11 Bó ṣe fẹ́ wọ Íjíbítì, ó sọ fún Sáráì ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Mo mọ̀ pé o rẹwà gan-an lóbìnrin.+12 Tí àwọn ará Íjíbítì bá sì rí ọ, ó dájú pé wọ́n á sọ pé, ‘Ìyàwó rẹ̀ nìyí.’ Wọ́n á pa mí, àmọ́ wọ́n á dá ọ sí.
7 Tí àwọn ọkùnrin ibẹ̀ bá ń béèrè nípa ìyàwó rẹ̀, ó máa ń sọ pé: “Àbúrò+ mi ni.” Ẹ̀rù ń bà á láti sọ pé “Ìyàwó mi ni,” nítorí ó sọ pé, “Àwọn ọkùnrin ibẹ̀ lè pa mí torí Rèbékà,” torí ó rẹwà gan-an.+