“Àwọn Ọkọ̀ Òkun Àwọn Ará Kítímù” Rìn Lójú Òkun Láyé Ọjọ́un
Ọ̀PỌ̀ ogun ojú omi ni wọ́n ti jà ní ìlà oòrùn Òkun Mẹditaréníà. Fojú inú wo ọ̀kan lára irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ tó wáyé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún kí Kristi tó wá sórí ilẹ̀ ayé. Ọkọ̀ òkun onípele mẹ́ta kan tó rọrùn gan-an láti darí, tí wọ́n ń pè ní trireme, ń bá eré lọ. Àwọn atukọ̀ tí wọ́n wà ní ìpele mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, tí iye wọn jẹ́ àádọ́sàn-án [170], ń fi gbogbo agbára wọn tukọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tẹ̀ síwá sẹ́yìn lórí tìmùtìmù aláwọ tí wọ́n jókòó sí.
Ọkọ̀ náà ń sá eré tó tó kìlómítà mẹ́tàlá sí mẹ́tàdínlógún ní wákàtí kan, ó sáré gbanú ìgbì òkun kọjá láti lé ọkọ̀ àwọn ọmọ ogun ọ̀tá bá. Bẹ́ẹ̀ nìyẹn náà ń sá lọ. Nígbà tọ́rọ̀ náà wá dójú ẹ̀, ọkọ̀ àwọn ọ̀tá náà bẹ̀rẹ̀ sí í fì sọ́tùn-ún sósì, ó sì kọ ẹgbẹ́ sí ọkọ̀ tó ń lé e. Ọ̀pá ṣóńṣó olórí idẹ tó wà lára ọkọ̀ tó ń lé e bá dá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lu. Bí pákó rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ nìyẹn, tí omi sì ń gba ibi tó dá lu yẹn rọ́ wọnú rẹ̀. Ni jìnnìjìnnì bá bo àwọn atukọ̀. Àwọn ọmọ ogun mélòó kan tí wọ́n dìhámọ́ra dáadáa nínú ọkọ̀ trireme wá sáré lọ síbi tí wọ́n máa gbà wọnú ọkọ̀ tó ti fọ́ yẹn láti gbógun ti àwọn tó wà ńbẹ̀. Ẹ ò rí i pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ làwọn ọkọ̀ òkun kan láyé ọjọ́un!
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń fẹ́ mọ̀ nípa “Kítímù” àti “àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Kítímù,” nítorí ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀, èyí táwọn kan lára rẹ̀ jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. (Númérì 24:24; Dáníẹ́lì 11:30; Aísáyà 23:1) Ibo ni Kítímù wà láyé ọjọ́un? Kí la mọ̀ nípa àwọn ọkọ̀ òkun tó wà níbẹ̀? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí?
Júù kan tó jẹ́ òpìtàn, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josephus sọ pé Kítímù náà ni “Hétímọsì,” ó sì fi hàn pé òun ni erékùṣù Kípírọ́sì. Bákan náà, ìlú Kítíónì (ìyẹn Sítíọ́mù) tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn erékùṣù náà fi hàn pé Kítímù yìí kan náà ni Kípírọ́sì. Nítorí ibi tó wà, àwọn ọkọ̀ òkun máa ń gbabẹ̀ kọjá bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò wọn, ó sì ń jàǹfààní ibi tó wà yìí torí pé kò jìnnà sáwọn èbúté tó wà ní ìlà oòrùn Òkun Mẹditaréníà. Bákan náà, nítorí ibi tí Kípírọ́sì wà yìí, kò sí bí ò ṣe ní gbè sẹ́yìn ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè méjì tó bá ń bára wọn jagun, yálà kó ran ọ̀kan lára wọn lọ́wọ́ tàbí kó dínà mọ́ ọn kó má bàa lè kọjá.
Àwọn Ará Kípírọ́sì Jọrọ̀ Òkun
Àwọn nǹkan táwọn awalẹ̀pìtàn rí nísàlẹ̀ òkun àti sàréè òkú, àtàwọn ìwé tí wọ́n kọ láyé ọjọ́un, tó fi mọ́ àwọn àwòrán tí wọ́n yà sára àwọn ohun èèlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, mú ká lè fojú inú wo bí ọkọ̀ òkun àwọn ará Kípírọ́sì ṣe rí nígbà náà lọ́hùn-ún. Ọ̀gá làwọn ará Kípírọ́sì ayé ìgbà yẹn tó bá di pé kéèyàn kan ọkọ̀ òkun. Igbó kìjikìji ni erékùṣù yẹn, àwọn èbúté tí ọkọ̀ òkun lè gúnlẹ̀ sí láìséwu sì wà níbẹ̀. Wọ́n máa ń fi igi tí wọ́n bá gé kan ọkọ̀ òkun, wọ́n sì tún máa ń fi dá iná tí wọ́n fi ń yọ́ bàbà, tó jẹ́ ohun àmúṣọrọ̀ tó mú kí òkìkí Kípírọ́sì kàn láyé ọjọ́un.
