JULY 29–AUGUST 4
SÁÀMÙ 69
Orin 13 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Jésù Tó Wà Nínú Sáàmù 69
(10 min.)
Wọ́n kórìíra Jésù láìnídìí (Sm 69:4; Jo 15:24, 25; w11 8/15 11 ¶17)
Ìtara ilé Jèhófà gba Jésù lọ́kàn (Sm 69:9; Jo 2:13-17; w10 12/15 8 ¶7-8)
Jésù ní ọgbẹ́ ọkàn tó lágbára, wọ́n sì fún un ní wáìnì tí wọ́n pò mọ́ òróòro (Sm 69:20, 21; Mt 27:34; Lk 22:44; Jo 19:34; g95 10/22 31 ¶4; it-2 650)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ káwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 69:30, 31—Báwo ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè mú kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i? (w99 1/15 18 ¶11)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 69:1-25 (th ẹ̀kọ́ 2)
4. Máa Ní Sùúrù—Ohun Tí Jésù Ṣe
(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 1-2.
5. Máa Ní Sùúrù—Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3-5 àti “Tún Wo.”
Orin 134
6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(5 min.)
7. Àwọn Ohun Tó Lè Mú Kẹ́ Ẹ Túbọ̀ Gbádùn Ìjọsìn Ìdílé Yín
(10 min.) Ìjíròrò.
Ní January 2009, ètò Ọlọ́run sọ pé ọjọ́ kan náà láàárín ọ̀sẹ̀ ni ká máa ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Èyí mú káwọn ìdílé ní ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀ tí wọ́n lè fi ṣe ìjọsìn ìdílé. Inú ọ̀pọ̀ àwọn ará dùn, wọ́n sì mọyì ètò yìí torí pé ó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì sún mọ́ ara wọn nínú ìdílé.—Di 6:6, 7.
Kí làwọn olórí ìdílé lè ṣe káwọn tó wà nínú ìdílé wọn lè gbádùn Ìjọsìn Ìdílé?
Ẹ máa ṣe é déédéé. Tó bá ṣeé ṣe, ẹ ní ọjọ́ kan pàtó tí ẹ̀ẹ́ máa ṣe ìjọsìn ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ sì lè yan ọjọ́ míì tẹ́ ẹ máa ṣe é tó bá ṣẹlẹ̀ pé nǹkan pàjáwìrì kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ máa ń ṣe é gan-an
Múra sílẹ̀. Béèrè ohun tí ìyàwó ẹ ronú pé ẹ lè ṣe, o sì tún lè bi àwọn ọmọ yín nípa ohun tí wọ́n rò. Kò pọn dandan kó o fi ọ̀pọ̀ àkókò múra sílẹ̀, pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn ohun kan wà tẹ́ ẹ sábà máa ń gbádùn láti ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé yín lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀
Jẹ́ kí àwọn ohun tẹ́ ẹ máa ṣe bá ipò ìdílé rẹ mu. Báwọn ọmọ ṣe ń dàgbà, èrò wọn àti ohun tí wọ́n nílò máa ń yí pa dà. Rí i dájú pé ohun tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé túbọ̀ lágbára lẹ̀ ń ṣe
Jẹ́ kí àsìkò náà tu gbogbo yín lára. Nígbà míì, ẹ lè ṣe ìjọsìn ìdílé yín níta tí ojú ọjọ́ bá dáa. Ẹ lè dá ìjọsìn ìdílé yín dúró fún ìṣẹ́jú díẹ̀ nígbàkigbà tẹ́ ẹ bá fẹ́, kẹ́ ẹ lè fi nasẹ̀. Kò sóhun tó burú tẹ́ ẹ bá jíròrò àwọn ìṣòro tẹ́ ẹ ní nínú ìdílé, àmọ́ ẹ má ṣe fi ìjọsìn ìdílé na ara yín lẹ́gba ọ̀rọ̀ tàbí kẹ́ ẹ fi bá ara yín wí
Ẹ máa ṣe onírúurú nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè múra apá ìpàdé kan sílẹ̀, ẹ lè wo fídíò kan lórí jw.org kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀ tàbí kẹ́ ẹ fi àwọn ohun tẹ́ ẹ lè sọ lóde ìwàásù dánra wò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjíròrò ni ìjọsìn ìdílé sábà máa ń jẹ́, ohun míì tẹ́ ẹ tún lè ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé ni pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́
Ẹ dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn ọ̀nà wo lẹ ti gbà lo àwọn àbá yìí nínú ìjọsìn ìdílé yín?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 13 ¶8-16, àpótí ojú ìwé 105