Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2024 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
JULY 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 57-59
Jèhófà Máa Ń Jẹ́ Kí Ìsapá Àwọn Alátakò Já sí Asán
“Títí Dé Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”
14 Sítéfánù fìgboyà wàásù káwọn ọ̀tá tó pa á. (Ìṣe 6:5; 7:54-60) Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe “inúnibíni tó lágbára” sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, gbogbo wọn tú ká, wọ́n sì lọ sí Jùdíà àti Samáríà. Àwọn àpọ́sítélì nìkan ló wá kù. Àmọ́, ìyẹn ò dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró. Fílípì lọ sí Samáríà kó lè lọ “wàásù nípa Kristi” níbẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ sì yọrí sí rere. (Ìṣe 8:1-8, 14, 15, 25) Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ìpọ́njú tó wáyé nítorí Sítéfánù mú kí wọ́n tú ká ń lọ títí dé Foníṣíà, Sápírọ́sì àti Áńtíókù, àmọ́ àwọn Júù nìkan ni wọ́n ń wàásù fún. Síbẹ̀, àwọn kan lára wọn tó wá láti Sápírọ́sì àti Kírénè wá sí Áńtíókù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì sọ̀rọ̀, wọ́n ń kéde ìhìn rere Jésù Olúwa.” (Ìṣe 11:19, 20) Lákòókò yẹn, inúnibíni mú kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tàn káàkiri.
15 Lóde òní, ohun kan tó jọ ìyẹn ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Soviet Union. Láàárín ọdún 1950 sí ọdún 1959, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Siberia. Bí wọ́n ṣe tú wọn ká sáwọn ibi àdádó tó wà níbẹ̀ mú kí ìhìn rere náà tàn káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ náà. Kò sí báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ṣe fẹ́ rí owó tí wọ́n á fi rìnrìn àjò lọ síbi tó jìnnà tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) kìlómítà kí wọ́n lè lọ wàásù ìhìn rere! Àmọ́, ìjọba fúnra ẹ̀ ló kó wọn sínú ọkọ̀ tó sì gbé wọn lọ sórílẹ̀-èdè náà. Arákùnrin kan sọ pé: “Ibi tọ́rọ̀ náà wá já sí ni pé àwọn aláṣẹ fúnra wọn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ọkàn tó wà ní Siberia láti mọ òtítọ́.”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
“Ẹ Dúró Gbọn-in, Ẹ Má Yẹsẹ̀”
16 Má ṣe yí ìpinnu ẹ pa dà. Ọba Dáfídì sọ pé òun ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ láé torí pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó ní: “Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run.” (Sm. 57:7) Àwa náà lè jẹ́ adúróṣinṣin, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Ka Sáàmù 112:7.) Ẹ jẹ́ ká wo bí ìdúróṣinṣin ṣe ran Bob tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé wọ́n máa tọ́jú ẹ̀jẹ̀ pa mọ́ síbì kan tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n máa nílò ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sọ pé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, òun máa kúrò nílé ìwòsàn náà láì jáfara. Lẹ́yìn náà Bob sọ pé, “Ohun tí màá ṣe dá mi lójú, mi ò sì bẹ̀rù ohun tó lè ṣẹlẹ̀.”
17 Kó tó di pé Bob lọ sílé ìwòsàn, ó ti pinnu tipẹ́ pé òun ò ní gbẹ̀jẹ̀, ìyẹn ló mú kó jẹ́ adúróṣinṣin. Ohun àkọ́kọ́ tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Ohun kejì ni pé ó fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ ṣe jẹ́ mímọ́, ó sì ṣèwádìí nípa ẹ̀ nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Ìkẹta, ó dá a lójú pé tóun bá pa àṣẹ Jèhófà mọ́, òun máa jàǹfààní títí láé. Torí náà, ìṣòro yòówù kó dé bá wa, àwa náà lè jẹ́ adúróṣinṣin.
JULY 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 60-62
Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá, Ó sì Ń Fẹsẹ̀ Wa Múlẹ̀
it-2 1118 ¶7
Ilé Gogoro
Bí Wọ́n Ṣe Lò Ó Lọ́nà Ìṣàpẹẹrẹ. Jèhófà máa dáàbò bo àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣègbọràn. Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Nítorí ìwọ [Jèhófà] ni ibi ààbò mi, ilé gogoro alágbára tó ń dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.” (Sm 61:3) Àwọn tó mọ bí orúkọ Ọlọ́run ṣe lágbára tó, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, tí wọ́n sì ń kéde orúkọ náà kò ní bẹ̀rù ohunkóhun, torí pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ààbò.”—Owe 18:10; fi wé 1Sa 17:45-47.
it-2 1084 ¶8
Àgọ́
Bíbélì tún lo “àgọ́” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn máa ń pàgọ́ kí wọ́n lè sinmi níbẹ̀, àgọ́ náà sì máa dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn nǹkan bí òjò àti oòrùn. (Jẹ 18:1) Ó máa ń dá àwọn àlejò lójú pé ẹni tó gbà wọ́n lálejò nínú àgọ́ rẹ̀ máa tọ́jú wọn dáadáa, á sì bọ̀wọ̀ fún wọn torí pé wọ́n máa ń tọ́jú àlejò dáadáa nínú àṣà wọn. Torí náà, nígbà tí Ìfihàn 7:15 ń sọ nípa àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn, ó sọ pé Ọlọ́run máa “fi àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n,” ìyẹn túmọ̀ sí pé ó máa tọ́jú wọn, ó sì máa dáàbò bò wọ́n. (Sm 61:3, 4) Àìsáyà sọ ètò tí Síónì tó jẹ́ ìyàwó Ọlọ́run máa ṣe láti múra sílẹ̀ fáwọn ọmọ tó máa bí. Ọlọ́run sọ fún un pé “mú kí ibi àgọ́ rẹ fẹ̀ sí i.” (Ais 54:2) Torí náà, ṣe ló mú kí ibi ààbò táwọn ọmọ rẹ̀ máa wà túbọ̀ fẹ̀ sí i.
