Sunday, December 1
Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?—Ìṣe 8:36.
Ṣé lóòótọ́ ni ọkùnrin ará Etiópíà tó jẹ́ ìjòyè yẹn ṣe tán láti ṣèrìbọmi? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀: Ọkùnrin ará Etiópíà yẹn “lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 8:27) Ó jọ pé ó ti gba ẹ̀sìn Júù. Torí náà, ó dájú pé á ti mọ̀ nípa Jèhófà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Síbẹ̀ ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Nígbà tí Fílípì pàdé ọkùnrin yìí lójú ọ̀nà, ó rí i tó ń ka ìwé àkájọ wòlíì Àìsáyà. (Ìṣe 8:28) Ó fẹ́ mọ̀ sí i. Ó gbéra láti Etiópíà kó lè lọ jọ́sìn Jèhófà ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ọkùnrin ará Etiópíà yẹn kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tuntun kan tó ṣe pàtàkì lọ́dọ̀ Fílípì. Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ náà ni pé Jésù ni Mèsáyà. (Ìṣe 8:34, 35) Ohun tó kọ́ yẹn jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. Torí náà, ó ṣe ìpinnu pàtàkì kan nígbèésí ayé ẹ̀, ìyẹn sì ni pé ó ṣèrìbọmi kó lè di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Nígbà tí Fílípì rí i pé ọkùnrin yẹn ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi, ó ṣèrìbọmi fún un. w23.03 8-9 ¶3-6
Monday, December 2
Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure.—Kól. 4:6.
Tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ máa sọ òótọ́. (Òwe 6:16, 17) Lónìí, àwọn èèyàn máa ń parọ́, wọn ò sì róhun tó burú níbẹ̀. Àmọ́, kò yẹ káwa máa parọ́ torí Jèhófà kórìíra irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Sm. 15:1, 2) Yàtọ̀ sí pé kò yẹ ká máa parọ́, kò tún yẹ ká máa fi òótọ́ pa mọ́ torí pé ìyẹn lè ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Kò sì yẹ ká máa sọ̀rọ̀ àwọn èèyàn láìdáa. (Òwe 25:23; 2 Tẹs. 3:11) Torí náà, tí ìwọ àti ẹnì kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ tó fẹ́ máa ṣòfófó ẹnì kan, o lè fọgbọ́n yí ọ̀rọ̀ náà pa dà, kẹ́ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ tó máa gbéni ró. Nínú ayé táà ń gbé lónìí, àwọn èèyàn máa ń sọ̀sọkúsọ gan-an. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká sì rí i pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa ń múnú Jèhófà dùn. Ó dájú pé ó máa bù kún wa tó bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, nígbà tá a bá wà nípàdé àti nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà bá pa ayé búburú yìí run, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa yìn ín lógo.—Júùdù 15. w22.04 9 ¶18-20
Tuesday, December 3
A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.—1 Jòh. 4:19.
Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà àti Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, àwa náà máa nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Jòh. 4:10) Ìfẹ́ tá a ní fún wọn jinlẹ̀ sí i nígbà tá a mọ̀ pé torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jésù ṣe kú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó sì fi hàn pé òun mọyì ohun tí Jésù ṣe nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn ará Gálátíà, ó ní: “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, [ó] sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gál. 2:20) Ẹbọ ìràpadà Jésù yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti pè ẹ́ wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀, kó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ṣé inú ẹ ò dùn nígbà tó o mọ̀ pé ohun tó dáa tí Jèhófà rí lára ẹ ló mú kó pè ẹ́ àti pé nǹkan ńlá ni Jèhófà san kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti di ọ̀rẹ́ ẹ̀? Ṣé ìyẹn ò mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àti Jésù pọ̀ sí i? Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Kí ni ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí mi máa sọ ọ́ di dandan pé kí n ṣe?’ Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Jésù ń jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.—2 Kọ́r. 5:14, 15; 6:1, 2. w23.01 28 ¶6-7