8 Ìgbàgbọ́ mú kí Ábúráhámù+ ṣègbọràn nígbà tí a pè é, ó lọ sí ibì kan tó máa gbà, tó sì máa jogún; ó jáde lọ, bí kò tiẹ̀ mọ ibi tó ń lọ.+ 9 Ìgbàgbọ́ mú kó máa gbé bí àjèjì ní ilẹ̀ ìlérí, bíi pé ó jẹ́ ilẹ̀ àjèjì,+ ó ń gbé inú àgọ́ + pẹ̀lú Ísákì àti Jékọ́bù, àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ajogún ìlérí kan náà.+