Àwọn ará Fòníṣíà ò ṣàì kíyè sí báwọn ará Kípírọ́sì ṣe máa ń kó ọ̀pọ̀ nǹkan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè lọ tà, ni wọ́n bá tẹ àwọn ìlú dó sí àwọn ibi tí wọ́n máa ń kẹ́rù wọn gbà. Ọ̀kan lára àwọn ìlú yẹn ni Kítíónì tó wà ní Kípírọ́sì.—Aísáyà 23:10-12.
Nígbà táwọn ọ̀tá pa ìlú Tírè run, ó hàn gbangba pé àwọn èèyàn kan láti ibẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lọ gbé ní Kítímù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ará Fòníṣíà tí wọ́n mọwọ́ òkun dáadáa ran àwọn ará Kípírọ́sì lọ́wọ́ gan-an tí wọ́n fi ní àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń jagun ojú omi. Nítorí ibi tí Kítíónì wà, ààbò ló jẹ́ fún àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Fòníṣíà.
Wọ́n Lọ́wọ́ Nínú Òwò Àgbáyé
Onírúurú nǹkan ni wọ́n ń tà ní ìlà oòrùn Òkun Mẹditaréníà lákòókò tá à ń sọ yìí. Wọ́n máa ń fọkọ̀ òkun kó àwọn nǹkan iyebíye láti Kípírọ́sì lọ sí Kírétè, Sadíníà àti Sísílì tó fi mọ́ àwọn erékùṣù Aegean. Wọ́n ti rí ìṣà àti orù tí wọ́n ń fi òdòdó sí táwọn oníṣòwò kó wá láti Kípírọ́sì nírú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀. Ní Kípírọ́sì, wọ́n tún rí ọ̀pọ̀ ohun èèlò táwọn ará Maisínì, ìyẹn àwọn ará Gíríìsì, fi amọ̀ ṣe. Nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ṣàyẹ̀wò àwọn ègé bàbà tí wọ́n rí ní Sadíníà, wọ́n gbà pé Kípírọ́sì ni wọ́n ti kó wọn wá.
Lọ́dún 1982, wọ́n rí ọkọ̀ òkun kan tó rì lápá ìparí ọ̀rúndún kẹrìnlá ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nítòsí etíkun ní gúúsù orílẹ̀-èdè Tọ́kì. Nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn wa ilẹ̀ abẹ́ òkun níbi tí ọkọ̀ yìí rì sí, wọ́n rí ọ̀pọ̀ nǹkan iyebíye. Lára rẹ̀ ni àwọn ègé bàbà tí wọ́n gbà pé Kípírọ́sì ni wọ́n ti kó wọn wá, oje igi aláwọ̀ yẹ́lò, ìṣà àwọn ará Kénáánì, igi ẹ́bónì, eyín erin, àkójọ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà àti fàdákà tó jẹ́ tàwọn ará Kénáánì, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ará Íjíbítì àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n kó wá láti Íjíbítì. Nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé kan ṣàyẹ̀wò àwọn ohun èèlò amọ̀ tí wọ́n rí nínú ọkọ̀ tó rì náà, wọ́n ní ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Kípírọ́sì lọkọ̀ òkun náà ti wá.
Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, àárín àkókò tí wọ́n fojú bù pé ọkọ̀ yìí rì ni Báláámù mẹ́nu kan àwọn ọkọ̀ òkun tó wá láti Kítímù nínú ọ̀rọ̀ “òwe” rẹ̀. (Númérì 24:15, 24) Ó hàn gbangba pé wọ́n ti mọ àwọn ọkọ̀ òkun Kípírọ́sì káàkiri Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn nígbà yẹn. Àmọ́, báwo làwọn ọkọ̀ wọ̀nyí ṣe rí?
Ọkọ̀ Òkun Àwọn Oníṣòwò
Wọ́n ti rí ọ̀pọ̀ ère ọkọ̀ òkun àti ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi amọ̀ mọ láwọn ibojì òkú ní ìlú Ámátúsì ayé ọjọ́un, tó wà ní Kípírọ́sì. Èyí jẹ́ ká mọ bí àwọn ọkọ̀ òkun Kípírọ́sì ṣe rí. Àwọn kan lára wọn wà ní àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí káwọn èèyàn lè máa lọ wò ó.
