Jẹ́nẹ́sísì 3:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 Inú òógùn ojú rẹ ni wàá ti máa jẹun títí wàá fi pa dà sí ilẹ̀, torí inú rẹ̀ lo ti wá.+ Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.”+ Sáàmù 146:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Ẹ̀mí* rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sínú ilẹ̀;+Ọjọ́ yẹn gan-an ni èrò inú rẹ̀ ṣègbé.+ Oníwàásù 9:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Nítorí àwọn alààyè mọ̀* pé àwọn máa kú,+ àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá,+ wọn kò sì ní èrè* kankan mọ́, nítorí pé wọ́n ti di ẹni ìgbàgbé.+ Oníwàásù 9:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú,*+ ibi tí ìwọ ń lọ. Ìsíkíẹ́lì 18:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Wò ó! Gbogbo ọkàn,* tèmi ni wọ́n. Bí ọkàn bàbá ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ. Ọkàn* tó bá ṣẹ̀ ni yóò kú. Róòmù 5:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀+—. 1 Kọ́ríńtì 15:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Nítorí bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú nínú Ádámù,+ bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.+
19 Inú òógùn ojú rẹ ni wàá ti máa jẹun títí wàá fi pa dà sí ilẹ̀, torí inú rẹ̀ lo ti wá.+ Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.”+
5 Nítorí àwọn alààyè mọ̀* pé àwọn máa kú,+ àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá,+ wọn kò sì ní èrè* kankan mọ́, nítorí pé wọ́n ti di ẹni ìgbàgbé.+
10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú,*+ ibi tí ìwọ ń lọ.
4 Wò ó! Gbogbo ọkàn,* tèmi ni wọ́n. Bí ọkàn bàbá ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ. Ọkàn* tó bá ṣẹ̀ ni yóò kú.
12 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀+—.