Sọ Ẹ̀kọ́ Afúnninílera Di Ọ̀nà Ìgbésí-Ayé Rẹ
“Ìfọkànsin Ọlọrun ṣàǹfààní fún ohun gbogbo.”—1 TIMOTEU 4:8, NW.
1, 2. Dé ìwọ̀n àyè wo ni àwọn ènìyàn ń fi ìdàníyàn hàn fún ìlera wọn, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?
Ọ̀PỌ̀ jùlọ ènìyàn ní yóò gbà láìsí ìlọ́tìkọ̀ pé ìlera dídára jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun-ìní ṣíṣeyebíye jùlọ nínú ìgbésí-ayé. Wọ́n ya àkókò ńláǹlà àti owó sọ́tọ̀ fún pípa ìlera araawọn mọ́ àti rírí i dájú pé wọ́n rí àfiyèsí ìṣègùn tí ó yẹ gbà nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní United States iye owó àbójútó ìlera ọdọọdún fún ti ọdún ẹnu-àìpẹ́ yìí ju $900 billion lọ. Ìyẹn fi púpọ̀ ju $3,000 lọ́dún fún olúkúlùkù ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé ní orílẹ̀-èdè yẹn, iye owó tí ẹnìkọ̀ọ̀kan sì ń rígbà ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí ó ti gòkè àgbà fẹ́rẹ̀ bá ìyẹn dọ́gba.
2 Kí ni gbogbo àkókò, agbára, àti owó tí a ń lò náà ti mú wá? Dájúdájú kò sí ẹni tí yóò sẹ́ pé, ní gbogbogbòò, a ni àwọn ohun èèlò ìṣègùn àti ìpèsè tí wọ́n jẹ́ ti ìgbàlódé gan-an lónìí ju ti ìgbà èyíkéyìí lọ nínú ìtàn. Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀sí ìgbésí-ayé tí ó kún fún ìlera lójú ẹsẹ̀. Ní tòótọ́, nínú ọ̀rọ̀ kan tí ń ṣe ìlapa èrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àbójútó ìlera kan tí a wéwèé fún United States, ààrẹ ṣàlàyé pé ní àfikún sí “iye gígadabú tí ìwà-ipá ń náni ní orílẹ̀-èdè yìí,” àwọn olùgbé United States “ní iye àrùn AIDS, sìgá mímu àti ọtí àmujù, ìlóyún àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún, àwọn kògbókògbó ọmọ tí ó pọ̀” ju ti orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn tí ó ti gòkè àgbà lọ. Kí ni ìparí èrò rẹ̀? “A níláti yí àwọn ọ̀nà wa padà bí àwa yóò bá fẹ́ láé láti jẹ́ onílera níti gidi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan.”—Galatia 6:7, 8.
Ọ̀nà Ìgbésí-Ayé tí Ó Jẹ́ Afúnninílera
3. Lójú ìwòye àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Griki, ìmọ̀ràn wo ni Paulu fúnni?
3 Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, a mọ àwọn Griki fún fífi ara jìn fún títọ́ ara-ìyára, ìmáralókun, àti àwọn eré-ìdíje ìdárayá. Pẹ̀lú ipò àtilẹ̀wá yìí, aposteli Paulu ni a mísí láti kọ̀wé sí Timoteu ọ̀dọ́mọkùnrin náà pé: “Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti ara ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀; ṣùgbọ́n ìfọkànsin Ọlọrun ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyíinì tí ń bọ̀.” (1 Timoteu 4:8, NW) Nípa báyìí, Paulu ń ṣàlàyé ohun tí àwọn ènìyàn ń jẹ́wọ́ rẹ̀ lónìí, ìyẹn ni pé, àwọn ìpèsè ìṣègùn tàbí ìpèsè ti ara kò mú ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó jẹ́ afúnninílera nítòótọ́ dánilójú. Bí ó ti wù kí ó rí, Paulu mú kí ó dá wa lójú pé ohun tí ó jẹ́ aláìṣeéyẹ̀sílẹ̀ ni mímú ipò ìlera nípa tẹ̀mí àti ìfọkànsin Ọlọrun dàgbà.