Ire Wa Ni Òfin Ọlọ́run Wà Fún
14 Òfin Ọlọ́run kì í yí padà rárá. Ní àkókò rúkèrúdò tí à ń gbé yìí, Jèhófà jẹ́ àpáta atóófaratì, tó wà títí ayé. (Sáàmù 90:2) Ó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Àwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ṣeé gbé gbogbo ara lé—kò dà bí àwọn èròǹgbà ènìyàn tí kò dúró sójú kan. (Jákọ́bù 1:17) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn afìṣemọ̀rònú fi ń sọ pé kíkẹ́ ọmọ lákẹ̀ẹ́bàjẹ́ ló dáa jù. Àmọ́ nígbà tó yá làwọn kan lára wọn tún pàlù dà, tí wọ́n ní ọ̀ràn ò rí báwọn ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ mọ́. Ńṣe ni ọ̀pá ìdiwọ̀n àti ìlànà ayé lórí ọ̀ràn yìí ń lọ tó ń bọ̀, láìdúró sójú kan bí ohun tí atẹ́gùn ń gbé kiri. Ṣùgbọ́n, Ọ̀rọ̀ Jèhófà kò ní àgbéyí. Látọjọ́ táláyé ti dáyé ni Bíbélì ti pèsè ìmọ̀ràn lórí ọ̀ràn fífi ìfẹ́ tọ́ ọmọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ẹ wo bó ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó pé a lè gbára lé ìlànà Jèhófà; kò lè yí padà!
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kejì Sáàmù
62:11. Kò síbi tí Ọlọ́run ti ń gba agbára. Òun gan-an ni orísun agbára. ‘Tirẹ̀ ni okun.’
JULY 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 63-65
“Ìfẹ́ Rẹ Tí Kì Í Yẹ̀ Sàn Ju Ìyè”
Ta Ni Yóò Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run?
17 Báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì sí ọ tó? Ṣé bó ṣe rí lára Dáfídì ló ṣe rí lára rẹ, ẹni tó kọ̀wé pé: “Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sàn ju ìyè, ètè mi yóò gbóríyìn fún ọ. Bí èmi yóò ṣe máa fi ìbùkún fún ọ nìyẹn ní ìgbà ayé mi; èmi yóò máa gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè ní orúkọ rẹ”? (Sáàmù 63:3, 4) Ká sọ tòótọ́, ǹjẹ́ nǹkan kan wà láyé yìí tó sàn ju gbígbádùn ìfẹ́ Ọlọ́run àti jíjẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ lílépa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí ń mówó wọlé sàn ju níní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ayọ̀ tí ń wá látinú níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run? (Lúùkù 12:15) Wọ́n ti sọ ọ́ di túláàsì fáwọn Kristẹni kan rí pé kí wọ́n yàn yálà láti sẹ́ Jèhófà tàbí ká pa wọ́n. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn nínú ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Yàtọ̀ sí àwọn díẹ̀ tó yẹsẹ̀, àwọn Kristẹni arákùnrin wa yàn láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n ṣe tán láti fi ẹ̀mí wọn dí i, bó bá di kàráǹgídá. Àwọn tó fi ìṣòtítọ́ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀ ní ìdánilójú pé àwọn yóò rí ọjọ́ ọ̀la ayérayé gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, a sì mọ̀ pé ayé kò lè fún wa ní èyí. (Máàkù 8:34-36) Àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìyè ayérayé nìkan ló wé mọ́ ọn.
18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe láti wà láàyè títí láé láìsí Jèhófà, gbìyànjú láti fojú inú wo bí pípẹ́ láyé yóò ṣe rí láìsí Ẹlẹ́dàá wa. Ìgbésí ayé òfìfo, tí kò ní ète gidi nínú ni yóò jẹ́. Jèhófà ti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní iṣẹ́ tí ń fúnni láyọ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Nítorí náà, ìdánilójú wà pé nígbà tí Jèhófà, Ọba Awíbẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀, bá fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, yóò kún fún àwọn ohun tó gbámúṣé, tó máa wú wa lórí láti kọ́, tó sì máa wù wá láti ṣe. (Oníwàásù 3:11) Bó ti wù ká ṣèwádìí tó nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí ń bọ̀, a ò lè rí gbogbo “ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run” tán láéláé.—Róòmù 11:33.
“Ẹ Máa Dúpẹ́ Ohun Gbogbo”
Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Kò sí àní-àní pé o máa ń ronú nípa àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí Jèhófà ti pèsè àtèyí tó ń pèsè báyìí títí kan àwọn nǹkan tara. (Diu. 8:17, 18; Ìṣe 14:17) Dípò kó o kàn ronú lóréfèé nípa oore tí Ọlọ́run ń ṣe fún ẹ, o ò ṣe fara balẹ̀ ronú nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tíwọ àtàwọn tó o fẹ́ràn ti rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Tó o bá ń fẹ̀sọ̀ ronú nípa gbogbo ohun rere tí Ẹlẹ́dàá ń ṣe fún ẹ, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì mọyì ẹ.—1 Jòh. 4:9.
Máa Ṣàṣàrò Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé kíkà lè má gba ìsapá rẹpẹtẹ, èèyàn gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ kó tó lè ṣàṣàrò. Ìdí nìyẹn tí ọpọlọ àwa ẹ̀dá aláìpé fi máa ń fẹ́ ṣe ohun tí kò gba ìsapá púpọ̀. Torí náà, ìgbà tí ara wa bá silé, tá a wà níbi tí kò sí ariwo, tí ọkàn wa sì pa pọ̀ ló dáa jù ká ṣe àṣàrò. Onísáàmù náà rí i pé ìgbà tóun bá jí lóru ló wu òun jù lọ láti máa ṣàṣàrò. (Sm. 63:6) Kódà, Jésù tó ní ọpọlọ pípé mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa wá ibi tó parọ́rọ́ láti ṣàṣàrò àti láti gbàdúrà.—Lúùkù 6:12.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Kọ́ni Pẹ̀lú Ìfẹ́
6 Ó máa ń wù wá láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a fẹ́ràn. Nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a fẹ́ràn, àwọn èèyàn máa ń rí bí ayọ̀ wa àti ìtara wa ṣe pọ̀ tó. Àgàgà nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tá a fẹ́ràn. Ó máa ń yá wa lára láti sọ ohun tá a mọ̀ nípa ẹni náà fáwọn èèyàn. A máa ń yìn ín, a máa ń bọlá fún un, a sì máa ń gbèjà ẹ̀. À ń ṣe gbogbo èyí torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ onítọ̀hún, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ànímọ́ ẹ̀ bíi tiwa.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ń Rí Ìtura Lọ́dọ̀ Rẹ?
