12Jèhófà sì sọ fún Ábúrámù pé: “Kúrò ní ilẹ̀ rẹ, kí o kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ àti ilé bàbá rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.+2 Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá, màá sì bù kún ọ. Màá mú kí orúkọ rẹ di ńlá, ó sì máa jẹ́ ìbùkún.+
5 Kí o kéde níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Ará Arémíà tó ń lọ káàkiri* ni bàbá mi,+ ó lọ sí Íjíbítì,+ ó sì di àjèjì tó ń gbé níbẹ̀, òun àti àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará ilé rẹ̀.+ Àmọ́ ibẹ̀ ló ti di orílẹ̀-èdè ńlá, tó lágbára, tó sì pọ̀ rẹpẹtẹ.+