ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 37
Fọkàn Tán Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Rẹ
“Ìfẹ́ . . . máa ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó máa ń retí ohun gbogbo.”—1 KỌ́R. 13:4, 7.
ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí nìdí tí ò fi yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ò lè fọkàn tán ẹnikẹ́ni?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn nínú ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí ò lè fọkàn tán ẹnikẹ́ni. Ìdí sì ni pé ohun táwọn oníṣòwò, àwọn olóṣèlú àtàwọn olórí ẹ̀sìn ń fojú wọn rí ò dáa. Kódà, àwọn èèyàn ò lè fọkàn tán ọ̀rẹ́ wọn, àwọn aládùúgbò wọn àtàwọn ará ilé wọn. Kò sì yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu torí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn á jẹ́ aláìṣòótọ́, abanijẹ́ àti ọ̀dàlẹ̀.’ Lédè míì, wọ́n á máa hùwà bíi Sátánì tó ń darí ayé yìí torí pé òun fúnra ẹ̀ ò ṣeé fọkàn tán.—2 Tím. 3:1-4; 2 Kọ́r. 4:4.
2. (a) Àwọn wo la lè fọkàn tán pátápátá? (b) Kí làwọn kan máa ń rò?
2 Torí pé Kristẹni ni wá, a mọ̀ pé a lè fọkàn tán Jèhófà pátápátá. (Jer. 17:7, 8) Ó dá wa lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì ní ‘pa àwa ọ̀rẹ́ ẹ̀ tì láé.’ (Sm. 9:10) A tún lè fọkàn tán Jésù Kristi torí pé ó kú nítorí wa. (1 Pét. 3:18) Àwọn nǹkan tó sì ti ṣẹlẹ̀ sí wa ti jẹ́ ká rí i pé Bíbélì máa ń tọ́ wa sọ́nà. (2 Tím. 3:16, 17) Torí náà, ó dá wa lójú pé a lè fọkàn tán Jèhófà, Jésù àti Bíbélì. Àmọ́ àwọn kan lè máa rò pé, ṣé àwọn á lè fọkàn tán àwọn ará nínú ìjọ ṣá? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló máa jẹ́ ká fọkàn tán wọn?
A NÍLÒ ÀWỌN ARÁKÙNRIN ÀTÀWỌN ARÁBÌNRIN WA
3. Àǹfààní ńlá wo la ní? (Máàkù 10:29, 30)
3 Jèhófà ti yàn wá pé ká wà lára àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀ kárí ayé lónìí. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn, ọ̀pọ̀ ohun rere la sì ń gbádùn torí pé à ń jọ́sìn Jèhófà! (Ka Máàkù 10:29, 30.) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi tiwa wà kárí ayé, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. Èdè wa, àṣà ìbílẹ̀ wa àti bá a ṣe ń múra lè yàtọ̀ sí tiwọn, síbẹ̀ a máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn tó bá tiẹ̀ jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tá a máa rí wọn nìyẹn. Inú wa máa ń dùn láti wà pẹ̀lú wọn ká lè jọ máa yin Jèhófà Bàbá wa ọ̀run, ká sì máa jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan.—Sm. 133:1.
4. Kí nìdí tá a fi nílò àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?
4 Àsìkò yìí gan-an ló ṣe pàtàkì jù pé ká wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Ìdí ni pé nígbà míì, àwọn ló máa ń bá wa gbé àwọn ìṣòro tó dà bí ẹrù tó wúwo. (Róòmù 15:1; Gál. 6:2) Wọ́n tún máa ń gbà wá níyànjú pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, wọ́n sì ń jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. (1 Tẹs. 5:11; Héb. 10:23-25) Báwo ni nǹkan ì bá ṣe rí fún wa ká sọ pé a ò ní àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti dúró sọ́dọ̀ Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì àti ayé burúkú yìí ń gbógun tì wá? Láìpẹ́, Sátánì àtàwọn èèyàn ẹ̀ máa gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run. Àmọ́, ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dúró tì wá!
5. Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fáwọn kan láti fọkàn tán àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn?
5 Ó máa ń ṣòro fáwọn kan láti fọkàn tán àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn. Ó lè jẹ́ torí pé ẹnì kan nínú ìjọ sọ̀rọ̀ àṣírí wọn síta tàbí torí pé ẹnì kan ò mú ìlérí tó ṣe fún wọn ṣẹ. Ó sì lè jẹ́ ẹnì kan nínú ìjọ ló ṣe ohun kan tàbí sọ ohun tó dùn wọ́n gan-an. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kó ṣòro fáwọn kan láti fọkàn tán àwọn míì. Torí náà, kí ló máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti fọkàn tán àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà?
