December
Sunday, December 1
Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?—Ìṣe 8:36.
Ṣé lóòótọ́ ni ọkùnrin ará Etiópíà tó jẹ́ ìjòyè yẹn ṣe tán láti ṣèrìbọmi? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀: Ọkùnrin ará Etiópíà yẹn “lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 8:27) Ó jọ pé ó ti gba ẹ̀sìn Júù. Torí náà, ó dájú pé á ti mọ̀ nípa Jèhófà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Síbẹ̀ ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Nígbà tí Fílípì pàdé ọkùnrin yìí lójú ọ̀nà, ó rí i tó ń ka ìwé àkájọ wòlíì Àìsáyà. (Ìṣe 8:28) Ó fẹ́ mọ̀ sí i. Ó gbéra láti Etiópíà kó lè lọ jọ́sìn Jèhófà ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ọkùnrin ará Etiópíà yẹn kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tuntun kan tó ṣe pàtàkì lọ́dọ̀ Fílípì. Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ náà ni pé Jésù ni Mèsáyà. (Ìṣe 8:34, 35) Ohun tó kọ́ yẹn jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. Torí náà, ó ṣe ìpinnu pàtàkì kan nígbèésí ayé ẹ̀, ìyẹn sì ni pé ó ṣèrìbọmi kó lè di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Nígbà tí Fílípì rí i pé ọkùnrin yẹn ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi, ó ṣèrìbọmi fún un. w23.03 8-9 ¶3-6
Monday, December 2
Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure.—Kól. 4:6.
Tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ máa sọ òótọ́. (Òwe 6:16, 17) Lónìí, àwọn èèyàn máa ń parọ́, wọn ò sì róhun tó burú níbẹ̀. Àmọ́, kò yẹ káwa máa parọ́ torí Jèhófà kórìíra irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Sm. 15:1, 2) Yàtọ̀ sí pé kò yẹ ká máa parọ́, kò tún yẹ ká máa fi òótọ́ pa mọ́ torí pé ìyẹn lè ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Kò sì yẹ ká máa sọ̀rọ̀ àwọn èèyàn láìdáa. (Òwe 25:23; 2 Tẹs. 3:11) Torí náà, tí ìwọ àti ẹnì kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ tó fẹ́ máa ṣòfófó ẹnì kan, o lè fọgbọ́n yí ọ̀rọ̀ náà pa dà, kẹ́ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ tó máa gbéni ró. Nínú ayé táà ń gbé lónìí, àwọn èèyàn máa ń sọ̀sọkúsọ gan-an. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká sì rí i pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa ń múnú Jèhófà dùn. Ó dájú pé ó máa bù kún wa tó bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, nígbà tá a bá wà nípàdé àti nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà bá pa ayé búburú yìí run, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa yìn ín lógo.—Júùdù 15. w22.04 9 ¶18-20
Tuesday, December 3
A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.—1 Jòh. 4:19.
Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà àti Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, àwa náà máa nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Jòh. 4:10) Ìfẹ́ tá a ní fún wọn jinlẹ̀ sí i nígbà tá a mọ̀ pé torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jésù ṣe kú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó sì fi hàn pé òun mọyì ohun tí Jésù ṣe nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn ará Gálátíà, ó ní: “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, [ó] sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gál. 2:20) Ẹbọ ìràpadà Jésù yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti pè ẹ́ wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀, kó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ṣé inú ẹ ò dùn nígbà tó o mọ̀ pé ohun tó dáa tí Jèhófà rí lára ẹ ló mú kó pè ẹ́ àti pé nǹkan ńlá ni Jèhófà san kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti di ọ̀rẹ́ ẹ̀? Ṣé ìyẹn ò mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àti Jésù pọ̀ sí i? Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Kí ni ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí mi máa sọ ọ́ di dandan pé kí n ṣe?’ Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Jésù ń jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.—2 Kọ́r. 5:14, 15; 6:1, 2. w23.01 28 ¶6-7
Wednesday, December 4
Màá yí èdè àwọn èèyàn pa dà sí èdè mímọ́.—Sef. 3:9.
Ipa kékeré kọ́ ni Bíbélì ń kó láti mú káwa èèyàn Jèhófà máa “sìn ín ní ìṣọ̀kan.” Jèhófà jẹ́ kí àwọn tó kọ Bíbélì kọ ọ́ lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ nìkan ló lè lóye ẹ̀. (Lúùkù 10:21) Ibi gbogbo láyé làwọn èèyàn ti máa ń ka Bíbélì. Àmọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ nìkan ló ń lóye ohun tó wà nínú ẹ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó sọ. (2 Kọ́r. 3:15, 16) Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà. Jèhófà máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti kọ́ gbogbo àwa èèyàn ẹ̀ lápapọ̀, ó sì tún máa ń lò ó láti tọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sọ́nà, kó sì tù wá nínú. Tá a bá ń ka Bíbélì, a máa ń rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Àìsá. 30:21) Ṣé gbogbo ìgbà lo máa ń ka Bíbélì, tó o wá ka ẹsẹ kan, tó sì dà bíi pé torí ẹ gan-an ni wọ́n ṣe kọ ọ́? Àmọ́, àìmọye èèyàn ló tún ń jàǹfààní Bíbélì. Kí ló jẹ́ kí àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì bóde mu, tó sì ń ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní? Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé Ẹni tó gbọ́n jù lọ láyé àti lọ́run ló ni Bíbélì.—2 Tím. 3:16, 17. w23.02 4-5 ¶8-10
Thursday, December 5
Máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí; jẹ́ kó gbà ọ́ lọ́kàn, kí gbogbo èèyàn lè rí i kedere pé ò ń tẹ̀ síwájú.—1 Tím. 4:15.
