Sunday, August 30
Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn.—Sm. 34:18.
Táwọn èèyàn bá ti hùwà ìkà sí ẹ rí, mọ̀ dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, o sì ṣeyebíye lójú ẹ̀. Tí “àárẹ̀ bá [bá] ẹ̀mí” ẹ, máa rántí pé Jèhófà rí ohun rere kan lọ́kàn ẹ, ìdí nìyẹn tó fi fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Kò sígbà tí ò ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ torí pé o ṣeyebíye lójú ẹ̀. Tá a bá wo àpẹẹrẹ Jésù, a máa mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára Jèhófà. Nígbà tí Jésù ń wàásù láyé, ó kíyè sí àwọn tí wọ́n ń fojú àbùkù wò, ó sì ṣàánú wọn. (Mát. 9:9-12) Nígbà tí obìnrin kan tó ń ṣàìsàn tó le gan-an fọwọ́ kan aṣọ Jésù, ó mọ̀ pé ara òun máa yá, torí náà Jésù tù ú nínú, ó sì gbóríyìn fún un torí pé ó nígbàgbọ́. (Máàkù 5:25-34) Ohun tí Jésù ṣe yìí fi hàn pé ó fìwà jọ Bàbá ẹ̀ láìkù síbì kan. (Jòh. 14:9) Torí náà, mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì ẹ, ó sì ń kíyè sí àwọn ìwà rere tó o ní, ìgbàgbọ́ tó o ní àti bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. w24.10 7 ¶4-5
Monday, August 31
Gba omijé mi sínú ìgò awọ rẹ.—Sm. 56:8.
Nígbà ayé Dáfídì, ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ní tó mú kó sunkún. Àwọn èèyàn kórìíra ẹ̀, kódà àwọn ará ilé ẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan dalẹ̀ ẹ̀. (1 Sám. 19:10, 11; 2 Sám. 15:10-14, 30) Nígbà kan, ó sọ pé: “Àárẹ̀ ti mú mi nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi; láti òru mọ́jú ni omijé mi ń rin ibùsùn mi gbingbin; ẹkún mi ti fi omi kún àga tìmùtìmù mi.” (Sm. 6:6) Láìka gbogbo ìṣòro tí Dáfídì ní sí, ó dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Ó sọ pé: “Jèhófà yóò gbọ́ igbe ẹkún mi.” (Sm. 6:8) Ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì mọ bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa. Ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń gba omijé ẹ̀ sínú ìgò kan tàbí tó ń kọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i sínú ìwé kan. Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sóun, ó sì mọ ẹ̀dùn ọkàn òun. Dáfídì mọ̀ pé kì í ṣe pé Jèhófà mọ gbogbo nǹkan tójú òun ti rí nìkan ni, ó tún mọ bó ṣe rí lára òun. w24.12 22 ¶11-12
Tuesday, September 1
Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́.—2 Kọ́r. 13:5.
A gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ká sì máa tẹ̀ síwájú. Kò yẹ ká dára wa lójú jù, ká wá máa rò pé òtítọ́ ti jinlẹ̀ nínú wa. (1 Kọ́r. 10:12) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká “máa dán ara [wa] wò,” ká sì rí i pé à ń tẹ̀ síwájú. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa, ká sì máa tẹ̀ síwájú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti di Kristẹni tó dàgbà di géńdé, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe máa ronú bí àwọn èèyàn ayé ṣe ń ronú. (Kól. 2:6-10) Épáfírásì tó mọ àwọn ará ìjọ dáadáa máa ń gbàdúrà nígbà gbogbo pé “níkẹyìn, kí [wọ́n] lè dúró ní pípé” tàbí kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. (Kól. 4:12) Kí la rí kọ́? Pọ́ọ̀lù àti Épáfírásì mọ̀ pé ká tó lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, àfi kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́, káwa fúnra wa sapá gan-an, ká sì máa tẹ̀ síwájú. Torí náà, ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé kí òtítọ́ máa jinlẹ̀ nínú àwọn ará Kólósè, kí wọ́n sì di Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí láìka ìṣòro tí wọ́n ní sí. w24.04 6-7 ¶16-17