Àwọn ère ọkọ̀ òkun náà fi hàn pé òwò ṣíṣe ni wọ́n máa ń lo àwọn ọkọ̀ òkun ìgbà ìjímìjí yẹn fún. Ogún èèyàn ló sábà máa ń tu àwọn ọkọ̀ òkun tó bá kéré díẹ̀. Wọ́n ṣe àwọn ọkọ̀ òkun tó fẹ̀ tó sì jinnú láti máa fi kó èrò àti ẹrù lọ síbi tí kò jìn lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ etíkun Kípírọ́sì. Ọ̀mọ̀wé Pliny Àgbà sọ pé àwọn ará Kípírọ́sì ṣe ọkọ̀ òkun kékeré tí kò fi bẹ́ẹ̀ wúwo tí wọ́n máa ń fi àjẹ̀ wà, èyí tó lè kó ẹrù tó wúwo tó àádọ́ta lé nírínwó [450] àgbá omi.
Ọkọ̀ òkun àwọn oníṣòwò tó tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ tún wà, bí irú èyí tí wọ́n rí nítòsí etíkun lórílẹ̀-èdè Tọ́kì. Àwọn kan lára wọn lè kó ẹrù tó wúwo tó ẹgbọ̀kànlá ó lé àádọ́ta [2,250] àgbá omi. Àwọn ọkọ̀ òkun ńlá lè ní tó àádọ́ta atukọ̀, ìyẹn atukọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan. Àwọn ọkọ̀ náà lè gùn tó ọgbọ̀n mítà, ìyẹn ọgọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà. Òpó ìgbòkun wọn sì lè gùn tó mítà mẹ́wàá, ìyẹn ọgbọ̀n ẹsẹ̀ bàtà.
Ọkọ̀ Ogun Ojú Omi Àwọn Ará “Kítímù” Tí Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Rẹ̀
Ẹ̀mí Jèhófà ló mú kí wòlíì kan sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọkọ̀ òkun yóò . . . wá láti etí òkun Kítímù, wọn yóò sì ṣẹ́ Ásíríà níṣẹ̀ẹ́ dájúdájú.” (Númérì 24:2, 24) Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn nímùúṣẹ? Báwo ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe kan àwọn ọkọ̀ òkun láti Kípírọ́sì? Àwọn “ọkọ̀ òkun” tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé ó “wá láti etí òkun Kítímù” yìí kì í ṣe ọkọ̀ òkun àwọn oníṣòwò tó máa ń rìnrìn àjò déédéé lójú Òkun Mẹditaréníà o. Àwọn ọkọ̀ ogun ojú omi tí wọ́n wá fi ṣọṣẹ́ ni.
Báwọn èèyàn ṣe ń rí i pé ó yẹ káwọn máa yí àwọn ohun táwọn fi ń jagun padà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ọkọ̀ ogun ojú omi tó túbọ̀ yára tó sì lágbára. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwòrán àwọn ọkọ̀ ogun ojú omi táwọn ará Kípírọ́sì kọ́kọ́ ṣe làwọn kan rí ní Ámátúsì. Ọkọ̀ òkun tó wà nínú àwòrán náà dà bíi tàwọn ará Fòníṣíà. Ó gùn, kò sì fẹ̀ púpọ̀. Ó gbẹ́nu sókè lọ́wọ́ ẹ̀yìn, ó sì tẹ̀ sínú. Ó ní ọ̀pá ṣóńṣó olórí idẹ, àwọn apata bìrìkìtì sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ méjèèjì, lápá iwájú àtẹ̀yìn rẹ̀.
Ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe ọkọ̀ òkun tí wọ́n ń pè ní bireme, ìyẹn ọkọ̀ òkun tó ní àwọn atukọ̀ ní ìpele méjì, ilẹ̀ Gíríìsì ni wọ́n sì ti ṣe é. Àwọn ọkọ̀ náà gùn tó mítà mẹ́rìnlélógún, ìyẹn ọgọ́rin ẹsẹ̀ bàtà, wọ́n sì fẹ̀ tó mítà mẹ́ta, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà mẹ́wàá. Àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kọ́kọ́ ń fi ọkọ̀ náà kó, orí ilẹ̀ sì ni wọ́n ti máa ń jà. Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi rí i pé ó máa ṣàǹfààní táwọn bá lè ṣe é kó jẹ́ pé ìpele mẹ́ta làwọn atukọ̀ máa wà dípò ìpele méjì. Wọ́n kan ọkọ̀ náà wọ́n sì ṣe ọ̀pá ṣóńṣó olórí idẹ sí iwájú rẹ̀. Ọkọ̀ òkun náà la wá mọ̀ sí trireme, tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Òkìkí àwọn ọkọ̀ náà kàn nígbà ogun tí wọ́n jà ní Sálámísì (lọ́dún 480 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) nígbà táwọn ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Gíríìsì ṣẹ́gun tàwọn ilẹ̀ Páṣíà.
