Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
“Ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—ÉFÉSÙ 6:4.
1. Kí ni ète Ọlọ́run fún ìdílé, ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀ dípò ìyẹn?
“ẸMÁA so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí ni Jèhófà Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà nígbà tó dá ètò ìdílé sílẹ̀. (Éfésù 3:14, 15) Tọkọtaya àkọ́kọ́ náà lè máa fojú inú wo bí gbogbo ilẹ̀ ayé yóò ṣe kún fún àtọmọdọ́mọ wọn lọ́jọ́ iwájú—tí gbogbo wọn á jẹ́ mọ̀lẹ́bí kan náà tó jẹ́ ti àwọn ẹni pípé tí ń fi ìdùnnú gbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé, tí gbogbo wọn á sì máa fi ìṣọ̀kan sin Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá. Àmọ́ Ádámù àti Éfà di ẹlẹ́ṣẹ̀, ilẹ̀ ayé kò sì wá di ibi tó kún fún àwọn olódodo, olùbẹ̀rù Ọlọ́run. (Róòmù 5:12) Kàkà bẹ́ẹ̀, kò pẹ́ rárá tí ètò ìdílé fi dojú rú, tí ìkórìíra, ìwà ipá, àti àìsí “ìfẹ́ni àdánidá” fi gbèèràn, àgàgà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí.—2 Tímótì 3:1-5; Jẹ́nẹ́sísì 4:8, 23; 6:5, 11, 12.
2. Àwọn ànímọ́ wo ni àtọmọdọ́mọ Ádámù ní, àmọ́ kí ló ń béèrè láti lè gbé ìdílé tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí ró?
2 Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà ní àwòrán ara rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù ti wá di ẹlẹ́ṣẹ̀, Jèhófà yọ̀ǹda pé kí ó bímọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 5:1-4) Gẹ́gẹ́ bíi ti bàbá wọn, àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ní làákàyè, wọ́n sì lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. A lè kọ́ wọn ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jọ́sìn Ẹlẹ́dàá wọn àti ìjẹ́pàtàkì fífi gbogbo ọkàn-àyà àti ọkàn, àti èrò inú, àti okun wọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Máàkù 12:30; Jòhánù 4:24; Jákọ́bù 1:27) Síwájú sí i, a lè kọ́ wọn láti máa “ṣe ìdájọ́ òdodo, kí [wọ́n] sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí [wọ́n] sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run . . . rìn.” (Míkà 6:8) Àmọ́ níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, iṣẹ́ ńlá ń bẹ lọ́rùn wọn láti gbé ìdílé tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí ró.
Ra Àkókò Padà
3. Báwo làwọn òbí ṣe lè ‘ra àkókò padà’ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà di Kristẹni?
3 Ní àwọn àkókò líle koko, tọ́ràn ayé ọ̀hún ò wá lójú mọ́ yìí, ó ń béèrè ìsapá ńláǹlà kí àwọn ọmọ tó lè di àwọn tó “nífẹ̀ẹ́ Jèhófà,” àwọn tó dìídì “kórìíra ohun búburú.” (Sáàmù 97:10) Àwọn òbí tó gbọ́n yóò máa ‘ra àkókò padà’ láti fi bójú tó iṣẹ́ takuntakun yìí. (Éfésù 5:15-17) Bí o bá jẹ́ òbí, báwo lo ṣe lè ṣe èyí? Èkíní, ṣètò àwọn ohun àkọ́múṣe, kí o sì gbájú mọ́ “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” títí kan kíkọ́ àti títọ́ àwọn ọmọ rẹ. (Fílípì 1:10, 11) Èkejì, má walé ayé máyà. Ó lè di dandan pé kí o jáwọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tí kò pọndandan. Tàbí kí o wá nǹkan ṣe sí àwọn ohun ìní tí kì í ṣe kòṣeémánìí, tó sì ṣòroó tọ́jú. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni òbí, o ò ní kábàámọ̀ láé pé o sa gbogbo ipá rẹ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ dàgbà gẹ́gẹ́ bí olùbẹ̀rù Ọlọ́run.—Òwe 29:15, 17.
