Monday, December 2
Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure.—Kól. 4:6.
Tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ máa sọ òótọ́. (Òwe 6:16, 17) Lónìí, àwọn èèyàn máa ń parọ́, wọn ò sì róhun tó burú níbẹ̀. Àmọ́, kò yẹ káwa máa parọ́ torí Jèhófà kórìíra irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Sm. 15:1, 2) Yàtọ̀ sí pé kò yẹ ká máa parọ́, kò tún yẹ ká máa fi òótọ́ pa mọ́ torí pé ìyẹn lè ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Kò sì yẹ ká máa sọ̀rọ̀ àwọn èèyàn láìdáa. (Òwe 25:23; 2 Tẹs. 3:11) Torí náà, tí ìwọ àti ẹnì kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ tó fẹ́ máa ṣòfófó ẹnì kan, o lè fọgbọ́n yí ọ̀rọ̀ náà pa dà, kẹ́ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ tó máa gbéni ró. Nínú ayé táà ń gbé lónìí, àwọn èèyàn máa ń sọ̀sọkúsọ gan-an. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká sì rí i pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa ń múnú Jèhófà dùn. Ó dájú pé ó máa bù kún wa tó bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, nígbà tá a bá wà nípàdé àti nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà bá pa ayé búburú yìí run, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa yìn ín lógo.—Júùdù 15. w22.04 9 ¶18-20
Tuesday, December 3
A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.—1 Jòh. 4:19.
Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà àti Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, àwa náà máa nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Jòh. 4:10) Ìfẹ́ tá a ní fún wọn jinlẹ̀ sí i nígbà tá a mọ̀ pé torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jésù ṣe kú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó sì fi hàn pé òun mọyì ohun tí Jésù ṣe nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn ará Gálátíà, ó ní: “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, [ó] sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gál. 2:20) Ẹbọ ìràpadà Jésù yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti pè ẹ́ wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀, kó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ṣé inú ẹ ò dùn nígbà tó o mọ̀ pé ohun tó dáa tí Jèhófà rí lára ẹ ló mú kó pè ẹ́ àti pé nǹkan ńlá ni Jèhófà san kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti di ọ̀rẹ́ ẹ̀? Ṣé ìyẹn ò mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àti Jésù pọ̀ sí i? Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Kí ni ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí mi máa sọ ọ́ di dandan pé kí n ṣe?’ Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Jésù ń jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.—2 Kọ́r. 5:14, 15; 6:1, 2. w23.01 28 ¶6-7
Wednesday, December 4
Màá yí èdè àwọn èèyàn pa dà sí èdè mímọ́.—Sef. 3:9.
Ipa kékeré kọ́ ni Bíbélì ń kó láti mú káwa èèyàn Jèhófà máa “sìn ín ní ìṣọ̀kan.” Jèhófà jẹ́ kí àwọn tó kọ Bíbélì kọ ọ́ lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ nìkan ló lè lóye ẹ̀. (Lúùkù 10:21) Ibi gbogbo láyé làwọn èèyàn ti máa ń ka Bíbélì. Àmọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ nìkan ló ń lóye ohun tó wà nínú ẹ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó sọ. (2 Kọ́r. 3:15, 16) Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà. Jèhófà máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti kọ́ gbogbo àwa èèyàn ẹ̀ lápapọ̀, ó sì tún máa ń lò ó láti tọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sọ́nà, kó sì tù wá nínú. Tá a bá ń ka Bíbélì, a máa ń rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Àìsá. 30:21) Ṣé gbogbo ìgbà lo máa ń ka Bíbélì, tó o wá ka ẹsẹ kan, tó sì dà bíi pé torí ẹ gan-an ni wọ́n ṣe kọ ọ́? Àmọ́, àìmọye èèyàn ló tún ń jàǹfààní Bíbélì. Kí ló jẹ́ kí àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì bóde mu, tó sì ń ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní? Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé Ẹni tó gbọ́n jù lọ láyé àti lọ́run ló ni Bíbélì.—2 Tím. 3:16, 17. w23.02 4-5 ¶8-10