọn ò mọ ẹni tí wọ́n lè fọkàn tán. Kò dá wọn lójú pé àwọn olóṣèlú, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn oníṣòwò ń gba tiwọn rò. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í bọ̀wọ̀ fáwọn olórí ẹ̀sìn tó pe ara wọn ní Kristẹni. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé wọn ò fọkàn tán Bíbélì táwọn olórí ẹ̀sìn yẹn sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé. Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà pé òun ni “Ọlọ́run òtítọ́” àti pé ohun tó dáa jù ló fẹ́ fún wa. (Sm. 31:5; Àìsá. 48:17) A fọkàn tán ohun tá a kà nínú Bíbélì. A gbà pé òótọ́ lohun tí ọ̀mọ̀wé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Kò sí irọ́ kankan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbogbo nǹkan tó bá sì sọ ló máa ń ṣẹ. Àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń gba ohun tó sọ gbọ́ torí pé wọ́n fọkàn tán Ọlọ́run.” w23.01 2 ¶1-2
Thursday, August 15
Ẹ jẹ́ ká gba ti ara wa rò.—Héb. 10:24.
Tá a bá ń ṣe ohun tó mú kí ìgbàgbọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lágbára, à ń gbé wọn ró nìyẹn. Nígbà míì, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn ará wa kan ń ṣàìsàn tó le gan-an, àwọn míì sì ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè borí ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Àwọn míì sì ń dúró de ìgbà tí ayé burúkú yìí máa dópin. Àwọn nǹkan yìí ló ń dán ìgbàgbọ́ àwọn ará wa wò lónìí. Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà sì dojú kọ irú àwọn ìṣòro yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo Ìwé Mímọ́ láti fún ìgbàgbọ́ àwọn ará lókun. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni lè má mọ ohun tí wọ́n máa sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Kristẹni, tí wọ́n sì ń sọ pé ẹ̀sìn Júù dáa ju ẹ̀sìn Kristẹni lọ. Àmọ́ ó dájú pé lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni yẹn fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. (Héb. 1:5, 6; 2:2, 3; 9:24, 25) Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú lẹ́tà yẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa sọ fáwọn tó ń ta kò wọ́n. w22.08 23-24 ¶12-14
Friday, August 16
Ìbùkún ni fún ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Jer. 17:7.
Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí ò lè fọkàn tán ẹnikẹ́ni. Ìdí sì ni pé ohun táwọn oníṣòwò, àwọn olóṣèlú àtàwọn olórí ẹ̀sìn ń fojú wọn rí ò dáa. Kódà, àwọn èèyàn ò lè fọkàn tán ọ̀rẹ́ wọn, àwọn aládùúgbò wọn àtàwọn ará ilé wọn. Kò sì yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu torí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn á jẹ́ aláìṣòótọ́, abanijẹ́ àti ọ̀dàlẹ̀.’ Lédè míì, wọ́n á máa hùwà bíi Sátánì tó ń darí ayé yìí torí pé òun fúnra ẹ̀ ò ṣeé fọkàn tán. (2 Tím. 3:1-4; 2 Kọ́r. 4:4) Torí pé Kristẹni ni wá, a mọ̀ pé a lè fọkàn tán Jèhófà pátápátá. Ó dá wa lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì ní ‘pa àwa ọ̀rẹ́ ẹ̀ tì láé.’ (Sm. 9:10) A tún lè fọkàn tán Jésù Kristi torí pé ó kú nítorí wa. (1 Pét. 3:18) Àwọn nǹkan tó sì ti ṣẹlẹ̀ sí wa ti jẹ́ ká rí i pé Bíbélì máa ń tọ́ wa sọ́nà.—2 Tím. 3:16, 17. w22.09 2 ¶1-2
Saturday, August 17
Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà, tó ń rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀.—Sm. 128:1.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fún àwọn èèyàn láyọ̀ lónìí, àmọ́ ayọ̀ náà kì í tọ́jọ́. Ayọ̀ tòótọ́ máa ń wà pẹ́ títí ni. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nínú Ìwàásù orí Òkè, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.” (Mát. 5:3) Jésù mọ̀ pé ìdí tí Jèhófà fi dá wa ni pé ká lè mọ Jèhófà, ká sì máa jọ́sìn ẹ̀. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe gan-an nìyẹn. Torí pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀ náà gbọ́dọ̀ máa láyọ̀. (1 Tím. 1:11) Ṣé ó dìgbà tí gbogbo nǹkan bá ń lọ dáadáa fún wa ká tó lè láyọ̀? Rárá o. Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù sọ nǹkan kan tó yani lẹ́nu, ó ní: “Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀” náà lè láyọ̀. Jésù tún sọ pé “àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo” tàbí àwọn tí wọ́n ń “pẹ̀gàn” wọn torí pé wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi náà lè láyọ̀. (Mát. 5:4, 10, 11) Ohun tí Jésù ń kọ́ wa ni pé kò dìgbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fún wa ká tó lè láyọ̀, àmọ́ ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀ tòótọ́ ni pé ká sún mọ́ Ọlọ́run, ká sì máa wá ìtọ́sọ́nà ẹ̀.—Jém. 4:8. w22.10 6 ¶1-3
Sunday, August 18
Ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa ń dákẹ́.—Òwe 11:12.
