-
Jẹ́nẹ́sísì 11:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ni Jèhófà bá lọ wo ìlú náà àti ilé gogoro tí àwọn ọmọ èèyàn kọ́.
-
-
Ẹ́kísódù 3:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Jèhófà sì sọ pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ igbe wọn torí àwọn tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́; mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora.+ 8 Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+
-
-
Sáàmù 14:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Àmọ́ Jèhófà ń bojú wo àwọn ọmọ èèyàn láti ọ̀run
Láti rí i bóyá ẹnì kan wà tó ní ìjìnlẹ̀ òye, bóyá ẹnì kan wà tó ń wá Jèhófà.+
-