4. Kí ni àwọn àǹfààní ìfọkànsin Ọlọrun?
4 Irú ipa-ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní fún “ìyè ti ìsinsìnyí” nítorí pé ó ń pèsè ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan tí ó lè panilára tí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọrun, tàbí àwọn wọnnì tí wọ́n ní kìkì “àwòrán-ìrísí [tàbí, ìrísí] ìfọkànsin Ọlọrun,” ń múwá sórí araawọn. (2 Timoteu 3:5, NW; Owe 23:29, 30; Luku 15:11-16; 1 Korinti 6:18; 1 Timoteu 6:9, 10) Àwọn wọnnì tí wọ́n fàyègba ìfọkànsin Ọlọrun láti darí ìgbésí-ayé wọn ní ọ̀wọ̀ yíyẹ fún àwọn òfin àti ohun tí Ọlọrun béèrè fún, ìyẹn sì ń ru wọ́n sókè láti sọ ẹ̀kọ́ Ọlọrun di ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn. Irú ipa-ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ń mú ìlera ti ara àti ti ẹ̀mí, ìtẹ́lọ́rùn, àti ayọ̀ wá fún wọn. Wọ́n sì ń “to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún araawọn de ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn kí ó lè di ìyè tòótọ́ mú.”—1 Timoteu 6:19.
5. Ìtọ́ni wo ni Paulu pèsè nínú orí kejì ìwé rẹ̀ sí Titu?
5 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìgbésí-ayé kan tí a ń tọ́sọ́nà nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ afúnninílera ti Ọlọrun ń mú irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ wá nísinsìnyí àti ní ọjọ́ iwájú, kí a sọ ọ́ lọ́nà gbígbéṣẹ́, ó yẹ kí a mọ bí a ṣe lè sọ ẹ̀kọ́ afúninílera ti Ọlọrun di ọ̀nà ìgbésí-ayé wa. Aposteli Paulu pèsè ìdáhùn náà nínú lẹ́tà rẹ̀ sí Titu. A óò fún orí kejì ìwé náà ní àkànṣe àfiyèsí, níbi tí ó ti gba Titu níyànjú pé “máa bá a nìṣó ní sísọ awọn ohun tí ó yẹ fún ẹ̀kọ́ afúnninílera.” Dájúdájú gbogbo wa, àti èwe àti àgbà, ọkùnrin àti obìnrin, lè jàǹfààní láti inú “ẹ̀kọ́ àfúninílera” bẹ́ẹ̀ lónìí.—Titu 1:4, 5; 2:1, NW.
Ìmọ̀ràn fún Àwọn Àgbà Ọkùnrin
6. Ìmọ̀ràn wo ni Paulu fifún “awọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí,” èésìtiṣe tí ó fi jẹ́ inúrere ní ìhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
6 Lákọ̀ọ́kọ́, Paulu ní ìmọ̀ràn díẹ̀ fún àwọn àgbà ọkùnrin nínú ìjọ. Jọ̀wọ́ ka Titu 2:2. (NW) “Àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí,” gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, ni a bọlá fún tí a sì ń wò gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin. (Lefitiku 19:32; Owe 16:31) Nítorí èyí, àwọn mìíràn lè lọ́tìkọ̀ láti fún àgbà ọkùnrin kan ní ìmọ̀ràn lórí àwọn ọ̀ràn tí kò léwu tóbẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Jobu 32:6, 7; 1 Timoteu 5:1) Nítorí náà, inúrere ni ó jẹ́ ní ìhà ọ̀dọ̀ Paulu láti kọ́kọ́ darí ọ̀rọ̀ sí àwọn àgbà ọkùnrin, yóò sì dára fún wọn láti fi àwọn ọ̀rọ̀ Paulu sọ́kàn kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn yẹ ni ẹni tí a lè ṣàfarawé rẹ́, bíi ti Paulu.—1 Korinti 11:1; Filippi 3:17.
7, 8. (a) Kí ni jíjẹ́ “oníwọ̀ntunwọ̀nsì nínú àṣà-ìhùwà” ní nínú? (b) Èéṣe tí a fi gbọ́dọ̀ fi jíjẹ́ ẹni “tí ó yèkooro ní èrò-inú” gbe “oníwà-àgbà” lẹ́sẹ̀?
