ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 21
ORIN 107 Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa
Báwo Lo Ṣe Lè Rí Ẹni Tó O Máa Fẹ́?
“Ta ló ti rí aya tó dáńgájíá? Ó níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju iyùn.”—ÒWE 31:10.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ ká mọ béèyàn ṣe lè rí ẹni tó dáa fẹ́ àti báwọn ará ìjọ ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́.
1-2. (a) Kí ló yẹ káwọn Kristẹni tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ gbé yẹ̀ wò kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan sọ́nà? (b) Kí ni “ìfẹ́sọ́nà”? (Wo “Àlàyé Ọ̀rọ̀.”)
TÓ O bá jẹ́ ọkùnrin, ṣé ó wù ẹ́ kó o láya, tó o bá sì jẹ́ obìnrin, ṣé ó wù ẹ́ kó o lọ́kọ? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò dìgbà téèyàn bá ṣègbéyàwó kó tó lè láyọ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà ló ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Àmọ́ kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, bi ara ẹ pé: Ṣé mo ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ṣé mo máa ń hùwà àgbà, ṣé mo sì lówó tí màá fi gbọ́ bùkátà lẹ́yìn ìgbéyàwó?a (1 Kọ́r. 7:36) Tó o bá ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí kó o tó ṣègbéyàwó, ó ṣeé ṣe kó o láyọ̀.
2 Àmọ́ o, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti rí ẹni tó dáa fẹ́. (Òwe 31:10) Kódà nígbà míì, tó o bá rí ẹni tó wù ẹ́ tó o sì fẹ́ mọ ẹni náà dáadáa, báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ẹni náà mọ̀?b Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tó lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà. A tún máa rí báwọn ará ìjọ ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́.
BÓ O ṢE LÈ RÍ ẸNI TÓ DÁA FẸ́
3. Kí làwọn nǹkan tó yẹ kí Kristẹni tó ń wá ẹni tó máa fẹ́ gbé yẹ̀ wò?
3 Tó bá wù ẹ́ láti ṣègbéyàwó, á dáa kó o mọ ohun tó ò ń wá lára ẹni tó o fẹ́ fẹ́ kó o tó bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà. Tí o ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹni tó dáa tó yẹ kó o fẹ́ lè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́ tàbí kó o bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹni tí ò yẹ sọ́nà. Àmọ́ ṣá o, ẹni tó o máa fẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ti ṣèrìbọmi. (1 Kọ́r. 7:39) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ẹni tó ti ṣèrìbọmi lo lè fẹ́. Torí náà, o lè bi ara ẹ pé: ‘Kí làwọn nǹkan tí mo fẹ́ fayé mi ṣe? Àwọn ìwà tó ṣe pàtàkì wo ni mò ń wá lára ẹni tí màá fẹ́? Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń wá ò pọ̀ jù?’
4. Kí làwọn kan máa ń sọ tí wọ́n bá ń gbàdúrà nípa ẹni tí wọ́n máa fẹ́?
4 Tó bá wù ẹ́ pé kó o ṣègbéyàwó, ó dájú pé wàá ti gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó o rẹ́ni tó o máa fẹ́. (Fílí. 4:6) Lóòótọ́, Jèhófà ò ṣèlérí pé òun máa bá ẹnikẹ́ni wá ọkọ tàbí ìyàwó. Àmọ́, ó mọ ohun tó o fẹ́ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rẹ́ni tó o máa fẹ́. Torí náà, máa sọ ohun tó o fẹ́ àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. (Sm. 62:8) Gbàdúrà pé kó jẹ́ kó o ní sùúrù àti ọgbọ́n. (Jém. 1:5) Arákùnrin Johnc tí ò tíì níyàwó tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣàlàyé ohun tóun máa ń sọ tóun bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní: “Mo máa ń sọ àwọn ìwà tí mò ń wá lára ẹni tí màá fẹ́ fún Jèhófà. Mo máa ń sọ fún un pé kó jẹ́ kí n rí ẹni tó ní àwọn ìwà yẹn. Mo tún máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n láwọn ìwà táá jẹ́ kí n di ọkọ rere.” Arábìnrin Tanya tó wá láti orílẹ̀-èdè Sri Lanka sọ pé: “Nígbà tí mò ń wá ẹni tí mo máa fẹ́, mo bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n jẹ́ olóòótọ́, kí n rí i pé nǹkan ṣì máa dáa, kí n sì máa láyọ̀.” Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò tètè rẹ́ni tó o máa fẹ́, Jèhófà ṣèlérí pé òun á máa bójú tó ẹ, òun á sì máa fìfẹ́ hàn sí ẹ.—Sm. 55:22.
5. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè rí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó máa fẹ́? (1 Kọ́ríńtì 15:58) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.) Tó o bá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tó o sì ń wà pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà, wàá gbádùn àjọṣe alárinrin pẹ̀lú wọn. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ń wà pẹ̀lú wọn, ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ táwọn náà ń sin Jèhófà tọkàntọkàn bíi tìẹ. Ohun tó dájú ni pé tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti múnú Jèhófà dùn, wàá láyọ̀.
6. Kí ló yẹ káwọn Kristẹni tí ò tíì rẹ́ni fẹ́ máa rántí?
6 Máa rántí pé: Kì í ṣe bó o ṣe máa rẹ́ni tó o máa fẹ́ ló yẹ kó gbà ẹ́ lọ́kàn jù. (Fílí. 1:10) Ohun tó máa jẹ́ kó o láyọ̀ ni àjọṣe tó dáa tó o ní pẹ̀lú Jèhófà, kì í ṣe torí pé o ti ṣègbéyàwó tàbí o ò tíì ṣe. (Mát. 5:3) Kó o sì máa wò ó o, àsìkò tó ò tíì rẹ́ni fẹ́ yìí lo lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (1 Kọ́r. 7:32, 33) Torí náà, lo àkókò yẹn lọ́nà tó dáa jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Jessica tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ogójì (40) ọdún nígbà tó ṣègbéyàwó. Ó sọ pé: “Nígbà tí mi ò tíì rẹ́ni tí màá fẹ́, iṣẹ́ ìwàásù ni mo gbájú mọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí n láyọ̀.”
FARA BALẸ̀ WO ẸNI TÓ O MÁA FẸ́
7. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o fara balẹ̀ wo ẹni tó o máa fẹ́ kó o tó sọ fún un pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀? (Òwe 13:16)
7 Kí lo máa ṣe tó o bá rẹ́ni tó wù ẹ́? Ṣé ohun tó kàn ni pé kó o sọ fún onítọ̀hún pé o fẹ́ fẹ́ ẹ? Bíbélì sọ pé ẹni tó gbọ́n máa ń ronú jinlẹ̀ kó tó ṣe nǹkan. (Ka Òwe 13:16.) Torí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o fara balẹ̀ wo ẹni náà kó o tó sọ fún un pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ gbọ́ ohun tí Arákùnrin Aschwin tó wá láti orílẹ̀-èdè Netherlands sọ. Ó ní: “Ìfẹ́ tó bá tètè kó séèyàn lórí máa ń tètè lọ. Torí náà, tó o bá fara balẹ̀ wo ẹni náà, kò ní jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lára ẹ ló mú kó o sọ fún un pé o fẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra yín sọ́nà.” Tó bá yá, o lè wá rí i pé kì í ṣe ẹni tó o lè fẹ́.