Àwa Kristẹni tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Ó sì máa ń wù wá pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Àmọ́ tá a bá fẹ́ lo àwọn ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa dáadáa, ó yẹ ká láwọn àfojúsùn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa hùwà tó yẹ Kristẹni, ká kọ́ṣẹ́ tá a lè lò nínú ètò Ọlọ́run, ká sì wo bá a ṣe lè túbọ̀ yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn ará lọ́wọ́. Kí nìdí tó fi yẹ kó wù wá pé ká tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà? Ìdí ni pé a fẹ́ múnú Jèhófà Bàbá wa ọ̀run dùn. Inú Jèhófà máa ń dùn tó bá ń rí i pé à ń lo àwọn ẹ̀bùn wa nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ìdí míì ni pé a fẹ́ túbọ̀ yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. (1 Tẹs. 4:9, 10) Bó ti wù ká pẹ́ tó nínú ètò Ọlọ́run, gbogbo wa ló yẹ ká máa tẹ̀ síwájú. w22.04 22 ¶1-2
Friday, December 6
Wọ́n máa jẹ ẹran ara rẹ̀, wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá.—Ìfi. 17:16.
Àwọn ìjọba ayé máa tó gbéjà ko Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ gbogbo ẹ̀sìn èké ayé yìí. Ìgbésẹ̀ yẹn ló máa fi hàn pé ìpọ́njú ńlá ti bẹ̀rẹ̀. Ṣé ìyẹn á wá mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá jọ́sìn Jèhófà? Rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìfihàn orí 6 sọ pé ní àkókò yẹn, gbogbo àwọn tí ò jọ́sìn Jèhófà máa wá ààbò lọ sọ́dọ̀ ètò òṣèlú àti ètò ìṣòwò ayé yìí, àwọn ètò yẹn ni ìwé Ìfihàn pè ní àwọn òkè. Alátakò ni Jèhófà sì máa kà wọ́n sí torí pé wọn ò ti Ìjọba ẹ̀ lẹ́yìn. (Lúùkù 11:23; Ìfi. 6:15-17) Ó dájú pé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa dá yàtọ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá. Ìdí ni pé àwọn nìkan lá máa jọ́sìn Jèhófà láyé, wọn ò sì ní ti “ẹranko náà” lẹ́yìn.—Ìfi. 13:14-17. w22.05 16-17 ¶8-9
Saturday, December 7
Ó ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti kéde fún àwọn tó ń gbé ayé, fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn.—Ìfi. 14:6.
Kì í ṣe ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nìkan làwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń wàásù. (Mát. 24:14) Wọ́n tún gbọ́dọ̀ bá àwọn áńgẹ́lì tí ìwé Ìfihàn orí 8 sí 10 sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣiṣẹ́. Àwọn áńgẹ́lì náà ń kéde ìyọnu tó máa bá àwọn tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kéde ìdájọ́ tó dà bí “yìnyín àti iná,” tó ń fi hàn pé Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ ayé búburú tí Sátánì ń darí yìí. (Ìfi. 8:7, 13) Ó yẹ káwọn èèyàn mọ̀ pé òpin ayé ti sún mọ́lé, ó sì yẹ kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà pàtàkì nígbèésí ayé wọn kí wọ́n lè yè bọ́ lọ́jọ́ ìbínú Jèhófà. (Sef. 2:2, 3) Àmọ́, àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí. Torí náà, ó gba ìgboyà ká tó lè sọ̀rọ̀ náà fáwọn èèyàn. Nígbà ìpọ́njú ńlá, a máa túbọ̀ kéde ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó kẹ́yìn lọ́nà tó lágbára jùyẹn lọ.—Ìfi. 16:21. w22.05 7 ¶18-19
Sunday, December 8
Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Mát. 22:37.
Ẹ jẹ́ ká ronú nípa tọkọtaya Kristẹni kan tí ò ní pẹ́ bímọ lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó. Ó dájú pé wọ́n á ti máa gbọ́ àsọyé Bíbélì tó dá lórí ọmọ títọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n á wá túbọ̀ mọyì àwọn ìlànà yẹn. Ìdí sì ni pé àwọn náà ti lọ́mọ tí wọ́n fẹ́ tọ́ dàgbà. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ńlá nìyẹn! Ó dájú pé tí ipò wa bá yí pa dà, àwọn ìlànà Bíbélì tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ á túbọ̀ yé wa. Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà fi máa ń ka Bíbélì, tí wọ́n sì ń ronú lórí ohun tí wọ́n kà “ní gbogbo ọjọ́ ayé” wọn bí Jèhófà ṣe sọ fáwọn ọba Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa ṣe. (Diu. 17:19) Ẹ̀yin òbí, ẹ ní ọ̀kan lára àǹfààní tó ṣe pàtàkì jù lọ táwa Kristẹni ní. Ìyẹn sì ni pé kí ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà. Àmọ́ iṣẹ́ náà kọjá kẹ́ ẹ kàn sọ nǹkan kan fún wọn nípa Ọlọ́run. Ẹ fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn. w22.05 26 ¶2-3
Monday, December 9
Ẹ . . . fi ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.—Kól. 3:10.