ÌFẸ́ LÓ MÁA JẸ́ KÁ FỌKÀN TÁN ÀWỌN ARÁ
6. Báwo ni ìfẹ́ ṣe lè mú ká fọkàn tán àwọn ará? (1 Kọ́ríńtì 13:4-8)
6 Ìfẹ́ ló máa ń jẹ́ ká fọkàn tánni. Kọ́ríńtì Kìíní orí 13 sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí ìfẹ́ ṣe lè mú ká fọkàn tán àwọn ará tàbí bá a ṣe lè pa dà fọkàn tán àwọn ará tí wọ́n bá tiẹ̀ ti ṣohun tó dùn wá. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4-8.) Bí àpẹẹrẹ, ẹsẹ kẹrin sọ pé “ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere.” Jèhófà máa ń mú sùúrù fún wa tá a bá tiẹ̀ ṣẹ̀ ẹ́. Torí náà, ó yẹ ká máa ní sùúrù fáwọn ará tí wọ́n bá tiẹ̀ ṣe ohun kan tàbí sọ ohun tó dùn wá. Ẹsẹ karùn-ún tún sọ pé: “[Ìfẹ́] kì í tètè bínú. Kì í di èèyàn sínú.” Kò yẹ ká máa ‘di àwọn èèyàn sínú,’ ìyẹn ni pé ká gbé ọ̀rọ̀ kan sọ́kàn, ká má sì gbàgbé ẹ̀, ká wá máa fi hùwà sí onítọ̀hún. Oníwàásù 7:9 sọ pé ká “má ṣe máa yára bínú.” Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa jù ni pé ká fi ohun tó wà nínú Éfésù 4:26 sílò, ó sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ìbínú”!
7. Báwo ni ìlànà tó wà nínú Mátíù 7:1-5 ṣe lè jẹ́ ká fọkàn tán àwọn ará?
7 Nǹkan míì tó máa jẹ́ ká fọkàn tán àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni pé ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n ni káwa náà máa fi wò wọ́n. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í sì í kọ àṣìṣe wọn sílẹ̀, torí náà kò yẹ káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 130:3) Dípò ká máa wo àṣìṣe wọn, ìwà tó dáa tí wọ́n ní àtàwọn ohun tó dáa tí wọ́n lè ṣe ló yẹ ká máa wò. (Ka Mátíù 7:1-5.) Ó yẹ ká gbà pé wọn ò ní ṣe ohun tí ò dáa sí wa torí ìfẹ́ “máa ń gba ohun gbogbo gbọ́.” (1 Kọ́r. 13:7) Jèhófà ò fẹ́ ká fọkàn tán àwọn ará láìnídìí, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ ká fọkàn tán wọn torí àwọn fúnra wọn ti fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán.b
8. Kí ló máa jẹ́ kó o fọkàn tán àwọn ará?
8 Bó ṣe jẹ́ pé ìwà wa ló ń jẹ́ káwọn èèyàn máa bọ̀wọ̀ fún wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé ìwà wa ló máa jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, ó sì lè gba àkókò díẹ̀ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀. Kí ló máa jẹ́ kó o fọkàn tán àwọn ará? Sún mọ́ wọn kó o lè mọ̀ wọ́n dáadáa. Máa bá wọn sọ̀rọ̀ nípàdé. Ẹ jọ máa lọ sóde ìwàásù. Máa mú sùúrù fún wọn, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán. Níbẹ̀rẹ̀, kò pọn dandan kó o sọ gbogbo nǹkan nípa ara ẹ fún ẹni tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀. Bí ẹ bá ṣe ń di ọ̀rẹ́ ara yín sí i, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan míì nípa ara ẹ fún un. (Lúùkù 16:10) Àmọ́, kí lo máa ṣe tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe nǹkan tó fi hàn pé òun ò ṣeé fọkàn tán? Má sọ pé o ò ní bá a ṣọ̀rẹ́ mọ́, ṣe ni kó o jẹ́ kí atẹ́gùn fẹ́ sí ọ̀rọ̀ náà kó o tó ṣèpinnu. Yàtọ̀ síyẹn, má jẹ́ kí nǹkan táwọn èèyàn mélòó kan ṣe sí ẹ mú kó o sọ pé o ò ní fọkàn tán àwọn ará mọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan táwọn èèyàn ṣe ohun tó dùn wọ́n, àmọ́ tí wọ́n ṣì fọkàn tán àwọn míì.
KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN TÓ FỌKÀN TÁN ÀWỌN ÈÈYÀN
9. (a) Kí ni Hánà ṣe tó fi hàn pé ó fọkàn tán àwọn tó ń ṣojú fún Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára wọn ṣàṣìṣe? (b) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ lára Hánà nípa ìdí tó fi yẹ kó o fọkàn tán àwọn tó ń ṣojú fún Jèhófà lónìí? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ 9.)
9 Ṣé arákùnrin kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gan-an ti ṣe nǹkan tó dùn ẹ́ rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hánà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ní àsìkò kan, Élì tó jẹ́ àlùfáà àgbà ló láṣẹ jù lọ nínú ìjọsìn Jèhófà nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́, ìdílé ẹ̀ kì í ṣe àpẹẹrẹ rere. Àwọn ọmọ ẹ̀ táwọn náà jẹ́ àlùfáà máa ń hùwà burúkú, wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe, síbẹ̀ bàbá wọn ò bá wọn wí bó ṣe yẹ. Kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà mú Élì kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà. Àmọ́, Hánà ò sọ pé torí pé Élì ṣì ni àlùfáà àgbà, òun ò ní lọ jọ́sìn mọ́ nínú àgọ́ ìjọsìn tí Jèhófà ti ní kí wọ́n máa jọ́sìn. Nígbà tí Élì rí Hánà tó ń gbàdúrà torí ìdààmú tó bá a, ó sọ pé ó ti mutí yó. Kò tiẹ̀ wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ kó tó bá obìnrin tó ní ẹ̀dùn ọkàn yìí wí. (1 Sám. 1:12-16) Láìka gbogbo ìyẹn sí, Hánà jẹ́jẹ̀ẹ́ pé tí Jèhófà bá fún òun ní ọmọkùnrin kan, òun máa mú un wá sínú àgọ́ ìjọsìn, Élì yìí kan náà lá sì máa bójú tó o. (1 Sám. 1:11) Ṣé ó yẹ kí wọ́n bá àwọn ọmọ Élì wí? Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló bá wọn wí nígbà tó tó àkókò lójú ẹ̀. (1 Sám. 4:17) Nígbà tó yá, Jèhófà fún Hánà ní ọmọkùnrin kan, Sámúẹ́lì lorúkọ ẹ̀.—1 Sám. 1:17-20.
10. Báwo ni Ọba Dáfídì ṣe fọkàn tán àwọn èèyàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun tó dùn ún?
10 Ṣé ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́ ti dalẹ̀ ẹ rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Dáfídì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó ní ọ̀rẹ́ kan tó ń jẹ́ Áhítófẹ́lì. Àmọ́ nígbà tí Ábúsálómù ọmọ Dáfídì fẹ́ gbàjọba mọ́ Dáfídì lọ́wọ́, Áhítófẹ́lì dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ọ̀tẹ̀ náà. Ẹ wo bó ṣe máa dun Dáfídì tó pé ọmọ ẹ̀ àti ẹni tó pè ní ọ̀rẹ́ ẹ̀ ló dà á! Àmọ́ Dáfídì ò sọ pé torí pé wọ́n da òun, òun ò ní fọkàn tán àwọn míì mọ́. Ó ṣì fọkàn tán ọ̀rẹ́ míì tó ń jẹ́ Húṣáì torí pé kò lọ́wọ́ nínú ọ̀tẹ̀ náà. Dáfídì rí i pé Húṣáì ṣeé fọkàn tán torí pé kò fi í sílẹ̀ nígbà ìṣòro yẹn, kódà ó fi ẹ̀mí ẹ̀ wewu nítorí Dáfídì.—2 Sám. 17:1-16.
11. Báwo ni ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Nábálì ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn míì?
11 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ nínú ohun tí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Nábálì ṣe. Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ ló dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ọkùnrin Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Nábálì, ọkùnrin yìí sì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nígbà tó yá, Dáfídì sọ fún Nábálì pé kó fún òun àtàwọn tó wà pẹ̀lú òun ní oúnjẹ, kódà tí oúnjẹ náà ò bá tiẹ̀ pọ̀. Nígbà tí Nábálì sọ pé òun ò ní fún Dáfídì ní oúnjẹ, Dáfídì bínú débi pé ó lóun máa pa gbogbo ọkùnrin tó wà nílé Nábálì. Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Nábálì wá lọ fẹjọ́ sun Ábígẹ́lì, ìyàwó Nábálì. Torí pé òun náà wà lára àwọn tí Dáfídì máa pa tó bá dé, ó tètè lọ bá Ábígẹ́lì kó lè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, káwọn má bàa kú. Dípò kó sá lọ, ó fọkàn tán Ábígẹ́lì pé ó máa gba àwọn sílẹ̀. Ohun tó mú kó fọkàn tán Ábígẹ́lì ni pé gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ó ní làákàyè, ó sì gbọ́n. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn fi hàn pé Ábígẹ́lì ṣeé fọkàn tán lóòótọ́. Ábígẹ́lì fìgboyà bá Dáfídì sọ̀rọ̀ kó má bàa ṣe ohun tó fẹ́ ṣe. (1 Sám. 25:2-35) Ó sì fọkàn tán Dáfídì pé ó máa ṣe ohun tó tọ́.
12. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ọmọlẹ́yìn òun bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń ṣàṣìṣe?
12 Jésù fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ọmọlẹ́yìn òun bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń ṣàṣìṣe. (Jòh. 15:15, 16) Nígbà tí Jémíìsì àti Jòhánù ní kí Jésù fi àwọn sípò pàtàkì nínú Ìjọba ẹ̀, Jésù ò bi wọ́n pé ṣé torí ìyẹn ni wọ́n ṣe ń sin Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì sọ pé wọn ò ní jẹ́ àpọ́sítélì òun mọ́. (Máàkù 10:35-40) Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló sá lọ lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un. (Mát. 26:56) Síbẹ̀, Jésù ò torí ìyẹn sọ pé òun ò ní fọkàn tán wọn mọ́. Jésù mọ àwọn ibi tí wọ́n kù sí, síbẹ̀ ó “nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòh. 13:1) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ mọ́kànlá (11) yẹn kan náà ló ní kí wọ́n máa bójú tó iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ọmọlẹ́yìn tó kù. (Mát. 28:19, 20; Jòh. 21:15-17) Àwọn àpọ́sítélì náà sì fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán torí gbogbo wọn ló jẹ́ olóòótọ́ títí wọ́n fi kú. Torí náà, ó dájú pé Hánà, Dáfídì, ìránṣẹ́ Nábálì, Ábígẹ́lì àti Jésù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fọkàn tán àwọn èèyàn aláìpé.
BÁ A ṢE LÈ PA DÀ FỌKÀN TÁN ÀWỌN ARÁ WA
13. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti fọkàn tán àwọn míì?
13 Ṣé o ti sọ̀rọ̀ àṣírí fún arákùnrin kan rí àmọ́ tó o wá gbọ́ nígbà tó yá pé ó ti sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹlòmíì? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn máa dùn ẹ́ gan-an. Lọ́jọ́ kan, arábìnrin kan sọ ọ̀rọ̀ àṣírí fún alàgbà kan. Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, ṣe ni ìyàwó alàgbà náà pe arábìnrin yẹn, kó lè tù ú nínú. Arábìnrin yẹn wá mọ̀ pé alàgbà yẹn ti sọ ọ̀rọ̀ náà fún ìyàwó ẹ̀. Torí náà, ó ṣòro fún arábìnrin yẹn láti fọkàn tán alàgbà yẹn. Àmọ́ arábìnrin yẹn ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu. Ó lọ sọ̀rọ̀ náà fún alàgbà míì, alàgbà yẹn sì ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà máa fọkàn tán àwọn alàgbà.
14. Kí ló jẹ́ kí arákùnrin kan pa dà fọkàn tán àwọn ará?
14 Ó ti pẹ́ tí arákùnrin kan ti ń bínú sáwọn alàgbà méjì kan torí ó gbà pé wọn ò ṣeé fọkàn tán. Àmọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tí arákùnrin kan tó bọ̀wọ̀ fún sọ, ohun tí arákùnrin náà sọ ni pé: “Àwọn ará wa kọ́ ni ọ̀tá wa, Sátánì ni.” Torí náà, arákùnrin náà ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó gbọ́ yẹn àtohun tó yẹ kóun ṣe. Lẹ́yìn náà, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó sì yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín òun àtàwọn alàgbà méjì náà.
