Friday, November 22
Ṣé o ò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá ni?—Lúùkù 23:40.
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀daràn tó ronú pìwà dà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù nígbà tí wọ́n kàn án mọ́gi yẹn jẹ́ Júù. Ọlọ́run kan ṣoṣo làwọn Júù ń sìn, àmọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń sin ọ̀pọ̀ ọlọ́run. (Ẹ́kís. 20:2, 3; 1 Kọ́r. 8:5, 6) Tó bá jẹ́ pé ọ̀daràn yẹn kì í ṣe Júù ni, ìbéèrè tí ì bá wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní ni, “Ṣé o ò bẹ̀rù àwọn ọlọ́run rárá ni?” Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run ò rán Jésù sáwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù” ló rán an sí. (Mát. 15:24) Ọlọ́run ti sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun máa jí àwọn òkú dìde, ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀daràn tó ronú pìwà dà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ohun tó sọ fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà máa jí Jésù dìde láti ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Ó hàn gbangba pé ọkùnrin náà nírètí pé Ọlọ́run máa jí òun dìde. Tó bá jẹ́ pé Júù ni ọ̀daràn tó ronú pìwà dà náà, ó ṣeé ṣe kó mọ̀ nípa Ádámù àti Éfà. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó mọ̀ pé ọgbà kan tó rẹwà, tó sì wà láyé ni Párádísè tí Jésù ń sọ nínú Lúùkù 23:43.—Jẹ́n. 2:15. w22.12 8-9 ¶2-3
Saturday, November 23
Gbogbo wọn tẹra mọ́ àdúrà pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan.—Ìṣe 1:14.
Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká lè máa ṣiṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Sátánì ń gbógun tì wá kó lè dá iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe dúró. (Ìfi. 12:17) Tá a bá fojú èèyàn wò ó, a ò lè borí Sátánì. Àmọ́ bá a ṣe ń wàásù nìṣó, ṣe là ń ṣẹ́gun Sátánì! (Ìfi. 12:9-11) Lọ́nà wo? Tá a bá ń wàásù, ṣe là ń fi hàn pé ẹ̀rù Sátánì ò bà wá bó ṣe ń halẹ̀ mọ́ wa. Gbogbo ìgbà tá a bá ń wàásù, ṣe là ń ṣẹ́gun Sátánì. Torí náà, a lè sọ pé ohun tó ń ràn wá lọ́wọ́ ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa. (Mát. 5:10-12; 1 Pét. 4:14) Ó dá wa lójú pé ẹ̀mí Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro èyíkéyìí tá a bá bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (2 Kọ́r. 4:7-9) Torí náà, kí la lè ṣe kí Ọlọ́run lè máa fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀? Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, kó sì dá wa lójú pé ó máa gbọ́ àdúrà wa. w22.11 5 ¶10-11
Sunday, November 24
Ẹ̀yin ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe ségesège, ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́, ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.—1 Tẹs. 5:14.
A máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn. Táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, a máa ń dárí jì wọ́n bíi ti Jèhófà. Tí Jèhófà bá lè yọ̀ǹda Ọmọ ẹ̀ kó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, ṣé kò wá yẹ káwa náà dárí ji àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá? A ò ní fẹ́ dà bí ẹrú burúkú tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú ọ̀kan lára àkàwé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ọ̀gá rẹ̀ fagi lé gbèsè ńlá tó jẹ, ẹrú yẹn kọ̀ láti dárí ji ẹrú míì tó jẹ ẹ́ ní gbèsè tí ò tó nǹkan. (Mát. 18:23-35) Torí náà, tí èdèkòyédè bá wà láàárín ìwọ àti ẹnì kan nínú ìjọ, ṣé o lè kọ́kọ́ lọ yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ẹni yẹn, kí àlàáfíà lè wà kó o tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi? (Mát. 5:23, 24) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù gan-an. w23.01 29 ¶8-9