Ká kàn kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tá a dá nìkan ò tó. Ó tún yẹ ká gbé ìgbésẹ̀ láti ṣàtúnṣe. Nǹkan pàtàkì tí Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dárí jini ni ìyípadà. Ìyípadà túmọ̀ sí kéèyàn “yí pa dà.” Lédè míì, ẹni náà gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ń hù, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí. (Àìsá. 55:7) Ẹni náà gbọ́dọ̀ yí èrò ẹ̀ pa dà kó lè máa ronú lọ́nà tí Jèhófà ń gbà ronú. (Róòmù 12:2; Éfé. 4:23) Ó gbọ́dọ̀ pinnu pé òun ò ní máa ro èròkerò, òun ò sì ní pa dà sídìí ìwà burúkú tóun hù mọ́. (Kól. 3:7-9) Lóòótọ́, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti dárí jì wá, kó sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́, ó dìgbà tí Jèhófà bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn mọ́ la máa tó jàǹfààní ẹbọ ìràpadà náà.—1 Jòh. 1:7. w22.06 6 ¶16-17
Tuesday, December 10
Má bẹ̀rù àwọn nǹkan tí o máa tó jìyà rẹ̀.—Ìfi. 2:10.
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń hùwà ìkà sáwọn míì. (Oníw. 8:9) Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn máa ń fi ipò tí wọ́n wà ni àwọn míì lára, àwọn ọ̀daràn máa ń fojú àwọn èèyàn rí màbo, àwọn ọmọ burúkú tó wà nílé ìwé máa ń bú àwọn ọmọ ilé ìwé wọn, wọ́n sì máa ń halẹ̀ mọ́ wọn, kódà ìwà burúkú làwọn míì máa ń hù sí ìdílé wọn. Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà pé àwa èèyàn máa ń bẹ̀rù ara wa! Àmọ́ báwo ni Sátánì ṣe máa ń mú ká bẹ̀rù èèyàn kó lè rí wa mú? Sátánì máa ń fẹ́ ká bẹ̀rù àwọn èèyàn débi pé a ò ní ṣe ohun tó tọ́, a ò sì ní wàásù mọ́. Sátánì ti mú káwọn ìjọba kan fòfin de iṣẹ́ wa, wọ́n sì tún ń ṣe inúnibíni sí wa. (Lúùkù 21:12) Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé lónìí ló máa ń parọ́ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn tó bá gba irọ́ yìí gbọ́ máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ gbéjà kò wá. (Mát. 10:36) Ṣé àwọn ọgbọ́n tí Sátánì ń dá yìí yà wá lẹ́nu? Rárá o. Ìdí ni pé àtìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ló ti ń dá irú ọgbọ́n yẹn.—Ìṣe 5:27, 28, 40. w22.06 16 ¶10-11
Wednesday, December 11
Àwọn tí wọ́n sì ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo máa tàn bí ìràwọ̀, títí láé àti láéláé.—Dán. 12:3.
Àwọn wo ló máa wà lára “ọ̀pọ̀lọpọ̀” tí wọ́n máa sọ di olódodo? Àwọn tó bá jíǹde àtàwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já ni, títí kan àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí nínú ayé tuntun. Nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá máa fi parí, gbogbo èèyàn tó wà láyé á ti di pípé. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé torí ẹnì kan ti di pípé kò sọ pé ọwọ́ ẹni náà ti tẹ ìyè àìnípẹ̀kun nìyẹn. Ṣé ẹ rántí Ádámù àti Éfà? Ẹni pípé ni wọ́n, àmọ́ kí Jèhófà tó lè fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n jẹ́ onígbọràn sí i. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé wọn ò gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. (Róòmù 5:12) Lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, ṣé gbogbo àwọn ẹni pípé ló máa fara mọ́ àkóso Jèhófà títí láé? Àbí àwọn kan máa dà bí Ádámù àti Éfà tí wọ́n di aláìṣòótọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni wọ́n? Ó yẹ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. w22.09 22-23 ¶12-14
Thursday, December 12
Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀.—Ìfi. 11:15.
Tó o bá ń wo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí, ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti gbà pé nǹkan ṣì máa dáa? Àwọn tó wà nínú ìdílé kan náà ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Àwọn èèyàn túbọ̀ ń hùwà ipá, tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, wọ́n sì máa ń bínú sódì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn ò fọkàn tán àwọn aláṣẹ mọ́. Àmọ́, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí yẹ kó fi wá lọ́kàn balẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn á máa ṣe ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí làwọn èèyàn ń ṣe gẹ́lẹ́. (2 Tím. 3:1-5) Kò sí olóòótọ́ èèyàn kan tó lè sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kò rí bẹ́ẹ̀, torí bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣe ń ṣẹ jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Kristi Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Àmọ́ èyí kàn jẹ́ ọ̀kan péré lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó ti ń ṣẹ báyìí. Bí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ń ṣẹ tẹ̀ lé ara wọn jẹ́ ká mọ ibi táwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ dé. w22.07 2 ¶1-2
Friday, December 13
A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.—Mát. 11:19.