Ó rọrùn láti wólé ju kéèyàn kọ́lé lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rọrùn fọ́mọ èèyàn láti bani jẹ́ ju kí wọ́n gbéni ró lọ. Níwọ̀n bí àwa èèyàn ti jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la ní kùdìẹ̀-kudiẹ. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20) Kì í pẹ́ ká tó rí àṣìṣe ọmọnìkejì wa, tá a ó sì wá fẹnu ba onítọ̀hún jẹ́. (Sáàmù 64:2-4) Àmọ́ ó máa ń gba ìsapá gan-an ká tó lè jẹ́ni tó ń sọ̀rọ̀ tó gbéni ró.
JULY 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 66-68
Jèhófà Ń Bá Wa Gbé Ẹrù Wa Lójoojúmọ́
Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Dáhùn Àdúrà Wa
15 Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, tó bá máa dáhùn ẹ̀, ó dájú pé ohun tó máa jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ sí i ló máa ṣe fún wa. Torí náà, máa kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà ẹ. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Yoko gbà pé Jèhófà kì í dáhùn àwọn àdúrà òun, síbẹ̀ ó ń ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ Jèhófà. Nígbà tó yá, ó lọ wo inú ìwé tó kọ àwọn ohun tó béèrè náà sí, ó wá rí i pé Jèhófà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dáhùn gbogbo àdúrà náà tán títí kan àwọn ohun tóun ò rántí mọ́. Látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa.—Sm. 66:19, 20.
Máa Fi Ìgbatẹnirò Hàn fún Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ
Jèhófà mí sí ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn orin tàbí sáàmù tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìjọsìn. Fojú inú wo ìṣírí tí àwọn opó àtàwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rí gbà nígbà tí wọ́n bá ń kọrin tí Ọlọ́run mí sí, tó ń rán wọn létí pé Jèhófà jẹ́ “baba” àti “onídàájọ́” fún wọn àti pé ó máa pèsè ìtura fún wọn. (Sáàmù 68:5; 146:9) Àwa náà lè sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí tí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ kò ní gbàgbé fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lógún ọdún, tayọ̀tayọ̀ ni Ruth, tó jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ fi máa ń rántí ọ̀rọ̀ kan tí bàbá kan tó ní ìrírí sọ fún un pé: “Mo gbóríyìn fún ẹ gan-an bó o ṣe ń tọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì yìí lọ́nà rere. Máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.” Ruth sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn mú kórí mí wú gan-an.” Ní tòdodo, “ọ̀rọ̀ rere jẹ́ oògùn tó dára” ó sì lè fún àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ níṣìírí gan-an ju bá a ti rò lọ. (Òwe 15:4, Bíbélì Contemporary English Version) Ǹjẹ́ o lè ronú nípa ohun kan ní pàtó tó o fi lè gbóríyìn látọkànwá fún òbí kan tó ń dá tọ́mọ?
Bàbá Àwọn Ọmọ Aláìníbaba
“BABA àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba . . . ni Ọlọ́run nínú ibùgbé rẹ̀ mímọ́.” (Sáàmù 68:5) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yẹn kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ kan nípa Jèhófà Ọlọ́run pé ó ṣe tán láti pèsè fáwọn tí ìyà ń jẹ. Òfin tó fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tí òbí wọn ti kú jẹ́ ẹ lógún gan-an ni. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ibi tí Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa “ọmọdékùnrin aláìníbaba,” ìyẹn nínú ìwé Ẹ́kísódù 22:22-24.
Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí
17 Ka Sáàmù 40:5. Tẹ́nì kan bá ń gun òkè, ohun tó fẹ́ ni pé kóun gùn ún dé òkè pátápátá. Àmọ́ bó ṣe ń gùn ún lọ, àwọn ibì kan wà tó ti lè dúró kó sì wo àwọn ohun tó wà láyìíká ibẹ̀. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa wáyè ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Ká tó lọ sùn lálẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti ṣe fún mi lónìí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro tí mo ní ò tíì lọ, báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ láti fara dà á?’ Wò ó bóyá wàá rí ohun tí Jèhófà ṣe fún ẹ, bí ò tiẹ̀ ju ẹyọ kan lọ.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kejì Sáàmù
68:18—Àwọn wo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”? Àwọn wọ̀nyí làwọn ọkùnrin tó wà lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn lákòókò tí wọ́n jagun tí wọ́n fi gba Ilẹ̀ Ìlérí. Wọ́n wá yan irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn.—Ẹ́sírà 8:20.
JULY 29–AUGUST 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 69
Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Jésù Tó Wà Nínú Sáàmù 69
Wọ́n Retí Mèsáyà
17 Àwọn èèyàn máa kórìíra Mèsáyà láìnídìí. (Sm. 69:4) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun tó gbọ́ lẹ́nu Jésù, ó ní: “Ká ní èmi kò ti ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹlòmíràn kankan kò ṣe láàárín [àwọn èèyàn náà] ni, wọn kì bá ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan; ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n ti rí, wọ́n sì ti kórìíra èmi àti Baba mi. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti lè mú ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú Òfin wọn ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’ ” (Jòh. 15:24, 25) Lọ́pọ̀ ìgbà “Òfin” túmọ̀ sí àpapọ̀ àwọn ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Jòh. 10:34; 12:34) Àwọn Ìwé Ìhìn rere fi hàn pé àwọn èèyàn kórìíra Jésù, pàápàá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù. Síwájú sí i, Kristi sọ pé: “Ayé kò ní ìdí kankan láti kórìíra yín, ṣùgbọ́n ó kórìíra mi, nítorí mo ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú.”—Jòh. 7:7.