15. Kí ló lè mú kó pẹ́ díẹ̀ ká tó pa dà fọkàn tán àwọn ará? Sọ àpẹẹrẹ kan.
15 Ṣé o ti pàdánù iṣẹ́ ìsìn kan tó ò ń ṣe rí? Ó dájú pé ó máa dùn ẹ́ gan-an. Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́ ni Grete àti ìyá ẹ̀ nígbà tí ìjọba Násì ń ṣàkóso ní Jámánì láwọn ọdún 1930, wọ́n sì tún fòfin de iṣẹ́ wa nígbà yẹn. Grete ló máa ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fáwọn ará. Àmọ́ nígbà táwọn ará mọ̀ pé bàbá ẹ̀ ti ń ta ko ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì, wọ́n gba àǹfààní yẹn lọ́wọ́ ẹ̀ torí wọ́n ń bẹ̀rù pé bàbá ẹ̀ lè dalẹ̀ àwọn ará. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ni ìṣòro tí Grete fara dà. Jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì fi jà, àwọn ará ò fún Grete àti ìyá ẹ̀ ní Ilé Ìṣọ́ kankan, wọn ò sì ní bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá rí wọn lójú ọ̀nà. Ẹ ò rí i pé ó máa dùn wọ́n gan-an! Ọkàn wọn gbọgbẹ́, kódà Grete sọ pé ó pẹ́ gan-an kóun tó dárí ji àwọn ará yẹn, kóun sì tún pa dà fọkàn tán wọn. Nígbà tó yá, ó gbà pé Jèhófà ti dárí jì wọ́n, ó sì yẹ kóun náà dárí jì wọ́n.c
“Àwọn ará wa kọ́ ni ọ̀tá wa, Sátánì ni”
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè pa dà fọkàn tán àwọn ará?
16 Tí irú nǹkan tó dunni wọra yẹn bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè pa dà fọkàn tán àwọn ará. Ó lè gba àkókò díẹ̀, àmọ́ wàá rí i pé ìsapá ẹ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o jẹ oúnjẹ kan tó ní májèlé, ó dájú pé wàá túbọ̀ máa ṣọ́ ohun tó o fẹ́ jẹ. Ó ṣe tán, torí pé o jẹ nǹkan kan tí kò dáa ò sọ pé kó o má jẹun mọ́. Lọ́nà kan náà, kò yẹ ká torí pé ẹnì kan ṣẹ̀ wá, ká wá sọ pé a ò ní fọkàn tán gbogbo àwọn ará yòókù mọ́, tá a sì mọ̀ pé aláìpé làwọn náà. Tá a bá pa dà fọkàn tán àwọn ará, inú wa máa dùn. Á sì rọrùn fún wa láti mọ ohun tá a lè ṣe tó máa jẹ́ káwọn ará máa fọkàn tán ara wọn nínú ìjọ.
17. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fọkàn tán àwọn ará, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Àwọn èèyàn kì í fọkàn tán ara wọn nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. Àmọ́ nínú ètò Ọlọ́run, ìfẹ́ ń mú ká fọkàn tán àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kárí ayé. Bá a ṣe ń fọkàn tán wọn yẹn ń jẹ́ ká wà níṣọ̀kan, a sì ń láyọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa dáàbò bò wá nígbà tá a bá dojú kọ ìṣòro lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ kí lo máa ṣe tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ ẹ́ tó ò sì fọkàn tán an mọ́? Ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan ni kó o fi wo ọ̀rọ̀ náà, máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénú, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì. A lè borí ẹ̀dùn ọkàn tá a ní nígbà táwọn ará ṣẹ̀ wá, ká sì pa dà máa fọkàn tán wọn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú wa máa dùn pé a láwọn ‘ọ̀rẹ́ tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.’ (Òwe 18:24) Àmọ́, kì í ṣe pé ká fọkàn tán àwọn èèyàn nìkan, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó máa jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe táá mú káwọn ará fọkàn tán wa.
ORIN 99 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará
a Ó yẹ ká fọkàn tán àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti fọkàn tán wọn torí wọ́n máa ń ṣohun tó dùn wá nígbà míì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì tá a lè lò, àá sì tún wo bá a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́. Ìyẹn máa jẹ́ ká lè túbọ̀ fọkàn tán àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, á sì tún jẹ́ ká lè pa dà fọkàn tán àwọn ará tí wọ́n bá tiẹ̀ ti ṣohun tó dùn wá.
b Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé àwọn kan wà nínú ìjọ tí kò yẹ ká fọkàn tán. (Júùdù 4) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn èké arákùnrin máa ń sọ “àwọn ọ̀rọ̀ békebèke” kí wọ́n lè ṣi àwọn ará lọ́nà. (Ìṣe 20:30) A ò gbọ́dọ̀ fọkàn tán irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tàbí ká fetí sí wọn.
c Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa ìrírí Arábìnrin Grete, wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—1974, ojú ìwé 129-131 lédè Gẹ̀ẹ́sì.