7 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ kí àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ Kristian jẹ́ “oníwọ̀ntunwọ̀nsì nínú àṣà-ìhùwà.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀sẹ̀ náà lè tọ́kasí àṣà ọtí mímu (“gbéjẹ́ẹ́ṣewọ̀ọ̀,” Kingdom Interlinear), ó tún ní ìtumọ̀ ti jíjẹ́ olùkíyèsára, olórí pípé, tàbí tí ń pa òye-ìmọ̀lára mọ́. (2 Timoteu 4:5; 1 Peteru 1:13) Nípa báyìí, yálà nínú ọtí mímu tàbí nínú àwọn nǹkan mìíràn, àwọn àgbà ọkùnrin gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwọ̀ntunwọ̀nsì, tí wọn kò fi araawọn fún àṣejù tàbí àṣerégèé.
8 Lẹ́yìn náà, ó tún yẹ kí wọ́n jẹ́ “oníwà-àgbà” àti ẹni “tí ó yèkooro ní èrò-inú.” Jíjẹ́ oníwà-àgbà, tàbí ẹni tí ó lọ́wọ̀ lára, tí ó sì yẹ ní bíbọ̀wọ̀ fún, sábà máa ń wá pẹ̀lú ọjọ́-orí gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí. Ṣùgbọ́n, àwọn kan lè nítẹ̀sí láti níwà-àgbà ní àníjù, ní dídi ẹni tí kò fàyègba ìṣeláńgbáláńgbá àwọn èwe. (Owe 20:29) Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí “yèkooro ní èrò-inú” fi gbe “oníwà-àgbà” lẹ́sẹ̀. Àwọn àgbà ọkùnrin gbọ́dọ̀ pa ìwà-àgbà tí ó bá ọjọ-orí rìn mọ́, síbẹ̀ kí wọ́n wàdéédéé ní àkókò kan-náà, ní mímú àwọn ìmọ̀lára àti òòfà-ọkàn wọn wá sábẹ́ ìdarí kíkún.
9. Èéṣe tí àwọn àgbà ọkùnrin fí gbọ́dọ̀ jẹ́ onílera nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ní pàtàkì nínú ìfaradà?
9 Ní àkótán, ó yẹ kí àwọn àgbà ọkùnrin jẹ́ “onílera ninu ìgbàgbọ́, ninu ìfẹ́, ninu ìfaradà.” Ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú àwọn ìwé rẹ̀, Paulu to ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ pọ̀ mọ́ ìrètí. (1 Korinti 13:13; 1 Tessalonika 1:3; 5:8) Níhìn-ín o fi “ìfaradà” rọ́pò “ìrètí.” Bóyá ó jẹ́ nítorí pé ìmọ̀lára ìjuwọ́sílẹ̀ lè fìrọ̀rùn wọlé wá nígbà tí ọjọ́ ogbó bá ń dé. (Oniwasu 12:1) Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣàlàyé, “ẹni tí ó bá forítì í títí dè òpin, òun náà ni a ó gbàlà.” (Matteu 24:13) Ní àfikún, àwọn àgbà ọkùnrin jẹ́ àpẹẹrẹ yíyẹ fún àwọn yòókù kìí wulẹ̀ ṣe nítorí ọjọ́-orí tàbí ìrírí wọn bíkòṣe nítorí àwọn ànímọ́ tẹ̀mí fífìdímúlẹ̀gbọnyin tí wọ́n ní—ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìfaradà.
Fún Àwọn Àgbà Obìnrin
10. Ìmọ̀ràn wo ni Paulu pèsè fún “awọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí” nínú ìjọ?
10 Tẹ̀lé èyí ni Paulu darí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn àgbà obìnrin nínú ìjọ. Jọ̀wọ́ ka Titu 2:3. (NW) “Awọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí” ni àwọn tí wọ́n dàgbà jù láàárín àwọn obìnrin nínú ìjọ, títíkan àwọn aya “awọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí” àti àwọn ìyá àti ìyá-àgbà àwọn mẹ́ḿbà mìíràn. Nítorí ìdí èyí, wọ́n lè ní agbára ìdarí ńláǹlà, fún rere tàbí búburú. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Paulu fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú “bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́,” tí ó túmọ̀sí pé “awọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí” pẹ̀lú tún ní àwọn ẹrù-iṣẹ́ pàtó kan tí wọ́n níláti múṣe kí wọ́n baà lè mú ipa-iṣẹ́ wọn nínú ìjọ ṣẹ.