Ẹ Jẹ́ Onítara Fún Ìjọsìn Tòótọ́
7 Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jésù fi bí ìtara tó ní ṣe pọ̀ tó hàn kedere. Kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, nígbà Ìrékọjá ọdún 30 Sànmánì Kristẹni. Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù, nígbà tí wọ́n sì dé tẹ́ńpìlì wọ́n rí “àwọn tí ń ta màlúù àti àgùntàn àti àdàbà àti àwọn onípàṣípààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn.” Kí wá ni Jésù ṣe, ipa wo ló sì ní lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?—Ka Jòhánù 2:13-17.
8 Ohun tí Jésù ṣe àtohun tó sọ ní àkókò yẹn mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ kan tí onísáàmù náà Dáfídì sọ, pé: “Ògédé ìtara fún ilé rẹ ti jẹ mí run.” (Sm. 69:9) Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ewu ló rọ̀ mọ́ ohun tí Jésù ṣe yẹn. Ó ṣe tán, àwọn aláṣẹ tẹ́ńpìlì, àwọn àlùfáà, àwọn akọ̀wé àtàwọn míì ló jẹ́ babaàsàlẹ̀ fún àwọn tó ń ṣe òwò tí wọ́n fi ń kó àwọn èèyàn nífà èyí tó ń wáyé níbẹ̀. Torí náà bí Jésù ṣe ń túdìí àṣírí ìwà àrékérekè wọn tó sì ń sọ èròǹgbà wọn dòfo yìí, ńṣe ló ń forí gbárí pẹ̀lú ẹ̀sìn tó ti fìdí múlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe kíyè sí i gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ náà rí, ó hàn gbangba pé Jésù ní, ‘ìtara fún ilé Ọlọ́run’ tàbí ìtara fún ìjọsìn tòótọ́. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ìtara túmọ̀ sí? Ǹjẹ́ ó yàtọ̀ sí ìjẹ́kánjúkánjú?
g95 10/22 31 ¶4
Ìbàjẹ́ Ọkàn Ha Lè Pa Ọ́ Bí?
Àwọn kan sọ pé, ìbàjẹ́ ọkàn jẹ́ okùnfà kan fún ikú Jésù Kristi, ẹni tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ẹ̀gàn ti bà mí ni ọkàn jẹ́; ọgbẹ́ náà kò sì ṣeé wò.” (Orin Dafidi 69:20, NW ) A ha ní láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí gẹ́lẹ́ gan-an bí ó ṣe wà yìí bí? Bóyá ni kò ni jẹ́ bẹ́ẹ̀, nítorí pé àwọn wákàtí tí ó ṣáájú ikú Jésù kún fún ìrora gógó—kì í ṣe ní ti ara nìkan ṣùgbọ́n ní ti ìmọ̀lára pẹ̀lú. (Matteu 27:46; Luku 22:44; Heberu 5:7) Síwájú sí i, ọkàn tí ó bàjẹ́ lè ṣàlàyé ìdí tí “ẹ̀jẹ̀ àti omi” fi ń tú jáde níbi ọgbẹ́ tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ dá sí Jésù lára, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀. Ìsúnkì ọkàn tàbí ti iṣan ẹ̀jẹ̀ ńlá lè mú kí ẹ̀jẹ̀ sun sínú igbáàyà tàbí sínú àpò ọkàn—awọ tí ó ní omi nínú, tí ó ṣò gbòjògbòjò, tí ó ṣe àpò fún ọkàn-àyà. Dídá èyíkéyìí nínú àwọn méjì yìí lu lè mú kí ohun tí ó dà bí “ẹ̀jẹ̀ àti omi” jáde.—Johanu 19:34.
it-2 650
Ewéko Onímájèlé
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa fún Mèsáyà ní “ewéko onímájèlé” dípò oúnjẹ. (Sm 69:21) Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n fún Jésù Kristi ní wáìnì tí wọ́n pò mọ́ òróòro láti dín ìrora ẹ̀ kù kó tó di pé wọ́n kàn án mọ́gi. Bí Jésù ṣe tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà kho·leʹ (òróòro) tí wọ́n lò nínú Mátíù (27:34) nígbà tí wọ́n ń ṣàkọsílẹ̀ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ ni wọ́n lò ní Sáàmù 69:21 nínú Bíbélì Septuagint ti èdè Gíríìkì. Àmọ́, nígbà tí Ìhìn Rere Máàkù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ó lo òjíá (Mk 15:23), ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “òjíá” ni “ewéko onímájèlé” tàbí “òróòro” náà. Ó sì lè jẹ́ pé òróòro àti òjíá ni wọ́n pò pọ̀ mọ́ wáìnì náà.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ẹ Máa Gbé Ọwọ́ Ìdúróṣinṣin Sókè Nínú Àdúrà
11 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ tọrọ nǹkan kan nìkan ni wọ́n ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ìfẹ́ wa fún Jèhófà Ọlọ́run sún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ká sì máa yìn ín nínú àdúrà tí a ń dá gbà àti èyí táa ń gbà láwùjọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Àní, ní àfikún sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ nǹkan, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn ìbùkún tẹ̀mí àti tara. (Òwe 10:22) Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ sí Ọlọ́run, kí o sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Sáàmù 50:14) Orin àdúrà Dáfídì sì ní àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí yìí nínú: “Ṣe ni èmi yóò máa fi orin yin orúkọ Ọlọ́run, èmi yóò sì fi ìdúpẹ́ gbé e ga lọ́lá.” (Sáàmù 69:30) Kò ha yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àdúrà táa ń gbà láwùjọ àti èyí táa ń dá nìkan gbà?
