2 Ábúráhámù sọ fún ìránṣẹ́ tó dàgbà jù nínú agbo ilé rẹ̀, tó sì ń bójú tó gbogbo ohun ìní+ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, 3 mo fẹ́ kí o fi Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀run àti Ọlọ́run ayé búra, pé o ò ní fẹ́ ìyàwó fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì tí mò ń gbé+ láàárín wọn.