11. Kí ni ìhùwàsí tí ó jẹ́ ọ̀wọ̀ onífọkànsìn?
11 Lákọ̀ọ́kọ́, “kí awọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí ní ọ̀wọ̀ onífọkànsìn ninu ìhùwàsí,” ní Paulu sọ. “Ìhùwàsí” jẹ́ ìfihànjáde ìṣarasíhùwà àti àkópọ̀-ànímọ́ inú lọ́hùn-ún tí ẹnìkan ní, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń farahàn nínú ìwà àti ìrísí. (Matteu 12:34, 35) Nígbà náà, kí ni ó níláti jẹ́ ìṣarasíhùwà tàbí àkópọ̀-ànímọ́ Kristian obìnrin kan tí ó jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí? Ní ọ̀rọ̀ kan, “ọ̀wọ̀ onífọkànsìn.” Èyí ni a túmọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Griki kan tí ó túmọ̀sí “èyí tí ó yẹ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan, nínú ìṣesí tàbí àwọn nǹkan tí a yàsímímọ́ fún Ọlọrun.” Èyí jẹ́ ìmọ̀ràn tí ó yẹ níti gidi lójú ìwòye agbára ìdarí tí wọ́n ní lórí àwọn ẹlòmíràn, ní pàtàkì lórí àwọn ọ̀dọ́bìnrin nínú ìjọ.—1 Timoteu 2:9, 10.
12. Àṣìlò ahọ́n wo ni gbogbo wa níláti yẹra fún?
12 Lẹ́yìn náà ni a rí àwọn ànímọ́ búburú méjì: “kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n máṣe di ẹrú fún ọ̀pọ̀ ọtí-wáìnì.” Ó dùnmọ́ni láti ríi pé àwọn méjì wọ̀nyí ni a kó papọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n E. F. Scott ṣàkíyèsí pé, “Ní ìgbà àtijọ́, nígbà tí wáìnì jẹ́ ohun mímu kanṣoṣo tí ó wà, ní àwọn ibi àpèjẹ wọn kékeré tí wọ́n ti ń mu ọtí wáìnì ni àwọn àgbà obìnrin ti ń fi ọ̀rọ̀ èké ba àwọn aládùúgbò wọn jẹ́.” Àwọn obìnrin ní gbogbogbòò máa ń dàníyàn púpọ̀ nípa àwọn ènìyàn ju àwọn ọkùnrin lọ, èyí tí ó yẹ fún ìgbóríyìn. Síbẹ̀, ìdàníyàn ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ lè di òfófó àní ìfọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ pàápàá, ní pàtàkì nígbà tí ọtí bá ti mú kí ahọ́n sọ ìkóra-ẹni-níjàánu nù. (Owe 23:33) Dájúdájú, gbogbo àwọn tí ń lépa ọ̀nà ìgbésí-ayé afúnninílera, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ṣe dáradára láti ṣọ́ra fún ọ̀fìn yìí.
13. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn àgbà obìnrin níláti gbà jẹ́ olùkọ́ni?
13 Láti lè lo àkókò tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó lọ́nà tí ń gbéniró, àwọn àgbà obìnrin ni a fún ní ìṣírí láti jẹ́ “olùkọ́ni ní ohun rere.” Ní ibòmíràn, Paulu fúnni ní àwọn ìtọ́ni ṣíṣe kedere pé àwọn obìnrin kò níláti jẹ olùkọ́ni nínú ìjọ. (1 Korinti 14:34; 1 Timoteu 2:12) Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò dí wọn lọ́wọ́ láti máṣe fi ìmọ̀ ṣíṣeyebíye ti Ọlọrun kọ́ni nínú agbo-ilé wọn àti ní gbangba. (2 Timoteu 1:5; 3:14, 15) Wọ́n tún lè ṣàṣeparí ohun púpọ̀ nípa jíjẹ́ àpẹẹrẹ Kristian fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin nínú ìjọ, bí àwọn ẹsẹ̀ tí ó tẹ̀lé e ti fihàn.