8. Báwo lo ṣe lè fara balẹ̀ wo ẹni tó o máa fẹ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Báwo lo ṣe lè fara balẹ̀ wo ẹni tó o máa fẹ́, tí ò sì ní fura? Tẹ́ ẹ bá wà nípàdé tàbí níbi ìkórajọ, o lè kíyè sí ìwà ẹni náà àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó. Àwọn wo lọ̀rẹ́ ẹ̀, àwọn nǹkan wo ló máa ń sọ? (Lúùkù 6:45) Ṣé àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lòun náà fẹ́ ṣe? O lè béèrè nípa ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ ẹ̀ tàbí kó o ní káwọn Kristẹni míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n sì mọ̀ ọ́n dáadáa sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀ fún ẹ. (Òwe 20:18) O tún lè wádìí bóyá àwọn èèyàn ń sọ ohun tó dáa nípa ẹ̀. (Rúùtù 2:11) Bó o ṣe ń fara balẹ̀ wo ẹni náà, rí i pé o ò ṣe nǹkan tó máa jẹ́ kó fura torí ara ẹ̀ ò ní balẹ̀ mọ́. Kò yẹ kó o máa tẹ̀ lé e ṣòóṣòó kiri tàbí kó o máa bi í láwọn ìbéèrè tí kò pọn dandan.
9. Kó o tó sọ fún ẹnì kan pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kí ló yẹ kó dá ẹ lójú?
9 Tó o bá ń wo ẹnì kan, báwo ló ṣe yẹ kó pẹ́ tó kó o tó sọ fún un pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀? Tó o bá tètè sọ fún ẹni náà pé o fẹ́ fẹ́ ẹ, ó lè rò pé o kì í ronú jinlẹ̀ kó o tó ṣèpinnu. (Òwe 29:20) Tó bá sì pẹ́ jù kó o tó sọ fún un, tó sì ti mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun, á rò pé o ò ní nǹkan ṣe. (Oníw. 11:4) Àmọ́ rántí o, kó o tó sọ fún ẹnì kan pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, má tíì pinnu pé òun ni wàá fẹ́. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kó dá ẹ lójú pé o ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó, ó sì ṣeé ṣe kíwọ àtẹni náà fẹ́ra.
10. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá kíyè sí i pé ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ ẹ, àmọ́ ìwọ ò nífẹ̀ẹ́ ẹ̀?
10 Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá kíyè sí i pé ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ ẹ? Tó o bá mọ̀ pé o ò nífẹ̀ẹ́ ẹni náà, á dáa kó o tètè jẹ́ kó mọ̀. Kò ní dáa tó o bá ń ṣe bíi pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, nígbà tó o mọ̀ pé o ò ní lè fẹ́ ẹ.—1 Kọ́r. 10:24; Éfé. 4:25.
11. Láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé àwọn míì ló máa ń ṣètò báwọn kan ṣe máa fẹ́ra, kí ló yẹ kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa rántí?
11 Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn òbí tàbí àwọn àgbàlagbà ló máa ń bá mọ̀lẹ́bí wọn wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Láwọn orílẹ̀-èdè míì, ìdílé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ ló máa ń bá àwọn èèyàn wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́, wọ́n á sì ṣètò báwọn méjèèjì ṣe máa pàdé kí wọ́n lè mọ̀ bóyá wọ́n lè máa fẹ́ra wọn sọ́nà. Tí wọ́n bá ní kó o ṣètò báwọn méjì kan ṣe máa fẹ́ra wọn, ronú nípa ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àtohun tó wù wọ́n. Tó o bá ti rí ẹni tẹ́ni náà lè fẹ́, á dáa kó o mọ bí ìwà ẹ̀ àti àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe rí, kó o sì mọ àwọn ànímọ́ tó ní. Ó ṣe pàtàkì kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà ju kéèyàn lówó, kó kàwé rẹpẹtẹ tàbí kó gbayì láwùjọ. Àmọ́, rántí pé arákùnrin àti arábìnrin náà ló máa pinnu bóyá wọ́n máa fẹ́ra tàbí wọn ò ní fẹ́ra.—Gál. 6:5.