Nígbà àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà, ètò Ọlọ́run sọ fún wa nípa ọ̀nà tá ó máa gbà ṣe ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù. Kíákíá la bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kíákíá la tún bẹ̀rẹ̀ sí í lo fóònù àti lẹ́tà láti fi wàásù fáwọn èèyàn. Jèhófà mú ká ṣàṣeyọrí. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ròyìn pé àwọn tó ṣèrìbọmi ń pọ̀ sí i. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ròyìn pé àwọn ohun rere tó ń mórí ẹni wú ṣẹlẹ̀ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà yẹn. Àwọn kan lè máa rò pé ọwọ́ tí ètò Ọlọ́run fi ń mú ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn yìí ti le jù. Àmọ́ ìgbà gbogbo là ń rí ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n ń sọ fún wa. Torí náà, tá a bá ń ronú lórí bí Jésù ṣe ń fìfẹ́ darí wa, ó dá wa lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí wa, Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ ò ní fi wá sílẹ̀.—Héb. 13:5, 6. w22.07 13 ¶15-16
Saturday, December 14
Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo. Ẹ máa dúpẹ́ ohun gbogbo. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún yín nìyí nínú Kristi Jésù.—1 Tẹs. 5:17, 18.
Yàtọ̀ sí pé ó yẹ ká máa yin Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà, ó tún yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ nítorí àwọn nǹkan rere tó ń pèsè fún wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó fún wa ní àwọ̀ mèremère tá à ń rí lára àwọn òdòdó, oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn àtàwọn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n tó ń dúró tì wá. Gbogbo àwọn nǹkan yìí ni Bàbá wa ọ̀run ń pèsè fún wa torí pé ó fẹ́ ká máa láyọ̀. (Sm. 104:12-15, 24) Àmọ́ ohun tó yẹ ká máa torí ẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà jù ni pé ó ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́ wa yó àti pé ó máa fún wa láwọn ohun rere lọ́jọ́ iwájú. A máa ń gbàgbé láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbà míì. Kí lá jẹ́ kó o máa rántí? O lè kọ àwọn nǹkan tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún ẹ sílẹ̀, kó o sì máa wò wọ́n látìgbàdégbà bí Jèhófà ṣe ń dáhùn wọn. Tó o ba kíyè sí pé Jèhófà ti dáhùn àwọn àdúrà ẹ kan, rí i pé o dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.—Kól. 3:15. w22.07 22 ¶8-9
Sunday, December 15
Òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.—Sm. 1:2.
Ká kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nìkan ò tó. Ká tó lè jàǹfààní ẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa hàn nígbèésí ayé wa, ìyẹn ni pé ká máa fi ohun tá à ń kọ́ ṣèwàhù, ìgbà yẹn la máa ní ayọ̀ tòótọ́. (Jém. 1:25) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí òtítọ́ tá a ti mọ̀ máa hàn nígbèésí ayé wa? Arákùnrin kan dábàá pé ká máa wo àwọn ibi tá a dáa sí àtàwọn ibi tá a kù sí ká lè ṣàtúnṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.” (Fílí. 3:16) Ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ṣiṣẹ́ kára láti “máa rìn nínú òtítọ́”! Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayé wa máa dáa sí i, a tún máa múnú Jèhófà dùn. Yàtọ̀ síyẹn, inú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà náà máa dùn. (Òwe 27:11; 3 Jòh. 4) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé àwọn nǹkan pàtàkì yìí ló máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ká sì máa fi ṣèwàhù. w22.08 18-19 ¶16-18
Monday, December 16
Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.—1 Pét. 5:2.
Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù? Ọ̀nà pàtàkì kan ni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (1 Pét. 5:1, 2) Jésù jẹ́ kí àpọ́sítélì Pétérù mọ̀ pé ohun tó yẹ kó máa ṣe nìyẹn. Lẹ́yìn tó sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó fẹ́ kí Jésù mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lóòótọ́. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó béèrè lọ́wọ́ Pétérù pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi?” Ó dájú pé Pétérù máa ṣe ohunkóhun láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọ̀gá òun. Torí náà, Jésù sọ fún un pé: “Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòh. 21:15-17) Jálẹ̀ ìgbésí ayé Pétérù, ó fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa rẹ̀, ìyẹn sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jésù gan-an. Ẹ̀yin alàgbà, báwo lẹ ṣe lè ṣe ohun tí Jésù sọ fún Pétérù? Tó o bá lọ ń bẹ àwọn ará wò déédéé, tó o sì ń ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù nìyẹn.—Ìsík. 34:11, 12. w23.01 29 ¶10-11
Tuesday, December 17
Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra.—1 Kọ́r. 10:13.