Fún Àwọn Ọ̀dọ́bìnrin
14. Báwo ni àwọn Kristian ọ̀dọ́bìnrin ṣe lè fi ìwàdéédéé hàn nínú bíbójútó iṣẹ́ wọn?
14 Ní fífún àwọn àgbà obìnrin ní ìṣírí láti jẹ́ “olùkọ́ni ní ohun rere,” Paulu mẹ́nukan àwọn ọ̀dọ́bìnrin ní pàtàkì. Jọ̀wọ́ ka Titu 2:4, 5. (NW) Nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú ìtọ́ni náà darí àfiyèsí sórí àwọn àlámọ̀rí inú ilé, àwọn Kristian ọ̀dọ́bìnrin kò níláti lọ rékọjá ààlà, ní fífàyègba àníyàn àwọn ohun ti ara láti jọba lé ìgbésí-ayé wọn lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti jẹ́ “ẹni tí ó yèkooro ní èrò-inú, oníwàmímọ́, . . . ẹni rere,” àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí wọ́n múratán láti kọ́wọ́ti ìṣètò ipò-orí Kristian, “kí ọ̀rọ̀ Ọlọrun má baà di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.”
15. Èéṣe tí ó fi yẹ kí a gbóríyìn fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́bìnrin nínú ìjọ?
15 Lónìí, ìrísí-ìran ìdílé ti yípadà lọ́pọ̀lọpọ̀ sí ohun tí ó jẹ́ ní ọjọ́ Paulu. Ọ̀pọ̀ ìdílé ti pínyà níti ìgbàgbọ́, àwọn mìíràn sì ní òbí kanṣoṣo. Àní nínú àwọn ìdílé tí a ń pè ní ti àbáláyé pàápàá, lọ́nà tí ń ga síi ni kò wọ́pọ̀ mọ́ pé kí aya tàbí ìyá jẹ́ olùṣàbójútó ilé fún àkókò kíkún. Gbogbo èyí gbé ìkìmọ́lẹ̀ gígadabú àti ẹrù-iṣẹ́ karí àwọn ọ̀dọ́bìnrin Kristian, ṣùgbọ́n èyí kò dá wọn sí kúrò nínú ojúṣe wọn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu. Nítorí náà, ìdùnnú ńláǹlà ni ó jẹ, láti rí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́bìnrin olùṣòtítọ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti mú àwọn ojúṣe púpọ̀ tí wọ́n ní wàdéédéé síbẹ̀ tí wọ́n ń tiraka láti fi àwọn ire Ìjọba náà sí ipò kìn-ín-ní, àwọn díẹ̀ tilẹ̀ wà nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. (Matteu 6:33) Ó yẹ kí a gbóríyìn fún wọn nítòótọ́!
Fún Àwọn Ọ̀dọ́kùnrin
16. Ìmọ̀ràn wo ni Paulu ní fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin, èésìtiṣe tí èyí fi bọ́ sákòókò?
16 Lẹ́yìn náà ni Paulu ba ọ̀rọ̀ dé orí àwọn ọ̀dọ́kùnrin, títíkan Titu. Jọ̀wọ́ ka Titu 2:6-8. (NW) Lójú ìwòye àwọn ọ̀nà aláìwúlò àti apanirun ti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lónìí—mímu sìgá, ìlòkulò oògùn àti ọtí-lílé, ìbálòpọ̀ tí kò bófinmu, àti àwọn ìlépa ayé mìíràn, gẹ́gẹ́ bí àwọn eré ìdárayá oníwà-ipá àti orin àti eré-ìnàjú arẹninípòwálẹ̀—nítòótọ́ èyí jẹ́ ìmọ̀ràn tí ó bọ́ sákòókò fún àwọn èwe Kristian tí wọ́n fẹ́ láti tẹ̀lé ọ̀nà ìgbésí-ayé afúnninílera àti èyí tí ń tẹ́nilọ́rùn.
17. Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe lè di ẹni tí ó “yèkooro ní èrò-inú” kí ó sì jẹ́ “àpẹẹrẹ awọn iṣẹ́ àtàtà”?
17 Ní ìyàtọ̀ sí àwọn èwe tí ń bẹ nínú ayé, ọ̀dọ́kùnrin Kristian kan níláti “yèkooro ní èrò-inú” kí ó sì jẹ́ “àpẹẹrẹ awọn iṣẹ́ àtàtà.” Paulu ṣàlàyé pé kìí ṣe àwọn tí wọ́n wulẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n ń jèrè èrò-inú yíyèkooro tí ó jẹ́ ti oníwà-àgbà, bíkòṣe àwọn “ẹni nípa ìrírí, tí wọ́n ń lo ọgbọ́n wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín rere àti búburú.” (Heberu 5:14) Ẹ sì wo bí ó ti jẹ́ àgbàyanu tó láti rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń fínnúfíndọ̀ yọ̀ọ̀da àkókò àti agbára wọn láti ní ìpín kíkún nínú ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú ìjọ Kristian, dípò fífi okun ìgbà ọ̀dọ́ wọn ṣòfò nínú àwọn ìlépa onímọtara-ẹni-nìkan! Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn, gẹ́gẹ́ bíi ti Titu, lè di àpẹẹrẹ “awọn iṣẹ́ àtàtà” nínú ìjọ Kristian.—1 Timoteu 4:12.