AUGUST 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 70-72
Máa Sọ Nípa Agbára Ọlọ́run “fún Ìran Tó Ń Bọ̀”
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Kọ́ Agbára Ìwòye Yín!
17 Yíyẹra fún ìdẹkùn Sátánì yóò béèrè pé kóo máa kíyè sára nígbà gbogbo—nígbà mìíràn, yóò béèrè pé kóo jẹ́ onígboyà. Họ́wù, nígbà mìíràn pàápàá o lè rí i pé kì í ṣe ohun tí àwọn ojúgbà rẹ ń ṣe nìkan ni o kò fara mọ́, àní o lè má fara mọ́ ohun tí ayé lápapọ̀ ń ṣe. Dáfídì, onísáàmù náà gbàdúrà pé: “Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá. Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá, títí di ìsinsìnyí, mo sì ń bá a nìṣó ní sísọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.” (Sáàmù 71:5, 17) Ṣùgbọ́n ìgbà wo ló mú ìwà náà dàgbà? Nígbà tó wà léwe ni! Kódà kó tó di pé Dáfídì lọ kojú Góláyátì nínú ìjà wọn tí òkìkí rẹ̀ kàn káyé, ó ti fi ìgboyà àrà ọ̀tọ̀ hàn nínú dídáàbò bo agbo ẹran baba rẹ̀—nípa pípa kìnnìún kan àti béárì kan. (1 Sámúẹ́lì 17:34-37) Ṣùgbọ́n, gbogbo ìgboyà tí Dáfídì fi hàn, Jèhófà ló fi ògo rẹ̀ fún, ó pè é ní “ìgbọ́kànlé [òun] láti ìgbà èwe [òun] wá.” Agbára tí Dáfídì ní láti gbára lé Jèhófà ló jẹ́ kí ó lè kojú àdánwò èyíkéyìí tó dé bá a. Ìwọ pẹ̀lú lè rí i pé bóo bá gbára lé Jèhófà, òun yóò fún ọ ní ìgboyà àti okun tí o nílò láti “ṣẹ́gun ayé.”—1 Jòhánù 5:4.
Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Hùwà Sí Àwọn Àgbàlagbà?
Onísáàmù gbàdúrà pé: “Má ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó; ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀.” (Sáàmù 71:9) Ọlọ́run kì í “gbé” àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń fi ìṣòtítọ́ sìn ín “sọnù,” àní nígbà tí àwọn fúnra wọn bá tilẹ̀ ń ronú pé àwọn ò wúlò mọ́. Onísáàmù ò gbà pé Jèhófà ti pa òun tì; kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọ̀ pé òun gan-an ló yẹ kóun túbọ̀ gbára lé Ẹlẹ́dàá òun bí òun ti ń dàgbà sí i. Jèhófà máa ń fi hàn pé inú òun dùn sí àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. (Sáàmù 18:25) Àwọn Kristẹni bíi tiwa ni Jèhófà máa ń lò láti pèsè irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀.
Bá A Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Kí Àwọn Ọjọ́ Oníwàhálà Tó Dé
4 Tó bá ti pẹ́ tó o ti ń sin Jèhófà, ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ kó o bi ara rẹ. Ìbéèrè náà ni pé, ‘Ní báyìí tí mo ṣì ní agbára àti okun díẹ̀, kí ni máa fi ìyókù ayé mi ṣe?’ Pẹ̀lú ìrírí tó o ti ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, o ní àwọn àǹfààní kan táwọn míì ò ní. O lè sọ àwọn nǹkan tó o ti kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà fáwọn ọ̀dọ́. O lè fún àwọn míì lókun nípa sísọ àwọn ìrírí tó o ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run fún wọn. Dáfídì Ọba tiẹ̀ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá. . . . Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà, fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.”—Sm. 71:17, 18.
5 Báwo lo ṣe lè jẹ́ káwọn míì jàǹfààní látinú ọgbọ́n tó o ti ní látọdún yìí wá? Ṣé o lè ní kí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run wá sílé rẹ kẹ́ ẹ lè jọ gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró? Ṣé o lè ní kí wọ́n bá ẹ jáde òde ẹ̀rí kí wọ́n lè rí bó o ṣe máa ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Élíhù ìgbàanì sọ pé: “Àwọn ọjọ́ ni kí ó sọ̀rọ̀, ògìdìgbó ọdún sì ni ó yẹ kí ó sọ ọgbọ́n di mímọ̀.” (Jóòbù 32:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn àgbà obìnrin tó wà nínú ìjọ pé kí wọ́n fún àwọn míì níṣìírí nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ wọn. Ó sọ pé: “Kí àwọn àgbàlagbà obìnrin jẹ́ . . . olùkọ́ni ní ohun rere.”—Títù 2:3.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 768
Yúfírétì
Ààlà Ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà tí Ọlọ́run ń bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀, ó bá a dá májẹ̀mú pé òun máa fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ilẹ̀ “láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, ìyẹn odò Yúfírétì.” (Jẹ 15:18) Nígbà tó yá, Ọlọ́run tún ìlérí yìí ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Ẹk 23:31; Di 1:7, 8; 11:24; Joṣ 1:4) Kíróníkà Kìíní 5:9 sọ pé ṣáájú ìṣàkóso Dáfídì, àwọn kan nínú ẹ̀yà Rúbẹ́nì mú kí ilẹ̀ wọn fẹ̀ “títí lọ dé àtiwọ aginjù tó wà ní odò Yúfírétì.” Téèyàn bá ń rìnrìn àjò láti “ìlà oòrùn Gílíádì,” ó máa rìn tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) kìlómítà kó tó dé Yúfírétì. Èyí fi hàn pé ṣe làwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì mú kí ilẹ̀ wọn fẹ̀ dé apá ìlà oòrùn Gílíádì títí dé bèbè Aṣálẹ̀ Síríà, aṣálẹ̀ yìí ló sì dé Yúfírétì. (Yoruba Bible sọ pé, “títí dé odò Yufurate”; Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní, sọ pé “títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate.”) Ìlérí tí Jèhófà ṣe yìí kọ́kọ́ ṣẹ nígbà ìṣàkóso Dáfídì àti Sólómọ́nì nígbà tí ààlà ilẹ̀ Ísírẹ́lì dé agbègbè àwọn ará Arémíà ní ilẹ̀ Sóbà. Ilẹ̀ Sóbà yìí wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àríwá ilẹ̀ Síríà, ààlà ilẹ̀ náà sì parí sí etíkun odò Yúfírétì. (2Sa 8:3; 1Ọb 4:21; 1Kr 18:3-8; 2Kr 9:26) Torí pé àwọn èèyàn mọ Odò Yúfírétì dáadáa, wọ́n sábà máa ń pè é ní “Odò.”—Joṣ 24:2, 15; Sm 72:8.
