Ohun Méje Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Oúnjẹ Léwu Táá sì Ṣara Lóore
Ìdí tí ohun tó ò ń jẹ fi ṣe pàtàkì
Oúnjẹ wà lára ohun táá mú kó o ní ìlera tó dáa. Tó o bá ń jẹ oúnjẹ tí kò léwu tó sì ń ṣara lóore déédéé, ìlera rẹ á sunwọ̀n sí i. Ṣùgbọ́n, bí epo ọkọ̀ tí kò dára ṣe lè mú kí ọkọ̀ níṣòro, bẹ́ẹ̀ ni síse oúnjẹ lọ́nà tó léwu àti jíjẹ pàrùpárù oúnjẹ ṣe lè fa àìsàn. Bí ò tiẹ̀ jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó máa wá bópẹ́ bóyá.—Gálátíà 6:7.
Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) sọ pé “gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé làwọn èèyàn ti níṣòro àìrí oúnjẹ aṣaralóore jẹ,” oríṣiríṣi nǹkan lèyí máa ń fà, ó sì ń mú káwọn kan tóbi gìdìgbì tàbí kí wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Tó o bá ń jẹ pàrùpárù oúnjẹ tàbí tó ò ń mu ọtí ẹlẹ́rìndòdò nígbà gbogbo, ó lè jẹ́ kó o tètè ní àrùn ọkàn, rọpárọsẹ̀, ìtọ̀ ṣúgà àti àrùn jẹjẹrẹ. Ìwádìí kan tiẹ̀ sọ pé lọ́dún kan láìpẹ́ yìí, àwọn tó kú torí pé wọn ò róunjẹ tó dáa jẹ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mọ́kànlá. Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú bù ú pé oúnjẹ tí kòkòrò àrùn ti wọ̀ ń pa èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún kan lọ lójoojúmọ́, ó sì ń dá àìsàn sí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lára.
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká fọwọ́ pàtàkì mu ọ̀rọ̀ oúnjẹ tá à ń jẹ. Ó kọ́ wa pé Ọlọ́run ni “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9) Ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn, a sì ń fi hàn pé a mọrírì rẹ̀ tá a bá ń bójú tó ìlera wa àti ti ìdílé wa. Wo ọ̀nà tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.
Ohun mẹ́rin tí ò ní jẹ́ kóúnjẹ léwu
1. Se oúnjẹ lọ́nà tí kò léwu.
Kí nìdí? Àwọn kòkòrò àrùna lè gba inú oúnjẹ àti omi tó ti di ẹlẹ́gbin wọnú ara rẹ kí wọ́n sì fa àìsàn.
Àwọn onímọ̀ nípa ìlera dábàá pé:
Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í se oúnjẹ, fi ọṣẹ àti omi fọ ọwọ́ rẹ.b Fi ọwọ́ méjèèjì gbora wọn fún nǹkan bí ogún ìṣẹ́jú àáyá. Fi ọwọ́ gbo ẹ̀yìn ọwọ́ rẹ méjèèjì àti àárín àwọn ìka ọwọ́ títí kan gbogbo abẹ́ èékánná rẹ. Fi omi ṣan ọwọ́ rẹ kó o sì jẹ́ kó gbẹ dáadáa.
Máa fi ọṣẹ àti omi fọ àwọn pákó tó o fi ń gé nǹkan, àwọn abọ́, àti ohunkóhun tó o bá máa fi oúnjẹ sí. Láfikún sí ìyẹn, má ṣe gé ohun tó o máa sè àti ohun tó ò ní sè níbì kan náà.
Fọ gbogbo èso àti ewébẹ̀ kó o sì tún fi oògùn apakòkòrò sí wọn tó o bá ń gbé ní àdúgbò tí wọ́n ti ń bomi rin ohun ọ̀gbìn tó sì ṣeé ṣe kí ìgbẹ́ ti sọ irú omi bẹ́ẹ̀ di ẹlẹ́gbin.
2. Má ṣe kó oúnjẹ tútù àti oúnjẹ tó o ti sè pa pọ̀.
Kí nìdí? Àwọn kòkòrò àrùn tó wà nínú oúnjẹ tútù, irú bí ẹran àti omi ara ẹran máa kó ìdọ̀tí ba àwọn oúnjẹ yòókù.