18. Kí ni ó túmọ̀sí láti fi àìdíbàjẹ́ hàn nínú ẹ̀kọ́, jẹ́ oníwà-àgbà nínú ìhùwàsí, àti ẹni tí ó sunwọ̀n nínú ọ̀rọ̀-sísọ?
18 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni a ránlétí pé wọ́n níláti máa “fi àìdíbàjẹ́ hàn ninu ẹ̀kọ́ [wọn] , ìwà àgbà, ọ̀rọ̀ tí ó sunwọ̀n tí a kò lè dálẹ́bi.” Ẹ̀kọ́ ‘àìdíbàjẹ́’ ni a gbọ́dọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọnyingbọnyin nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun; fún ìdí yìí, àwọn ọ̀dọ́kùnrin gbọ́dọ̀ jẹ́ aláápọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Bíi ti àwọn àgbà ọkùnrin, àwọn ọ̀dọ́kùnrin pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ní ìwà-àgbà. Ó yẹ kí wọ́n mọ̀ pé jíjẹ́ òjíṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ wíwúwo, àti nítorí náà wọ́n gbọ́dọ̀ “hùwà ní irú-ọ̀nà kan tí ó yẹ ìhìnrere.” (Filippi 1:27, NW) Bákan náà ni ọ̀rọ̀ wọn gbọ́dọ̀ “sunwọ̀n” kí ó sì jẹ́ irú èyí “tí a kò lè dálẹ́bi” kí wọ́n má baà fún àwọn aṣòdì ní ìdí fún ríráhùn.—2 Korinti 6:3; 1 Peteru 2:12, 15.
Fún Àwọn Ẹrú àti Ìránṣẹ́
19, 20. Báwo ni àwọn wọnnì tí àwọn ẹlòmíràn gbàsíṣẹ́ ṣe lè “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọrun, ní ọ̀ṣọ́”?
19 Ní àkótán, Paulu darí àfiyèsí sí àwọn wọnnì tí àwọn ẹlòmíràn gbàsíṣẹ́. Jọ̀wọ́ ka Titu 2:9, 10. (NW) Kìí ṣe púpọ̀ nínú wa ni ó jẹ́ ẹrú tàbí ìránṣẹ́ lónìí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jẹ́ àwọn tí a gbàsíṣẹ́ àti òṣìṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Nípa báyìí, àwọn ìlànà tí Paulu kà lẹ́sẹẹsẹ ṣeéfisílò bákan náà lónìí.
20 Láti “wà ní ìtẹríba fún awọn oluwa wọn ninu ohun gbogbo” túmọ̀sí pé àwọn Kristian tí a gbàsíṣẹ́ gbọ́dọ̀ fi ojúlówó ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn agbanisíṣẹ́ àti olùṣàbójútó iṣẹ́ wọn. (Kolosse 3:22) A tún gbọ́dọ̀ ròyìn wọn ní rere pé wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ aláìlábòsí, tí ń ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iṣẹ́ òòjọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú agbanisíṣẹ́ wọn. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ pa ọ̀pá ìdíwọ̀n gíga ti ìwà Kristian mọ́ ní àwọn ibi iṣẹ́ wọn láìka ìhùwàsí àwọn mìíràn tí wọ́n wà níbẹ̀ sí. Gbogbo èyí jẹ́ nítorí “kí wọ́n baà lè ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọrun, ní ọ̀ṣọ́ ninu ohun gbogbo.” Ẹ sì wo bí a ti ń gbọ́ nípa ìyọrísí aláyọ̀ náà lọ́pọ̀ ìgbà tó nígbà tí àwọn tí ń fi òtítọ́-inú kíyèsí wa bá dáhùnpadà sí òtítọ́ nítorí ìwà àtàtà àwọn alábàáṣiṣẹ́ tàbí ẹni àgbàsíṣẹ́ wọn tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí! Èyí jẹ́ èrè kan tí Jehofa ń fifún àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ̀lé ẹ̀kọ́ afúnninílera rẹ̀ àní ní ibi iṣẹ́ wọn pàápàá.—Efesu 6:7, 8.