BẸ́ Ẹ ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í FẸ́RA YÍN SỌ́NÀ
12. Tó o bá fẹ́ kí ìwọ àti ẹnì kan máa fẹ́ra yín sọ́nà, báwo lo ṣe lè sọ fún un?
12 Tó o bá fẹ́ kí ìwọ àti ẹnì kan máa fẹ́ra yín sọ́nà, báwo lo ṣe lè sọ fún un?d O lè ṣètò bẹ́yin méjèèjì á ṣe sọ̀rọ̀, bóyá níbi táwọn èèyàn wà tàbí kó o pè é lórí fóònù. Lẹ́yìn náà, sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún un. (1 Kọ́r. 14:9) Tó bá sọ pé kó o fún òun lákòókò díẹ̀ kóun lè lọ ronú nípa ẹ̀, ó yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 15:28) Tẹ́ni náà bá sì sọ pé òun ò fẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra, rọra fi í sílẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.
13. Tẹ́nì kan bá sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ, kí lo máa ṣe? (Kólósè 4:6)
13 Tẹ́nì kan bá sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ, kí lo máa ṣe? Má sọ̀rọ̀ àbùkù sí i, ṣe ni kó o bọ̀wọ̀ fún un torí pé ó gba ìgboyà kó tó lè wá bá ẹ. (Ka Kólósè 4:6.) Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa kó o tó fún un lésì, á dáa kó o sọ fún un. Àmọ́, má jẹ́ kó pẹ́ kó o tó fún un lésì. (Òwe 13:12) Tí o ò bá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, má bú u, ṣe ni kó o jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ ò ní lè fẹ́ra yín. Wo bí Arákùnrin Hans tó wá láti orílẹ̀-èdè Austria ṣe fèsì nígbà tí arábìnrin kan sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó sọ pé: “Mi ò kàn án lábùkù, mo sì jẹ́ kó mọ̀ pé a ò ní lè fẹ́ra wa. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo sọ fún un torí mi ò fẹ́ kó rò pé mo ti gbà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo máa ń ṣọ́ bí mo ṣe ń bá arábìnrin náà sọ̀rọ̀, kó má bàa rò pé mo ti yí èrò mi pa dà.” Àmọ́, tó o bá fẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra yín sọ́nà, ẹ jọ sọ ohun tẹ́ ẹ máa ṣe. Ìdí ni pé àṣà ìbílẹ̀ yín lè yàtọ̀ síra àti pé ojú tí ẹ̀yin méjèèjì fi ń wo nǹkan lè má rí bákan náà.
BÁWO LÀWỌN ARÁ ÌJỌ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÁWỌN TÓ Ń WÁ ẸNI TÍ WỌ́N MÁA FẸ́?
14. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́?
14 Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe é ni pé ká máa ṣọ́ ohun tá à ń sọ. (Éfé. 4:29) A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń fi àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ ṣàwàdà? Tí mo bá rí arákùnrin kan tó ń bá arábìnrin kan sọ̀rọ̀, ṣé mo máa ń rò pé wọ́n ń fẹ́ra wọn ni?’ (1 Tím. 5:13) Yàtọ̀ síyẹn, a ò gbọ́dọ̀ máa rò pé nǹkan kan ń ṣe àwọn tí ò tíì lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́. Arákùnrin Hans tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àwọn ará kan máa ń béèrè pé, ‘Kí ló dé tó ò tíì ṣègbéyàwó? Ṣé o ò mọ̀ pé o ti ń dàgbà ni?’ Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń mú káwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ rò pé àwọn ò wúlò. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n rò pé ó yẹ káwọn tètè lọ wá ẹni táwọn máa fẹ́.” Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbóríyìn fáwọn tí ò tíì láya àtàwọn tí ò tíì lọ́kọ.—1 Tẹs. 5:11.
15. (a) Bí Róòmù 15:2 ṣe sọ, kí ló yẹ ká máa rántí ká tó bá arákùnrin tàbí arábìnrin kan wá ẹni tó máa fẹ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo lo kọ́ nínú fídíò yẹn?