Àwọn onímọ̀ nípa ìlera dábàá pé:
Jẹ́ kí oúnjẹ tútù, pàápàá ẹran, àti oúnjẹ sísè, máa wà níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wàá fi kó wọn délé láti ọjà tí wàá sì tọ́jú wọn.
Lẹ́yìn tó o bá gé ẹran tútù, fọ ọwọ́ rẹ, ọ̀bẹ tó o fi gé e àti pátákó tó o fi gé e dáadáa, kó o tó gé nǹkan míì.
3. Jẹ́ kí oúnjẹ tó o bá máa sè jinná dáadáa.
Kí nìdí? Bí oúnjẹ ò bá gbóná tó bó ṣe yẹ, àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn ò ní kú.
Àwọn onímọ̀ nípa ìlera dábàá pé:
Se oúnjẹ títí tá a fi gbóná gan-an. Omi gbọ́dọ̀ hó mọ́ oúnjẹ dáadáa, kó gbóná dénú ẹran dáadáa, ó kéré tán fún nǹkan bí ààbọ̀ ìṣẹ́jú.
Jẹ́ kí ọbẹ̀ tàbí oúnjẹ tó lómi nínú hó dáadáa.
Kó o tó jẹ́ oúnjẹ tó o ti sè tẹ́lẹ̀, gbé e kaná títí táá fi gbóná táá sì máa yọ ooru.
4. Jẹ́ kí oúnjẹ tó yẹ kó gbóná gbóná, kí èyí tó yẹ kó tutù sì tutù.
Kí nìdí? Tó o bá gbé oúnjẹ tí kò gbóná dáadáa kalẹ̀ fún ogún ìṣẹ́jú péré, àwọn kòkòrò àrùn inú rẹ̀ á ti di ìlọ́po méjì. Àti pé, tó ò bá tọ́jú ẹran tútù síbi tó tutù gan-an, àwọn kòkòrò àrùn kan lè pọ oró sí i, tí oró náà ò sì ní kúrò tó o bá sè é
Àwọn onímọ̀ nípa ìlera dábàá pé:
Tó ò bá fẹ́ kí kòkòrò àrùn wọnú oúnjẹ tàbí kó yára pọ̀ sí i tó bá wọnú ẹ̀, jẹ́ kó máa wà ní gbígbóná tàbí tútù, má ṣe jẹ́ kó lọ́ wọ́ọ́wọ́ọ́.
Má ṣe gbé oúnjẹ sínú yàrá ju wákàtí méjì lọ, tàbí kó má ju wákàtí kan lọ bí yàrà náà bá tutù.
Lẹ́yìn tó o bá se oúnjẹ tán, má ṣe jẹ́ kó tutù kó o tó jẹ ẹ́.
Ohun mẹ́ta táá jẹ́ kí oúnjẹ ṣara lóore
1. Máa jẹ oríṣiríṣi èso àti ẹ̀fọ́ lójoojúmọ́.
Èròjà fítámìn àtàwọn èròjà pàtàkì míì tó ń jẹ́ kára jí pépé pọ̀ gan-an nínú èso àti ẹ̀fọ́. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ohun tí ara rẹ ń fẹ́ ni pé kó o máa jẹ èso àti ẹ̀fọ́ nígbà márùn-ún lójoojúmọ́. Àwọn oúnjẹ onítááṣì bí iṣu, ọ̀dùnkún tàbí pákí ò sí lára ìgbà márùn-ún náà.
2. Má máa jẹ ọ̀rá àti òróró ní àjẹjù.
Àjọ Ìlera Àgbáyé dábàá pé kó o dín oúnjẹ dídín àti oúnjẹ inú agolo tó ní èròjà àtọwọ́dá kù, torí pé wọ́n sábà máa ń ní ọ̀rá tó ń ṣàkóbá fún ara. Tó bá ṣeé ṣe, òróró tí ọ̀rá inú rẹ̀ ò pọ̀ ni kó o máa fi se oúnjẹ.c Irú àwọn òróró bẹ́ẹ̀ dáa ju àwọn tí ọ̀rá inú wọn pọ̀.