Nígbà tí Alẹkisáǹdà Ńlá wá ń wá bó ṣe máa sọ àwọn ìlú kan dèyí tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀, ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ òkun trireme lọ sápá ìlà oòrùn láti lọ jagun. Ogun ni wọ́n ṣe àwọn ọkọ̀ òkun náà fún, wọn ò ṣe wọ́n fún ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn lórí agbami òkun, torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ láyè tí wọ́n lè kó àwọn nǹkan sí. Nítorí náà, wọ́n ní láti máa dúró láwọn erékùṣù Aegean kí wọ́n lè kó àwọn nǹkan tí wọ́n nílò kí wọ́n sì ṣe àtúnṣe tó bá yẹ lára àwọn ọkọ̀ náà. Ńṣe ni Alẹkisáńdà fẹ́ rí i pé òun rẹ́yìn àwọn ọmọ ogun Páṣíà pátápátá. Àmọ́ kó tó lè kẹ́sẹ járí, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹ́gun Tírè tó jẹ́ ìlú olódi tó lágbára gan-an. Nígbà tó ń rìnrìn àjò ogun yìí, ó dúró díẹ̀ ní Kípírọ́sì.
Àwọn ará Kípírọ́sì ran Alẹkisáńdà Ńlá lọ́wọ́ nígbà tó sàga ti Tírè (lọ́dún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni). Ọgọ́fà [120] ọkọ̀ òkun ni wọ́n fún un pé kó lò. Bákan náà, àwọn ọba mẹ́ta láti Kípírọ́sì kó àwọn ọmọ ogun wọn lọ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Alẹkisáńdà. Oṣù méje gbáko ni wọ́n jọ fi sàga ti ìlú Tírè. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n ṣẹ́gun Tírè, bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sì ṣe nímùúṣẹ nìyẹn. (Ìsíkíẹ́lì 26:3, 4; Sekaráyà 9:3, 4) Alẹkisáńdà fìmoore hàn, ó gbé àwọn ọba tó wà ní Kípírọ́sì sí ipò ńlá.
Ìmúṣẹ Tó Pabanbarì
Òpìtàn kan ní ọ̀rúndún kìíní, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Strabo, sọ pé Alẹkisáńdà ṣètò pé kí wọ́n kó ọkọ̀ òkun wá láti Kípírọ́sì àti Fòníṣíà láti fi ran òun lọ́wọ́ nígbà tó fẹ́ lọ gbógun ja ilẹ̀ Arébíà. Àwọn ọkọ̀ òkun náà ò fi bẹ́ẹ̀ wúwo wọ́n sì rọrùn-ún tú palẹ̀. Nítorí náà, ọjọ́ méje péré ni wọ́n lò lójú òkun tí wọ́n fi dé Tápúsákù (Tífísà) ní àríwá Síríà. (1 Àwọn Ọba 4:24) Wọ́n wa lọ sí Bábílónì látibẹ̀.
Bí ọ̀rọ̀ kan tó dà bíi pé ó fara sin nínú Bíbélì ṣe ní ìmúṣẹ tó pabanbarì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n sọ ọ́ nìyẹn! Bí Númérì 24:24 ṣe sọ, àwọn ọkọ̀ òkun Alẹkisáńdà Ńlá lọ sí apá ìlà oòrùn láti Makedóníà wọ́n sì ṣẹ́gun Ásíríà. Nígbà tó yá, wọ́n ṣẹ́gun ilẹ̀ ọba Mídíà àti Páṣíà tó jẹ́ alágbára.
Àní àkọsílẹ̀ díẹ̀ tá a rí nípa “àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Kítímù” pàápàá jẹ́ ká mọ bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe nímùúṣẹ lọ́nà tó pabanbarì. Irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn asọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì ò ní ṣàì ṣẹ. Ọ̀pọ̀ lára irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ mọ́ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, nítorí náà, ó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú wọn.
[Máàpù tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÍTÁLÌ
Sadíníà
Sísílì
Òkun Aegean
GÍRÍÌSÌ
Kírétè
LÍBÍYÀ
TỌ́KÌ
KÍPÍRỌ́SÌ
Kítíónì
Tírè
ÍJÍBÍTÌ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àpẹẹrẹ bí trireme, ìyẹn ọkọ̀ ogun ojú omi kan tó jẹ́ tàwọn ará Gíríìsì ṣe rí
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àpẹẹrẹ bí bireme, ìyẹn ọkọ̀ ogun ojú omi kan tó jẹ́ tàwọn ará Fòníṣíà ṣe rí
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Orù tí wọ́n ń fi òdòdó sí tí wọ́n ya àwòrán ọkọ̀ òkun àwọn ará Kípírọ́sì sí lára
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Director of Antiquities and the Cyprus Museum
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń kẹ́rù láyé ọjọ́un, irú bí àwọn tí Aísáyà 60:9 mẹ́nu kàn