Má rò pé kò sẹ́ni tó lè mọ ìṣòro tó o ní àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Tó o bá ń ronú bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o máa rò pé ọ̀rọ̀ ẹ ò látùnṣe àti pé o ò ní lè borí kùdìẹ̀-kudiẹ tó o ní. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Ó sọ pé: “Nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.” Torí náà, tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá ń wá sí wa lọ́kàn ṣáá, a lè fara dà á ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ó sì dájú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé e kúrò lọ́kàn. Máa rántí pé ó lè má ṣeé ṣe fún ẹ láti gbé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kúrò lọ́kàn pátápátá torí pé aláìpé ni wá. Àmọ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá wá sí wa lọ́kàn, ó yẹ ká gbé e kúrò lọ́kàn kíákíá bí Jósẹ́fù ti ṣe nígbà tó tètè sá kúrò lọ́dọ̀ ìyàwó Pọ́tífárì. (Jẹ́n. 39:12) Ẹ ò rí i pé kò yẹ ká fàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ́kàn wa! w23.01 12-13 ¶16-17
Wednesday, December 18
Kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Róòmù 2:11.
Ìdájọ́ òdodo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. (Diu. 32:4) Tẹ́nì kan bá jẹ́ onídàájọ́ òdodo, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ojúsàájú. Irú ẹni tí Jèhófà sì jẹ́ nìyẹn. (Ìṣe 10:34, 35) Torí pé Jèhófà kì í ṣojúsàájú, ó jẹ́ kí wọ́n fi àwọn èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ nígbà àtijọ́ kọ Bíbélì. Jèhófà ṣèlérí pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, “ìmọ̀ tòótọ́” tó wà nínú Bíbélì “máa pọ̀” gan-an. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Dán. 12:4) Ọ̀nà kan tí ìmọ̀ tòótọ́ ń gbà pọ̀ gan-an ni bá a ṣe ń túmọ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, tá à ń tẹ̀ ẹ́, tá a sì ń pín in fáwọn èèyàn. Iye èdè táwa èèyàn Jèhófà ti túmọ̀ Bíbélì sí, bóyá lápá kan tàbí lódindi ti ju igba ó lé ogójì (240) lọ, gbogbo èèyàn ló sì ní àǹfààní láti ní Bíbélì yìí láì jẹ́ pé wọ́n fowó rà á. Ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn níbi gbogbo láyé láti gbọ́ “ìhìn rere Ìjọba” Ọlọ́run kí òpin tó dé. (Mát. 24:14) Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Ọlọ́run wa, ó fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní láti ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí wọ́n lè wá mọ̀ ọ́n. Ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo wa gan-an. w23.02 5 ¶11-12
Thursday, December 19
Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà.—Róòmù 12:2.
Ṣé o nífẹ̀ẹ́ òdodo? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ torí pé aláìpé ni gbogbo wa, tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a ò nífẹ̀ẹ́ òdodo bíi tàwọn èèyàn ayé. (Àìsá. 5:20) Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ olódodo, ọ̀pọ̀ ló gbà pé ẹni náà ní láti jẹ́ agbéraga, ó máa ń dá àwọn míì lẹ́jọ́, ó sì gbà pé òun dáa ju àwọn tó kù lọ. Àmọ́ inú Ọlọ́run ò dùn sí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó dẹ́bi fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó gbé ìlànà òdodo tiwọn kalẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe òdodo àṣelékè. (Oníw. 7:16; Lúùkù 16:15) Ẹni tó bá ń tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà kì í ronú pé òun dáa ju àwọn ẹlòmíì lọ. Ànímọ́ tó dáa ni òdodo. Ní ṣókí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run. Nínú Bíbélì, tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ olódodo, ó túmọ̀ sí pé ẹni náà ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà délẹ̀délẹ̀. w22.08 27 ¶3-5
Friday, December 20
Mo pè yín ní ọ̀rẹ́.—Jòh. 15:15.
Jésù fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ọmọlẹ́yìn òun bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń ṣàṣìṣe. (Jòh. 15:16) Nígbà tí Jémíìsì àti Jòhánù ní kí Jésù fi àwọn sípò pàtàkì nínú Ìjọba ẹ̀, Jésù ò bi wọ́n pé ṣé torí ìyẹn ni wọ́n ṣe ń sin Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì sọ pé wọn ò ní jẹ́ àpọ́sítélì òun mọ́. (Máàkù 10:35-40) Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló sá lọ lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un. (Mát. 26:56) Síbẹ̀, Jésù ò torí ìyẹn sọ pé òun ò ní fọkàn tán wọn mọ́. Jésù mọ àwọn ibi tí wọ́n kù sí, síbẹ̀ ó “nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòh. 13:1) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ mọ́kànlá (11) yẹn kan náà ló ní kí wọ́n máa bójú tó iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ọmọlẹ́yìn tó kù. (Mát. 28:19, 20; Jòh. 21:15-17) Àwọn àpọ́sítélì náà sì fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán torí gbogbo wọn ló jẹ́ olóòótọ́ títí wọ́n fi kú. Torí náà, ó dájú pé Jésù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fọkàn tán àwọn èèyàn aláìpé. w22.09 6 ¶12
Saturday, December 21
Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù.—Sm. 118:6.