15 Tá a bá rí i pé tí arákùnrin àti arábìnrin kan bá fẹ́ra wọn, wọ́n máa láyọ̀ ńkọ́? Bíbélì sọ fún wa pé ká máa gba tàwọn ẹlòmíì rò. (Ka Róòmù 15:2.) Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò tíì lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́ kì í fẹ́ kí wọ́n báwọn wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́, torí náà ó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn, ká má sì fúngun mọ́ wọn. (2 Tẹs. 3:11) Àwọn kan lè fẹ́ ká ran àwọn lọ́wọ́, àmọ́ tí wọn ò bá sọ fún wa, kò yẹ ká tojú bọ̀rọ̀ wọn.e (Òwe 3:27) Àwọn kan ò sì fẹ́ kí wọ́n dìídì sọ pé káwọn fẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin kan. Arábìnrin Lydia tí ò tíì lọ́kọ tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Tó o bá fẹ́ pe àpèjẹ kan, o lè jẹ́ kírú arákùnrin tàbí arábìnrin bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn tó o máa pè wá síbẹ̀. Ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti rí ara wọn, tí arákùnrin tàbí arábìnrin náà bá wá rí i pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan níbẹ̀, ọwọ́ ẹ̀ ló kù sí bóyá òun máa bá a sọ̀rọ̀ tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.”
16. Kí ló yẹ káwọn tí ò tíì lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́ máa rántí?
16 Bóyá a ti ṣègbéyàwó tàbí a ò tíì ṣe, gbogbo wa la lè láyọ̀. (Sm. 128:1) Torí náà, tó bá wù ẹ́ láti ṣègbéyàwó àmọ́ tó ò tíì rí ẹni tó o máa fẹ́, gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Arábìnrin Sin Yi tó wá láti ìlú Macao lórílẹ̀-èdè Ṣáínà sọ pé: “Tó o bá fi àkókò tó o máa lò pẹ̀lú olólùfẹ́ ẹ nínú Párádísè wé àkókò tó ò tíì lẹ́ni tó ò ń fẹ́ báyìí, wàá rí i pé àkókò náà ò tó nǹkan rárá. Torí náà, lo àkókò tó ò tíì lẹ́ni tó ò ń fẹ́ nísinsìnyí lọ́nà tó dáa jù.” Àmọ́ ká sọ pé o ti rí ẹni tó o máa fẹ́ ńkọ́, tẹ́ ẹ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà? Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò bó o ṣe lè mọ̀ bóyá kó o fẹ́ ẹni náà tàbí kó o má fẹ́ ẹ.
ORIN 137 Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa
a Kó o lè mọ̀ bóyá o ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó, wo àpilẹ̀kọ yìí lórí jw.org, “Ìfẹ́sọ́nà—Apá Kìíní: Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?”
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, “ìfẹ́sọ́nà” ni àkókò tí ọkùnrin àti obìnrin kan ń fẹ́ra sọ́nà kí wọ́n lè túbọ̀ mọ ara wọn dáadáa, kí wọ́n sì lè pinnu bóyá àwọn máa ṣègbéyàwó. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìfẹ́sọ́nà ni àkókò tí ọkùnrin àti obìnrin kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ ara wọn. Ìfẹ́sọ́nà máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ọkùnrin kan bá sọ fún obìnrin kan pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí obìnrin náà sì sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Wọ́n á sì máa fẹ́ra wọn sọ́nà títí dìgbà tí wọ́n bá sọ pé àwọn fẹ́ ṣègbéyàwó tàbí káwọn fòpin sí ìfẹ́sọ́nà náà.
c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
d Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, ọkùnrin ló sábà máa ń sọ fún obìnrin pé káwọn máa fẹ́ra sọ́nà. Àmọ́ kò burú tí obìnrin bá sọ fún ọkùnrin pé káwọn máa fẹ́ra sọ́nà. (Rúùtù 3:1-13) Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Mi fún Un?” nínú Jí! November 8, 2004.
e Wo fídíò yìí lórí jw.org, Ìgbàgbọ́ Ń Mú Kí Wọ́n Ja Àjàṣẹ́gun—Àwọn Tí Kò Ní Ọkọ Tàbí Aya.