Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àìsàn Bá Dé Láìròtẹ́lẹ̀
Ṣé ìlera ẹ ṣàdédé ń burú sí i? Àìsàn lè mú kí gbogbo nǹkan súni, ó máa ń bani lọ́kàn jẹ́, owó kékeré kọ́ ló sì máa ń náni. Kí ló máa jẹ́ kó o lè fara dà á? Báwo lo ṣe lè ṣèrànwọ́ fún mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ń ṣàìsàn? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn, àmọ́ àwọn ìlànà tó wúlò wà nínú ẹ̀ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ipò tó o wà débi tágbára ẹ lè gbé e dé.
Àwọn àbá tó máa jẹ́ kó o lè fara da àìsàn
Lọ rí dókítà
Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.”—Mátíù 9:12.
Bó o ṣe máa fi í sílò: Jẹ́ kí dókítà ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.
Gbìyànjú èyí: Lọ sílé ìwòsàn tó dára jù lọ lágbègbè rẹ. Nígbà míì, ó lè bọ́gbọ́n mu pé kó o rí ju dókítà kan lọ. (Òwe 14:15) Bá àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn dókítà sọ̀rọ̀ dáadáa, rí i dájú pé o lóye wọn, kó o sì jẹ́ káwọn náà lóye gbogbo ohun tó ń ṣe ẹ́ dáadáa. (Òwe 15:22) Mọ irú àìsàn tó ń ṣe ẹ́, títí kan onírúurú ìtọ́jú tó wà. Tó o bá mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó o lè múra sílẹ̀ láti fara da ipò tó o wà, wàá sì lè ṣe ìpinnu tó dáa nípa bó o ṣe máa gba ìtọ́jú.
Máa tọ́jú ìlera rẹ
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ere-idaraya ti ara ni ere.”—1 Tímótì 4:8, Bíbélì Mímọ́.
Bó o ṣe máa fi í sílò: Tó o bá ń ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ìlera rẹ dáa sí i, bíi ṣíṣe eré ìmárale déédéé, á ṣe ẹ́ láǹfààní.
Gbìyànjú èyí: Máa ṣe eré ìmárale déédéé, máa jẹ́ oúnjẹ aṣaralóore, kó o sì máa lo ọ̀pọ̀ àkókò láti sùn lálaalẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe ẹ́ lè má tíì mọ́ ẹ lára, àmọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n gbà pé tó o bá ń sapá láti ṣe ohun táá jẹ́ kí ìlera ẹ dáa sí i, wàá rí àbájáde rere. Rí i dájú pé, ohunkóhun tó o bá fẹ́ ṣe kò ní jẹ́ kí ìlera ẹ burú sí i, kò sì ní ta ko ìtọ́jú ìṣègùn tí wọ́n fún ẹ.
Jẹ́ kí àwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”—Òwe 17:17.
Bó o ṣe máa fi í sílò: Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lè mú kó o fara dà á lásìkò tí nǹkan nira.
Gbìyànjú èyí: Bá ọ̀rẹ́ rẹ tó ṣe é fọkàn tán, tó o sì lè sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ fún sọ̀rọ̀. Èyí á jẹ́ kára tù ẹ́, wàá sì túbọ̀ láyọ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì, àmọ́ wọ́n lè má mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Torí náà, sọ ohun tí wọ́n máa ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́nà tó máa yé wọ́n. Má ṣàṣejù tó bá kan ohun tó o retí pé kí wọ́n ṣe, kó o sì máa dúpẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe. Àmọ́, rántí pé bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, wọ́n lè ṣe àwọn ohun tó lè mú kí nǹkan sú ẹ nígbà míì. Torí náà, ó yẹ kó o jẹ́ kí wọ́n mọ iye ìgbà tí wọ́n lè wá sọ́dọ̀ ẹ àti bí wọ́n á ṣe máa pẹ́ tó.
Gbà pé ara ẹ máa yá
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọkàn tó ń yọ̀ jẹ́ oògùn tó dára fún ara, àmọ́ ẹ̀mí tí ìdààmú bá máa ń tánni lókun.”—Òwe 17:22.
Bó o ṣe máa fi í sílò: Tó o bá nírètí pé ọ̀la máa dáa, ó máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, wàá sì lè fara da àìsàn tó ń kó ìdààmú bá ẹ.
Gbìyànjú èyí: Bó o ṣe ń mú ara ẹ bá ipò tó o wà mu, àwọn ohun tó o lè ṣe ni kó o gbájú mọ́, kì í ṣe àwọn ohun tó ò lè ṣe. Má fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì, tàbí kó o máa fi bí ìlera ẹ ṣe rí báyìí wé ìgbà tóò tíì ṣàìsàn. (Gálátíà 6:4) Tó o bá ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ ẹ lè tètè tẹ̀, á jẹ́ kó o gbà pé ọ̀la máa dáa, o ò sì ní bọkàn jẹ́. (Òwe 24:10) Máa fáwọn èèyàn ní nǹkan bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ayọ̀ tó wà nínú fífúnni kò ní jẹ́ kó o máa ronú lórí ìṣòro ẹ.—Ìṣe 20:35.
Ṣé Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da àìsàn náà?
Bíbélì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́runa lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti fara da àìsàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò retí pé kí Jèhófà wò wá sàn nípasẹ̀ ìyanu, àmọ́ Ọlọ́run lè ran gbogbo àwọn tó ń sìn ín lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà yìí:
Àlááfíà. Jèhófà lè fún wa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye.” (Fílípì 4:6, 7) Àlááfíà tàbí ìbàlẹ̀ ọkàn yìí kò ní jẹ́ kéèyàn máa ṣàníyàn àṣejù. Gbogbo ẹni tó bá gbàdúrà tó sì sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ fún Ọlọ́run ló máa ń fún ní àlááfíà yìí.—1 Pétérù 5:7.
Òye. Jèhófà lè fún wa ní òye ká lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. (Jémíìsì 1:5) Kéèyàn tó lè ní òye yìí, ẹni náà gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ kó sì fi àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì sílò, kò sígbà táwọn ìlànà yìí kìí wúlò.
Ìrètí ọjọ́ iwájú tó ń gbéni ró. Jèhófà ṣèlérí pé lọ́jọ́ iwájú “kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’” (Àìsáyà 33:24) Ìrètí yìí máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ní èrò pé ọ̀la máa dáa bí wọ́n tiẹ̀ ń fara da àìsàn tó burú jáì.—Jeremáyà 29:11, 12.
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.