Tí Kristẹni kan bá jẹ́ olóye, ó gbọ́dọ̀ mọ ‘ìgbà tó yẹ kéèyàn dákẹ́ àti ìgbà tó yẹ kéèyàn sọ̀rọ̀.’ (Oníw. 3:7) Àwọn kan máa ń sọ pé: “Ẹyin lohùn, tó bá ti bọ́ kì í ṣeé kó mọ́.” Ìyẹn ni pé, àwọn àkókò kan wà tó sàn kéèyàn dákẹ́ ju kó sọ̀rọ̀ lọ. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Alàgbà tó nírìírí kan wà tí wọ́n sábà máa ń sọ fún pé kó lọ ran àwọn ìjọ tó níṣòro lọ́wọ́. Nígbà tí alàgbà míì ń sọ̀rọ̀ nípa alàgbà yẹn, ó ní: “Ó máa ń kíyè sára gan-an kó má bàa sọ̀rọ̀ àṣírí àwọn ìjọ yẹn síta.” Torí pé alàgbà yẹn jẹ́ olóye, ìyẹn jẹ́ káwọn alàgbà yòókù tí wọ́n jọ wà níjọ máa bọ̀wọ̀ fún un. Ó dá wọn lójú pé kò ní sọ̀rọ̀ àṣírí ìjọ wọn fáwọn èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá jẹ́ olóòótọ́, àwọn èèyàn máa fọkàn tán wa. A máa ń fọkàn tán ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ torí a mọ̀ pé gbogbo ìgbà ló máa ń sòótọ́.—Éfé. 4:25; Héb. 13:18. w22.09 12 ¶14-15
Monday, August 19
Kò sí ọgbọ́n tàbí òye tàbí ìmọ̀ràn tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.—Òwe 21:30.
Ọ̀pọ̀ ló kọ etí dídi sí ọgbọ́n tòótọ́ nígbà tó “ń ké jáde ní ojú ọ̀nà.” (Òwe 1:20) Àwọn mẹ́ta kan ni Bíbélì sọ pé wọ́n kọ ọgbọ́n tòótọ́: Àwọn “aláìmọ̀kan,” àwọn “afiniṣẹ̀sín” àtàwọn “òmùgọ̀.” (Òwe 1:22-25) Àwọn “aláìmọ̀kan” làwọn tí kò ní ìrírí, tí wọ́n tètè máa ń gba ohun táwọn èèyàn bá sọ fún wọn gbọ́, ìyẹn sì máa ń mú káwọn èèyàn ṣì wọ́n lọ́nà. (Òwe 14:15, àlàyé ìsàlẹ̀) Bí àpẹẹrẹ, ẹ ronú nípa ọ̀pọ̀ èèyàn táwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn olóṣèlú ń ṣì lọ́nà. Inú máa ń bí àwọn kan lẹ́yìn tí wọ́n bá mọ̀ pé wọ́n ti kó àwọn ṣìnà. Àmọ́ àwọn tí Òwe 1:22 sọ̀rọ̀ nípa wọn pinnu pé àwọn ṣì máa jẹ́ aláìmọ̀kan, kódà lẹ́yìn tí wọ́n rí i pé irọ́ ni wọ́n ń pa fáwọn. (Jer. 5:31) Ohun tó bá wù wọ́n ni wọ́n ń ṣe, wọn ò fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ, wọn ò sì fẹ́ tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀. Torí náà, ó dájú pé a ò ní fẹ́ fìwà jọ àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ pinnu pé aláìmọ̀kan làwọn máa jẹ́!—Òwe 1:32; 27:12. w22.10 19 ¶5-7
Tuesday, August 20
Ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí èèyàn dá sílẹ̀.—1 Pét. 2:13.
