Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àìtó Oúnjẹ Tó Kárí Ayé Lónìí?
Àwọn alákòóso ayé ń sapá lójú méjèèjì láti yanjú ìṣòro àìtó oúnjẹ tó kárí ayé. Wọ́n tiẹ̀ máa ń sọ pé láìpẹ́ ebi ò ní pa ẹnikẹ́ni mọ́.a Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ebi ò ní pa ẹnikẹ́ni mọ́? Kí ni Bíbélì sọ?
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àìtó oúnjẹ máa wà lákòókò wa yìí
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àìtó oúnjẹ máa wà lákòókò wa yìí, ó sì pè é ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Ọlọ́run kọ́ ló fà á tí ebi fi ń pa àwa èèyàn, àmọ́ ó kìlọ̀ fún wa pé ó máa ṣẹlẹ̀. (Jémíìsì 1:13) Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí.
“Àìtó oúnjẹ . . . máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.” (Mátíù 24:7) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé oúnjẹ ò ní tó àwọn èèyàn kárí ayé. Àjọ kan tó ń rí sí bí wọ́n ṣe ń pín oúnjẹ kárí ayé sọ pé: “Pàbó ni gbogbo ìsapá àwọn èèyàn láti fòpin sí àìtó oúnjẹ ń já sí. Kódà, kàkà kí ewé àgbọn dẹ̀, líle ló ń le sí i.”b Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ni ebi àpafẹ́ẹ̀kú ń pa kárí ayé, ọ̀pọ̀ nínú wọn lebi ọ̀hún sì ń pa kú.
“Sì wò ó! mo rí ẹṣin dúdú kan, òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì sì wà lọ́wọ́ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀.” (Ìfihàn 6:5) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin ìṣàpẹẹrẹ náà dúró fún ìyàn tó máa mú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn.c Òṣùwọ̀n tó wà lọ́wọ́ ẹlẹ́ṣin náà ń ṣàpẹẹrẹ bí wọ́n á ṣe máa yín oúnjẹ lé àwọn èèyàn lọ́wọ́. Bí ẹlẹ́ṣin náà ṣe ń gẹṣin lọ, ohùn kan ń kìlọ̀ pé owó oúnjẹ máa wọ́n gan-an, àti pé káwọn èèyàn má ṣe fi oúnjẹ ṣòfò. (Ìfihàn 6:6) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ lónìí nìyẹn torí pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn nì ò lówó tí wọ́n lè fi ra oúnjẹ tó ń ṣaralóore, irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ sì ṣọ̀wọ́n láwọn agbègbè míì.
Bí ọ̀rọ̀ ebi tó ń pa àwa èèyàn ṣe máa yanjú
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé oúnjẹ tó wà láyé yìí máa tó láti bọ́ gbogbo èèyàn, kódà àá jẹ àjẹyó àti àjẹsẹ́kù. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí wá ló dé tí oúnjẹ ò fi tó? Kí sì ni Bíbélì sọ pé Jèhófàd Ẹlẹ́dàá wa máa ṣe láti yanjú ìṣòro yìí?
Ìṣòro: Ìjọba èèyàn ò lè fòpin sí ipò òṣì àti bí àwọn jẹgúdújẹrá tó ń walé ayé mọ́yà ṣe ń jẹ́ kébi pa àwọn èèyàn.
Ojútùú: Ọlọ́run máa fi Ìjọba rẹ̀ tó pé rọ́pò ìjọba èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn tálákà ló máa ń ṣiṣẹ́ àṣelàágùn kí wọ́n tó lè rí nǹkan jẹ, àmọ́ ìyẹn máa yí pa dà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì sọ ohun tí Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe, ó ní: “yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀, yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. . . . Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀; ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.”—Sáàmù 72:12, 16.
Ìṣòro: Ogun máa ń ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́, kì í sì í jẹ́ kí ìlú tòòrò, ìyẹn máa ń mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti rí oúnjẹ.
Ojútùú: “[Jèhófà] ń fòpin sí ogun kárí ayé. Ó ṣẹ́ ọrun, ó sì kán ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun nínú iná.” (Sáàmù 46:9) Ọlọ́run máa pa àwọn arógunyọ̀ run, gbogbo ohun ìjà ogun pátápátá ló sì máa rún wómúwómú. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo èèyàn á lè fẹ̀dọ̀ lórí òróòró, wọ́n á sì rí oúnjẹ jẹ́. Bíbélì ṣèlérí pé: “Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀, àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀.”—Sáàmù 72:7.
Ìṣòro: Ojú ọjọ́ tó ń burú sí i àtàwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ máa ń ba irè oko jẹ́, ó sì máa ń pa àwọn ẹran ọ̀sìn.
Ojútùú: Ọlọ́run á dá àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ dúró, á sì mú kí ojú ọjọ́ dáa. Nípa bẹ́ẹ̀, irè oko á lè hù dáadáa. Bíbélì sọ pé: “[Jèhófà] mú kí ìjì náà rọlẹ̀, ìgbì òkun sì pa rọ́rọ́. . . . Ó ń sọ aṣálẹ̀ di adágún omi tí esùsú kún inú rẹ̀, ó sì ń sọ ilẹ̀ gbígbẹ di ìṣàn omi. Ó ń mú kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀ . . . Wọ́n dáko, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà tí irè oko rẹ̀ pọ̀ dáadáa.”—Sáàmù 107:29, 35-37.
Ìṣòro: Àwọn jẹgúdújẹrá máa ń ṣe àwọn oúnjẹ tí ò dáa nítorí èrè àjẹpa, wọ́n kì í sì í jẹ́ kí oúnjẹ gidi dé ọ̀dọ̀ àwọn tó nílò ẹ̀.
Ojútùú: Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn ẹni ibi run. (Sáàmù 37:10, 11; Àìsáyà 61:8) Bíbélì pe Jèhófà Ọlọ́run ní “Ẹni tó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn tí wọ́n lù ní jìbìtì, Ẹni tó ń fún àwọn tí ebi ń pa lóúnjẹ.”—Sáàmù 146:7.
Ìṣòro: Lọ́dọọdún, ìdá kan nínú mẹ́ta oúnjẹ tí wọ́n ń pèsè karí ayé ni wọ́n fi ń ṣòfò.
Ojútùú: Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a ò ní máa fi oúnjẹ ṣòfò mọ́. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó rí i dájú pé òun ò fi oúnjẹ ṣòfò. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó bọ́ àwọn tó jú ẹgbẹ̀rún márùn-ún lọ lọ́nà ìyanu. Nígbà tó yá, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù jọ, kí ohunkóhun má bàa ṣòfò.”—Jòhánù 6:5-13.
Torí pé Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ohun tó ń fa ebi, gbogbo èèyàn máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore ní àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù. (Àìsáyà 25:6) Tó o bá fẹ́ mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe èyí, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?”
a Àjẹ́ńdà Nípa Ìtẹ́síwájú Tó Máa Dé Bá Ohun Ìgbẹ́mìíró Lọ́dún 2030 tí gbogbo àwọn Orílẹ̀-èdè Tó Wà Nínú Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbàyé fọwọ́ sí lọ́dún 2015.
b Ìròyìn látọ̀dọ̀ àwọn àjọ wọ̀nyí, Food and Agriculture Organization of the United Nations, International Fund for Agricultural Development, United Nations Children’s Fund, United Nations World Food Programme, àti World Health Organization.
c Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tó wà nínú ìwé Ìfihàn, ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?”
d Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”