AUGUST 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 73-74
Kí La Lè Ṣe Tá Ò Fi Ní Máa Jowú Àwọn Tí Ò Sin Jèhófà?
Jèhófà Ń Tu Àwọn Tó Rẹ̀wẹ̀sì Nínú
14 Ọmọ Léfì lẹni tó kọ Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin (73). Torí náà, ó láǹfààní láti máa sìn níbi ìjọsìn Jèhófà. Síbẹ̀, ìgbà kan wà tí òun alára rẹ̀wẹ̀sì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ń jowú àwọn agbéraga àti àwọn ẹni burúkú torí pé lójú ẹ̀, wọ́n ń gbádùn ìgbésí ayé wọn. (Sm. 73:2-9, 11-14) Lérò tiẹ̀, gbogbo nǹkan ni wọ́n ní, wọ́n lọ́lá, wọ́n lọ́là, ayé yẹ wọ́n, ọkàn wọn sì balẹ̀. Ohun tí onísáàmù náà rí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a débi tó fi sọ pé: “Ó dájú pé lásán ni mo pa ọkàn mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi mọ́ pé mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.” Kò sí àní-àní pé tí ò bá yí èrò ẹ̀ pa dà, ó lè fi Jèhófà sílẹ̀.
Jèhófà Ń Tu Àwọn Tó Rẹ̀wẹ̀sì Nínú
15 Ka Sáàmù 73:16-19, 22-25. Ọmọ Léfì náà “wọ ibi mímọ́ títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run” tó ṣeé ṣe káwọn olùjọsìn bíi tiẹ̀ wà. Ìyẹn mú kó lè ronú jinlẹ̀, kó sì fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà. Ó wá rí i pé èrò òun kò tọ́ àti pé tóun ò bá ṣàtúnṣe òun lè fi Jèhófà sílẹ̀. Ó tún lóye pé “orí ilẹ̀ tó ń yọ̀” làwọn ẹni burúkú wà, wọ́n á sì “pa run.” Tí ọmọ Léfì náà bá máa borí ìlara àti ìrẹ̀wẹ̀sì, ó ṣe pàtàkì kó máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Torí pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, inú ẹ̀ sì dùn. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn [Jèhófà], kò sí ohun míì tó wù mí ní ayé.”
16 Ohun tá a rí kọ́. Ẹ má ṣe jẹ́ ká jowú àwọn ẹni burúkú tó jọ pé wọ́n ń gbádùn ayé wọn. Tó bá tiẹ̀ dà bíi pé wọ́n ń gbádùn ara wọn, ojú ayé lásán ni, kò sì lè tọ́jọ́. (Oníw. 8:12, 13) Tá a bá ń jowú wọn, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, tá ò bá sì ṣọ́ra a lè fi Jèhófà sílẹ̀. Tó bá jọ pé o ti ń jowú àwọn ẹni burúkú, tètè ṣe ohun tí ọmọ Léfì yẹn ṣe. Fi ìmọ̀ràn Jèhófà sílò, kó o sì bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kẹ́gbẹ́. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju ohunkóhun míì lọ, wàá ní ojúlówó ayọ̀, o ò sì ní kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí “ìyè tòótọ́.”—1 Tím. 6:19.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Mósè
5 Kí ló máa mú kó o kọ̀ láti ‘jẹ̀gbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀’? Má ṣe gbàgbé pé ìgbádùn téèyàn ń rí nínú dídá ẹ̀ṣẹ̀ kì í tọ́jọ́. Máa fi ojú ìgbàgbọ́ wò ó pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Jòh. 2:15-17) Máa ṣe àṣàrò lórí ohun tó máa gbẹ̀yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà. “Orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni” wọ́n wà, “tí a mú wọn wá sí òpin wọn nípasẹ̀ ìpayà òjijì!” (Sm. 73:18, 19) Tó o bá dojú kọ ìdẹwò láti dẹ́ṣẹ̀, bí ara rẹ pé, ‘Ibo ni mo fẹ́ kí ayé mí já sí?’
Sá Fún Àwọn Nǹkan Tí Kò Ní Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dá ẹ Lọ́lá
3 Ohun tí onísáàmù kan sọ fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà máa dá òun lọ́lá. (Ka Sáàmù 73:23, 24.) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dá àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn lọ́lá? Bó ṣe máa ń dá wọn lọ́lá ni pé ó máa ń jẹ́ kí wọ́n rí ìtẹ́wọ́gbà òun, ó sì máa ń bù kún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tí òun fẹ́, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun.—1 Kọ́r. 2:7; Ják. 4:8.
4 Jèhófà tún fi iṣẹ́ ìwàásù dá wa lọ́lá. (2 Kọ́r. 4:1, 7) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń fún wa ní àǹfààní láti máa fi ògo fún Ọlọ́run. Jèhófà ṣe ìlérí kan fún àwọn tó ń fi iṣẹ́ ìwàásù yìn ín tí wọ́n sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Ó ní: “Àwọn tí ń bọlá fún mi ni èmi yóò bọlá fún.” (1 Sám. 2:30) Láìsí àní-àní, Jèhófà ń dá àwọn tó bá ń fògo fún un nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù lọ́lá. Wọ́n ní orúkọ rere lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ti pé wọ́n rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. A sì máa ń sọ̀rọ̀ wọn ní rere nínú ìjọ.—Òwe 11:16; 22:1.