4. Báwo ni ìdílé ṣe lè wà níṣọ̀kan?
4 Lílo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, àgàgà tó bá jẹ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí ni ẹ ń lo àkókò yẹn fún, kì í ṣe fífi àkókò ṣòfò rárá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó dáa jù lọ láti fi mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan. Ṣùgbọ́n má sọ ọ́ di ọ̀ràn ìgbà-tí-mo-bá-ráyè. Ṣètò àkókò pàtó tí ẹ óò máa lò pa pọ̀. Èyí kì í ṣe ọ̀ràn wíwulẹ̀ jọ máa gbénú ilé kan náà bíi ti awùsá, kí kálukú máa ṣe tiẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Fífún àwọn ọmọ láfiyèsí lójoojúmọ́ máa ń jẹ́ kí ìdàgbàsókè wọn yára kánkán. Ìfẹ́ àti ìtọ́jú kò gbọ́dọ̀ wọ́n wọn. Àní kí tọkọtaya tó pinnu àtibímọ ni wọ́n ti gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ lórí ojúṣe pàtàkì yìí. (Lúùkù 14:28) Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ọmọ títọ́ kò ní di ẹtì sí wọn lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àǹfààní tí ń mú ìbùkún wá ni wọ́n á kà á sí.—Jẹ́nẹ́sísì 33:5; Sáàmù 127:3.
Máa Kọ́ni Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ àti Àpẹẹrẹ
5. (a) Báwo la ṣe ń bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ àwọn ọmọdé láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? (b) Ìmọ̀ràn wo la fún àwọn òbí nínú Diutarónómì 6:5-7?
5 Kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ tí ìwọ alára ní fún Jèhófà. Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tóo bá ní fún Ọlọ́run yóò sún ọ láti fi òtítọ́ tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́ni rẹ̀. Èyí kan títọ́ àwọn ọmọ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ọlọ́run gba àwọn òbí nímọ̀ràn pé kí wọ́n fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn, kí wọ́n jùmọ̀ máa sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Diutarónómì 6:5-7 sọ pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” Nípa gbígba àwọn ọmọ rẹ níyànjú léraléra, o lè gbin àwọn àṣẹ Ọlọ́run sí wọn lọ́kàn. Nítorí èyí, ọmọ rẹ yóò rí i pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èyí ẹ̀wẹ̀, yóò sì jẹ́ kóun náà sún mọ́ Jèhófà dáadáa.—Òwe 20:7.
6. Báwo làwọn òbí ṣe lè lo àǹfààní náà pé àwọn ọmọ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ?
6 Àwọn ọmọdé máa ń hára gàgà láti kẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n máa ń tẹ́tí léko, wọ́n sì máa ń fojú sílẹ̀, kíá ni wọ́n á sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ. Nígbà tí wọ́n bá rí i pé o kì í ṣe onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, èyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè mú ìmọ̀ràn Jésù lò. Ńṣe lo ń kọ́ wọn láti má ṣe máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tara, bí kò ṣe kí wọ́n ‘máa wá ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:25-33) Nípa níní ìjíròrò tó gbámúṣé, tó sì ń gbéni ró nípa òtítọ́ Bíbélì, nípa ìjọ Ọlọ́run, àti nípa àwọn alàgbà táa yàn sípò, ńṣe lo ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, kí wọ́n sì mọyì àwọn ìpèsè tẹ̀mí rẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn ọmọdé ti tètè máa ń rí àgàbàgebè, ìwà àti ìṣe rẹ gbọ́dọ̀ bá ìtọ́ni tóo ń fún wọn mu, kí ìwọ̀nyí sì máa fi hàn pé lóòótọ́ lo ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún nǹkan tẹ̀mí. Ẹ ò rí i pé ìbùkún gidi ló jẹ́, táwọn òbí bá rí i pé àpẹẹrẹ rere táwọn fi lélẹ̀ ti mú kí àwọn ọmọ wọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn!—Òwe 23:24, 25.
7, 8. Àpẹẹrẹ wo ló fi ìjẹ́pàtàkì títọ́ àwọn ọmọ láti ìgbà ọmọdé jòjòló hàn, ta sì ni ọpẹ́ yẹ nítorí àṣeyọrí náà?
7 A lè rí ìjẹ́pàtàkì títọ́ àwọn ọmọ láti ìgbà ọmọdé jòjòló nínú àpẹẹrẹ kan láti Venezuela. (2 Tímótì 3:15) Ó jẹ́ àpẹẹrẹ tọkọtaya kan tí kò tíì dàgbà púpọ̀, tórúkọ wọn ń jẹ́ Félix àti Mayerlín. Aṣáájú ọ̀nà òjíṣẹ́ ni wọ́n. Nígbà tí wọ́n bí Felito ọmọ wọn ọkùnrin, ara wọn wà lọ́nà láti sa gbogbo ipá wọn láti tọ́ ọ dàgbà di olùjọsìn tòótọ́ fún Jèhófà. Mayerlín bẹ̀rẹ̀ sí ka Iwe Itan Bibeli Mi, táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, sí Felito létí. Ó jọ pé Felito, ọmọ kékeré pínníṣín yìí, ti dá àwòrán Mósè àti àwòrán àwọn míì tó wà nínú ìwé yìí mọ̀.