Tá a bá gbà pé Jèhófà fẹ́ràn wa àti pé ó ń tì wá lẹ́yìn, Sátánì ò ní lè dẹ́rù bà wá. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó kọ Sáàmù 118 ní ọ̀pọ̀ ìdààmú. Ó láwọn ọ̀tá tó pọ̀ gan-an, kódà àwọn èèyàn pàtàkì wà lára wọn (ẹsẹ 9, 10). Wọ́n sì máa ń fúngun mọ́ ọn nígbà míì (ẹsẹ 13). Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà bá a wí gan-an (ẹsẹ 18). Síbẹ̀, onísáàmù yẹn sọ pé: “Mi ò ní bẹ̀rù.” Ó mọ̀ pé bí Jèhófà Bàbá òun bá tiẹ̀ bá òun wí, ó nífẹ̀ẹ́ òun. Ó dá onísáàmù náà lójú pé ipò èyíkéyìí tóun bá wà, Ọlọ́run tó fẹ́ràn òun ṣe tán láti gba òun. (Sm. 118:29) Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Tá a bá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́, a máa borí nǹkan mẹ́ta tó sábà máa ń dẹ́rù bà wá. Àwọn nǹkan náà ni, (1) ìbẹ̀rù pé a ò ní lè pèsè fún ìdílé wa, (2) ìbẹ̀rù èèyàn àti (3) ìbẹ̀rù ikú. w22.06 15 ¶3-4
Sunday, December 22
Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò, torí tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà, ó máa gba adé ìyè.—Jém. 1:12.
Rí i dájú pé o fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́. Torí pé Jèhófà ló dá wa, òun ló yẹ ká máa jọ́sìn. (Ìfi. 4:11; 14:6, 7) Torí náà, ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bá a ṣe máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, ìyẹn “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòh. 4:23, 24) Ká lè máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ máa tọ́ wa sọ́nà. Kódà tó bá jẹ́ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́ tàbí fòfin de iṣẹ́ wa là ń gbé, ìjọsìn Jèhófà la gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́. Ní bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ju ọgọ́rùn-ún (100) lọ ló wà lẹ́wọ̀n torí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n ń láyọ̀, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa gbàdúrà, láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń wàásù nípa Ọlọ́run àti Ìjọba ẹ̀ fáwọn èèyàn. Táwọn èèyàn bá ń pẹ̀gàn wa tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wa, inú wa máa ń dùn torí a mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa àti pé ó máa san wá lérè.—1 Pét. 4:14. w22.10 9 ¶13
Monday, December 23
Ọgbọ́n jẹ́ ààbò.—Oníw. 7:12.
Jálẹ̀ ìwé Òwe, Jèhófà fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní, táá sì jẹ́ káyé wa túbọ̀ dáa tá a bá ń tẹ̀ lé wọn. Wo méjì lára ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n náà. Àkọ́kọ́, jẹ́ kí ohun tó o ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Òwe 23:4, 5 fún wa ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Má fi wàhálà pa ara rẹ torí kí o lè kó ọrọ̀ jọ. . . . Nígbà tí o bá bojú wò ó, kò ní sí níbẹ̀, torí ó dájú pé ó máa hu ìyẹ́ bí ẹyẹ idì, á sì fò lọ sójú ọ̀run.” Àmọ́ lónìí, àtolówó àti tálákà ló ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè di ọlọ́rọ̀. Bí wọ́n ṣe ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lépa owó yìí ti mú kí wọ́n ba ara wọn lórúkọ jẹ́. Ó ti mú kí àjọṣe àárín wọn àtàwọn èèyàn bà jẹ́, ó sì ti kó bá ìlera wọn. (Òwe 28:20; 1 Tím. 6:9, 10) Ìkejì, máa ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Tá ò bá ṣọ́ra, ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè kó bá wa. Òwe 12:18 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni, àmọ́ ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.” Àárín àwa àtàwọn èèyàn máa dáa tá ò bá sọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn fáwọn ẹlòmíì.—Òwe 20:19. w22.10 21 ¶14; 22 ¶16-17
Tuesday, December 24
Jẹ àkájọ ìwé yìí, kí o sì lọ bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.—Ìsík. 3:1.
Ìsíkíẹ́lì gbọ́dọ̀ mọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fẹ́ lọ sọ fáwọn èèyàn náà dunjú, ó sì gbọ́dọ̀ yé e dáadáa. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yani lẹ́nu. Ìsíkíẹ́lì rí i pé àkájọ ìwé náà “dùn bí oyin.” (Ìsík. 3:3) Kí nìdí tó fi sọ pé ó dùn bí oyin? Ìdí ni pé bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń ṣojú fún Jèhófà dà bí ohun kan tó dùn bí oyin, ó sì kà á sí àǹfààní ńlá. (Sm. 19:8-11) Torí náà, ó mọyì bí Jèhófà ṣe yan òun láti máa ṣiṣẹ́ wòlíì. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà wá sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Fetí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fún ọ, kí o sì fi í sọ́kàn.” (Ìsík. 3:10) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ó fẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì rántí ohun tó wà nínú àkájọ ìwé náà, kó sì ṣàṣàrò lórí ẹ̀. Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì ṣe àwọn nǹkan yìí, ìgbàgbọ́ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. Yàtọ̀ síyẹn, inú àkájọ ìwé yẹn kan náà ni ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tí Jèhófà ní kó lọ sọ fáwọn èèyàn yẹn wà. (Ìsík. 3:11) Torí náà, tí Ìsíkíẹ́lì bá ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun sọ fáwọn èèyàn náà dáadáa, ìgbà yẹn ló máa wá lọ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. w22.11 6 ¶12-14
Wednesday, December 25
Ṣíṣe ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ.—1 Sám. 15:22.
