-
Jẹ́nẹ́sísì 41:48, 49Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
48 Ó sì ń kó gbogbo oúnjẹ jọ ní ilẹ̀ Íjíbítì fún ọdún méje náà, ó ń kó oúnjẹ pa mọ́ sí àwọn ìlú. Ó máa ń kó àwọn irè oko agbègbè ìlú kọ̀ọ̀kan pa mọ́ sí ìlú náà. 49 Jósẹ́fù sì ń kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà pa mọ́, ó pọ̀ bí iyanrìn etíkun, débi pé wọn ò lè wọ̀n ọ́n torí kò ṣeé wọ̀n mọ́.
-