Àwọn Ènìyàn tí A Wẹ̀mọ́
21. Èéṣe tí Jehofa fi pèsè ẹ̀kọ́ afúnninílera, báwo ni a sì ṣe níláti hùwàpadà?
21 Ẹ̀kọ́ afúnninílera tí Paulu ṣàlàyé rẹ̀ kìí wulẹ̀ ṣe àkójọ-òfin díẹ̀ nípa àwọn ìlànà ìwàhíhù tàbí àwọn èrò ìwàrere tí a lè yíjú sí bí a bá ti fẹ́. Paulu ń báa lọ láti ṣàlàyé ète rẹ̀. Jọ̀wọ́ ka Titu 2:11, 12. Láti inú ìfẹ́ àti inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ fún wa, Jehofa Ọlọrun ti pèsè ẹ̀kọ́ afúnninílera náà kí á baà lè kẹ́kọ̀ọ́ láti gbé ìgbésí-ayé tí ó ní ète nínú tí ó sì ń tẹ́nilọ́rùn ní àwọn àkókò lílekoko tí ó sì léwu wọ̀nyí. Ìwọ ha múratán láti tẹ́wọ́gbà kí o sì sọ ẹ̀kọ́ afúnninílera náà di apákan ìgbésí-ayé rẹ bí? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò túmọ̀sí ìgbàlà rẹ.
22, 23. Àwọn ìbùkún wo ni àwa yóò kórè rẹ̀ nípa sísọ ẹ̀kọ́ afúnninílera di ọ̀nà ìgbésí-ayé wa?
22 Ju èyíinì lọ, sísọ ẹ̀kọ́ afúnninílera di ọ̀nà ìgbésí-ayé wa ń mú àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ wá fún wa nísinsìnyí àti ìrètí aláyọ̀ fún ọjọ́-ọ̀la. Jọ̀wọ́ ka Titu 2:13, 14. Níti tòótọ́, sísọ ẹ̀kọ́ afúnninílera di ọ̀nà ìgbésí-ayé wa ń yà wá sọ́tọ̀ nínú ayé dídíbàjẹ́ tí ń kú lọ yìí gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí a wẹ̀mọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ Paulu dọ́gba pẹ̀lú àwọn ìránnilétí Mose fún àwọn ọmọ Israeli ní Sinai pé: “OLUWA . . . ó sì mú ọ ga ju orílẹ̀-èdè gbogbo lọ tí ó dá, ní ìyìn, ní orúkọ, àti ọlá; kí ìwọ kí ó lè máa jẹ́ ènìyàn mímọ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, bí ó ti sọ.”—Deuteronomi 26:18, 19.
23 Ǹjẹ́ kí a lè máa ka àǹfààní jíjẹ́ àwọn ènìyàn Jehofa tí a ti wẹ̀mọ́ sí ìṣúra títíláé nípa sísọ ẹ̀kọ́ afúnninílera di ọ̀nà ìgbésí-ayé wa! Kí á máa wà lójúfò nígbà gbogbo láti kọ irú àìṣèfẹ́ Ọlọrun lọ́nà èyíkéyìí àti àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ayé sílẹ̀, ní títipa bẹ́ẹ̀ wà ní wíwẹ̀mọ́ àti ní yíyẹ fún ìlò Jehofa nínú iṣẹ́ títóbilọ́lá tí ó ń mú kí ó di ṣíṣe lónìí.—Kolosse 1:10.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èéṣe tí ìfọkànsin Ọlọrun fi ṣàǹfààní fún ohun gbogbo?
◻ Báwo ni àwọn àgbà ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristian ṣe lè lépa ẹ̀kọ́ afúnninílera gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbésí-ayé?
◻ Ẹ̀kọ́ afúnninílera wo ni Paulu ní fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin nínú ìjọ?
◻ Àǹfààní àti ìbùkún wo ni ó lè jẹ́ tiwa bí a bá sọ ẹ̀kọ́ afúnninílera di ọ̀nà ìgbésí-ayé wa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọ̀pọ̀ lónìí ń fi ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Titu 2:2-4 sílò