Táwọn àyípadà kan bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run, ó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Torí náà, kí ló yẹ ká ṣe? Máa fara mọ́ àwọn àyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù, iṣẹ́ pàtàkì làwọn ọmọ Kóhátì máa ń ṣe. Àwọn ló máa ń gbé àpótí májẹ̀mú lọ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbàkigbà tí wọ́n bá ti ń ṣí láti ibì kan sí ibòmíì. (Nọ́ń. 3:29, 31; 10:33; Jóṣ. 3:2-4) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn! Àmọ́ nǹkan yí pa dà fún wọn nígbà tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí torí pé wọn kì í gbé àpótí májẹ̀mú yẹn káàkiri mọ́. Torí náà, wọ́n yan iṣẹ́ míì fún wọn. (1 Kíró. 6:31-33; 26:1, 24) Kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé àwọn ọmọ Kóhátì ráhùn pé àwọn ju ẹni tó ń ṣerú iṣẹ́ yẹn lọ tàbí kí wọ́n sọ pé kí wọ́n fún àwọn níṣẹ́ tó gbayì jùyẹn lọ. Kí la rí kọ́? Tí àyípadà bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run, rí i pé o fara mọ́ àwọn àyípadà náà, kódà tí àyípadà náà bá kan iṣẹ́ tó ò ń ṣe. Jẹ́ kí inú ẹ máa dùn sí iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá yàn fún ẹ. Máa rántí pé iṣẹ́ tó ò ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run kọ́ ló ń sọ bó o ṣe wúlò tó lójú Jèhófà. Jèhófà mọyì ẹ̀ gan-an tó o bá jẹ́ onígbọràn, ìyẹn sì ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ èyíkéyìí tó ò ń ṣe lọ. w22.11 23 ¶10-11
Thursday, December 26
Kò sì tijú pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí.—2 Tím. 1:16.
Ónẹ́sífórù wá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kàn. Nígbà tó rí i, ó ṣe àwọn nǹkan tó ràn án lọ́wọ́. Torí náà, Ónẹ́sífórù fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu nítorí Pọ́ọ̀lù. Kí la rí kọ́? A ò gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù èèyàn torí ìyẹn lè jẹ́ ká pa àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa tì nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká dúró tì wọ́n, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 17:17) Torí náà, ó yẹ ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, ká sì dúró tì wọ́n. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà ṣe dúró ti àwọn ará wa tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n níbẹ̀. Nígbà táwọn kan lọ jẹ́jọ́ ní kọ́ọ̀tù, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan lọ síbẹ̀ láti fún wọn níṣìírí. Kí la rí kọ́? Tí wọ́n bá ba àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa lórúkọ jẹ́, tí wọ́n fàṣẹ ọba mú wọn, tí wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wọn, ká má bẹ̀rù, ká má sì pa wọ́n tì. A lè gbàdúrà fún wọn, ká bá wọn bójú tó ìdílé wọn, ká sì ṣe àwọn nǹkan míì tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ìṣe 12:5; 2 Kọ́r. 1:10, 11. w22.11 17 ¶11-12
Friday, December 27
Wọ́n ti di orísun ìtùnú fún mi gan-an.—Kól. 4:11.
Ara ojúṣe àwọn alàgbà ni láti máa fi Bíbélì tọ́ àwọn ará sọ́nà kí wọ́n sì máa tù wọ́n nínú nígbà ìṣòro. (1 Pét. 5:2) Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, wọ́n á kọ́kọ́ rí i dájú pé kò sí arákùnrin tàbí arábìnrin kankan nínú ewu àti pé gbogbo wọn ní oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí àjálù náà ti wáyé, àwọn ará ṣì máa nílò ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì. (Jòh. 21:15) Arákùnrin Harold tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó sì ti bá ọ̀pọ̀ àwọn ará sọ̀rọ̀ nígbà tí àjálù dé bá wọn sọ pé: “Ó máa ń gba àkókò kí ẹ̀dùn ọkàn tí àjálù náà fà tó tán lára àwọn ará. Wọ́n ti lè máa gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn díẹ̀díẹ̀, àmọ́ wọ́n á ṣì máa rántí àwọn èèyàn wọn tó kú àtàwọn ohun ìní tí wọ́n pàdánù. Wọ́n sì tún lè máa rántí bí Jèhófà ṣe kó wọn yọ nínú àjálù náà. Àwọn nǹkan tí wọ́n ń rántí yìí tún lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Ìyẹn ò sì fi hàn pé wọn ò nígbàgbọ́ torí bó ṣe máa ń ṣe gbogbo èèyàn nìyẹn.” Àwọn alàgbà máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé “ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.”—Róòmù 12:15. w22.12 22 ¶1; 24-25 ¶10-11
Saturday, December 28
Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kò sì ní ṣe ìfẹ́ ti ara rárá.—Gál. 5:16.
