30 Bí Ísákì ṣe súre fún Jékọ́bù tán, tí Jékọ́bù sì kúrò lọ́dọ̀ Ísákì bàbá rẹ̀ ni Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dé láti oko ọdẹ.+ 31 Òun náà se oúnjẹ tó dùn, ó gbé e wá fún bàbá rẹ̀, ó sì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dìde, kí o sì jẹ lára ẹran ìgbẹ́ tí ọmọ rẹ pa, kí o lè súre fún mi.”