3. Dín ìyọ àti ṣúgà tó ò ń jẹ kù.
Àjọ Ìlera Àgbáyé dábàá pé káwọn tó ti dàgbà má máa jẹ tó iyọ̀ ṣíbí ìpo-tíì kan lóòjọ́. Àjọ Ìlera Àgbáyé tún dábàá pé kí wọ́n má máa jẹ tó ṣúgà ẹ̀kún ṣíbí ìpo-tíì méjìlá lóòjọ́.d Ṣúgà ló máa ń pọ̀ jù nínú ọ̀pọ̀ oúnjẹ inú agolo àti àwọn ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò. Bí àpẹẹrẹ, ṣúgà tó máa ń wà nínú ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò agolo kan máa ń pọ̀ tó ẹ̀kún ṣíbí ìpo-tíì mẹ́wàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò lè fúnni ní ọ̀pọ̀ kálórì, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣara lóore.
Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́, àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.” (Òwe 22:3) Tó o bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú ọ̀nà tó ò ń gbà jẹun tó o sì ń ṣe ìyípadà èyíkéyìí tó bá yẹ, ò ń fi ìmọrírì hàn fún Ọlọ́run nìyẹn torí ìwàláàyè tó fún ẹ àti ìlera tó fi jíǹkí rẹ.
Èrò tí kò tọ̀nà tó wọ́pọ̀
Èrò tí kò tọ̀nà: Bí oúnjẹ bá fani mọ́ra, tó ń ta sánsán, tó sì dùn, kò léwu.
Òótọ́: Kí omi lítà kan tó rí bí omi tó dọ̀tí, kòkòrò àrùn tó máa wà nínú rẹ̀ á ti ju bílíọ̀nù mẹ́wàá lọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kòkòrò àrùn tó léwu mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún péré lè mú kéèyàn ṣàìsan. Tó o bá ń se oúnjẹ, kó o tó jẹ ẹ́, kó o sì tó tọ́jú ẹ̀, tẹ̀ lé àbá nípa bó ṣe gbọ́dọ̀ gbóná tó àti bó ṣe gbọ́dọ̀ pẹ́ tó lórí iná. Ìyẹn ò ní jẹ́ kí oúnjẹ àti omi tó ò ń mu léwu.
Èrò tí kò tọ̀nà: Eṣinṣin kì í kó ẹgbin bá oúnjẹ.
Òótọ́: Àwọn ẹṣinṣin máa ń jẹ ohun ẹlẹ́gbin bí ìgbẹ́ wọ́n sì máa ń pamọ síbẹ̀, torí náà wọ́n sábà máa ń fi ẹsẹ̀ wọn gbé ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù kòkòrò tó ń fa àrùn káàkiri. Kí àwọn ẹṣinṣin má bàa sọ oúnjẹ tó o fẹ́ jẹ di ẹlẹ́gbin, máa dé e pa pátápátá.
Èrò tí kò tọ̀nà: “Ó pẹ́ tí mo ti ń jẹ oúnjẹ tí kò ṣara lóore débi pé bí mi ò bá tiẹ̀ jẹ ẹ́ mọ́ kò yí nǹkan kan pa dà.”
Òótọ́: Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé tó o bá ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore ní báyìí, ó máa dín àgbákò ikú àìtọ́jọ́ kù, wàá sì jàǹfààní púpọ̀ sí i, tó o bá ń jẹ oúnjẹ tó dáa.
a Ohun alààyè ni àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn, ṣùgbọ́n wọ́n kéré gan-an débi pé o ò lè fi ojúyòójú rí wọn. Lára àwọn kòkòrò àrùn náà ni bakitéríà, fáírọ́ọ̀sì àti onírúurú kòkòrò àrùn míì. Àwọn kan lára àwọn kòkòrò náà ń ṣara lóore, ṣùgbọ́n àwọn tó léwu nínú wọn lè fa jàǹbá tàbí ikú.
b Ọṣẹ àti òmi máa ń pa kòkòrò àrùn tó pọ̀ ju omi nìkan lọ.
c Òróró tí ọ̀rá inú rẹ̀ ò pọ̀ kì í dì pọ̀ tó bá wà níbi tó tutù.
d Lára irú àwọn ṣúgà bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó ní èròjà àtọwọ́dá, bí ṣúgà tá à ń fi sí tíì, oyin àti onírúurú òmi èso. Kì í ṣe àwọn ṣúgà tó máa ń wà nínú èso, ẹ̀fọ́ àti wàrà.