Ètò Ọlọ́run máa ń tọ́ wa sọ́nà ká má bàa kó sínú ewu. Léraléra ni wọ́n ń rán wa létí pé ká fún àwọn alàgbà ní nọ́ńbà fóònù àti àdírẹ́sì ilé wa, kó lè rọrùn fún wọn láti kàn sí wa tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ lójijì. Wọ́n tún lè sọ fún wa pé ká má jáde kúrò nílé wa tàbí kí wọ́n ní ká tètè kúrò nílé kíákíá. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lè jẹ́ ká mọ ibi tá a ti máa rí àwọn nǹkan tá a nílò gbà, bá a ṣe máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ àtìgbà tó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Tá ò bá tẹ̀ lé ohun tí wọ́n sọ fún wa, a lè fi ẹ̀mí ara wa àti tàwọn alàgbà sínú ewu. Ìdí sì ni pé wọn ò fẹ́ kí aburú kankan ṣẹlẹ̀ sí wa. (Héb. 13:17) Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ti kúrò nílé wọn nítorí àjálù tàbí rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ lágbègbè wọn. Tí wọ́n bá dé ibi tí wọ́n sá lọ, wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kára wọn lè mọlé, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì máa ń bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn Jèhófà níbẹ̀. Àwọn náà máa ń “kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà” bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n tú ká káàkiri nítorí inúnibíni. (Ìṣe 8:4) Bí wọ́n ṣe ń wàásù yẹn ń jẹ́ kí wọ́n máa ronú nípa Ìjọba Ọlọ́run, dípò kí wọ́n máa ronú ṣáá nípa ìṣòro wọn. Ìyẹn ló ń jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀, kọ́kàn wọn sì balẹ̀. w22.12 19 ¶12-13
Wednesday, August 21
Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù.—Sm. 118:6.
Jèhófà mọyì ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Kí Jésù tó rán àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ jáde láti lọ wàásù, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má bẹ̀rù àwọn tó máa ta kò wọ́n. (Mát. 10:29-31) Torí náà, ó sọ̀rọ̀ nípa ẹyẹ ológoṣẹ́ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní Ísírẹ́lì. Owó táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n máa ń ra àwọn ẹyẹ yìí nígbà ayé Jésù. Àmọ́, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ìkankan nínú wọn ò lè já bọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.” Jésù tún sọ pé: “Ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” Jésù wá fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé Jèhófà mọyì ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, torí náà wọn ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù inúnibíni. Ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa rántí ohun tó sọ fún wọn bí wọ́n ṣe ń rí àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ nígbà tí wọ́n ń wàásù láwọn ìlú àti abúlé ní Ísírẹ́lì. Ìgbàkigbà tí ìwọ náà bá rí ẹyẹ kékeré kan, máa rántí pé Jèhófà mọyì ẹ torí pé o “níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” Torí náà, má bẹ̀rù táwọn èèyàn bá ń ta kò ẹ́, Jèhófà máa wà pẹ̀lú ẹ. w23.03 18 ¶12
Thursday, August 22
Ẹ ti mú kí Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kórìíra wa, ẹ sì ti fi idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa wá.—Ẹ́kís. 5:21.