8 Nígbà tí Felito ṣì kéré gan-an ló ti bẹ̀rẹ̀ sí dá jẹ́rìí. Ọwọ́ rẹ̀ tẹ góńgó tó ń lé láti di akéde Ìjọba náà, ó sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn náà. Nígbà tó ṣe, Felito di aṣáájú ọ̀nà déédéé. Àwọn òbí rẹ̀ sọ pé: “Báa ti ń wo ìtẹ̀síwájú ọmọ wa, a mọ̀ pé ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà àti ìtọ́ni tó fún wa ló jẹ́ kó ṣeé ṣe.”
Ran Àwọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Dàgbà Nípa Tẹ̀mí
9. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ fún ìtọ́ni tẹ̀mí tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń fún wa?
9 Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwé ìròyìn àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé, àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ibùdó Ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló ń fúnni nímọ̀ràn nípa báa ṣe lè tọ́ ọmọ. Àkànṣe ẹ̀dà ìwé ìròyìn Newsweek tí wọ́n gbé jáde lórí ọ̀ràn àwọn ọmọdé, sọ pé àìmọye ìgbà ni “ìsọfúnni wọn máa ń ta kora. Ohun tó tilẹ̀ túbọ̀ ń bani lọ́kàn jẹ́ ni pé ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tóo rò pé ó ṣeé gbára lé, lè má tọ̀nà rárá.” A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ti pèsè ìsọfúnni jaburata láti fi tọ́ àwọn ìdílé sọ́nà, kí wọ́n lè máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí! Ǹjẹ́ o máa ń lo gbogbo ìpèsè táa ń rí gbà látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye?—Mátíù 24:45-47.
10. Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tó múná dóko ṣe ń ṣàǹfààní fún àwọn òbí àtàwọn ọmọ?
10 Ohun kan tó ṣe pàtàkì gidigidi ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé táa ń ṣe déédéé pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀. Kí ó bàa lè kún fún ẹ̀kọ́, kí ó gbádùn mọ́ni, kí ó sì fúnni níṣìírí, a gbọ́dọ̀ máa múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa. Táwọn òbí bá ń jẹ́ káwọn ọmọ wọn sọ tinú wọn jáde, wọ́n á lè mọ ohun tó wà nínú ọkàn àti èrò inú wọn. Ọ̀nà kan táa fi lè mọ̀ bóyá ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé múná dóko ni ṣíṣàkíyèsí bóyá gbogbo mẹ́ńbà ìdílé ló máa ń fojú sọ́nà fún un.
11. (a) Àwọn góńgó wo làwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti gbé kalẹ̀? (b) Kí ni ìyọrísí lílépa tí ọmọdébìnrin ará Japan kan lépa góńgó rẹ̀?
11 Àwọn góńgó táa gbé ka Ìwé Mímọ́ tún máa ń jẹ́ kí ìdílé túbọ̀ dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, ó sì yẹ káwọn òbí ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti gbé góńgó wọ̀nyí kalẹ̀. Lára àwọn góńgó tó bójú mu ni kíka Bíbélì lójoojúmọ́, dídi akéde ìhìn rere náà tó ń ṣe déédéé, àti títẹ̀síwájú dórí ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti ìbatisí. Àwọn góńgó mìíràn lè jẹ́ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, bí ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì, tàbí gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Nígbà tí ọmọdébìnrin ará Japan kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ayumi wà ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ó fi í ṣe góńgó rẹ̀ láti jẹ́rìí fún gbogbo ọmọ kíláàsì rẹ̀. Kí ó lè ru ìfẹ́ olùkọ́ àtàwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sókè, ó gba àṣẹ láti kó àwọn ìtẹ̀jáde mélòó kan táa gbé ka Bíbélì sí ibi ìkówèésí. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́tàlá ni Ayumi ń darí láàárín ọdún mẹ́fà tó fi wà ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ náà. Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn àtàwọn míì nínú ìdílé akẹ́kọ̀ọ́ náà di Kristẹni táa batisí.