5 Kí ló máa jẹ́ èrè àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà? Bíbélì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wọn. Ó ní: “Òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.” (Sm. 37:34) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run máa dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́ ní ti pé ó máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Sm. 37:29.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 240
Léfíátánì
Sáàmù 74 sọ nípa bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là, ẹsẹ 13 àti 14 sì ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. Ohun kan náà ni “àwọn ẹran ńlá inú òkun” àti “Léfíátánì” tí wọ́n lò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ń tọ́ka sí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe fọ́ orí Léfíátánì túmọ̀ sí bí Jèhófà ṣe ṣẹ́gun Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde kúrò ní Íjíbítì. Àwọn apá Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè Árámáíkì lo “àwọn alágbára Fáráò” dípò “orí Léfíátánì.” (Fi wé Isk 29:3-5, níbi tó ti fi Fáráò wé “ẹran ńlá inú àwọn odò” tó wà láàárín Náílì; tún wo Isk 32:2.) Àìsáyà 27:1 fi Léfíátánì (Bíbélì Mímọ́, “dragoni”) wé ìjọba kan tí àkóso ẹ̀ nasẹ̀ kárí ayé tí Bíbélì sì pe ẹni tó ń darí ẹ̀ ní “ejò” àti “dírágónì.” (Ifi 12:9) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ nípa bí ilẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, torí náà ó dájú pé Bábílónì máa wà lára Léfíátánì tí Jèhófà “yíjú sí.” Àmọ́, ẹsẹ 12 àti 13 mẹ́nu ba Ásíríà àti Íjíbítì náà. Torí náà, Léfíátánì nínú àwọn ẹsẹ yìí dúró fún àjọ tàbí ìjọba kan tó kárí ayé tó sì ń ta ko Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀.
AUGUST 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 75-77
Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Gbéra Ga?
Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Àwọn Tó Ń Sin Ọlọ́run Àtàwọn Tí Kò Sìn Ín
4 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti sọ pé àwọn èèyàn máa jẹ́ olùfẹ́ ara wọn àti olùfẹ́ owó, ó ní wọ́n tún máa jẹ́ ajọra-ẹni-lójú, onírera àti awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga. Ẹ̀mí yìí làwọn tó gbà pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ máa ń ní, bóyá torí ohun tí wọ́n lè ṣe, ẹwà wọn, ọrọ̀ wọn tàbí ipò tí wọ́n wà láwùjọ. Àwọn tó nírú ẹ̀mí yìí fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ kí wọ́n sì máa gbógo fún àwọn. Ọ̀mọ̀wé kan sọ ohun tí agbéraga èèyàn máa ń ṣe, ó ní: “Ó ka ara rẹ̀ sí ọlọ́run kan, ó sì máa ń júbà ara rẹ̀.” Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé agbéraga èèyàn kì í fẹ́ kí ẹlòmíì gbéra ga tàbí fọ́nnu lójú òun.
5 Jèhófà kórìíra ìgbéraga. Bíbélì sọ pé Jèhófà kórìíra “ojú gíga fíofío.” (Òwe 6:16, 17) Ìgbéraga máa ń jẹ́ kéèyàn jìnnà sí Ọlọ́run. (Sm. 10:4) Èṣù lẹni tó ń gbéra ga fìwà jọ. (1 Tím. 3:6) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ti jẹ́ kí ìgbéraga wọ àwọn lẹ́wù. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni Ùsáyà ọba Júdà fi sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àmọ́ nígbà tó yá, Bíbélì sọ pé “gbàrà tí ó di alágbára, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera àní títí dé àyè tí ń fa ìparun, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, tí ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọba Hesekáyà náà hùwà ìgbéraga, àmọ́ ó tètè ronú pìwà dà.—2 Kíró. 26:16; 32:25, 26.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù
75:4, 5, 10—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìwo” dúró fún? Ohun ìjà tó lágbára ni ìwo orí ẹranko jẹ́. Nítorí náà, agbára tàbí okun ni ọ̀rọ̀ náà “ìwo” dúró fún. Jèhófà ń gbé ìwo àwọn èèyàn rẹ̀ ga, ìyẹn ni pé ó ń mú kí wọ́n di ẹni ìgbéga, àmọ́ ńṣe ló ń ‘ké ìwo àwọn ẹni burúkú lulẹ̀.’ Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fún wa pé ká má ṣe ‘gbé ìwo wa ga sí ibi gíga lókè,’ tó túmọ̀ sí pé a kò gbọ́dọ̀ máa gbéra ga tàbí ká máa fẹgẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló ń gbéni ga, ńṣe ló yẹ ká máa wo àwọn ẹrù iṣẹ́ táwọn ará wa ní nínú ètò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló ti wá.—Sáàmù 75:7.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù
76:10—Báwo ni “ìhónú ènìyàn” ṣe lè gbé Jèhófà lárugẹ? Tí Ọlọ́run bá gba àwọn èèyàn láyè láti fi ìhónú hàn sí wa torí pé a jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ó lè yọrí sí ohun tó dára fún wa. A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ láwọn ọ̀nà kan látinú ìyà èyíkéyìí tí wọ́n bá fi jẹ wá. Ìyà tó sì máa jẹ́ ká lè rí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ ni Jèhófà máa ń gbà láyè kí wọ́n fi jẹ wá. (1 Pétérù 5:10) ‘Ọlọ́run máa ń fi ìyókù ìhónú èèyàn di ara rẹ̀ lámùrè.’ Ká ní ìyà náà pọ̀ débi pé ó yọrí sí ikú ńkọ́? Èyí náà lè gbé Jèhófà ga ní ti pé àwọn tó rí i pé a fara da ìnira náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í fògo fún Ọlọ́run.
AUGUST 26–SEPTEMBER 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 78
Ìkìlọ̀ Ni Ìwà Àìṣòótọ́ Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Jẹ́ fún Wa
“Ẹ Máa Rántí Àwọn ọjọ́ Tí Ó Ti Kọjá”—Èé ṣe?