Nígbà míì, àwọn ìṣòro tó le gan-an máa ń dé bá wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará ilé wa lè máa ta kò wá tàbí kí iṣẹ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Tá a bá ti ń fara da ìṣòro kan tipẹ́tipẹ́, ó lè mú ká sọ̀rètí nù, inú wa sì lè má dùn mọ́. Àwọn ìgbà tá a bá níṣòro yìí ni Sátánì máa ń fẹ́ ká ṣiyèméjì pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa. Èṣù fẹ́ ká máa rò pé Jèhófà tàbí ètò ẹ̀ ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan nírú èrò yìí nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì. Wọ́n kọ́kọ́ gbà pé Jèhófà ló yan Mósè àti Áárónì láti wá gbà wọ́n sílẹ̀ lóko ẹrú. (Ẹ́kís. 4:29-31) Àmọ́ nígbà tí Fáráò túbọ̀ ni wọ́n lára, wọ́n dá Mósè àti Áárónì lẹ́bi pé àwọn ló fa ìyà tó ń jẹ wọ́n. (Ẹ́kís. 5:19, 20) Wọ́n dá àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́bi. Ìyẹn mà bani nínú jẹ́ o! Tó bá ti pẹ́ gan-an tó o ti ń fara da ìṣòro tó le, máa gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, kó o sì gbà pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. w22.11 15 ¶5-6
Friday, August 23
Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn òkú máa gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọ́run, tí àwọn tó fiyè sílẹ̀ sì máa yè.—Jòh. 5:25.
Jèhófà ni Olùfúnni-ní-Ìyè, ó sì lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde. Ó fún wòlíì Èlíjà lágbára láti jí ọmọkùnrin opó Sáréfátì dìde. (1 Ọba 17:21-23) Nígbà tó yá, Ọlọ́run ran wòlíì Èlíṣà lọ́wọ́ láti jí ọmọkùnrin obìnrin ará Ṣúnémù kan dìde. (2 Ọba 4:18-20, 34-37) Àwọn àjíǹde yìí àtàwọn àjíǹde míì tó wáyé nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn pé Bàbá òun ti fún òun lágbára láti jí àwọn èèyàn dìde. (Jòh. 11:23-25, 43, 44) Ní báyìí tí Jésù ti wà lọ́run, “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé” ni Bàbá rẹ̀ ti fún un. Torí náà, ipò tí Jésù wà lọ́run báyìí máa jẹ́ kó lè mú ìlérí Jèhófà ṣẹ pé “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí” máa jíǹde, wọ́n á sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé.—Mát. 28:18; Jòh. 5:26-29. w22.12 5 ¶10
Saturday, August 24
Ilé Ísírẹ́lì ò ní tẹ́tí sí ọ torí wọn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.—Ìsík. 3:7.
Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá kọ̀ tí wọn ò fetí sí Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà ni wọn ò fetí sí yẹn. Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní jẹ́ kó dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé tí wọn ò bá tiẹ̀ fetí sí i, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò ṣàṣeyọrí. Jèhófà tún fi dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé tí ọ̀rọ̀ tí òun ní kó lọ sọ fún àwọn èèyàn náà bá ṣẹ, “wọ́n á mọ̀ pé wòlíì kan wà láàárín wọn.” (Ìsík. 2:5; 33:33) Torí náà, ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì yìí fún un lókun, ó sì máa jẹ́ kó lè jíṣẹ́ tó rán an. Ọkàn tiwa náà balẹ̀ lónìí torí a mọ̀ pé Jèhófà ló rán wa níṣẹ́. Jèhófà dá wa lọ́lá torí ó pè wá ní “ẹlẹ́rìí” òun. (Àìsá. 43:10) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn! Bí Jèhófà ṣe gba Ìsíkíẹ́lì níyànjú pé: “Má bẹ̀rù,” bẹ́ẹ̀ náà ló gba àwa náà níyànjú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá yín.” (Ìsík. 2:6) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn tó ń ta kò wá? Ìdí ni pé Jèhófà ló rán àwa náà níṣẹ́, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ bó ṣe ran Ìsíkíẹ́lì lọ́wọ́.—Àìsá. 44:8. w22.11 3-4 ¶4-5
Sunday, August 25
Ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń pa àṣírí mọ́.—Òwe 11:13.