12. Báwo làwọn ọmọdé ṣe lè jàǹfààní jù lọ látinú àwọn ìpàdé Kristẹni?
12 Ohun mìíràn tó tún ṣe pàtàkì fún ìlera tẹ̀mí ni lílọ sípàdé déédéé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn pé ‘kí wọ́n má kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà.’ Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìyẹn jẹ́ àṣà wa, torí pé tọmọdé tàgbà ló ń jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. (Hébérù 10:24, 25; Diutarónómì 31:12) A gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọdé láti máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa múra ìpàdé sílẹ̀, nítorí pé ìgbà táa bá lóhùn sí ohun táa bá ń sọ lọ́wọ́ la máa ń jàǹfààní jù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ kékeré kan lè bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ ọ̀rọ̀ tó ṣe ṣókí, tàbí nípa kíka àyọkà ráńpẹ́ nínú ìpínrọ̀ kan, yóò ṣàǹfààní jù lọ bí a bá kọ́ àwọn ọmọ wa láti wá ibi tí ìdáhùn wà, kí wọ́n sì sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara wọn. Ṣé ẹ̀yin òbí alára ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa dídáhùn déédéé lọ́nà tó ṣe gúnmọ́? Ó tún dáa pé kí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé ní Bíbélì, ìwé orin, àti ẹ̀dà ìwé táa ń lò fún ìjíròrò nínú Ìwé Mímọ́.
13, 14. (a) Èé ṣe tó fi yẹ káwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? (b) Kí ni yóò jẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn pápá ṣàǹfààní, kí ó sì máa múnú àwọn ọmọdé dùn?
13 Àwọn òbí tó gbọ́n yóò darí okun ọ̀dọ́ àwọn ọmọ wọn síhà sísin Jèhófà, nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ iṣẹ́ ìwàásù di ohun pàtàkì nínú ìgbésí ayé wọn. (Hébérù 13:15) Àyàfi táwọn òbí bá ń bá àwọn ọmọ wọn ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ni wọ́n fi lè rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ń rí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yíyẹ gbà láti di òjíṣẹ́ “tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Nítorí náà, ìwọ alára ńkọ́? Bóo bá jẹ́ òbí, ṣé o ń ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá? Ṣíṣe èyí yóò jẹ́ kí wọ́n gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, kí ó nítumọ̀ lójú wọn, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn sì so èso rere.
14 Èé ṣe tó fi ṣàǹfààní kí àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn jọ máa ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ láti rí àpẹẹrẹ rere àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé e. Lẹ́sẹ̀ kan náà, á jẹ́ káwọn òbí ṣàkíyèsí báwọn ọmọ wọn ṣe ń ronú, ìṣesí wọn, àti ibi tí òye wọ́n mọ. Rí i dájú pé o ń mú àwọn ọmọ rẹ dání nígbà tóo bá ń lọ́wọ́ nínú onírúurú apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Bó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ọmọ kọ̀ọ̀kan ní àpò òde ẹ̀rí tirẹ̀, kí o sì kọ́ ọ bí yóò ṣe máa tọ́jú rẹ̀ kí ó lè máa wà ní mímọ́ tónítóní. Nípa kíkọ́ àwọn ọmọ déédéé àti nípa fífún wọn níṣìírí, wọn yóò ní ìmọrírì àtinúwá fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, wọn yóò sì rí i pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ ọ̀nà táa lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa.—Mátíù 22:37-39; 28:19, 20.
Gbájú Mọ́ Nǹkan Tẹ̀mí
15. Níwọ̀n bí ó ti ṣe pàtàkì gan-an láti gbájú mọ́ nǹkan tẹ̀mí nínú ìdílé, kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà táa lè gbà ṣe èyí?
15 Gbígbájúmọ́ nǹkan tẹ̀mí nínú ìdílé ṣe kókó. (Sáàmù 119:93) Ọ̀nà kan tóo lè gbà ṣe èyí ni jíjíròrò nǹkan tẹ̀mí pẹ̀lú ìdílé rẹ ní gbogbo ìgbà tí àkókò rẹ̀ bá yọ. Ǹjẹ́ o máa ń jíròrò ẹsẹ Bíbélì ojoojúmọ́ pẹ̀lú wọn? Ṣé àṣà rẹ ni láti máa sọ ìrírí tóo ní nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí láti máa jíròrò àwọn kókó látinú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó dé gbẹ̀yìn “nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà”? Ṣé o máa ń rántí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nínú àdúrà fún ìwàláàyè ojoojúmọ́ àti fún àwọn ohun tó ń pèsè fún wa lọ́pọ̀ yanturu “nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde”? (Diutarónómì 6:6-9) Nígbà táwọn ọmọ rẹ bá rí i pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run hàn nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe, èyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ òtítọ́ di tiwọn.