Ó bani nínú jẹ́ pé, lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ ìgbàgbé. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? “Wọ́n yí padà, wọ́n . . . dán Ọlọ́run wò, wọ́n sì ṣe àròpin Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì. Wọn kò rántí ọwọ́ rẹ̀, tàbí ọjọ́ nì tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ ọ̀tá.” (Orin Dáfídì 78:41, 42) Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbígbàgbé tí wọ́n gbàgbé àṣẹ Jèhófà yọrí sí kíkọ̀ tí ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀.—Mátíù 21:42, 43.
Onísáàmù náà fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Èmi óò rántí iṣẹ́ Olúwa: ní tòótọ́ èmi óò rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ àtijọ́. Ṣùgbọ́n èmi óò máa ṣe àṣàrò gbogbo iṣẹ́ rẹ pẹ̀lú, èmi óò sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.” (Orin Dáfídì 77:11, 12) Irú ṣíṣàṣàrò tí ń múni rántí iṣẹ́ ìsìn àtijọ́ tí a fi ìdúróṣinṣin ṣe àti ìṣe onífẹ̀ẹ́ Jèhófà yóò pèsè ìsúnniṣe, ìṣírí, àti ìmọrírì tí a nílò fún wa. Bákan náà, “rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́” lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àárẹ̀ kúrò, ó sì lè ru wá sókè láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, kí a sì di ìfaradà àfòtítọ́ṣe mú.
“Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Láìsí Ìkùnsínú”
16 Téèyàn bá ń ráhùn, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ àti ìṣòro rẹ̀ ló máa gbà á lọ́kàn, kò ní fọkàn sí àwọn ìbùkún tá à ń ní bá a ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tá a bá fẹ́ borí ẹ̀mí ìráhùn, àwọn ìbùkún wọ̀nyí ló yẹ ká jẹ́ kó gbawájú lọ́kàn wa. Bí àpẹẹrẹ, olúkúlùkù wa ni Jèhófà dá lọ́lá, tó jẹ́ ká máa bá òun jẹ́ orúkọ pọ̀. (Aísáyà 43:10) A lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a sì lè bá òun, “Olùgbọ́ àdúrà” sọ̀rọ̀ nígbàkigbà. (Sáàmù 65:2; Jákọ́bù 4:8) À ń gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀ torí a mọ̀ nípa ọ̀ràn tó ńbẹ nílẹ̀, ìyẹn ọ̀rọ̀ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. A sì tún mọ̀ pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. (Òwe 27:11) A láǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. (Mátíù 24:14) Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi sì ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Jòhánù 3:16) Gbogbo wa ló ní àwọn ìbùkún yìí yálà ìṣòro wa pọ̀ tàbí ó kéré.
Báwo Ni Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Jèhófà?
Onísáàmù náà sọ pé: “Ẹ wo bí iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù ti pọ̀ tó!” (Ẹsẹ 40) Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e fi kún un pé: “Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò.” (Ẹsẹ 41) Ẹ kíyè sí i pé, ẹni tó kọ sáàmù yìí ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run léraléra. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí Ọlọ́run dá wọn sílẹ̀ ní Íjíbítì, ìyẹn ìgbà tí wọ́n wà ní aginjù ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ọ̀tẹ̀ àti ìwà àìlọ́wọ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Ọlọ́run, wọ́n ń sọ pé àwọn kò rò pé ó lè bójú tó àwọn, àwọn kò sì rò pé ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Númérì 14:1-4) Ìwé kan táwọn atúmọ̀ Bíbélì máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, “ọ̀nà míì téèyàn lè gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ‘wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i’ ni pé ‘wọ́n mú ọkàn wọn le sí Ọlọ́run’ tàbí ‘wọ́n sọ pé “Rárá” fún Ọlọ́run.’ ” Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run àánú máa ń dárí ji àwọn èèyàn rẹ̀ yìí tí wọ́n bá ronú pìwà dà. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà máa ń pa dà sídìí ìwà búburú wọn, wọ́n á sì tún ṣọ̀tẹ̀, bí wọ́n sì ṣe ń bá a nìṣó nìyẹn.—Sáàmù 78:10-19, 38.
Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà nígbà tí àwọn èèyàn tí kò láyọ̀ lé yìí bá ṣọ̀tẹ̀? Ẹsẹ 40 sọ pé, “Wọn a máa mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́.” Ohun tí ìtúmọ̀ Bíbélì míì sọ ni pé, wọ́n “mú kó ní ẹ̀dùn ọkàn.” Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, ìwà àwọn Hébérù yìí mú kó ní ìrora ọkàn, ìyẹn bí ìgbà tí ìwà ọmọ tó jẹ́ aláìgbọràn àti ọlọ̀tẹ̀ ṣe máa ń mú kí òbí rẹ̀ ní ìrora ọkàn.” Bí ọmọ tí kò gbọ́ràn ṣe lè mú kí àwọn òbí rẹ̀ ní ìrora ọkàn, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà ọ̀tẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”—Ẹsẹ 41.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù
78:24, 25—Kí nìdí tí Bíbélì fi pe mánà ní “ọkà ọ̀run” àti “oúnjẹ àwọn alágbára”? Àwọn áńgẹ́lì ni “àwọn alágbára” tí ibí yìí ń sọ. Àmọ́, kò sí èyíkéyìí nínú ohun tí Bíbélì pe mánà yìí tó fi hàn pé oúnjẹ àwọn áńgẹ́lì ni. Ìdí tó fi jẹ́ “ọkà ọ̀run” ni pé láti ọ̀run ló ti wá. (Sáàmù 105:40) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òkè ọ̀run làwọn áńgẹ́lì tàbí “àwọn alágbára” ń gbé, ọ̀rọ̀ náà “oúnjẹ àwọn alágbára” lè túmọ̀ sí pé Ọlọ́run tó ń gbé òkè ọ̀run ló pèsè rẹ̀. (Sáàmù 11:4) Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà lò láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní mánà ọ̀hún.