Lónìí, a mọyì àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa torí wọ́n ṣeé fọkàn tán. Àwọn arákùnrin olóòótọ́ yìí ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa gan-an, a sì ń dúpẹ́ pé Jèhófà fi wọ́n jíǹkí wa! Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tó máa fi hàn pé a ṣeé fọkàn tán? A nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a ò sì fẹ́ kí nǹkan kan ṣe wọ́n. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká ṣàṣejù, kò sì yẹ ká tojú bọ ọ̀rọ̀ wọn. Àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ “ń ṣòfófó, wọ́n sì ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀, wọ́n ń sọ àwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n sọ.” (1 Tím. 5:13) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe bíi tiwọn. Àmọ́ ká sọ pé ẹnì kan sọ ọ̀rọ̀ àṣírí fún wa ńkọ́, tó sì sọ pé ká má sọ fáwọn èèyàn? Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan lè sọ ìṣòro àìsàn tó ní fún wa tàbí ìṣòro míì tó ní, ó sì sọ fún wa pé ká má sọ̀rọ̀ náà fún ẹlòmíì. Ó yẹ ká ṣe ohun tó sọ. w22.09 10 ¶7-8
Monday, August 26
Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà.—Róòmù 12:2.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí ‘yí èrò pa dà’ tún lè túmọ̀ sí “tún èrò ṣe.” Torí náà, ká yí èrò wa pa dà kọjá ká máa ṣe àwọn ohun rere kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa yẹ irú ẹni tá a jẹ́ wò, ká sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ, ká lè máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Ìgbà gbogbo ló sì yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dìgbà tá a bá dẹni pípé ká tó lè máa ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ní Róòmù 12:2, ṣé ẹ kíyè sí pé Pọ́ọ̀lù sọ pé kéèyàn tó lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ yí èrò inú ẹ̀ pa dà. Dípò ká jẹ́ kí ayé yìí máa darí èrò wa, a gbọ́dọ̀ máa yẹ ara wa wò ká lè mọ̀ bóyá Ọlọ́run ló ń darí èrò wa tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan tàbí tá a bá fẹ́ yan nǹkan tá a máa ṣe. w23.01 8-9 ¶3-4
Tuesday, August 27
Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró. Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú láé.—Sm. 55:22.
Ṣé Jèhófà máa ń gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro tó bá dé bá wa? Ṣé gbogbo aburú tó bá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa ni Jèhófà máa ń yí pa dà sí rere? Rárá o. Bíbélì ò sọ bẹ́ẹ̀. (Oníw. 8:9; 9:11) Àmọ́ ohun tó dá wa lójú ni pé tá a bá níṣòro, Jèhófà mọ̀, ó sì máa ń gbọ́ wa tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 34:15; Àìsá. 59:1) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà máa ń fún wa lókun ká lè fara da àwọn ìṣòro tá a ní. Báwo ló ṣe ń ṣe é? Jèhófà máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń fún wa níṣìírí lákòókò tá a nílò ẹ̀ gan-an. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Ṣé ìwọ náà rántí ìgbà kan tó o níṣòro, tí Jèhófà tù ẹ́ nínú tó sì fún ẹ lókun lákòókò tó o nílò ẹ̀ gan-an? Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá wà nínú ìṣòro, a kì í mọ bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ àfi tá a bá ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀. w23.01 17-18 ¶13-15
Wednesday, August 28
Ẹranko tó wà tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí kò sí . . . lọ sí ìparun.—Ìfi. 17:11.
Ẹranko ẹhànnà yìí jọ ẹranko olórí méje yẹn gan-an, àmọ́ ní tiẹ̀, àwọ̀ rírẹ̀dòdò ló ní. Bíbélì pè é ní “ère ẹranko,” ó sì sọ pé òun ni “ọba kẹjọ.” (Ìfi. 13:14, 15; 17:3, 8) Bíbélì sọ pé “ọba” yìí wà tẹ́lẹ̀, nígbà tó yá kò sí mọ́, àmọ́ lẹ́yìn náà, ó tún wà. Ẹ ò rí i pé àlàyé yìí bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé mu gẹ́lẹ́! Kódà, òun ló ń ti àwọn ìjọba ayé lẹ́yìn. Nígbà tó wà tẹ́lẹ̀, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni wọ́n ń pè é. Lẹ́yìn ìyẹn, kò sí mọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà tó yá, ó tún pa dà wá, ó sì ń jẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé. Àwọn ìjọba tó dà bí ẹranko ẹhànnà yẹn máa ń parọ́ káwọn èèyàn lè ta ko Jèhófà àtàwa èèyàn ẹ̀. Jòhánù sọ pé ṣe ló máa dà bíi pé wọ́n kó “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” jọ sí ogun Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn ogun “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.”—Ìfi. 16:13, 14, 16. w22.05 10 ¶10-11
Thursday, August 29
Kí lo kà níbẹ̀?—Lúùkù 10:26.