16. Kí làǹfààní tó wà nínú kíkọ́ àwọn ọmọ láti máa fúnra wọn ṣe ìwádìí?
16 Nígbà míì, àwọn ọmọdé yóò nílò ìtọ́sọ́nà láti lè kojú àwọn ìṣòro àti ipò tó bá yọjú. Dípò sísọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn nígbà gbogbo, kí ló dé tí o ò fi hàn wọ́n bí wọ́n ṣe lè ṣàwárí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan nípa fífún wọn níṣìírí láti fúnra wọn ṣe ìwádìí? Kíkọ́ àwọn ọmọdé láti lo gbogbo ohun èlò àtàwọn ìtẹ̀jáde tí ‘ẹrú olóòótọ́’ pèsè yóò jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (1 Sámúẹ́lì 2:21b) Nígbà tí wọ́n bá sì ń sọ ohun tí wọ́n rí kọ́ nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe nínú Bíbélì fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé yòókù, ńṣe ni ipò tẹ̀mí ìdílé yóò máa sunwọ̀n sí i.
Gbára Lé Jèhófà Pátápátá
17. Èé ṣe tí kò fi yẹ káwọn òbí tó ń dá tọ́ ọmọ sọ̀rètí nù nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn láti di Kristẹni?
17 Àwọn òbí tó ń dá tọ́ ọmọ ńkọ́? Àwọn ìdílé wọ̀nyí tún dojú kọ àfikún ìpèníjà nínú ọ̀ràn ọmọ títọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin òbí tí ẹ ń dá tọ́ ọmọ, ẹ má sọ̀rètí nù o! Ẹ lè kẹ́sẹ járí, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ọ̀ràn ọ̀pọ̀ àwọn òbí tó ń dá tọ́ ọmọ, tí wọ́n gbára lé Ọlọ́run, tí wọ́n fi tìgbọràn-tìgbọràn fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, tí wọ́n sì ti tọ́ àwọn ọmọ àtàtà, tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí dàgbà. (Òwe 22:6) Àmọ́ o, àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí tó ń dá tọ́ ọmọ ní láti gbára lé Jèhófà pátápátá. Wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ pé òun yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 121:1-3.
18. Kí ni àwọn ọmọ wọn ń fẹ́ tó jẹ ti èrò orí àti ti ara tó yẹ káwọn òbí pe àfiyèsí sí, ṣùgbọ́n kí ló yẹ kí wọ́n gbájú mọ́?
18 Àwọn òbí ọlọgbọ́n mọ̀ pé ‘ìgbà rírẹ́rìn-ín wà, ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri sì wà.’ (Oníwàásù 3:1, 4) Àkókò fàájì àti eré ìtura tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó sì jíire ṣe pàtàkì fún títọ́ èrò inú àti ara ọmọdé. Orin tó mọ́yán lórí, pàápàá jù lọ kíkọ orin ìyìn sí Ọlọ́run, yóò ran ọmọ kan lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí rere tí ó lè kópa pàtàkì nínú mímú kí àjọṣe òun pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Kólósè 3:16) Ìgbà èwe tún jẹ́ ìgbà mímúra sílẹ̀ láti di àgbàlagbà tó bẹ̀rù Ọlọ́run, kí gbígbádùn ìgbésí ayé lè máa bá a lọ títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Gálátíà 6:8.
19. Èé ṣe tí ọkàn àwọn òbí fi lè balẹ̀ pé Jèhófà yóò bù kún gbogbo ìsapá wọn bí wọ́n ti ń tọ́ àwọn ọmọ wọn?
19 Jèhófà fẹ́ kí gbogbo ìdílé Kristẹni kẹ́sẹ járí gẹ́gẹ́ bí ìdílé tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, táa sì ń sa gbogbo ipá wa láti ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀, òun yóò bù kún ìsapá wa, yóò sì fún wa lókun táa nílò láti máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ onímìísí. (Aísáyà 48:17; Fílípì 4:13) Rántí pé àǹfààní tóo ní báyìí láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ, kí o sì tọ́ wọn dàgbà ní ààlà, àǹfààní yẹn kì í sì í wá lẹ́ẹ̀mejì. Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, Jèhófà yóò sì bù kún ìsapá rẹ láti gbé ìdílé tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí ró.
Ẹ̀kọ́ Wo La Rí Kọ́?
• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì gan-an láti ra àkókò padà nígbà táa bá ń tọ́ àwọn ọmọ?
• Èé ṣe tí àpẹẹrẹ rere àwọn òbí fi ṣe kókó?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà pàtàkì táa fi lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí?
• Báwo ni ìdílé kan ṣe lè gbájú mọ́ nǹkan tẹ̀mí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Àwọn ìdílé tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, wọ́n ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, wọ́n sì ń jáde òde ẹ̀rí pa pọ̀