Ká bàa lè borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun tó tọ́. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ẹ̀mí Ọlọ́run á máa darí wa. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìpàdé wa. Láwọn ìpàdé Kristẹni yìí, a máa ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin táwọn náà ń ṣe ipa tiwọn bíi tiwa láti máa ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn sì máa ń fún wa níṣìírí. (Héb. 10:24, 25; 13:7) Tá a bá sì gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti borí kùdìẹ̀-kudiẹ kan, ó máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, gbogbo nǹkan tá à ń ṣe yìí ò sọ pé kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ má wá sí wa lọ́kàn, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa jẹ́ ká gbé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ náà kúrò lọ́kàn, a ò sì ní ṣe nǹkan ọ̀hún. Tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe àwọn nǹkan náà nìṣó ká lè máa ṣe ohun tó tọ́. w23.01 11 ¶13-14
Sunday, December 29
Mi ò ní jẹ́ kí ohunkóhun máa darí mi.—1 Kọ́r. 6:12.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn tàbí ìwé tó ń sọ nípa ohun tá a máa jẹ àtohun tá ò ní jẹ, ó jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan yìí. Bí àpẹẹrẹ, ó gbà wá níyànjú pé ká ‘sá fún àwọn ohun tó lè ṣe wá léṣe.’ (Oníw. 11:10) Bíbélì sọ fún wa pé àjẹkì àti ọtí àmujù ò dáa, àwọn nǹkan yìí sì lè dá àìsàn sí wa lára tàbí kí wọ́n ṣekú pa wá. (Òwe 23:20) Jèhófà fẹ́ ká kó ara wa níjàánu tó bá kan irú oúnjẹ tá a fẹ́ jẹ àtohun tá a fẹ́ mu àti bó ṣe máa pọ̀ tó. (1 Kọ́r. 9:25) Tá a bá ń lo làákàyè, àwọn ìpinnu tá a bá ń ṣe máa fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa. (Sm. 119:99, 100; Òwe 2:11) Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa ṣọ́ra tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a máa jẹ. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ oúnjẹ kan àmọ́ tá a mọ̀ pé kò bá wa lára mu, làákàyè wa máa sọ fún wa pé kò yẹ ká jẹ oúnjẹ náà mọ́. Bákan náà, tá a bá ní ìfòyemọ̀, àá máa sùn dáadáa, àá máa ṣeré ìmárale déédéé, àá máa tọ́jú ara wa dáadáa, àá sì máa bójú tó ilé wa kó lè mọ́ tónítóní. w23.02 21 ¶6-7
Monday, December 30
Kí lo kà níbẹ̀?—Lúùkù 10:26.
Báwo lo ṣe lè wá àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tó o bá ń ka Bíbélì? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí 2 Tímótì 3:16, 17 sọ. Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé ‘gbogbo Ìwé Mímọ́ ló wúlò’ fún (1) kíkọ́ni, (2) bíbáni wí, (3) mímú nǹkan tọ́ àti fún (4) títọ́nisọ́nà. O ṣì lè jàǹfààní àwọn nǹkan mẹ́rin yẹn, kódà látinú àwọn ìwé Bíbélì tí o kì í sábà kà. Ronú nípa ohun tí ìtàn náà kọ́ ẹ nípa Jèhófà, ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé àtàwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe ń bá wa wí. Tó o bá ń ka Bíbélì, wo àwọn ìwà tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ní kó o yẹra fún, kó o sì pinnu pé o ò ní hu irú àwọn ìwà yẹn mọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Wo bí ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe lè mú kó o mú nǹkan tọ́, ìyẹn ni pé kó o fi ṣàtúnṣe èrò tí ò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè fi ran ẹnì kan tó o pàdé lóde ìwàásù lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, wo bí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà ṣe lè tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin yìí, wàá rí àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ jàǹfààní nínú Bíbélì tó ò ń kà. w23.02 11 ¶11
Tuesday, December 31
Ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.—Dán. 7:14.
Àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì sọ pé Jésù máa gba Ìjọba lẹ́yìn tí ìgbà méje bá parí. Ṣé ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ìgbà tí Jésù di Ọba? (Dán. 4:10-17) “Ìgbà méje” yẹn jẹ́ 2,520 ọdún. Ìgbà méje yẹn bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 607 Ṣ.S.K., nígbà tí àwọn ará Bábílónì mú ọba tó jẹ kẹ́yìn lórí ìtẹ́ Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù kúrò. Ìgbà méje náà sì parí lọ́dún 1914 S.K., nígbà tí Jèhófà fi Jésù “ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin” jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Ìsík. 21:25-27) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe máa ṣe wá láǹfààní? Tá a bá mọ̀ nípa “ìgbà méje” yẹn, á jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa ń mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ lákòókò tó yẹ. Bó ṣe jẹ́ kí Ìjọba ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lásìkò tó yẹ kó bẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa jẹ́ kí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó kù náà ṣẹ lásìkò tó yẹ. Ó dájú pé ọjọ́ Jèhófà “kò ní pẹ́ rárá!”—Háb. 2:3. w22.07 3 ¶3-5