Nígbà tí Jésù kọ́ bá á ṣe máa dá ka Ìwé Mímọ́ fúnra ẹ̀, ó jẹ́ kó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, kó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kó sì máa darí gbogbo nǹkan tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹ rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá (12) péré? Ṣe lẹnu ya gbogbo àwọn olùkọ́ tó mọ Òfin Mósè dáadáa nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù “nítorí òye tó ní àti bó ṣe ń dáhùn.” (Lúùkù 2:46, 47, 52) Táwa náà bá ń ka Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, a máa mọ̀ ọ́n, àá sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Jésù sọ fáwọn tó mọ Òfin dáadáa, ìyẹn àwọn akọ̀wé òfin, àwọn Farisí àtàwọn Sadusí. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn máa ń ka Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, àmọ́ ohun tí wọ́n ń kà ò ṣe wọ́n láǹfààní kankan. Jésù sọ nǹkan mẹ́ta tí ò jẹ́ kí wọ́n jàǹfààní látinú ohun tí wọ́n ń kà. Ohun tí Jésù sọ fún wọn yẹn máa jẹ́ ká rí (1) bá a ṣe lè túbọ̀ lóye ohun tá à ń kà, (2) bá a ṣe lè wá àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye, (3) ká sì jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. w23.02 8-9 ¶2-3
Friday, August 30
Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́.—Òwe 22:3.
Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó yẹ ká sá fún ni kéèyàn máa tage, ọtí àmujù, àjẹjù, kéèyàn máa sọ̀rọ̀ àbùkù sáwọn ẹlòmíì, kéèyàn máa wo fíìmù ìwà ipá, àwòrán ìṣekúṣe àtàwọn nǹkan míì tó jọ wọ́n. (Sm. 101:3) Gbogbo ìgbà ni Èṣù máa ń wá bó ṣe fẹ́ ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. (1 Pét. 5:8) Tá ò bá kíyè sára, Sátánì lè mú ká di onílara, oníwọra, ká máa parọ́, ká kórìíra àwọn èèyàn, ká máa gbéra ga, ká sì máa di àwọn èèyàn sínú. (Gál. 5:19-21) Àmọ́ tá ò bá tètè jáwọ́, ó lè gbilẹ̀ lọ́kàn wa, kí ìwà náà sì kó wa síṣòro. (Jém. 1:14, 15) Ewu kan tá a lè má tètè fura sí àmọ́ tó yẹ ká sá fún ni ẹgbẹ́ búburú. Ó yẹ ká máa rántí pé ìwà àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè ṣàkóbá fún wa. (1 Kọ́r. 15:33) Tá a bá ń kíyè sára, a ò ní máa bá àwọn tí kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà rìn. (Lúùkù 21:34; 2 Kọ́r. 6:15) Tá a bá ń kíyè sára, a máa tètè rí àwọn nǹkan tó lè kó wa síṣòro, àá sì sá fún wọn. w23.02 16 ¶7; 17 ¶10-11
Saturday, August 31
Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.—1 Jòh. 5:3.
Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà sí i, ìyẹn ti jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó dájú pé o fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ ọn báyìí, kó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀ títí láé. Ó sì ṣeé ṣe torí ó ń rọ̀ ẹ́ pé kó o mú ọkàn òun yọ̀. (Òwe 23:15, 16) Ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ àti ìṣe ẹ lo fi lè mú ọkàn ẹ̀ yọ̀. Ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbé ayé ẹ ló máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́. Ohun tó dáa jù lọ tó yẹ kó o fayé ẹ ṣe nìyẹn. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Ohun àkọ́kọ́ tó o máa ṣe ni pé kó o gbàdúrà àkànṣe sí Jèhófà láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún un. (Sm. 40:8) Lẹ́yìn náà kó o ṣèrìbọmi, ìyẹn máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìrìbọmi tó o fẹ́ ṣe ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ, táá sì jẹ́ kó o máa láyọ̀. O ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tuntun báyìí, kó o lè máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, kì í ṣe ìfẹ́ tara ẹ. (Róòmù 14:8; 1 Pét. 4:1, 2) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, ìpinnu ńlá lo ṣe yẹn. Àmọ́, á jẹ́ kó o lè gbé ìgbé ayé tó dáa jù lọ. w23.03 5-6 ¶14-15